“Ọjọ́ Ìfàyègba Ẹ̀sìn Mìíràn”
Ọ̀GÁ iléèwé kan ní Poland, tí ìjíròrò tó ní pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wú u lórí gan-an, ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ tó pè ní “Ọjọ́ Ìfàyègba Ẹ̀sìn Mìíràn” níléèwé rẹ̀. Obìnrin yìí dá a lábàá pé kí àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn lára àwọn ọmọléèwé òun tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹlẹ́sìn Búdà, àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, múra láti ṣe àlàyé ṣókí fáwọn ọmọléèwé yòókù nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ojú ẹsẹ̀ làwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yọ̀ǹda ara wọn.
Nígbà tí ọjọ́ náà kò, Malwina ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Ara ohun tí ọmọbìnrin náà sọ rèé: “Ọ̀pọ̀ nínú yín ló mọ̀ wá kó tó di pé a wọ iléèwé yìí, nítorí pé a máa ń wá yín wá sílé. Ẹ lè má mọ ìdí tá a fi ń wá yín wá sílé ṣáá. Ìdí ni pé a ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, tí í ṣe Olùdásílẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni. Gbogbo ibi táwọn èèyàn bá wà ló ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe iṣẹ́ kan náà yìí. Ọ̀pọ̀ ibi làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fojú winá àdánwò ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n inú wa dùn pé àlàáfíà wà níléèwé tiwa, ọlá yín náà ni. Ẹ ṣeun wa o!”
Nígbà tí Malwina fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Ìdí míì tún wà tá a fi ń wá yín wá sílé. A bìkítà nípa yín. Bíbélì sọ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mi ayé jìgìjìgì yóò wáyé láìpẹ́. Nítorí náà, nígbà tá a bá tún wá sílé yín, ẹ jọ̀wọ́ ẹ má ṣàì fetí sí wa. A fẹ́ sọ fún yín nípa bí gbogbo wa yóò ṣe jùmọ̀ wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.”
Mateusz lẹni tó sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lòun náà. Mateusz sọ fáwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé onírúurú ọ̀nà làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gbà wàásù ìhìn rere náà bí ọdún ti ń gorí ọdún. Fún àpẹẹrẹ, ní 1914—nígbà tí kò tíì sí sinimá tó ń gbé ohùn jáde—àwa Ẹlẹ́rìí ṣe “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá], tí í ṣe sinimá tó ní àwọn àwòrán ara ògiri nínú, tó tún ní ohùn tó ń dún lábẹ́lẹ̀.
Mateusz sọ nípa bá a ṣe fi rédíò wàásù ìhìn Ìjọba náà. Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tá a ń pè ní MEPS táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Ó tún ṣàlàyé bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran àwọn dókítà lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀. Ọmọkùnrin náà sọ pé: “Ní báyìí o, àwọn oníṣègùn jàǹkànjàǹkàn ní Poland sọ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ wa, wọ́n sì sọ pé lọ́dọọdún, àwọn aláìsàn púpọ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí làwọn ń ṣe iṣẹ́ abẹ fún láìlo ẹ̀jẹ̀.”
Nígbà tí Mateusz ń kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn nípa àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti kọ́, ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ óò fẹ́ láti wá sí tiwa? A kì í gbowó ìwọlé, a kì í sì í dáwó igbá.” Nígbà tí Mateusz ń sọ̀rọ̀ nípa ibi tá a ti ń ṣe àpéjọpọ̀ ní Sosnowiec, ó sọ pé: “Ó yẹ kẹ́ ẹ wá wo ilé ńlá tá a ń lò lọ́nà rere yìí. Ẹ ò ṣe jẹ́ ká jọ lọ? A fẹ́ dá àbá kan, Katarzyna ọ̀rẹ́ wa á sọ fún yín nípa àbá yẹn.”
Lẹ́yìn náà ni Katarzyna ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fi tìtara-tìtara sọ pé: “A fi tìfẹ́tìfẹ́ pè yín sí Sosnowiec, fún àpéjọpọ̀ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ó sọ ọ̀rọ̀ tó kan àwọn ọ̀dọ́ gbọ̀ngbọ̀n níbẹ̀.” Katarzyna tún mẹ́nu kan àṣeyẹ pàtàkì táwọn Kristẹni ń ṣe—ìyẹn, Ìṣe Ìrántí ikú Jésù Kristi. Ọmọbìnrin náà wá rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Lọ́dún tó kọjá, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlá tó pésẹ̀ síbi àṣeyẹ yìí kárí ayé. Ṣé ẹ máa wá sí èyí tó ń bọ̀?”
Nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ tán, Malwina, Mateusz, àti Katarzyna fún àwọn olùkọ́ wọn ní ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom àti kásẹ́ẹ̀tì amóhùnmáwòrán méjì tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.a Àwọn olùkọ́ náà fi tayọ̀tayọ̀ gbà wọ́n, wọ́n sì sọ pé àwọn máa lò wọ́n nígbà táwọn bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìtàn.
Láti kádìí ètò náà nílẹ̀, Martyna ọmọ ọdún méjìlá wá fi ohun èlò kọ orin tó ní àkọlé náà “A Dupẹ Lọwọ Rẹ, Jehofah” fún gbogbo àwọn tó péjú pésẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ‘máyà le nípasẹ̀ Ọlọ́run wọn,’ wọ́n sì jẹ́rìí lọ́nà tó múná dóko. (1 Tẹsalóníkà 2:2) Ẹ wo àpẹẹrẹ àtàtà tí èyí jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí níbi gbogbo!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Malwina rèé nígbà tó ń múra ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọjọ́ díẹ̀ kó tó sọ ọ̀rọ̀ náà níléèwé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Katarzyna ń wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa lò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀