ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 1/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Ṣe Pàtàkì Gan-an fún Ọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Idi Ti Ounjẹ Alẹ́ Oluwa Fi Ní Itumọ Fun Ọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 1/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí”?

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìdásílẹ̀ Ìṣe Ìrántí ikú Jésù, ó kọ̀wé pé: “Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.” (1 Kọ́ríńtì 11:25, 26) Àwọn kan rò pé ọ̀rọ̀ náà “nígbàkúùgbà” tá a lò níhìn-ín túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ máa ṣe ìrántí ikú Kristi léraléra, ìyẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Ìdí nìyẹn tí iye ìgbà tí wọ́n máa ń ṣe ìrántí rẹ̀ lọ́dún fi ju ẹ̀ẹ̀kan lọ. Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn?

Ó ti ń lọ sí nǹkan bí ẹgbàá ọdún báyìí tí Jésù ti dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí náà, ṣíṣe Ìrántí náà lẹ́ẹ̀kan lọ́dún pàápàá túmọ̀ sí pé a ti ṣe é lọ́pọ̀ ìgbà láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Àmọ́, kì í ṣe iye ìgbà tó yẹ ká máa ṣe é ní Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú 1 Kọ́ríńtì 11:25, 26, bí kò ṣe bó ṣe yẹ ká máa ṣe Ìṣe Ìrántí náà gan-an. Nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, kò lo ọ̀rọ̀ náà pol·laʹkis, tó túmọ̀ sí “lọ́pọ̀ ìgbà” tàbí “léraléra.” Dípò ìyẹn, ọ̀rọ̀ náà ho·saʹkis ló lò, èyí tó túmọ̀ sí “nígbàkúùgbà,” ìyẹn ni pé “ìgbà yòówù,” “gbogbo ìgbà tí.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé: ‘Gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń ṣe èyí ńṣe lẹ̀ ń pòkìkí ikú Olúwa.’a

Báwo ló wá ṣe yẹ ká máa ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Jésù léraléra tó? Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ló yẹ ká máa ṣe é lọ́dún. Ìṣe ìrántí ni lóòótọ́, ọdọọdún la sì máa ń ṣe àwọn ohun ìrántí. Yàtọ̀ síyẹn, ọjọ́ àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Júù ni Jésù kú, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n sì máa ń ṣe é. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi pe Jésù ní “Kristi ìrékọjá wa,” níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ikú ìrúbọ tí Jésù kú ló ṣí ọ̀nà ìyè sílẹ̀ fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ Ìrékọjá àkọ́kọ́ pàá ṣe mú kí àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àbínibí bọ́ lọ́wọ́ ikú ní Íjíbítì, tó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún orílẹ̀-èdè náà láti kúrò lóko ẹrú. (1 Kọ́ríńtì 5:7; Gálátíà 6:16) Ìsopọ̀ tó ní pẹ̀lú Ìrékọjá ọdọọdún ti àwọn Júù yìí jẹ́ ẹ̀rí tó túbọ̀ mú un dáni lójú pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dún ló yẹ ká máa ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Jésù.

Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù tún so ikú Jésù pọ̀ mọ́ àjọ̀dún mìíràn táwọn Júù máa ń ṣe lọ́dọọdún, ìyẹn ni Ọjọ́ Ètùtù. A kà á nínú Hébérù 9:25, 26 pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe kí [Jésù] lè máa fi ara rẹ̀ rúbọ lọ́pọ̀ ìgbà, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà ti máa ń wọ ibi mímọ́ lọ ní tòótọ́ láti ọdún dé ọdún [ní Ọjọ́ Ètùtù] pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe tirẹ̀. . . . Ṣùgbọ́n nísinsìnyí láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípasẹ̀ ẹbọ òun fúnra rẹ̀, ó ti fi ara rẹ̀ hàn kedere ní ìparí àwọn ètò àwọn nǹkan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹbọ Jésù ló rọ́pò ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún, a jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ló yẹ ká máa ṣe Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ nìyẹn. Kò sí ẹ̀rí kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé ó yẹ ká máa ṣe Ìṣe Ìrántí náà léraléra ju ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún lọ.

Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, òpìtàn nì, John Laurence von Mosheim ròyìn pé ó jẹ́ àṣà àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kejì ní Éṣíà Kékeré láti máa ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Jésù “ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní àwọn Júù [ìyẹn Nísàn].” Àwọn ọdún ẹ̀yìn ìgbà náà ló ṣẹ̀ṣẹ̀ di pé Kirisẹ́ńdọ̀mù sọ ọ́ di àṣà láti máa ṣe é léraléra ju ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún lọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fi wé ìtàn tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 1:3, 7. Níbẹ̀, “nígbàkúùgbà” (nínú ìtumọ̀ èdè Hébérù òde òní) ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa ń wáyé “lọ́dọọdún,” tàbí lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, nígbà tí Ẹlikénà àti àwọn aya rẹ̀ méjèèjì bá lọ sí àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́