ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 15
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Bá Lómìnira Àtijáde Bíi Ti Tẹ́lẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Bá Lómìnira Àtijáde Bíi Ti Tẹ́lẹ̀
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run
  • Ka àwọn apá ibi tó máa jẹ́ kára tù ẹ́ nínú Bíbélì
  • Kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè mọ ohun tó fà á táwọn nǹkan fi rí bó ṣe rí yìí
  • Má ṣe kó ara ẹ lọ́kàn sókè láìnídìí
  • Wá ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́
  • Ṣe ohun tó máa jẹ́ kára ẹ yá gágá
  • Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ọ̀rẹ́ Nínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́ Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kó Gbogbo Àníyàn Rẹ lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìwọ́ Lè Gbádùn Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Pípẹ́ Títí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 15
Obìnrin kan wà nínú ilé rẹ̀, ó ń wo ìta látojú wíńdò.

Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Bá Lómìnira Àtijáde Bíi Ti Tẹ́lẹ̀

Ṣé nǹkan ti sú ẹ torí pé o ò lè jáde nílé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ bíi tí onísáàmù kan tó sọ pé: “Mo dà bí ẹyẹ tó dá wà lórí òrùlé.” (Sáàmù 102:7) Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè jẹ́ kó o rọ́gbọ́n dá sí ìṣòro tó máa ń wáyé tí èèyàn ò bá lè kúrò nílé torí àwọn ìdí kan.

  • Túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run

  • Ka àwọn apá ibi tó máa jẹ́ kára tù ẹ́ nínú Bíbélì

  • Kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè mọ ohun tó fà á táwọn nǹkan fi rí bó ṣe rí yìí

  • Má ṣe kó ara ẹ lọ́kàn sókè láìnídìí

  • Wá ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́

  • Ṣe ohun tó máa jẹ́ kára ẹ yá gágá

Túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run

Kódà tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti kúrò lójú kan, o ṣì lè láyọ̀ tó o bá ní in lọ́kàn pé ó fẹ́ túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run tó o sì ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Mátíù 5:3, 6) Àwọn ohun tó o lè rí lọ́fẹ̀ẹ́ tá a tò sísàlẹ̀ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe máa ṣe é.

  • Bíbélì tó péye tó sì rọrùn láti lóye látorí ìkànnì

  • Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì lórí ìkànnì tó máa jẹ́ kó o rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó yẹ kéèyàn mọ̀ nípa ìgbésí ayé

  • Àwọn fídíò tí kò gùn púpọ̀ tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì

  • Apá tá a pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ” máa jẹ́ kó o rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó máa ń wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn

  • Abala tá a pè ní “Tẹ̀ Lé àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” máa jẹ́ kó o mọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn

  • Abala tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” máa jẹ́ kó o rí báwọn ohun tí Ọlọ́run dá ṣe rẹwà tó, tí kò sì sẹ́ni tó mọ ohun tí Ọlọ́run fi pilẹ̀ rẹ̀

Ka àwọn apá ibi tó máa jẹ́ kára tù ẹ́ nínú Bíbélì

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tò sísàlẹ̀ yìí ti tu ọ̀pọ̀ èèyàn nínú. Má wulẹ̀ ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì yìí lẹ́ẹ̀kàn náà, lo àkókò tó o fi wà nílé yìí láti fi ka àwọn Bíbélì náà díẹ̀díẹ̀, kó o ronú lórí ohun tó o kà, kó o sì gbàdúrà.​—Máàkù 1:35.

  • Sáàmù 23:1-6

  • Sáàmù 34:1-22

  • Sáàmù 46:1-11

  • Sáàmù 63:6-8

  • Sáàmù 91:1-6

  • Mátíù 6:25-34

  • 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4

  • Fílípì 4:6, 7

  • 1 Pétérù 5:6, 7

Kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè mọ ohun tó fà á táwọn nǹkan fi rí bó ṣe rí yìí

Wàá lókun láti fara da ipò kan tó ń kó ìdààmú bá ẹ tó o bá mọ ohun tó fà á tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ àti bí Ọlọ́run ṣe máa dáwọ́ ẹ̀ dúró táa sì ṣàtúnṣe sáwọn ohun tó ti bà jẹ́.​—Àìsáyà 65:17.

  • Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé?

  • Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí àìsàn àti ìlera àwọn èèyàn?

  • Kí ni àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?

  • Ta ni àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tí ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa wọn?

  • Kí ni ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

Má ṣe kó ara ẹ lọ́kàn sókè láìnídìí

Tó o bá ka àwọn àpilẹ̀kọ tá a sọ nísàlẹ̀ yìí, á jẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀ kí ìdààmú tí àìlè kúrò nílé máa ń fà má bàa bò ẹ́ mọ́lẹ̀, á sì jẹ́ kó o “yéé ṣàníyàn.”​—Mátíù 6:25.

  • Bó o ṣe lè kojú àìbalẹ̀ ọkàn

  • Bó ṣe lè dá ẹ lójú pé nǹkan ṣì máa dáa

  • Àníyàn nípa ewu

  • Àníyàn nípa owó

  • Àníyàn tó máa ń bá àwọn ọ̀dọ́

Wá ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́

Tó o bá lọ́rẹ̀ẹ́ tó o lè fọ̀rọ̀ lọ̀, wàá lè ronú lọ́nà tó já gaara, inú ẹ sì máa dùn, àgàgà lásìkò téèyàn ò lè rí ọ̀rẹ́ náà lójúkojú. Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti kúrò nílé, o lè pe àwọn ọ̀rẹ́ tó o ti ní tẹ́lẹ̀ lórí fóònù kẹ́ ẹ lè gbóhùn ara yín tàbí kẹ́ ẹ tiẹ̀ ríra yín látorí fóònù, èyí máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọwọ́ ara yín, kó o sì tún ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Àwọn àpilẹ̀kọ tá a tò sísàlẹ̀ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti bíwọ náà ṣe lè jẹ́ “ọ̀rẹ́ tòótọ́.”​—Òwe 17:17.

  • Báwo lèèyàn ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi?

  • Ṣé wàá fẹ́ ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun kún àwọn tó o ti ní tẹ́lẹ̀?

  • Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní ọ̀rẹ́ kankan?

  • Jẹ́ ọ̀làwọ́ tó o bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tòótọ́

  • Wàá láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó o bá ń moore

Ṣe ohun tó máa jẹ́ kára ẹ yá gágá

Bíbélì sọ pé “àǹfààní . . . wà nínú eré ìmárale.” (1 Tímótì 4:8) Ó máa jẹ́ kó o lè ronú dáadáa, kò sì ní jẹ́ kí ọkàn ẹ bà jẹ́, pàápàá lásìkò tó ò lè kúrò nílé. A ti rí i pé kódà tí o ò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti kúrò nílé, ó ṣì láwọn nǹkan tó o lè ṣe tí kò ní jẹ́ kí nǹkan sú ẹ.

  • Má ṣe máa jókòó gẹlẹtẹ sójú kan

  • Ní ìlera tó dáa kó o sì tún ní ìfaradà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́