Ìdánwò Ìgbàgbọ́ ní Poland
GẸ́GẸ́ BÍ JAN FERENC ṢE SỌ Ọ́
Ọ̀DỌ́MỌDÉ ni mí lákòókò tí Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń gbóná janjan. Mo ṣì rántí ìbátan bàbá mi kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó máa ń wá sílé wa tí yóò sì ka Bíbélì fún wa. Àwọn òbí mi kò nífẹ̀ẹ́ sí i, ṣùgbọ́n èmi, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin Józef, àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin Janina, nífẹ̀ẹ́ sí èyí gidigidi. Kò sì pẹ́ táa fi fẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni mí nígbà tí mo ṣe ìrìbọmi.
Nígbà táwọn òbí wa ṣàkíyèsí ipa dídára tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní lórí ìgbésí ayé wa, làwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́. Nígbà tí bàbá mi wá rí i pé Bíbélì sọ pé ìbọ̀rìṣà kò dáa, ó ní: “Tó bá jẹ́ pé ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ rèé, a jẹ́ pé àwọn àlùfáà ti fi júújú bò wá lójú nìyẹn o. Ọmọ, lọ kó gbogbo àwọn ère tó wà lára ògiri dà sígbó!” Ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà, àwọn òbí mi ṣèrìbọmi. Wọ́n fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà títí dìgbà tí wọ́n fi kú.
A Dojú Kọ Wàhálà
Òde ò dẹrùn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rárá lẹ́yìn tí ogun parí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀ṣọ́ láti Ilé Iṣẹ́ Aláàbò fipá gba ọ́fíìsì tó wà ní Lodz, wọ́n sì fi ọlọ́pàá mú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ní ìhà ìlà oòrùn Poland, àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì mú kí àwọn ọmọ ogun adàlúrú ti Ológun Orílẹ̀ Èdè náà gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nà rírorò.a
Kò tán síbẹ̀, lákòókò yìí kan náà làwọn aláṣẹ Kọ́múníìsì fagi lé àṣẹ tí wọ́n fún wa tẹ́lẹ̀ láti máa ṣe àwọn àpéjọ wa, wọ́n tiẹ̀ gbìyànjú láti dá àwọn àpéjọ tí à ń ṣe lọ́wọ́ dúró pàápàá. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni àtakò tó gbalẹ̀ sí i náà túbọ̀ mú kí ìpinnu wa láti máa bá wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run nìṣó lágbára sí i. Ní 1949, iye akéde tó wà ní Poland ju ẹgbàáje [14,000] lọ.
Láìpẹ́, mo di aṣáájú ọ̀nà, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ibi tí a yan iṣẹ́ àkọ́kọ́ sí fún mi jìnnà tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà sílé. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn èyí tí a fi yàn mí láti sìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní àgbègbè ìlà oòrùn Lublin, tí kò jìnnà sí ibi tí àwọn òbí mi ń gbé kí wọ́n tó kú.
Àwọn Aláṣẹ Fọlọ́pàá Mú Mi Wọ́n sì Ṣe Inúnibíni sí Mi
Ní oṣù June 1950, àwọn aláṣẹ Kọ́múníìsì fi ọlọ́pàá mú mi wọ́n sì fẹ̀sùn kàn mí pé ńṣe ni mò ń ṣe amí fún Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n jù mí sínú àjàalẹ̀ kan tó lọ́rinrin. Nígbà tó dòru, ọ̀gá ọlọ́pàá kan tó jẹ́ olùṣèwádìí wá mú mi jáde láti béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ mi. Ó sọ fún mi pé: “Ẹ̀ya ẹ̀sìn ni ẹgbẹ́ ìsìn tí ò ń dara pọ̀ mọ́, ọ̀tá Orílẹ̀ Èdè wa sì ni pẹ̀lú. Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Amẹ́ríkà ni orílé iṣẹ́ yín ń bá ṣiṣẹ́. A lè fẹ̀rí rẹ̀ hàn ọ́! Àwọn arákùnrin rẹ ti jẹ́wọ́ pé àwọn máa ń rìnrìn àjò káàkiri orílẹ̀ èdè yìí láti gba àwọn ìsọfúnni nípa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ti ológun àti àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ.”
Dájúdájú, irọ́ funfun báláú ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá yìí. Síbẹ̀, ọ̀gá ọlọ́pàá náà ní kí n fọwọ́ síwèé kan láti fi hàn pé mo ti sẹ́ ohun tó pè ní “ètò àjọ ìyà, ètò àjọ ẹ̀sín tóo lọ dara pọ̀ mọ́.” Léraléra ló ń gbìyànjú láti mú mi fọwọ́ sí i. Ó tiẹ̀ tún gbìyànjú láti fẹ́ kí n kọ orúkọ àti àdírẹ́sì gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tí mo mọ̀ àti àwọn ibi tí a ti ń ṣe ìpínkiri àwọn ìtẹ̀jáde wa. Àmọ́, pàbó ni gbogbo akitiyan rẹ̀ já sí.
Lẹ́yìn ìyẹn, làwọn ọlọ́pàá bá bẹ̀rẹ̀ sí jàn mí ní kóńdó, wọ́n lù mí títí mo fi dákú. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ́mi lé mi lórí tí mo fi sọjí, bẹ́ẹ̀ ni ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò tún bẹ̀rẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ kejì, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ lu gìgísẹ̀ mi fọ́. Mo gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sókè ketekete sí Ọlọ́run pé kó fún mi lókun láti lè fara dà á. Mo sì mọ̀ pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Fún nǹkan bí ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò lórulóru.
Wọ́n dá mi sílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní April 1951, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ló ṣì wà lẹ́wọ̀n. Mo lọ sọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan tó dipò pàtàkì mú, mo sì béèrè fún iṣẹ́ àyànfúnni tuntun. Ló bá béèrè lọ́wọ́ mi pé: “Ṣé ìwọ ò tiẹ̀ bẹ̀rù pé wọ́n lè tún fọlọ́pàá mú ẹ ni?” Mo dáhùn pé: “Mo tiẹ̀ ti wá pinnu gan-an báyìí láti ṣiṣẹ́ níbi tí àìní gbé pọ̀.” Ni mo bá tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi bí alábòójútó arìnrìn-àjò, nígbà tó ṣe díẹ̀ la wá pè mí wá sí Poland láti wá ṣètò títẹ àwọn ìtẹ̀jáde wa àti ìpínkiri wọn.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn ẹ̀rọ aṣàdàkọ ayé ọjọ́un la fi ń ṣàdàkọ Ilé Ìṣọ́. Ohun tí a ń tẹ̀ jáde gan-an kò fani lójú mọ́ra, bẹ́ẹ̀ sì rèé owó gọbọi la fi ń ra bébà, nígbà yẹn kẹ̀ rèé, bébà ọ̀hún kò tó. Àwọn ibi tó ṣe kọ́lọ́fín bí abà, àjà-ilẹ̀, àti òkè àjà la ti máa ń ṣẹ̀dà àwọn ìwé wa. Àmọ́, ńṣe làwọn tí wọ́n gbá mú lọ fẹ̀wọ̀n jura.
Mo rántí kànga kan tómi inú ẹ̀ ti gbẹ táa lò nígbà yẹn. Ó fi nǹkan bíi mítà mọ́kànlá jìn sísàlẹ̀, ọ̀nà gbórógbóró kan sì wà nísàlẹ̀ kànga yìí táa máa ń gbà lọ sí yàrá kékeré kan níbi táa ti ń ṣàdàkọ àwọn ìwé ìròyìn náà. Táa bá fẹ́ lọ síbẹ̀, okùn la máa tòrò mọ́ táa ó fi dé ìsàlẹ̀. Lọ́jọ́ kan báyìí, mo wà nínú àpótí ńlá kan tí a figi ṣe tí mo máa ń gùn lọ sísàlẹ̀ kànga náà, lójijì lokùn bá já. Àfi gbìgìdì nísàlẹ̀, ẹsẹ̀ mi sì kán. Lẹ́yìn tí mo kúrò ní ọsibítù, mo padà sídìí ẹ̀rọ aṣàdàkọ náà tí mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí lò ó.
Lákòókò yìí ni mo pàdé Danuta, òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tó nítara ni. A ṣe ìgbéyàwó ní 1956, a sì fọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e ṣiṣẹ́ papọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àárín gbùngbùn Poland. Nígbà tó fi máa di 1960, a ti bí ọmọ méjì làǹtì-lanti, la bá kúkú pinnu pé kí Danuta dá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún dúró kó bàa lè tọ́jú àwọn ọmọ. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún fọlọ́pàá mú mi, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, àwọn èkúté pọ̀ bí eléèmọ̀ nínú galagálá tí wọ́n sọ mí sí. Oṣù méje lẹ́yìn náà, wọ́n sọ pé kí n lọ fẹ̀wọ̀n ọdún méjì jura.
Mo Di Oníbàárà Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Bydgoszcz lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300], mo sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n lè ṣàjọpín ìhìn Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ ọkàn. Mo bá olórí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n náà sọ̀rọ̀, mo sì sọ fún un pé ì bá wù mí kí n máa gẹrun fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Sí ìyàlẹ́nu mi, ó gbà. Kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí gẹrun àwọn ẹlẹ́wọ̀n, bẹ́ẹ̀ sì ni mò ń wàásù fún àwọn tó fẹ́ láti gbọ́.
Kò pẹ́ tí ẹlẹ́wọ̀n kan báyìí táa jọ ń ṣiṣẹ́ agẹrun fi bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ohun tí a jọ ń jíròrò ṣèwà hù. Kódà ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàjọpín àwọn ohun tó ti kọ́ látinú Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Láìpẹ́, olórí ọgbà ẹ̀wọ̀n pàṣẹ fún wa pé kí á dáwọ́ títan ohun tó pè ní “ìpolongo tó lòdì sófin ìjọba” kálẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni táa jọ ń ṣe iṣẹ́ agẹrun yìí dúró gbọn-in. Ó ṣàlàyé pé: “Gbéwiri ni mí tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní báyìí n kì í ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Sìgá mímu ti di bárakú fún mi nígbà kan rí, ṣùgbọ́n n kì í mu ún mọ́. Ìgbésí ayé mi ti nítumọ̀, mo sì fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, a rán mi lọ sí Poznan pé kí n lọ máa ṣàbójútó “ilé iṣẹ́ búrẹ́dì,” bí a ṣe ń pe àwọn ilé ìtẹ̀wé wa tó wà níkọ̀kọ̀. Ní apá ìparí àwọn ọdún 1950, ìwé títẹ̀ wa ti gbé pẹ́ẹ́lí sí i. A kọ́ báa ṣe lè fi fọ́tò dín fífẹ̀ ojú ìwé kù—ohun kan tá ò ní gbàgbé láé báa bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ wa—àti báa ṣe ń lo àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo Rotaprint. Nígbà tó fi máa di 1960, a bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀wé tí a sì tún ń dì í papọ̀.
Ní kété lẹ́yìn náà, ni ọkùnrin kan tó ń gbé àdúgbò wa bá lọ fi ẹjọ́ wa sùn, ni ọlọ́pàá bá tún gbá mi mú. Lẹ́yìn ìgbà tí mo jáde lẹ́wọ̀n ní 1962, a rán mi lọ láti sìn ní Szczecin pẹ̀lú àwọn mìíràn. Nígbà tó kù díẹ̀ ká gbéra, la bá rí ìtọ́ni táa rò pé ó wá látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni adúróṣinṣin pé Kielce ni ká lọ. Nígbà táa dọ́hùn-ún, lọwọ́ ṣìnkún àwọn ọlọ́pàá bá tẹ̀ wá tí wọ́n sì sọ pé kí n lọ faṣọ péńpé roko ọba fún ọdún kan àtààbọ̀. Àwọn afàwọ̀rajà tó wà láàárín wa ló tú àṣírí wa. Àmọ́ láìpẹ́, àṣírí wọn tú, a sì yọ wọ́n bí ẹni yọ jìgá kúrò láàárín wa.
Nígbà tó yá tí mo jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, a yàn mí láti máa bójú tó títẹ àwọn ìwé wa ní Poland. Ní 1974, lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá gbáko tí wọn ò fi rí wa mú, ọwọ́ wá tẹ̀ mí ní Opole. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí wọ́n fi sọ pé kí n lọ faṣọ péńpé roko ọba ní Zabrze. Olórí ọgbà ẹ̀wọ̀n sọ fún mi pé: “Iṣẹ́ bíṣọ́ọ̀bù tí o ń ṣe ti tán nìyẹn o. Tóo bá sì tún ń tan ìpolongo èké rẹ kálẹ̀, a jẹ́ pé ibi táa máa jù ọ́ sí, kò sẹ́ni tó máa gbúròó rẹ̀ mọ́ láé.”
Wíwàásù Nínú Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Dájúdájú, iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kò tíì parí. Kódà mo bẹ̀rẹ̀ sí bá méjì lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n tẹ̀ síwájú dépò pé mo ṣe ìrìbọmi fún wọn nínú ọpọ́n ìwẹ̀ ńlá tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n níbẹ̀.
Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn náà tẹ́wọ́ gba ìwàásù wa, nígbà tó sì di April 1977, a péjọ pọ̀ láti ṣe Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi. (Lúùkù 22:19) Oṣù méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn ní June 1977, ni wọ́n dá mi sílẹ̀, wọn ò sì tún fọlọ́pàá mú mi mọ́.
Nígbà táà ń wí yìí, àwọn aláṣẹ ò fúngun mọ́ wa mọ́. Kò sí àní-àní pé bíbẹ̀ tí àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀ wá wò ṣe ìrànlọ́wọ́ gan-an ni. Ní ọdún 1977, mẹ́ta lára wọn bá àwọn alábòójútó, àwọn aṣáájú ọ̀nà, àti àwọn Ẹlẹ́rìí ọlọ́jọ́ pípẹ́ sọ̀rọ̀ ní onírúurú àwọn ìlú ńlá. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, méjì lára wọn ṣe ìbẹ̀wò ẹ-ǹlẹ́-ń-bẹ̀un sí Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìsìn. Ṣùgbọ́n ọdún 1989 ni wọ́n tó gbà wá láyè láti máa bá iṣẹ́ wa lọ ní fàlàlà. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, nǹkan bí ẹgbàá méjìlélọ́gọ́ta [124,000] àwọn Ẹlẹ́rìí ló ń ṣiṣẹ́ déédéé ní Poland.
Danuta ò lè máa bá mi káàkiri láti bí ọdún díẹ̀ báyìí nítorí àìlera rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ń fún mi níṣìírí ó sì fẹ́ kí n máa bá a lọ ní ṣíṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ìjọ. Títí láé ni n óò máa dúpẹ́ fún àwọn ọ̀nà tó gbà fún mi lókun ní gbogbo àkókò tí mo fi ń ṣẹ̀wọ̀n.
Mo ti wá rí i dájú pé ìpinnu tí mo ṣe ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn láti sin Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ èyí tó dára gan-an ni. Mo ti rí ayọ̀ ńláǹlà nínú sísìn ín tọkàntọkàn. Èmi àti ìyàwó mi ti rí òótọ́ àwọn ọ̀rọ̀ táa kọ sínú ìwé Aísáyà 40:29 tó sọ pé: “Ó [Jèhófà] ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé ọdọọdún1994 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 213 sí 222.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ẹ̀rọ aṣàdàkọ la fi ń tẹ àwọn ìtẹ̀jáde tẹ́lẹ̀, nígbà tó yá, a wá ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo Rotaprint
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Èmi àti aya mi Danuta