ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 11/15 ojú ìwé 21-23
  • Fi Ẹ̀mí Ìmúratán Sin Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ẹ̀mí Ìmúratán Sin Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọn Ò Tiẹ̀ Fẹ́ Sìn Rárá
  • Iṣẹ́ Ìsìn Táa Ṣe Tinútinú La Béèrè
  • Iṣẹ́ Ìsìn Táa Ń Lọ́ra Ṣe Ńkọ́?
  • Ní Inú Dídùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
  • ‘Ẹ̀mí Ń Hára Gàgà, Ṣùgbọ́n Ẹran Ara Ṣe Aláìlera’
  • Iwọ Yoo Ha Dahun Pada Si Ifẹ Jesu Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kí Lo Máa Yááfì Kó O Lè Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • “Ọ̀fẹ́ Ni Ẹ̀yin Gbà, Ọ̀fẹ́ Ni Kí Ẹ Fúnni”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ta Ni Yóò Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 11/15 ojú ìwé 21-23

Fi Ẹ̀mí Ìmúratán Sin Ọlọ́run

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá fún ọkàn yín.” (2 Kọ́ríńtì 12:15) Kí làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń sọ fún ọ nípa ojú ìwòye àti irú ẹ̀mí tó yẹ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbìyànjú láti ní? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ohun tó ń sọ ni pé: “Mo múra tán láti ná okun mi, àti àkókò mi, àti ìgbésí ayé mi, àti gbogbo ohun tí mo ní fún ire yín, bí baba kan ṣe ń fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ṣe nǹkan fún àwọn ọmọ rẹ̀.” Pọ́ọ̀lù ti múra tán láti “ná” ara rẹ̀ “tán pátápátá,” tàbí láti “lo gbogbo okun rẹ̀, kí àárẹ̀ sì mú un,” tó bá jẹ́ pé ohun tí mímú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni rẹ̀ ṣẹ máa gbà nìyẹn.

Láfikún sí i, “tayọ̀tayọ̀” ni Pọ́ọ̀lù ṣe gbogbo èyí. Ó “múra tán pátápátá” láti ṣe bẹ́ẹ̀, ni The Jerusalem Bible sọ. Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o múra tán láti lo àkókò rẹ, agbára rẹ, ẹ̀bùn rẹ, àti ohun ìní rẹ fún sísin Jèhófà Ọlọ́run àti fún ire àwọn ẹlòmíràn, bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ máa mú ọ “lo gbogbo okun rẹ, kí àárẹ̀ sì mú ọ” lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pàápàá? Ṣé wàá sì ṣe èyí “tayọ̀tayọ̀”?

Wọn Ò Tiẹ̀ Fẹ́ Sìn Rárá

Kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń lọ́ra láti sin Ọlọ́run nìkan ni, àmọ́ wọn kò tiẹ̀ fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹ̀mí tí wọ́n ní jẹ́ ti àìmoore, ti ìmọtara-ẹni-nìkan, kódà ti ìṣọ̀tẹ̀ pàápàá. Sátánì sún Ádámù àti Éfà láti ronú nírú ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Ó fi àìtọ́ sọ pé wọn yóò “dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú”—wọn ó lè máa fúnra wọn pinnu ohun tó dára àti ohun tó burú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Àwọn tó ní irú ẹ̀mí kan náà lónìí ronú pé ó yẹ káwọn ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n láìní ojúṣe kankan níwájú Ọlọ́run tàbí kí wọ́n tiẹ̀ gbàṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 81:11, 12) Wọ́n fẹ́ lo gbogbo ohun tí wọ́n ní láti lépa ire ti ara wọn nìkan.—Òwe 18:1.

Ó ṣeé ṣe kóo máà ní irú èrò burúkú yìí. Ó lè jẹ́ pé tinútinú ló fi mọyì ẹ̀bùn ìwàláàyè tóo ń gbádùn nísinsìnyí àti àgbàyanu ìrètí ti wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:10, 11; Ìṣípayá 21:1-4) O lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an nítorí oore tó ṣe fún ọ. Àmọ́, gbogbo wa gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí ewu náà pé Sátánì lè gbé ìrònú wa gbòdì ní irú ọ̀nà tó jẹ́ pé iṣẹ́ ìsìn wa lè di èyí tí Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà mọ́ ní ti gidi. (2 Kọ́ríńtì 11:3) Báwo lèyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?

Iṣẹ́ Ìsìn Táa Ṣe Tinútinú La Béèrè

Iṣẹ́ ìsìn táa ṣe tinútinú àti tọkàntọkàn ni Jèhófà fẹ́. Kò fagbára mú wa láti ṣe ìfẹ́ òun rí. Sátánì ló máa ń ta gbogbo ọgbọ́n láti fagbára mú àwọn èèyàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú sísin Ọlọ́run, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe, àwọn àṣẹ, ohun tí a béèrè, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Oníwàásù 12:13; Lúùkù 1:6) Síbẹ̀ lájorí ohun tó ń jẹ́ ká sin Ọlọ́run ni ìfẹ́ táa ní fún un.—Ẹ́kísódù 35:21; Diutarónómì 11:1.

Bó ti wù kí Pọ́ọ̀lù ná ara rẹ̀ tó nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó mọ̀ pé èyí ò já mọ́ nǹkan kan rárá ‘bí òun kò bá ní ìfẹ́.’ (1 Kọ́ríńtì 13:1-3) Nígbà tí àwọn tó kọ Bíbélì ń tọ́ka sí àwọn Kristẹni gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrú Ọlọ́run, kì í ṣe fífi agbára múni sìnrú ni wọ́n ń tọ́ka sí. (Róòmù 12:11; Kólósè 3:24) Ohun tó túmọ̀ sí ni yíyọ̀ǹda ara ẹni tinútinú, tó sinmi lórí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ látọkànwá fún Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi.—Mátíù 22:37; 2 Kọ́ríńtì 5:14; 1 Jòhánù 4:10, 11.

Iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run tún gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ táa ní fún àwọn ènìyàn hàn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.” (1 Tẹsalóníkà 2:7) Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lóde òní, òfin ìjọba sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn ìyá láti tọ́jú àwọn ọmọ wọn. Àmọ́, ó dájú pé ọ̀pọ̀ jù lọ ìyá ló jẹ́ pé kì í ṣe tìtorí àtipa òfin mọ́ nìkan ni wọ́n ṣe ń ṣe èyí, àbí bẹ́ẹ̀ ni? Ó tì o. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n mọyì àwọn ọmọ wọn. Ìdí nìyẹn tí abiyamọ ṣe ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀! Nítorí pé Pọ́ọ̀lù ní “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” bákan náà fún àwọn tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún, ó ‘dùn mọ́ ọn nínú jọjọ’ (“múra tán,” King James Version; “ní inú dídùn,” New International Version) láti fi ìwàláàyè tiẹ̀ gan-an ràn wọ́n lọ́wọ́. (1 Tẹsalóníkà 2:8) Ìfẹ́ ń sún wa láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù.—Mátíù 22:39.

Iṣẹ́ Ìsìn Táa Ń Lọ́ra Ṣe Ńkọ́?

Àmọ́ ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ táa ní fún ara wa pọ̀ ju èyí táa ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ewu wà pé a lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn tí kò tọkàn wa wá, táa kàn ń lọ́ra ṣe. A tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí kanra, ká máa bínú pé a ò lè gbé ìgbésí ayé wa bó ṣe wù wá. Èyí ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi mélòó kan tí wọn ò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run mọ́, àmọ́ tí wọ́n ṣì ń fi ẹ̀mí iṣẹ́-yìí-ò-ṣeé-yẹ̀-sílẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ ìsìn kan sí i. Kí ni àbájáde rẹ̀? Sísin Ọlọ́run wá di “ìdánilágara” lójú wọn.—Málákì 1:13.

Ọrẹ ẹbọ èyíkéyìí tí wọ́n bá mú wá fún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí “ara rẹ̀ dá ṣáṣá,” tí kò ní àbùkù, tó “dára jù lọ” lára ohun tí wọ́n ní. (Léfítíkù 22:17-20; Ẹ́kísódù 23:19) Àmọ́, kàkà tí wọn ì bá fi fún Jèhófà ní èyí tó dára jù lọ nínú àwọn ẹran wọn, àwọn èèyàn ọjọ́ Málákì bẹ̀rẹ̀ sí fún un ní àwọn nǹkan táwọn fúnra wọn ò fẹ́. Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ó sọ fún àwọn àlùfáà pé: “Nígbà tí ẹ bá . . . mú ẹran tí ó fọ́jú wá fún fífi rúbọ [ẹ ó sọ pé]: ‘Kì í ṣe ohun tí ó burú.’ Nígbà tí ẹ bá sì mú ẹran tí ó yarọ tàbí aláìsàn wá: ‘Kì í ṣe ohun tí ó burú.’ Jọ̀wọ́, mú un wá sọ́dọ̀ gómìnà rẹ. Yóò ha ní inú dídùn sí ọ, tàbí yóò ha fi inú rere gbà ọ́? . . . Ẹ sì ti mú ohun tí a fà ya wá, àti èyí tí ó yarọ, àti aláìsàn; bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ti mú un wá bí ẹ̀bùn. Èmi ha lè ní ìdùnnú nínú rẹ̀ ní ọwọ́ yín bí?”—Málákì 1:8, 13.

Báwo lèyí ṣe lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lára wa? Ẹbọ wa lè di “ìdánilágara” lójú wa bí a kò bá ní ọkàn-àyà àti ẹ̀mí tó múra tán. (Ẹ́kísódù 35:5, 21, 22; Léfítíkù 1:3; Sáàmù 54:6; Hébérù 13:15, 16) Fún àpẹẹrẹ, ṣé èyí táa lò kù nínú àkókò wa ni à ń lò fún Jèhófà?

Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ronú pé Ọlọ́run yóò tẹ́wọ́ gbà á, bí mẹ́ńbà ìdílé kan tó jẹ́ onínúure tàbí ọmọ Léfì kan tó jẹ́ onítara bá fagbára mú ọmọ Ísírẹ́lì kan láti fi èyí tó dára jù lọ nínú ẹran rẹ̀ rúbọ nígbà tó jẹ́ pé kò wu onítọ̀hún gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀? (Aísáyà 29:13; Mátíù 15:7, 8) Jèhófà kọ irú ẹbọ bẹ́ẹ̀, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó kọ àwọn tó ń rú àwọn ẹbọ ọ̀hún pẹ̀lú.—Hóséà 4:6; Mátíù 21:43.

Ní Inú Dídùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

Ká tó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn tí Ọlọ́run yóò tẹ́wọ́ gbà, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi. Ó sọ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mo ń wá, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 5:30) Jésù rí ayọ̀ ńlá nínú fífi tinútinú sin Ọlọ́run. Jésù mú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Dáfídì ṣẹ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.”— Sáàmù 40:8.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Jésù dùn láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà, síbẹ̀ èyí kò fi gbogbo ìgbà rọrùn. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ kété ṣáájú ìgbà tí wọ́n mú un, tí wọ́n dán an wò, tí wọ́n sì pa á, yẹ̀ wò. Nígbà tí Jésù wà nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó ní “ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi,” ó sì wà “nínú ìroragógó.” Ẹ̀dùn ọkàn náà le débi pé bó ṣe ń gbàdúrà, “òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.”—Mátíù 26:38; Lúùkù 22:44.

Èé ṣe tí Jésù fi ní irú ìroragógó bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé kì í ṣe nítorí ire ara rẹ̀ tàbí nítorí pé ó ń lọ́ra láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó múra tán láti kú, kò tiẹ̀ gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” (Mátíù 16:21-23) Ohun tó ká Jésù lára ni bí ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn táa tẹ́ńbẹ́lú ṣe máa rí lára Jèhófà àti ipa tó máa ní lórí orúkọ mímọ́ Rẹ̀. Jésù mọ̀ pé yóò dun Jèhófà ládùnwọra láti rí ìwà òkú òǹrorò tí wọ́n hù sí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.

Jésù tún mọ̀ pé àkókò tó le koko jù lọ nínú ìmúṣẹ àwọn ète Jèhófà lòun ń sún mọ́. Fífi ìṣòtítọ́ pa òfin Ọlọ́run mọ́ yóò fi hàn láìsí iyèméjì rárá pé Ádámù náà lè ṣe irú yíyàn kan náà tó bá fẹ́ ṣe é. Ìdúróṣinṣin Jésù yóò fi hàn pé irọ́ ńlá ni gbogbo ohun tí Sátánì sọ pé àwọn èèyàn kò lè fi tinútinú àti tòótọ́tòótọ́ sin Ọlọ́run lábẹ́ àdánwò. Jèhófà yóò tipasẹ̀ Jésù tẹ Sátánì rẹ́ níkẹyìn, yóò sì mú gbogbo ipa tí ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ti ní kúrò.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.

Ẹ ò rí i pé ẹrù iṣẹ́ ńlá ló já lé Jésù léjìká yìí! Orúkọ Baba rẹ̀, àlàáfíà gbogbo ayé, àti ìgbàlà ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, gbogbo rẹ̀ sinmi lórí ìdúróṣinṣin Jésù. Mímọ̀ tó mọ èyí ló mú kó gbàdúrà pé: “Baba mi, bí ó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá lọ. Síbẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́.” (Mátíù 26:39) Kódà nínú másùnmáwo tó lé kenkà, Jésù kò fìgbà kan jáwọ́ nínú mímúra tí ó múra tán láti ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀.

‘Ẹ̀mí Ń Hára Gàgà, Ṣùgbọ́n Ẹran Ara Ṣe Aláìlera’

Níwọ̀n bí Jésù ti ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ tó báyẹn nítorí pé ó ń sin Jèhófà, a lè retí pé Sátánì yóò gbé ìṣòro ka àwa táa jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run níwájú. (Jòhánù 15:20; 1 Pétérù 5:8) Láfikún sí i, aláìpé ni wá. Nítorí náà, báa tilẹ̀ ń fi tinútinú sin Ọlọ́run, kò lè jẹ́ pẹ̀lú gbẹ̀fẹ́. Jésù rí i bí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe ń là kàkà láti ṣe gbogbo ohun tó ní kí wọ́n ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” (Mátíù 26:41) Kò sí ohun tó jọ àìlera rárá nínú ẹran ara pípé rẹ̀. Àmọ́, ohun tó ní lọ́kàn ni àìlera ti ẹran ara àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn àìpé tí wọ́n jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Jésù mọ̀ pé nítorí àìpé tí wọ́n jogún àti, bí ìyẹn ṣe wá jẹ́ kó ní ibi tí agbára wọ́n mọ, wọ́n ní láti làkàkà láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Nítorí náà, a lè ní irú ìmọ̀lára kan náà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní, ẹni tó jẹ́ pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi nígbà tí àìpé ń ká a lọ́wọ́ kò láti sin Ọlọ́run dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí.” (Róòmù 7:18) Àwa náà rí i pé a kì í lè ṣe gbogbo ohun rere táa fẹ́ ṣe tán pátápátá. (Róòmù 7:19) Èyí kì í ṣe nítorí pé a ń lọ́ tìkọ̀. Ó wulẹ̀ jẹ́ nítorí àìlera ara wa tó máa ń dí wa lọ́wọ́ láti sapá dé ibi tí a fẹ́ ṣe é dé ni.

Ẹ má ṣe jẹ́ kí a sọ̀rètí nù. Táa bá fi tọkàntọkàn múra tán láti ṣe gbogbo ohun táa bá lè ṣe, ó dájú pé Ọlọ́run yóò tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn wa. (2 Kọ́ríńtì 8:12) Ǹjẹ́ kí a ‘sa gbogbo ipá wa’ láti fara wé ẹ̀mí tí Kristi ní tó fi yọ̀ǹda ara rẹ̀ pátápátá láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (2 Tímótì 2:15; Fílípì 2:5-7; 1 Pétérù 4:1, 2) Jèhófà yóò san èrè fún irú ẹ̀mí ìmúratán bẹ́ẹ̀, yóò sì tì í lẹ́yìn. Yóò fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti ṣe ohun tí àìlera wa kò jẹ́ kí a ṣe. (2 Kọ́ríńtì 4:7-10) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwa náà yóò ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù ní ‘fífi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná wa tán pátápátá’ nínú iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀ tó ṣeyebíye.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Pọ́ọ̀lù fi tinútinú sin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kódà nínú másùnmáwo tó lé kenkà, Jésù ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́