ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 1/15 ojú ìwé 30-31
  • Igi Tó “Ń Sunkún” àti “Omijé” Rẹ̀ Tó Wúlò Púpọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Igi Tó “Ń Sunkún” àti “Omijé” Rẹ̀ Tó Wúlò Púpọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtàn Irúgbìn Kan Tó Níye Lórí Gan-an
  • Oje Tó Wúlò fún Gbogbo Nǹkan
  • Básámù Gílíádì Òróró Ìkunra Tó ń Woni Sàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bí Wọ́n Ṣe Ń Lo Ohun Ìṣaralóge Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 1/15 ojú ìwé 30-31

Igi Tó “Ń Sunkún” àti “Omijé” Rẹ̀ Tó Wúlò Púpọ̀

Jeremáyà 51:8 sọ pé: “Ẹ mú básámù fún ìrora.” Ibi tá a ti ń wá ọ̀kan lára orísun èròjà tó ń tuni lára tó sì ń woni sàn gan-an yìí kiri ni ọkàn wa ti lọ sí erékùṣù Kíósì, ní Òkun Aegean.

NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn àgbẹ̀ tó wà ní Kíósì máa ń múra sílẹ̀ de ìkórè lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Nígbà tí wọ́n bá gbálẹ̀ tán, wọ́n á fi amọ̀ funfun ṣe pèpéle pẹrẹsẹ kan yíká ohun ọ̀gbìn tí a ń pè ní igi olóje. Àwọn àgbẹ̀ ọ̀hún á wá ṣá èèpo igi náà, tí yóò mú kó máa “sunkún.” “Omijé” aláwọ̀ ṣíṣì tó jẹ́ oje rẹ̀ yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí sẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta, àwọn oje tó kán sílẹ̀ náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí dì, àwọn àgbẹ̀ náà yóò sì kó wọn jọ, yálà kí wọ́n kò ó láti ara igi náà fúnra rẹ̀ tàbí láti orí pèpéle pẹrẹsẹ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe sísàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn “omijé” wọ̀nyí tó ti dì pọ̀ láti ara igi olóje ni wọ́n fi ń ṣe básámù.

Àmọ́, ó gba ọ̀pọ̀ sùúrù àti iṣẹ́ àṣekára kí wọ́n tó lè kórè rẹ̀. Igi tí ara rẹ̀ lọ́ bìrìpà, tó sì ní àwọ̀ eérú yìí kì í tètè dàgbà. Ó máa ń gbà tó ogójì ọdún sí àádọ́ta ọdún kí igi kan tó ga dé ibi tó máa ga dé—tí ó sábà máa ń jẹ́ nǹkan bíi mítà méjì sí mẹ́ta.

Yàtọ̀ sí iṣẹ́ ṣíṣá igi náà àti kíkó “omijé” rẹ̀ jọ, iṣẹ́ tún ṣì wà láti ṣe kí wọ́n tó lè mú oje tí ń ta sánsán jáde. Lẹ́yìn táwọn àgbẹ̀ bá ti kó “omijé” náà jọ, wọ́n á sẹ́ ẹ, wọ́n á ṣàn án, wọ́n á wá fi bí wọ́n ṣe tóbi sí àti bí wọ́n ṣe dáa sí ṣà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á tún oje náà ṣàn, wọ́n á sì wá lò ó ní onírúurú ọ̀nà.

Ìtàn Irúgbìn Kan Tó Níye Lórí Gan-an

Ọ̀rọ̀ tí èdè Gíríìkì ń lò fún “oje tí ń ta sánsán” tan mọ́ ọ́rọ́ tó tú mọ̀ sí “ìpayínkeke.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé láti ìgbà láéláé ni wọ́n ti ń lo oje igi tí ń ta sánsán náà bíi ṣingọ́ọ̀mù kí òórùn tó dáa lè máa ti ẹnu èèyàn jáde.

Ìsọfúnni tó lọ́jọ́ lórí jù lọ nípa oje tí ń ta sánsán ọ̀hún ni èyí tí Herodotus, òpìtàn ará Gíríìsì nì, mu jáde ní ọ̀rúndún kárùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn mìíràn tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti oníṣègùn ìgbàanì—títí kan Apollodorus, Dioscorides, Theophrastus, àti Hippocrates—mẹ́nu kan lílo oje tí ń ta sánsán yìí fún ìṣègùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé igi olóje yìí máa ń hù ní gbogbo àyíká Etíkun Mẹditaréníà, láti nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa, síbẹ̀ àwọn ará Kíósì nìkan ló ń ṣe oje tí ń ta sánsán yìí. Oje tí ń ta sánsán yìí sì ni lájorí ohun tó wọ àwọn tó ṣẹ́gun àwọn ará Kíósì lójú, látorí àwọn ará Róòmù, títí dórí àwọn ará Genoa, àti àwọn Ottoman níkẹyìn.

Oje Tó Wúlò fún Gbogbo Nǹkan

Àwọn oníṣègùn ilẹ̀ Íjíbítì ayé ọjọ́un lo oje yìí fún ìtọ́jú onírúurú àìsàn, títí kan àrunṣu àti àrùn oríkèé-ara-ríro. Wọ́n tún lò ó gẹ́gẹ́ bíi tùràrí àti gẹ́gẹ́ bí èròjà tí wọ́n fi ń kun òkú lọ́ṣẹ. Igi olóje náà ti lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orísun ‘básámù ti Gílíádì,’ tí Bíbélì sọ nípa bó ṣe wúlò tó fún ìtọ́jú àìsàn àti bí wọ́n ṣe ń lò ó fún èròjà ìṣaralóge àti fún kíkun òkú lọ́ṣẹ. (Jeremáyà 8:22; 46:11) Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ara igi kan tó jẹ́ ẹ̀yà igi olóje ni èròjà sítákítè ti ń jáde, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe tùràrí mímọ́ onílọ́fínńdà, èyí tí wọ́n ń lò fún kìkì ohun mímọ́.—Ẹ́kísódù 30:34, 35.

Lóde òní, oje yìí wà nínú èròjà olómi tí ń mú nǹkan dán gbinrin, èyí tá a fi ń dáàbò bo àwọn àwòrán tá a fọ̀dà kùn, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti àwọn ohun èlò orin. Wọ́n tún ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń gba ooru mọ́ra àti ohun tí kì í jẹ́ kí omi wọnú nǹkan, wọ́n sì tún kà á sí ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń jẹ́ kí àwọ̀ dúró lára aṣọ tá a pa láró àti lára àwọn iṣẹ́ ọnà táwọn ayàwòrán ṣe. Wọ́n tún ti lo oje yìí nínú àwọn àtè àti nínú èròjà tí ń mú kí awọ di rírọ́. Wọ́n ń fi oje yìí ṣe ọṣẹ, èròjà ìṣaralóge àti lọ́fínńdà, nítorí òórùn dídùn rẹ̀ àti àwọn èròjà mìíràn tó ní.

Ọ̀nà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sọ pé àwọn ògbógi ti fọwọ́ sí pé a lè gbà lo oje tí ń ta sánsán yìí nínú iṣẹ́ ìṣègùn jákèjádò ayé. Wọ́n ṣì ń lò ó dáadáa nínú ìṣègùn àbáláyé láàárín àwọn Lárúbáwá. Wọ́n tún ń lo oje yìí nínú èròjà tí wọ́n fi ń dí ihò eyín àti nínú ohun tí wọ́n fi ń di àwọn oògùn oní-káńsù.

Ohun tó di básámù, ni “omijé” tó wúlò fún ọ̀pọ̀ nǹkan, tí igi olóje tí “ń sunkún” ń mú jáde. Wọ́n ti lò ó gẹ́gẹ́ bí amáratuni àti fún ìwòsàn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Abájọ tí àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà fi sọ pé: ‘Ẹ mú básámù fún ìrora.’

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíósì

Kíkórè oje tí ń ta sánsán náà

Ńṣe la ń fara balẹ̀ gba “omijé” igi olóje náà

[Àwọn Credit Line]

Àwòrán Kíósì àtàwọn olùkórè: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Ibi Ìkówèésí ti Korais; gbogbo àwọn tó kù: Kostas Stamoulis

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́