ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 7/1 ojú ìwé 3-4
  • Ǹjẹ́ O Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Ń Wá Ìbàlẹ̀ Ọkàn
  • lbo Lo Ti Lè Rí Ìbàlẹ̀ Ọkàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ǹjẹ́ O Lè Ní Àlàáfíà Nínú Ayé Oníwàhálà Yìí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jòhánù 14:27—“Alaafia Ni Mo Fi Sílẹ̀ Fun Yín”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Àlàáfíà​—Báwo Lo Ṣe Lè Ní In?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 7/1 ojú ìwé 3-4

Ǹjẹ́ O Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn?

Ní ọdún 1854 lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà nì, Henry Thoreau, kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló ń gbé ìgbésí ayé àìnírètí, tí wọn kò sì fọhùn.”

Ó dájú pé, nígbà ayé rẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ni kò ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Àmọ́, ìyẹn ti ń lọ sí nǹkan bí àádọ́jọ ọdún sẹ́yìn báyìí. Ṣé nǹkan ti wá yàtọ̀ lóde òní ni? Àbí àwọn ọ̀rọ̀ Thoreau ṣì bóde òní mu? Ìwọ gan-an alára ńkọ́? Ṣé ọkàn rẹ balẹ̀? Àbí o ò láàbò, tí ọjọ́ ọ̀la ò sì dá ọ lójú, táa bá sì tún ọ̀rọ̀ Thoreau sọ lọ́nà mìíràn, ṣé o ò kì í ṣe ‘aláìnírètí tí kò lè fọhùn’?

Ó ṢENI láàánú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà láyé tí kì í jẹ́ kí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀. Ẹ jẹ́ ká mẹ́nu ba díẹ̀ níbẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àìríṣẹ́ṣe àti owó táṣẹ́rẹ́ tí ń wọlé ń fa ipò òṣì, tó sì ń yọrí sí àìnírètí nínú ọ̀ràn àtijẹ àtimu. Ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọ̀pọ̀ ló máa ń fi gbogbo agbára wọn wá ọrọ̀ àti àwọn nǹkan ìní ti ara kiri. Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbésí ayé ìbára-ẹni-díje máa ń fa hílàhílo dípò àlàáfíà. Bákan náà ni àìsàn, ogun, ìwà ọ̀daràn, ìrẹ́nijẹ, àti ìninilára kì í fọkàn àwọn èèyàn balẹ̀.

Wọ́n Ń Wá Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Ọ̀pọ̀ ni ọ̀ràn bí ilé ayé ṣe ń lọ kò tẹ́ lọ́rùn rárá. Ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ńlá kan ní São Paulo, nílùú Brazil ni Antônio.a Pẹ̀lú ìrètí pé òun lè tún ipò nǹkan ṣe, ó kópa nínú fífi ẹ̀hónú hàn, ó sì báwọn ṣe ìwọ́de, síbẹ̀, èyí kò fi í lọ́kàn balẹ̀.

Àwọn kan rò pé ìgbéyàwó yóò jẹ́ kí àwọn tiẹ̀ ní ìbàlẹ̀ ọkàn díẹ̀ nínú ìgbésí ayé, àmọ́ ìyẹn náà tún lè já wọn kulẹ̀. Oníṣòwò kan tó ti rí towó ṣe ni Marcos. Ó kópa nínú ìṣèlú ó sì di olórí ìlú ńlá kan tí ilé iṣẹ́ pọ̀ sí. Àmọ́, ilé rẹ̀ kò tòrò rárá. Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò nílé, òun àti aya rẹ̀ pínyà nítorí àwọn èdè àìyedè tí wọn ò lè yanjú.

Gerson, ọmọ asùnta kan ní Salvador, Brazil, fẹ́ ṣe ohun tẹ́nì kan ò ṣe rí. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ti ìlú kan dé ìlú kejì nìyẹn, tó ń gán àwọn ọkọ̀ akẹ́rù kiri. Kò pẹ́ tó fi di ajoògùnyó, tó ń jáwó lọ́wọ́ àwọn èèyàn kó lè máa rówó ra oògùn olóró. Àìmọye ìgbà làwọn ọlọ́pàá ti mú un. Pẹ̀lú gbogbo bí Gerson ṣe jẹ́ oníjàgídíjàgan àti oníwà ipá tó yẹn, ó tún ń wá ìbàlẹ̀ ọkàn. Ǹjẹ́ ó lè rí i?

Ìgbà tí Vania ṣì wà lọ́mọdé ni ìyá rẹ̀ ti kú, tó fi jẹ́ pé Vania ni gbogbo iṣẹ́ ilé wá já lé léjìká, títí kan títọ́jú àbúrò rẹ̀ obìnrin tó ń ṣàìsàn. Vania ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ ni pé Ọlọ́run ti pa òun tì. Ó dájú gbangba pé ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ rárá.

Marcelo náà tún wà níbẹ̀. Gbogbo ohun tí Marcelo ń wá ni pé kí òun sáà máa ṣe ọmọ jayéjayé kiri. Ó fẹ́ràn àríyá ṣíṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ mìíràn—kí wọ́n máa jó, kí wọ́n máa mutí, kí wọ́n sì máa lo oògùn líle. Ìgbà kan wà tó jà, tó sì pa ọ̀dọ́ mìíràn lára. Níkẹyìn, ó kábàámọ̀ ohun tó ṣe, ó sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. Òun náà ń wá ìbàlẹ̀ ọkàn.

Àwọn ìrírí wọ̀nyí fi àwọn ipò tí kì í mú kí ọkàn ẹni balẹ̀ hàn. Ǹjẹ́ ọ̀nà èyíkéyìí ha wà tí ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́, òṣèlú, ọmọ asùnta, ọmọbìnrin tó ń ṣe àṣekúdórógbó iṣẹ́, àti ẹni tó ń ṣe ọmọ jayéjayé kiri fi lè rí ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n ń wá? Ǹjẹ́ a lè rí ohunkóhun kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn? Bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè méjèèjì, bí a ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ṣé ó wù ọ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́