ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 3/15 ojú ìwé 12-14
  • Wò Ó! Àgbàyanu Ni Ìmọ́lẹ̀ Náà!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wò Ó! Àgbàyanu Ni Ìmọ́lẹ̀ Náà!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìwọ Ti Fi Ìfẹ́ Tí Ìwọ Ní ní Àkọ́kọ́ Sílẹ̀”
  • ‘Òtítọ́ Tó Dá Wa Sílẹ̀ Lómìnira’
  • Ìmọ́lẹ̀ sí Òpópónà Wa
  • Ẹ Máa Tàn bí Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé
  • ‘Ra Oògùn Ojú Láti Fi Pa Ojú Rẹ’
  • Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run Ń lé Òkùnkùn Dà Nù!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Imọlẹ Ti Wá Sinu Aye”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ Tẹle Ìmólẹ̀ Ayé Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Ẹ Gbé Awọn Ohun Ija Imọlẹ Wọ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 3/15 ojú ìwé 12-14

Wò Ó! Àgbàyanu Ni Ìmọ́lẹ̀ Náà!

ǸJẸ́ o ti gba ibi tó ṣókùnkùn rí, tó jẹ́ pé ńṣe lò ń táràrà láti mọ ibi tí wàá gbà kọjá? Tó bá ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí, ó dájú pé wàá mọ bó ṣe nira tó. Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí tẹ́nì kan bá tanná kó o lè ríran? Kò sí àní-àní pé inú ẹ á dùn gan-an! Ó ṣeé ṣe kó o ti wà nínú ipò kan rí tó dà bí ìgbà téèyàn wà nínú òkùnkùn. Bóyá ńṣe lo bá ara rẹ nínú ìṣòro kan tí o ò sì mọ ọ̀nà àbáyọ. Ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe, Ọlọ́run bá ẹ ṣé, o rọ́nà àbáyọ. Ńṣe ló máa dà bí ìgbà tẹ́ni tó wà nínú òkùnkùn biribiri wá bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀. Ohun àgbàyanu gbáà ni!

Láyé ìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, inú òkùnkùn tẹ̀mí ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn wà, ìyẹn ni pé wọn ò ní ìmọ̀ Ọlọ́run. Nínú ìwé tí àpọ́sítélì Pétérù kọ sáwọn tó kúrò nínú ẹ̀sìn wọn wá sínú ẹ̀sìn Kristẹni, ó ní: “[Ọlọ́run] pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:9) Lójú àwọn wọ̀nyí, ńṣe ni dídi tí wọ́n di Kristẹni dà bíi pé wọ́n kúrò nínú òkùnkùn biribiri, tí wọ́n wá wá síbi tó mọ́lẹ̀ rekete. A tún lè fi ipò wọn wé ìgbà tẹ́nì kan wà lóun nìkan láìní ìrètí kankan, àmọ́ tó wá di ara àwọn tó ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la.—Éfésù 2:1, 12.

“Ìwọ Ti Fi Ìfẹ́ Tí Ìwọ Ní ní Àkọ́kọ́ Sílẹ̀”

Àwọn Kristẹni ìjímìjí rí “òtítọ́,” ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. (Jòhánù 18:37) Wọ́n rí àgbàyanu ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú òtítọ́, wọ́n sì kúrò nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn kan tí ìtara wọn ń jó lala bí iná nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni wá dẹni tí ò nítara mọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó máa fi di ìparí ọ̀rúndún kìíní, ìṣòro ńlá kan ti yọ́ wọnú ìjọ tó wà ní Éfésù. Jésù Kristi tó ti jíǹde tó sì ti lọ sọ́run sọ ohun tí ìṣòro náà jẹ́, ó ní: “Mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀. Nítorí náà, rántí inú ohun tí o ti ṣubú, kí o sì ronú pìwà dà, kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ ti ìṣáájú.” (Ìṣípayá 2:4, 5) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ní láti mú kí iná ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àti fún òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run padà máa jó bíi ti ìṣáájú.

Àwa náà ńkọ́ lóde òní? Àwa náà ti rí ìmọ́lẹ̀, a ti mọ àgbàyanu òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nǹkan ayọ̀ lèyí sì jẹ́ fún wa. A ti dẹni tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Àmọ́ àwọn ohun kan wà tó lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún òtítọ́ lọ sílẹ̀. Lára àwọn ohun náà ni onírúurú ìṣòro tó ń bá ẹ̀dá èèyàn fínra. Àwọn mìíràn ni àwọn ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. À ń gbé nínú ayé tí ‘àwọn àkókò ti le koko tó sì nira láti bá lò.’ Àwọn èèyàn tó sì kúnnú ayé ọ̀hún jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin.” (2 Tímótì 3:1, 2) Tí ìwà wọn bá lọ ràn wá, ó lè mú kí ìtara wa jó àjórẹ̀yìn, ó sì tún lè bomi paná ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà.

Tó bá jẹ́ pé a ti fi ìfẹ́ tá a ní nígbà tá a kọ́kọ́ mọ òtítọ́ sílẹ̀, ó yẹ ká ‘rántí inú ohun tá a ti ṣubú, ká sì ronú pìwà dà.’ Ó yẹ ká padà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí bíi tìgbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tá a bá sì ti ń ṣe dáadáa, ó yẹ ká ṣọ́ra kí ìfẹ́ tá a ní fún òtítọ́ má padà di tútù. Ó ṣe pàtàkì gan-an ká má ṣe tìtorí ìṣòro inú ayé sọ̀rètí nù tàbí ká bọkàn jẹ́, dípò ìyẹn ńṣe ni ká jẹ́ kí iná ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti fún òtítọ́ máa jó lala!

‘Òtítọ́ Tó Dá Wa Sílẹ̀ Lómìnira’

Àgbàyanu ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì nítorí pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì-pàtàkì tọ́mọ aráyé ò rí ojútùú rẹ̀ fún àìmọye ọdún. Lára àwọn ìbéèrè ọ̀hún ni: Kí nìdí téèyàn fi wà nílé ayé? Torí kí ni Ọlọ́run ṣe dá wa? Kí nìdí tí nǹkan burúkú fi máa ń ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ èèyàn ṣì máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn téèyàn bá ti kú? Jèhófà ti là wá lóye nípa nǹkan wọ̀nyí, ó ti jẹ́ ká mọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jẹ́ àgbàyanu òtítọ́. Ǹjẹ́ kò yẹ ká dúpẹ́ fún gbogbo ìmọ̀ tá a ti ní yìí? Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká di abaraámóorejẹ.

Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Ẹbọ ìràpadà tí Jésù fi ara rẹ̀ rú ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Bákan náà ni àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye wọ̀nyí ṣe dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú àìmọ̀kan àti ipò àìdánilójú inú ayé tí òkùnkùn tẹ̀mí bò yìí. Tá a bá mọrírì àwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ wọ̀nyí tá a sì ń ronú lé wọn lórí, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀ á máa jinlẹ̀ sí i.

Nínú ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà, ó ní: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹ̀lú nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Àwọn ará Tẹsalóníkà gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì “tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà . . . pẹ̀lú ìdùnnú.” Wọ́n ò sí “nínú òkùnkùn” mọ́. Wọ́n ti di “ọmọ ìmọ́lẹ̀.” (1 Tẹsalóníkà 1:4-7; 5:4, 5) Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, pé òun ni Ọlọ́run Olódùmarè, pé ó jẹ́ ọlọgbọ́n, onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú. Wọ́n tún wá mọ̀, bí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi mìíràn náà ṣe mọ̀, pé Jèhófà ti ṣètò bó ṣe máa pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ fi ara rẹ̀ rú.—Ìṣe 3:19-21.

Òótọ́ ni pé àwọn ará Tẹsalóníkà ò mọ gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì tán, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé ibẹ̀ làwọn ti lè gba ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ìwé Mímọ́ tó ní ìmísí Ọlọ́run lè mú kéèyàn Ọlọ́run “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà lè máa kẹ́kọ̀ọ́ síwájú àti síwájú sí i, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n máa rí i pé àgbàyanu ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo èyí jẹ́ ìdí tó fi yẹ kínú wọn máa dùn nígbà gbogbo. (1 Tẹsalóníkà 5:16) Bó sì ṣe yẹ kó rí fáwa náà nìyẹn.

Ìmọ́lẹ̀ sí Òpópónà Wa

Onísáàmù sọ ìdí kan tí ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi jẹ́ àgbàyanu, ó ní: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Ìtọ́sọ́nà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń fún wa ń jẹ́ ká lè mọ ọ̀nà tó yẹ ká tọ̀ nígbèésí ayé tá ò fi ní ko ìṣòro, àti bá a ó ṣe gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀. Kò yẹ ká dà bí ọkọ̀ òkun tí omi ń gbé lọ. Tá a bá mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a sì ń fi sílò, a ò ní dẹni “tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́.”—Éfésù 4:14.

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jékọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.” (Sáàmù 146:3, 5) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a ò ní máa bẹ̀rù, a ò sì ní máa ṣàníyàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kí ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣamọ̀nà wa!

Ẹ Máa Tàn bí Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé

Ohun mìíràn tó mú kí ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ àgbàyanu ni pé ó jẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù láyé. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Kí Jésù tó pa àṣẹ yẹn, ó kọ́kọ́ sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 28:18-20.

Ìwọ ronú nípa àwọn tó ń ti àwọn Kristẹni tòótọ́ lẹ́yìn nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere àti iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun máa wà pẹ̀lú wọn. Jésù ò sì fi wọ́n sílẹ̀ lóòótọ́, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń jẹ́ ‘kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn’ nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù náà àti nípa ṣíṣe “àwọn iṣẹ́ àtàtà” mìíràn. (Mátíù 5:14-16) Àwọn áńgẹ́lì pàápàá ń ṣe nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere yìí. (Ìṣípayá 14:6) Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ńkọ́, ǹjẹ́ òun náà ń ṣe nínú iṣẹ́ náà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.” Ẹ ò rí i pé iyì ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”!—1 Kọ́ríńtì 3:6, 9.

Ìwọ tún ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe ń bù kún wa bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ yìí. Kò sóhun tá a lè fi wé àǹfààní tí Ọlọ́run fún wa láti máa ‘tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé.’ Gbígbé tá à ń gbé ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yọ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa ń ṣèrànwọ́ gidi fún àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́. (Fílípì 2:15) Ó yẹ kínú wa máa dùn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ wíwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ni lójú méjèèjì, ‘nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tá a fi hàn fún orúkọ rẹ̀.’—Hébérù 6:10.

‘Ra Oògùn Ojú Láti Fi Pa Ojú Rẹ’

Jésù ránṣẹ́ sí ìjọ Laodíkíà ní ọ̀rúndún kìíní, ó ní: “Ra . . . oògùn ojú láti fi pa ojú rẹ, kí o bàa lè ríran. Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, tí mo sì ń bá wí.” (Ìṣípayá 3:18, 19) Kí ojú ẹni tí kò ríran nípa tẹ̀mí tó lè là, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ lo “oògùn ojú,” ìyẹn ni pé kó gba àwọn ẹ̀kọ́ àti ìbáwí Jésù. Tá a bá fẹ́ jẹ́ ẹni tó gbó ṣáṣá nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Jésù, ká sì máa tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Bíbélì. A tún gbọ́dọ̀ ní irú ẹ̀mí tí Kristi ní, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Fílípì 2:5; 1 Pétérù 2:21) Ọ̀fẹ́ kọ́ ni oògùn ojú tí Jésù sọ yìí o. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: ‘Rà á lọ́dọ̀ mi.’ Àkókò tá a máa lò lórí àwọn ohun tó dà bí oògùn ojú yìí àti akitiyan wa lórí rẹ̀ ni owó tá a máa san.

Tá a bá kúrò níbi tó ṣókùnkùn tá a sì bọ́ síbi tó mọ́lẹ̀ rekete, ó lè ṣe díẹ̀ kí ojú wa tó padà sípò tàbí ká tó lè ríran dáadáa. Bákan náà, ó gba àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì rí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́. Ó gba àkókò láti ṣe àṣàrò lórí àwọn nǹkan tá a kọ́, ó sì tún gba àkókò láti ronú lórí bí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà ṣe ṣeyebíye tó. Àmọ́ gbogbo ìyẹn náà ò tíì pọ̀ jù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àgbàyanu ni ìmọ́lẹ̀ náà!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

‘Ra oògùn ojú lọ́dọ̀ mi láti fi pa ojú rẹ, kí o bàa lè ríran’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́