ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 7/15 ojú ìwé 3
  • Ǹjẹ́ a Lè Dá Wà Láìfi Tàwọn Ẹlòmíràn Ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ a Lè Dá Wà Láìfi Tàwọn Ẹlòmíràn Ṣe?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Ìdánìkanwà Túbọ̀ Ń Burú Sí I—Kí Ni Bíbélì Sọ
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ẹ̀dùn Ọkàn Lóríṣiríṣi
    Jí!—2001
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Bá Lómìnira Àtijáde Bíi Ti Tẹ́lẹ̀
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìdí Tá Ò Fi Lè Dá Wà Láìfi Tàwọn Ẹlòmíràn Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 7/15 ojú ìwé 3

Ǹjẹ́ a Lè Dá Wà Láìfi Tàwọn Ẹlòmíràn Ṣe?

ÌLÚMỌ̀Ọ́KÁ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nì, Albert Einstein, sọ pé: “Tá a bá fojú ṣùnnùkùn wo ìgbésí ayé wa àtàwọn ohun tá à ń gbé ṣe, àá rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tá à ń ṣe àtèyí tó wà lọ́kàn wa láti ṣe ni ò sọ́gbọ́n tá a fi lè ṣe wọ́n láìjẹ́ pé a fi tàwọn ẹlòmíràn ṣe.” Ó tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “À ń jẹ oúnjẹ táwọn ẹlòmíràn gbọ́, aṣọ táwọn ẹlòmíràn ṣe là ń wọ̀, à ń gbénú ilé táwọn ẹlòmíràn kọ́. . . . Ohun yòówù kí ẹnì kan jẹ́ tàbí bó ti wù kí ẹnì kan jẹ́ èèyàn pàtàkì tó kì í ṣe nítorí pé ó ń yara rẹ̀ láṣo bí kò ṣe nítorí pé àwọn èèyàn ló fi bora bí aṣọ. Àwọn èèyàn yìí ló sì ń nípa lórí rẹ̀ yálà nípa tara tàbí ní ti ìlànà ẹ̀sìn, láti kékeré títí tá a fi máa wọ sàréè.”

Lágbo àwọn ẹranko, a sábà máa ń rí i tí wọ́n ń ṣe ara wọn ní òṣùṣù ọwọ̀. Ńṣe làwọn erin máa ń kọ́wọ̀ọ́ rìn, tí wọ́n sì máa ń jùmọ̀ dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Àwọn abo kìnnìún máa ń ṣọdẹ pọ̀, tí wọ́n á sì jùmọ̀ jẹ oúnjẹ tí wọ́n bá rí pẹ̀lú àwọn akọ. Ńṣe làwọn ẹja òbéjé máa ń ṣeré pọ̀ ní tiwọn, kódà wọ́n tiẹ̀ ti dáàbò bo àwọn ẹranko mìíràn àtàwọn òmùwẹ̀ tómi fẹ́ gbé lọ pàápàá.

Àmọ́ láàárín àwọn ẹ̀dá èèyàn, àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ti ṣàkíyèsí àṣà kan tó ti bẹ̀rẹ̀ sí kọni lóminú báyìí. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn kan tí wọ́n tẹ̀ jáde ní Mẹ́síkò sọ, àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá gbà pé “bí àwọn èèyàn ṣe ń ya ara wọn láṣo láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún àti bí ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń gbé ìgbésí ayé wọn láwùjọ ṣe ń dìdàkudà ti ṣàkóbá púpọ̀ fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé “kí orílẹ̀-èdè tó lè di èyí tó wà bó ṣe yẹ, ìyípadà ńláǹlà gbọ́dọ̀ wáyé nínú ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, èyí tó túmọ̀ sí pé kí gbogbo èèyàn ṣe ara wọn ní òṣùṣù ọwọ̀.”

Ìṣòro yìí ti gbalẹ̀ gan-an àgàgà láàárín àwọn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà. Ohun tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ máa gbé ìgbésí ayé kóńkó jabele, kí kálukú máa ṣe tiẹ̀. Àwọn èèyàn fẹ́ ‘wà láyè ara wọn’ wọn ò sì fẹ́ kí ẹni kẹ́ni ‘tojú bọ ọ̀ràn àwọn.’ Àwọn èèyàn ti wá rí i pé ìwà yìí ti túbọ̀ fa ìdààmú ọkàn, ó ti jẹ́ kí ìbànújẹ́ sorí àwọn èèyàn kodò, ó sì ti fa fífọwọ́ ẹni gbẹ̀mí ara ẹni láàárín àwùjọ ẹ̀dá èèyàn.

Èyí ló fà á tí Ọ̀mọ̀wé Daniel Goleman fi sọ pé: “Yíya ara ẹni láṣo láàárín àwùjọ—ìyẹn èrò náà pé èèyàn ò ní alábàárò kankan tó lè bá sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tàbí tó lè bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́—túbọ̀ ń mú kí ọ̀ràn àìsàn àti ikú ròkè sí i ní ìlọ́po méjì.” Ìròyìn kan tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Science sọ pé yíya ara ẹni láṣo láwùjọ ‘lè ṣekú pani lọ́nà kan náà tí sìgá mímu, ẹ̀jẹ̀ ríru, àpọ̀jù èròjà cholesterol, ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ àti àìkìí ṣeré ìdárayá, lè gbà ṣekú pani.’

Nígbà náà, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tá ò fi lè dá wà láìfi tàwọn ẹlòmíràn ṣe. Igi kan ò sì lè dágbó ṣe. Nítorí náà, báwo la ṣe lè yanjú ìṣòro báwọn èèyàn ṣe ń ya ara wọn láṣo láwùjọ? Àwọn ohun wo ló ti mú kí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn nítumọ̀? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun táà ń ṣe àtèyí tó wà lọ́kàn wa láti ṣe ni ò sọ́gbọ́n tá a fi lè ṣe wọ́n láìjẹ́ pé a fi tàwọn ẹlòmíràn ṣe.”—Albert Einstein

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́