ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 1/15 ojú ìwé 4-7
  • Ṣé Èṣù Ti Borí Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Èṣù Ti Borí Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀dá Èèyàn Lè Ṣàkóso Ara Rẹ̀ Kó Sì Yọrí sí Rere?
  • Ǹjẹ́ Sátánì Lè Mú Kí Gbogbo Èèyàn Kẹ̀yìn sí Ọlọ́run?
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?
  • Ẹ̀yìn Ta Lo Máa Wà?
  • Àwọn Olùṣàkóso Ní Ilẹ̀-Àkóso Ẹ̀mí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìjìyà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ṣọ́ra! Sátánì Fẹ́ Pa Ọ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 1/15 ojú ìwé 4-7

Ṣé Èṣù Ti Borí Ni?

Ọ̀RÀN pé ìforígbárí kan ń lọ láyé lọ́run láàárín ibi àti ire ti mú kí àwọn òǹkọ̀wé àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí máa méfò lóríṣiríṣi látìgbà pípẹ́ wá. Àmọ́ o, ìwé kan wà tó ní àkọsílẹ̀ pípé pérépéré nípa ìforígbárí tó wáyé láàárín Ọlọ́run àti Èṣù. Bíbélì ni ìwé náà. Ó jẹ́ ká mọ ohun tó fa ìforígbárí náà ó sì tún jẹ́ ká mọ ẹni tó borí.

Kété lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ẹ̀dá ẹ̀mí kan, ìyẹn Sátánì Èṣù, sọ pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Ọ̀nà wo ló gbà sọ bẹ́ẹ̀? Nípa fífi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí sọ pé Ọlọ́run ò fún ìṣẹ̀dá rẹ̀ láwọn ohun rere tó yẹ wọ́n àti pé ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn á túbọ̀ rọ̀ ṣọ̀mù láìfi ti Ọlọ́run pè.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣípayá 12:9.

Nígbà tó yá, Sátánì tún gbé àríyànjiyàn mìíràn dìde lásìkò baba ńlá náà Jóòbù. Níbi tí Sátánì ti ń wọ́nà láti ba ìwà títọ́ Jóòbù sí Ọlọ́run jẹ́, ó sọ pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Ẹ ò rí i pé àríyànjiyàn ńlá gbáà lèyí jẹ́! Bí Sátánì kò ṣe dárúkọ Jóòbù níhìn-ín, ṣùgbọ́n tó lo ọ̀rọ̀ náà “èèyàn,” tó kan gbogbo ẹ̀dá, ńṣe ló tipa bẹ́ẹ̀ ń sọ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: ‘ohunkóhun tó bá gbà lèèyàn máa fún un láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Tí mo bá lè rí àyè rẹ̀, mo lè mú kí gbogbo èèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run.’

Láti mọ ẹni tó borí nínú ìforígbárí láàárín Ọlọ́run àti Èṣù, a gbọ́dọ̀ dáhùn ìbéèrè méjì yìí: Ǹjẹ́ ẹ̀dá èèyàn ti ṣàṣeyọrí nínú ṣíṣàkóso ara rẹ̀? Ǹjẹ́ ó ti ṣeé ṣe fún Èṣù láti kẹ̀yìn gbogbo èèyàn sí Ọlọ́run tòótọ́?

Ǹjẹ́ Ẹ̀dá Èèyàn Lè Ṣàkóso Ara Rẹ̀ Kó Sì Yọrí sí Rere?

Onírúurú ìṣàkóso ni ẹ̀dá èèyàn ti gbìyànjú wò láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá. Wọ́n ti gbìyànjú ìjọba àdáṣe, ìjọba tàwọn ọ̀tọ̀kùlú, ìjọba tiwa-n-tiwa, ìjọba tí gbogbo agbára á wà lọ́wọ́ ẹnì kan ṣoṣo, ìjọba oníkùmọ̀ àti ìjọba Kọ́múníìsì. Ǹjẹ́ bó ṣe di pé à ń gbìyànjú oríṣiríṣi ìjọba wò yìí kò ti fi hàn pé ṣíṣe ìjọba lónírúurú ọ̀nà wọ̀nyí kò pé ẹ̀dá èèyàn?

Ohun tí H. G. Wells kọ sínú ìwé A History of the World, tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1922, ni pé: “Àwọn ará Róòmù ò mọ̀gbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dán onírúurú ìṣàkóso wò.” Ó tún sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n ń pààrọ̀ ìjọba bí ẹní pààrọ̀ aṣọ, kò séyìí tó fìdí múlẹ̀ rí. Lọ́nà kan, pàbó ni gbogbo àyẹ̀wò tí wọ́n ń ṣe náà já sí. Lọ́nà mìíràn, wọn ò lè bá àyẹ̀wò náà débi kan tó ṣe sàn-án. Ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti Yúróòpù ṣì ń jà raburabu títí dòní olónìí láti wá ojútùú sáwọn ìṣòro tó wà nínú ṣíṣe ìjọba, èyí tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sáwọn ará Róòmù.”

Àṣà dídán onírúurú ìjọba wò yìí ṣì ń bá a lọ títí di àkókò tá a wà yìí. Ìjọba tiwa-n-tiwa gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta láwọn ọdún tó gbẹ̀yìn ọ̀rúndún ogún. Wọ́n sọ pé tẹrú tọmọ ló máa lẹ́nu ọ̀rọ̀ nínú ìjọba yìí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ìjọba tiwa-n-tiwa ti fi hàn pé ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn lè yọrí sí rere láìfi ti Ọlọ́run ṣe? Jawaharlal Nehru, tó jẹ́ olórí ìjọba ilẹ̀ Íńdíà tẹ́lẹ̀ sọ pé ìjọba tiwa-n-tiwa dára, àmọ́ ó fi kún un pé: “ìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn ọ̀nà ìṣèjọba tó kù burú bògìrì.” Valéry Giscard d’Estaing tí í ṣe ààrẹ ilẹ̀ Faransé tẹ́lẹ̀, sọ pé: “Wàhálà tá à ń rí báyìí ni tàwọn tó ń ṣojú fún àwọn aráàlú nínú ìjọba tiwa-n-tiwa.”

Kódà ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Tiwa, onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì nì, Plato rí i pé àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan wà nínú ìjọba tiwa-n-tiwa. Gẹ́gẹ́ bí ìwé A History of Political Theory, ṣe sọ, ó gbéjà ko “àìmọ̀kan àti àìtóótun àwọn olóṣèlú, èyí sì ni olórí àrùn tó ń bá ìjọba tiwa-n-tiwa jà.” Ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú òde òní ló ń kédàárò fún àìsí àwọn èèyàn tó gbọ́n nínú gbọ́n lẹ́yìn tó sì tóótun láti ṣèjọba. Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, sọ pé àwọn èèyàn “máa ń bínú nítorí àwọn alákòóso tó jọ pé wọn ò tóótun láti kojú àwọn ìṣòro tó bá jẹ yọ.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Ó máa ń rí wọn lára nígbà tí wọ́n bá ń retí káwọn aṣáájú tọ́ wọn sọ́nà àmọ́ tó jẹ́ pé ìwà àìnípinnu àti ìwà ìbàjẹ́ ni wọ́n bá lọ́wọ́ wọn.”

Wàyí o, wá gbé ìṣàkóso Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì yẹ̀ wò. Jèhófà Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n tí kò láfiwé. (1 Àwọn Ọba 4:29-34) Báwo ni nǹkan ṣe rí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láàárín ogójì ọdún tí Sólómọ́nì fi ṣàkóso? Bíbélì dáhùn pé “Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà lẹ́bàá òkun nítorí tí wọ́n jẹ́ ògìdìgbó, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀.” Àkọsílẹ̀ náà tún sọ pé: “Júdà àti Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀, láti Dánì dé Bíá-ṣébà, ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì.” (1 Àwọn Ọba 4:20, 25) Bó ṣe jẹ́ pé ọlọgbọ́n ọba tó ṣe é fojú rí, tó ń ṣojú fún Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Alákòóso Gíga Jù Lọ téèyàn ò lè rí, ló ń ṣàkóso lé wọn lórí, nǹkan tòrò ní orílẹ̀-èdè náà, aásìkí ń bẹ, ayọ̀ sì wà níbẹ̀.

Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìṣàkóso èèyàn àti ìṣàkóso Ọlọ́run kì í ṣe kékeré! Ǹjẹ́ a rí ẹni tó lè fi òótọ́ inú sọ pé Sátánì ti borí nínú ọ̀ràn ìṣàkóso? Rárá o, nítorí wòlíì Jeremáyà ti sọ ọ́ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

Ǹjẹ́ Sátánì Lè Mú Kí Gbogbo Èèyàn Kẹ̀yìn sí Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ Sátánì ti ṣàṣeyọrí láti mú kí gbogbo èèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ? Ní orí kọkànlá ìwé Hébérù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dárúkọ àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dáyé. Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Àkókò kì yóò tó fún mi bí mo bá ń bá a lọ láti ṣèròyìn nípa Gídíónì, Bárákì, Sámúsìnì, Jẹ́fútà, Dáfídì, àti Sámúẹ́lì àti àwọn wòlíì yòókù.” (Hébérù 11:32) Pọ́ọ̀lù pe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ní “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀.” (Hébérù 12:1) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò fún “àwọsánmà” níhìn-ín kò túmọ̀ sí àwọsánmà kéréje kan, tá a lè sọ pé bó ti tóbi tó àti bó ṣe rí rèé, bí kò ṣe ìṣùpọ̀ tó ṣú dùdù tá ò lè sọ bó ṣe rí ní pàtó. Èyí sì bá a mú rẹ́gí nítorí pé láyé àtijọ́, ńṣe làwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run pọ̀ débi pé wọ́n dà bí ìṣùpọ̀ àwọsánmà. Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo àwọn ọ̀rúndún tó kọjá làwọn èèyàn tí iye wọn ò lóǹkà ti lo òmìnira wọn láti jọ́sìn ẹni tó wù wọ́n, wọ́n sì fi òmìnira yìí yàn láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run.—Jóṣúà 24:15.

Báwo lọ̀ràn ṣe rí lákòókò tá a wà yìí náà? Iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà láìfi inúnibíni tó kọjá sísọ àti àtakò tá a ti ṣe sí wọn ní ọ̀rúndún ogún pè. Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́sàn-án mìíràn ló tún ń dara pọ̀ mọ́ wọn, ọ̀pọ̀ lára àwọn yìí ò sì tíì ṣèpinnu gúnmọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ọ̀dọ̀ Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ìyẹn Jésù Kristi la ti lè rí ìdáhùn sí ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ pé òun lè kẹ̀yìn gbogbo èèyàn sí Ọlọ́run. Kódà ìrora ńláǹlà tó ní nígbà tí wọ́n kàn án mọ́gi kò ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́. Nígbà tí Jésù mí èémí àmígbẹ̀yìn, ó kígbe pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.”—Lúùkù 23:46.

Sátánì pa gbogbo itú ọwọ́ rẹ̀—látorí àdánwò títí dorí inúnibíni tó hàn sójútáyé—láti kó ẹ̀dá èèyàn sábẹ́ ara rẹ̀. Ó ń fi “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” dán àwọn èèyàn wò láti tàn wọ́n kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. (1 Jòhánù 2:16) Sátánì tún ti ‘fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi má bàa mọ́lẹ̀ dé inú wọn.’ (2 Kọ́ríńtì 4:4) Bẹ́ẹ̀ ni Sátánì ò jáfara láti lo ìhalẹ̀mọ́ni àti ìbẹ̀rù èèyàn kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun tó ń fẹ́.—Ìṣe 5:40.

Àmọ́ o, Èṣù ò lè borí àwọn tó wà níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn wọ̀nyí ti mọ Jèhófà Ọlọ́run wọ́n sì ti ‘nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú wọn.’ (Mátíù 22:37) Dájúdájú, ìdúróṣinṣin Jésù Kristi tí mìmì kan ò lè mì àti ti àìmọye ẹ̀dá èèyàn mìíràn ti mú kí Sátánì Èṣù pòfo nínú ìjà tó ń jà.

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?

Ṣé títí ayé ni ẹ̀dá èèyàn á fi máa torí ìjọba kan bọ́ sórí òmíràn ni? Wòlíì Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba tí Ọlọ́run ọ̀run gbé kalẹ̀ ni ìjọba tó wà lọ́run èyí tí Jésù Kristi ń ṣàkóso rẹ̀. Ìjọba yìí kan náà ni Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà fún. (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba náà máa pa gbogbo ìjọba ẹ̀dá èèyàn run nígbà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè [tó ń bọ̀ lọ́nà],” gbogbo orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé ló sì máa kàn.—Ìṣípayá 16:14, 16.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì? Bíbélì ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú yìí, ó ní: “[Áńgẹ́lì Jèhófà] sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ó tì í, ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin.” (Ìṣípayá 20:1-3) Ẹ̀yìn ìgbà tá a bá fi Sátánì sọ̀kò sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, ìyẹn ibi tí ò ti ní lè ta pútú, ni Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù Kristi yóò bẹ̀rẹ̀.

Ayé á mà dùn nígbà náà o! Ìwà ibi àtàwọn ẹni ibi á ti lọ tèfètèfè. Bíbélì ṣèlérí pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:9-11) Kò sóhun tó máa dún mọ̀huru mọ̀huru mọ́ wọn mọ́—ì báà jẹ́ látọ̀dọ̀ èèyàn tàbí ẹranko. (Aísáyà 11:6-9) Kódà, gbogbo ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí àìmọ̀kan tàbí àìní àǹfààní láti mọ Jèhófà mú kí wọ́n wà lẹ́yìn Èṣù nígbà ayé wọn, la máa jí dìde tí wọ́n á sì gba ẹ̀kọ́ Ọlọ́run.—Ìṣe 24:15.

Nígbà tó bá fi máa di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba náà, gbogbo ilẹ̀ ayé á ti di párádísè ẹlẹ́wà, ìran èèyàn á sì ti padà dé ìjẹ́pípé. A óò wá tú Sátánì sílẹ̀ fun “ìgbà díẹ̀,” lẹ́yìn náà la óò pa àtòun àti gbogbo àwọn tí kò tẹ́wọ́ gba ìṣàkóso Ọlọ́run run títí láé.—Ìṣípayá 20:3, 7-10.

Ẹ̀yìn Ta Lo Máa Wà?

Ọ̀rúndún ogún jẹ́ àkókò tí Sátánì dìídì hùwà láabi ọwọ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, gbogbo èyí kò fi hàn pé ó ti borí o, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló jẹ́ àmì pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé búburú yìí. (Mátíù 24:3-14; Ìṣípayá 6:1-8) Kì í ṣe bí ìwà láabi ṣe pọ̀ tó láyé tàbí ohun tó jẹ́ èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ ẹni tó borí. Ohun tó máa jẹ́ ká mọ ẹni tó borí ni ẹni tí ìṣàkóso rẹ̀ dára jù lọ àti bóyá a ti ráwọn èèyàn tí ìfẹ́ ti sún láti jọ́sìn Ọlọ́run. Àbájáde àwọn kókó méjèèjì yìí ti fi hàn pé Jèhófà ló borí.

Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni àkókò tí Ọlọ́run yọ̀ǹda ti fi hàn pé Sátánì kò lè rọ́wọ́ mú, kí ló wá dé tí Ọlọ́run ò tíì mú ìwà ibi kúrò? Jèhófà ń ṣe sùúrù “nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ìfẹ́ Ọlọ́run ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Nítorí náà, gbìyànjú láti fi àkókò tó ṣẹ́ kù kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o sì ‘gba ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú àti ti ẹni tó rán jáde, Jésù Kristi.’ (Jòhánù 17:3) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ yìí kí ìwọ náà lè dara pọ̀ mọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó wà lọ́dọ̀ ẹni tó ń ja àjàṣẹ́gun.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ fẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run ti borí Sátánì nípa pípa ìwà títọ́ wọn mọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀pọ̀ jaburata àwọn adúróṣinṣin ló wà lọ́dọ̀ Jèhófà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́