ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 10/1 ojú ìwé 8
  • “Mi Ò Gbọ́ Irú Èyí Rí!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mi Ò Gbọ́ Irú Èyí Rí!”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdánwò Ìgbàgbọ́ ní Poland
    Jí!—2000
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tẹ́ Ẹ Ní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 10/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

“Mi Ò Gbọ́ Irú Èyí Rí!”

ÒJÍṢẸ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Dorota nílùú Poland. Ó bá ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́rìnlá lọ sí ọsibítù ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ fún àyẹ̀wò ìtọ́jú àtìgbàdégbà. Lákòókò àyẹ̀wò náà, dókítà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Janinaa bi Dorota léèrè nípa iṣẹ́ ilé tí ọmọ rẹ̀ máa ń ṣe.

Dorota dáhùn pé: “Ó máa ń ṣe oúnjẹ fún àwa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà nínú ìdílé mi, nígbà tí mi ò bá lè ṣe é. Ó tún máa ń mú kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní, ó sì tún máa ń ṣàtúnṣe àwọn nǹkan nínú ilé. Ó fẹ́ràn láti máa kàwé. Kò sì fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣeré nílé ìwé.”

Janina dáhùn pé: Mi ò rírú ẹ̀ rí. Ọdún kejìlá rèé ti mo ti ń ṣiṣẹ́ níbí yìí, mi ò sì tíì gbọ́ irú èyí rí.”

Nígbà tí Dorota rí i pé àǹfààní láti wàásù ló ṣí sílẹ̀ yìí, ó ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn òbí lónìí ti kùnà láti tọ́ àwọn ọmọ wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ. Ìdí nìyẹn táwọn ọmọ wọn fi máa ń rò pé àwọn ò jámọ́ nǹkankan.”

Janina béèrè pé: “Báwo lo ṣe mọ gbogbo èyí? Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ni kò mọ nǹkankan nípa èyí.”

Dorota fèsì pé: “Bíbélì ni orísun ìsọfúnni ṣíṣeyebíye náà. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Diutarónómì 6:6-9 sọ, a ní láti kọ́kọ́ dá ara wa lẹ́kọ̀ọ́ kí á tó lè dá àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́. Ṣé kò yẹ kí a kọ́kọ́ gbin ìwà rere tá a fẹ́ sínú ọkàn àti èrò àwa fúnra wa kí á tó lè gbìn wọ́n sínú àwọn ọmọ wa ni?”

Janina sọ pé: “Èyí mà ga lọ́lá o. Èyí mà ga lọ́lá o!” Ó wá béèrè lọ́wọ́ Dorota bí Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bó ti tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Dorota ṣàlàyé pé: “A máa ń kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. A máa ń lo ìwé tí a pè ní Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.”b Ó tẹ̀ síwájú láti ṣàlàyé ìwé náà ó sì mẹ́nu bá díẹ̀ lára àwọn àkòrí tó wà nínú rẹ̀.

Janina lahùn, ó ní: “Mi ò gbọ́ irú èyí rí! Ǹjẹ́ o lè jẹ́ kí ń rí ìwé náà?”

Dorota mú ìwé náà wá fún un ní wákàtí kan lẹ́yìn náà.

Bí Janina ti ń yẹ ìwé náà wò, ó béèrè pé: “Ẹ̀sìn wo lò ń ṣe?”

Ó dáhùn pé: “Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.”

Janina béèrè pé: “Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe sí àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn?”

Dorota dáhùn, ó ní: “Bí mo ṣe ṣe sí ọ gan-an ni—pẹ̀lú ọ̀wọ̀.” Ó tún fi kún un pé: “Àmọ́ ṣá o, à ń fẹ́ kí àwọn náà wá mọ òtítọ́ tí Bíbélì fi ń kọ́ni.”

Janina sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, o ní: “Ara tiẹ̀ ti tù mí báyìí.”

Nígbà tí Dorota fẹ́ kúrò níbẹ̀, ó rọ Janina láti máa ka Bíbélì. Ó ní: “Yóò mú kí ìgbésí ayé rẹ nítumọ̀, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ nídìí iṣẹ́ rẹ.”

Janina sòótọ́, o ní: “O ti fún mi lókun gan-an láti máa ṣe bẹ́ẹ̀.”

Nípa lílo ọgbọ́n pẹ̀lú ìmúratán, Dorota lo àkókò tó fi wà lọ́dọ̀ dókítà yìí láti wàásù fún un lọ́nà rere.—1 Pétérù 3:15.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-gan.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́