Ó “Fara Dà Á Dé Òpin”
LYMAN Alexander Swingle sọ nínú fídíò kan táa ṣe ní 1993, táa ń fi han àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di mẹ́ńbà orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé, nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tóun rawọ́ lé yìí sẹ́, “Orí iṣẹ́ laago ń kú sí!”a
Arákùnrin Swingle tó jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ṣe ohun náà gan-an tó fáwọn ẹlòmíì níṣìírí láti ṣe. Ó “fara dà á dé òpin.” (Mátíù 24:13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ kò yá, ó ṣì bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèpàdé lọ́jọ́ Wednesday, March 7. Nígbà tó máa fi di Tuesday tó tẹ̀ lé e, àìsàn ọ̀hún ti wọ̀ ọ́ lára gan-an, nígbà tó sì di aago mẹ́rin kọjá ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ní ìdájí March 14, dókítà rẹ̀ kéde pé ó ti kú.
Lyman Swingle bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, ní April 5, 1930. Ó sìn níbẹ̀ fún ohun tó fi díẹ̀ dín ní ọdún mọ́kànléláàádọ́rin. Ibi ìdìwépọ̀ ni iṣẹ́ táa kọ́kọ́ yan Arákùnrin Swingle sí, lẹ́yìn náà ló ṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, ó tún bá wọn ṣiṣẹ́ nídìí ṣíṣe yíǹkì. Àní, Arákùnrin Swingle lo nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nídìí ṣíṣe yíǹkì. Ó tún sìn fún nǹkan bí ogún ọdún ní ẹ̀ka ìwé kíkọ ní orílé iṣẹ́. Ọ́fíìsì Akápò ló ti ṣiṣẹ́ ní ọdún mẹ́tàdínlógún tó lò gbẹ̀yìn láyé.
Arákùnrin Swingle jẹ́ ẹni tó fi àìṣojo pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Ní àwọn ọdún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Brooklyn, òun àti Arthur Worsley tí wọ́n jọ ń gbé yàrá, máa ń tu ọ̀kan lára ọkọ̀ ojú omi àwọn Ẹlẹ́rìí ní Odò Hudson. Wọ́n máa ń lo ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní ọ̀pọ̀ òpin ọ̀sẹ̀ láti fi kéde ìhìn rere Ìjọba náà fún àwọn tí ń gbé létí omi.
November 6, 1910, ni wọ́n bí Arákùnrin Swingle nílùú Lincoln, ní Ìpínlẹ̀ Nebraska, ṣùgbọ́n láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni ìdílé wọn ṣí lọ sí Salt Lake City, ní Ìpínlẹ̀ Utah. Níbẹ̀, ní 1913, làwọn òbí rẹ̀ ti di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, agboolé Swingle gba ọ̀pọ̀ àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tó wá láti orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ní Brooklyn lálejò, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sì ní ipa rere lórí Lyman. Ọdún 1923, nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, ló ṣèrìbọmi láti fi hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
Lẹ́yìn tí Arákùnrin Swingle sìn gẹ́gẹ́ bí àpọ́n fún nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ní Brooklyn, ayé rẹ wá túbọ̀ dùn bí oyin nígbà tó gbé Crystal Zircher níyàwó ní June 8, 1956. Wọn kì í ya ara wọn, ṣe ni wọ́n jọ ń jáde òde ẹ̀rí kó tó di pé Crystal kú ní 1998. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ṣáájú ìgbà yẹn ni àrùn ẹ̀gbà kọlu Crystal, tó sì sọ ọ́ di abirùn. Bí Arákùnrin Swingle ṣe ń tọ́jú rẹ̀ lójoojúmọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó wúni lórí, àgàgà fún àwọn tó máa ń rí Arákùnrin Swingle bó ṣe ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ti àga onítáyà tí Crystal wà nínú rẹ̀ gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tó wà ládùúgbò, níbi tí Crystal ti ń fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ èrò ọ̀nà.
Arákùnrin Swingle jẹ́ ẹni tó lọ́yàyà, tí kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tó sì jẹ́ adùn-únbárìn. Gẹ́gẹ́ bíi ti bàbá àti ìyá rẹ̀, ó ní ìrètí táa gbé ka Bíbélì láti wà pẹ̀lú Jésù Kristi nínú Ìjọba ọ̀run, ó sì dá wa lójú pé ìrètí yẹn á ti tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ báyìí.—1 Tẹsalóníkà 4:15-18; Ìṣípayá 14:13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí túmọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́ títí dọjọ́ ikú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Arákùnrin Swingle lo nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nídìí ṣíṣe yíǹkì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Lyman àti Crystal kì í ya ara wọn