ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 7/1 ojú ìwé 32
  • Èrò Tí Kì í Kúrò Lọ́kàn Ẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èrò Tí Kì í Kúrò Lọ́kàn Ẹni
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 7/1 ojú ìwé 32

Èrò Tí Kì í Kúrò Lọ́kàn Ẹni

ỌDỌỌDÚN làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kóra jọ sí àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ Kristẹni tí wọ́n máa ń ṣe lórílẹ̀-èdè tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọ́n bá wà. Wọ́n máa ń ṣe èyí láti gbádùn àwọn ìtọ́ni tí ń gbéni ró nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì bára wọn kẹ́gbẹ́ pọ̀. Àmọ́, àwọn apá mìíràn nínú ìpàdé náà tún lè jẹ́ káwọn àlejò ní èrò tí kì í kúrò lọ́kàn ẹni.

Fún àpẹẹrẹ, ní July 1999, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Mòsáńbíìkì ló kóra jọ fún ọjọ́ mẹ́ta dídùn yùngbà tí wọ́n fi ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa wá sí àpéjọpọ̀ nìyẹn. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń gbọ́ lórí pèpéle nìkan ló mórí wọn wú bí kò ṣe ohun tí wọ́n rí láyìíká wọn.

Ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Maputo ni pé: “Mi ò tíì rí ibi tó lẹ́wà tó báyìí rí láyé mi! Ọṣẹ àti dígí wà nílé ìtura, òórùn tó dáa ló sì ń tibẹ̀ jáde. Gbogbo àyíká náà ló tòrò minimini láìsí ariwo àwọn ọmọdé tó ń bára wọn jà. Kò sí pé ẹnì kan ń ti ẹnì kejì! Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tínú wọn ń dùn, tí wọ́n sì ń bára wọn sọ̀rọ̀ ìṣírí. Ohun tó tún wú mi lórí ni bí olúkúlùkù ṣe múra nigínnigín. Tó bá dìgbà mìíràn, màá mú àwọn ọmọ mi wá, màá sì jẹ́ kí ọkọ mi mọ̀ pé ó yẹ kí ìdílé wa wà níbi àpéjọpọ̀ yìí.”

Ó dájú pé àwọn èèyàn ń kíyè sí àìṣàbòsí, ìwà títọ́ àti ìmọ́tónítóní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ló fà á táwọn Ẹlẹ́rìí fi yàtọ̀? Ìdí ni pé wọ́n ń fi tòótọ́tòótọ́ gbìyànjú láti fi ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. O ò ṣe dara pọ̀ mọ́ wọn lọ́dún yìí láwọn àpéjọpọ̀ tí wọ́n ń ṣe kárí orílẹ̀-èdè rẹ tàbí láwọn ìpàdé wọn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò rẹ, kóo lè fojú ara rẹ rí i?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

ZAMBIA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

KẸ́ŃYÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

MÒSÁŃBÍÌKÌ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́