ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 8/1 ojú ìwé 16-20
  • Jèhófà Máa Ń San Èrè Rẹpẹtẹ Fáwọn Tó Ń Pa Ọ̀nà Rẹ̀ Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Máa Ń San Èrè Rẹpẹtẹ Fáwọn Tó Ń Pa Ọ̀nà Rẹ̀ Mọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Gba Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni
  • Mó Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì, Àwọ́n Aláṣẹ sì Mú Mi
  • Mo Ṣiṣẹ́ Alábòójútó Àyíká, Wọ́n Tún Fi Mí Sẹ́wọ̀n Lẹ́ẹ̀kejì
  • Àwọn Ìyípadà Pàtàkì Méjì
  • Mò Ń Bójú Tó “Àwọn Iléeṣẹ́ Búrẹ́dì” Náà
  • Mo Gbèjà Ìhìn Rere
  • Wọ́n Yan Iṣẹ́ Tuntun fún Mi
  • Ìdánwò Ìgbàgbọ́ ní Poland
    Jí!—2000
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Lábẹ́ Ọwọ́ Ìfẹ́ Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Olóore Sí Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 8/1 ojú ìwé 16-20

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà Máa Ń San Èrè Rẹpẹtẹ Fáwọn Tó Ń Pa Ọ̀nà Rẹ̀ Mọ́

GẸ́GẸ́ BÍ ROMUALD STAWSKI TI SỌ Ọ́

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní oṣù September ọdún 1939, àríwá ilẹ̀ Poland di pápá ogun gbígbóná janjan. Nígbà yẹn, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré ni mí, mo sì fẹ́ ṣe ojúmìító, ni mo bá lọ sí pápá ogun tó wà nítòsí ilé wa kí n lè rí nǹkan tó ń lọ. Ohun tí mo rí níbẹ̀ burú jáì, àwọn òkú wà nílẹ̀ káàkiri, èéfín tó ń séni léèémí sì gba gbogbo afẹ́fẹ́ kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí mò ń rò kò ju bí mo ṣe máa délé lálàáfíà, àwọn ìbéèrè kan ń wá sí mi lọ́kàn, àwọn ìbéèrè bíi: “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àwọn ohun búburú bẹ́ẹ̀ láti máa ṣẹlẹ̀? Ọ̀dọ̀ ta ni Ọlọ́run wà nínú àwọn ọmọ ogun tó dojú ìjà kọ́ ara wọn yìí?”

NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí ogun náà parí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fipá mú àwọn ọ̀dọ́ láti ṣiṣẹ́ fún ìjọba Jámánì. Wọ́n á so ẹni tó bá ṣàyà gbàǹgbà pé òun ò lọ sógun kọ́ igi tàbí afárá, wọ́n á sì gbé àmì kan sí i láyà tó kà pé “ọ̀dàlẹ̀” tàbí “adojú-ìjọba-dé.” Àárín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó dojú kọ ara wọn yìí ni ìlú wa tó ń jẹ́ Gdynia wà. Nígbà tá a bá lọ pọnmi lẹ́yìn ìlú, ńṣe ni ọta ìbọn àti bọ́ǹbù máa ń fo kọjá lórí wa, kódà ọta ìbọn ba Henryk, àbúrò mi ọkùnrin, ó ṣèṣe gan-an, ó sì kú. Nítorí yánpọnyánrin yìí, màmá mi kó àwa ọmọ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ sí àjà ilẹ̀ ilé kan kí nǹkan kan má bàa ṣe wá. Ibẹ̀ ní akọ èfù ti pa Eugeniusz àbúrò mi ọkùnrin.

Mo tún béèrè lọ́wọ́ ara mi pé: “Ibo ni Ọlọ́run wà? Kí nìdí tó fi fàyè gba gbogbo ìyà wọ̀nyí?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kátólíìkì tó nítara ni mí tí mo sì ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé, mi ò rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

Mo Gba Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni

Ibi tí mo fojú sí kọ́ ni ìdáhùn mi ti wá. Ogun náà parí lọ́dún 1945, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì wá sílé wa nílùú Gdynia níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1947. Màmá mi bá Ẹlẹ́rìí náà sọ̀rọ̀, mo sì gbọ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tí Ẹlẹ́rìí náà sọ. Ó jọ pé ohun tó sọ náà mọ́gbọ́n dání, nítorí náà a gbà láti lọ sí ìpàdé Kristẹni. Oṣù kan péré lẹ́yìn náà, mo dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àdúgbò wa, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì lóye gbogbo òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni. Mo ń wàásù fún àwọn èèyàn nípa ayé tuntun tí kò ti ní sí ogun àtàwọn nǹkan búburú mìíràn mọ́. Èyí múnú mi dùn gan-an.

Ní oṣù September ọdún 1947, mo ṣèrìbọmi ní ìpàdé àyíká tá a ṣe nílùú Sopot. Ní oṣù May tó tẹ̀ lé e, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, tí mo sì ń lo ọ̀pọ̀ lára àkókò mi láti wàásù ọ̀rọ̀ inú Bíbélì fáwọn èèyàn. Àwọn àlùfáà tó wà ní àdúgbò yẹn kò nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa rárá wọ́n sì ní káwọn èèyàn máa lù wá. Nígbà kan, àwọn èèyànkéèyàn gbéjà kò wá, wọ́n sọ wá lókùúta wọ́n sì lù wá játijàti. Ó tún ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àtàwọn àlùfáà àdúgbò náà ní káwọn èèyàn kan wá gbéjà kò wá. La bá sá lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, àmọ́ àwọn èèyànkéèyàn wọ̀nyí yí àgọ́ ọlọ́pàá náà ká, wọ́n sì ń pariwo pé àwọn máa lù wá. Nígbà tó yá, àwọn ọlọ́pàá ya dé, àwọn ló wá mú wa kúrò níbẹ̀.

Kò sí ìjọ kankan lágbègbè tá a ti ń wàásù lákòókò yẹn. Ìgbà mìíràn wà tá a máa ń sùn inú igbó mọ́jú. Inú wa dùn pé a lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù láìka ipò líle kókó tá a wà náà sí. Lónìí, àwọn ìjọ tó ń gbèrú ti wà lágbègbè náà.

Mó Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì, Àwọ́n Aláṣẹ sì Mú Mi

Lọ́dún 1949, wọ́n pè mí wá sí Bẹ́tẹ́lì nílùú Łódź. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti sìn ní irú ibí yìí! Ó ṣeni láàánú pé mi ò pẹ́ níbẹ̀. Ní oṣù June ọdún 1950, oṣù kan ṣáájú kí wọ́n tó fòfin de iṣẹ́ wa, wọ́n mú èmi àtàwọn arákùnrin mìíràn ní Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n, wọ́n sì fìyà jẹ mí gan-an nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò.

Nítorí pé bàbá mi ń bá ọkọ̀ òkun kan tó ń ná ìlú New York ṣiṣẹ́, àwọn aláṣẹ tó ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò gbìyànjú láti mú mi sọ pé ńṣe ni bàbá mi ń ṣamí fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n fìyà jẹ mí gan-an bí wọ́n ti ń wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi. Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tún gbìyànjú láti mú mi fẹ̀sùn èké kan arákùnrin Wilhelm Scheider tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù wa nílẹ̀ Poland lákòókò yẹn. Wọ́n fi ẹgba nà mí látẹ̀ẹ́lẹsẹ̀. Bí mo ṣe nà gbalaja sórí ilẹ̀ nìyẹn tí ara mi ń ṣẹ̀jẹ̀, nígbà tí mo rí i pé mi ò lè fara dà á mọ́, ni mo bá kígbe pé, “Jèhófà, ràn mí lọ́wọ́!” Ẹnu ya àwọn tó ń ṣenúnibíni sí mi náà, wọ́n ò sì nà mí mọ́. Láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, wọ́n sùn lọ. Ará tù mí mo sì tún lókun padà. Èyí mú un dá mi lójú pé Jèhófà máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún un nígbà tí wọ́n bá ké pè é fún ìrànwọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fún ìgbàgbọ́ mi lókun ó sì kọ́ mi láti máa gbọ́kàn lé Ọlọ́run pátápátá.

Ẹ̀rí tí wọ́n purọ́ mọ́ mi pé mo jẹ́ wà nínú àkọsílẹ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe. Nígbà tí mo yarí pé mi ò sọ ohun tí wọ́n ní mo sọ yìí, ọ̀kan nínú àwọn sójà náà sọ fún mi pé, “Wàá máa ṣàlàyé ìyẹn ní kóòtù!” Ẹlẹ́wọ̀n bíi tèmi kan tó ṣèèyàn wá sọ fún mi pé kí n má ṣèyọnu, nítorí olùpẹ̀jọ́ fáwọn ológun ṣì máa ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ náà, ìyẹn á sì fún mi láǹfààní láti ta ko ẹ̀rí èké tí wọ́n ní mo jẹ́ náà. Lóòótọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn.

Mo Ṣiṣẹ́ Alábòójútó Àyíká, Wọ́n Tún Fi Mí Sẹ́wọ̀n Lẹ́ẹ̀kejì

Wọ́n dá mi sílẹ̀ ní oṣù January ọdún 1951. Oṣù kan lẹ́yìn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Láìfi òfin tí wọ́n fi dè wá pè, mò ń bá àwọn arákùnrin yòókù ṣiṣẹ́ láti fún àwọn ìjọ lókun àti láti ṣèrànwọ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi tí wọ́n fọ́n káàkiri nítorí pé àwọn ọlọ́pàá ń sọ wọ́n lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. A gba àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin níyànjú láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nìṣó. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn arákùnrin wọ̀nyẹn ló ń fìgboyà ran àwọn alábòójútó àyíká lọ́wọ́. Àwọn ló ń tẹ̀wé, tí wọ́n sì ń pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kiri ní bòókẹ́lẹ́.

Lọ́jọ́ kan lóṣù April lọdún 1951, lẹ́yìn tí mo dé láti ìpàdé Kristẹni, àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n ti ń ṣọ́ mi lójú méjèèjì mu mí lójú pópó. Nítorí pé mi ò dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bi mí, wọ́n mú mi lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n nílùú Bydgoszcz wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà. Wọ́n ní kí n fara ti ògiri kan fún ọjọ́ mẹ́fà gbáko, láìjẹ láìmu tí èéfín sìgá àwọn ọlọ́pàá náà sì gba gbogbo ibẹ̀ kan. Wọ́n fi kùmọ̀ lù mí wọ́n sì fi iná sìgá jó mi. Nígbà tí mo dákú, wọ́n da omi lé mi lórí, wọ́n sì tún ń bá a lọ́ láti má fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Mo bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun láti lè fara dà á, ó sì fún mi lókun.

Lílọ ti mo lọ ṣẹ̀wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Bydgoszcz ní àwọn àǹfààní kan nínú. Ibẹ̀ ni mo ti fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn tí kò sí ọ̀nà mìíràn láti rí wọn ju inú ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ àǹfààní ni mo ní láti wàásù fún wọn. Ipò ìbànújẹ́ àti àìnírètí táwọn ẹlẹ́wọ̀n náà wà máa ń jẹ́ kí wọ́n fetí sílẹ̀ sí ìhìn rere náà.

Àwọn Ìyípadà Pàtàkì Méjì

Kété lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní ọdún 1952, mo pàdé Nela, arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà onítara. Ó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà tẹ́lẹ̀ ní gúúsù ilẹ̀ Poland. Nígbà tó yá, ó ṣiṣẹ́ níbi kan tá à ń pè ní “iléeṣẹ́ búrẹ́dì,” ìyẹn ibi tá a ti ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ní bòókẹ́lẹ́. Iṣẹ́ ibẹ̀ le gan-an nítorí iṣẹ́ náà gba kéèyàn wà lójúfò kó sì jẹ́ aláápọn. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1954, a sì ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wa lọ títí dìgbà tá a bí ọmọ wa, Lidia. Lẹ́yìn náà a pinnu pé kí Nela dáwọ́ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rẹ̀ dúró, kó padà sílé, kó lọ máa bójú tó ọmọ wa, kí n lè máa bá iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò tí mò ń ṣe nìṣó.

Lọ́dún yẹn kan náà, a tún dojú kọ ìpinnu pàtàkì mìíràn tá a ní láti ṣe. Wọ́n ní kí n wá ṣe iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè ní àgbègbè tó jẹ́ ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ilẹ̀ Poland. A gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà. Mo mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti gbé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa táwọn aláṣẹ fòfin dè wọ̀nyí ró. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ni wọ́n ń mú lákòókò náà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi nílò ìṣírí nípa tẹ̀mí gan-an. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Nela, mo tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè yìí fún ọdún méjìdínlógójì.

Mò Ń Bójú Tó “Àwọn Iléeṣẹ́ Búrẹ́dì” Náà

Lákòókò yẹn, alábòójútó àgbègbè ló máa ń bójú tó àwọn ibi tá à ń pè ní iléeṣẹ́ búrẹ́dì wọ̀nyí tó wà ní ibi àdádó. Ìgbà gbogbo làwọn ọlọ́pàá máa ń wá wa kiri tí wọ́n á fẹ́ mọ ibi tá a ti ń tẹ̀wé náà kí wọ́n lè dá iṣẹ́ náà dúró. Nígbà mìíràn wọ́n á rí wa mú, àmọ́ kò sígbà tá ò rí oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò. Ó hàn gbangba pé Jèhófà ń bójú tó wa.

Kí wọ́n tó lè pe ẹnì kan láti wá ṣiṣẹ́ ìwé títẹ̀ tó jẹ́ iṣẹ́ àṣekára tó sì léwu yìí, onítọ̀hún ní láti jẹ́ adúróṣinṣin, ẹni tó wà lójúfò, ẹni to ṣe tán láti ṣiṣẹ́ dáadáa tó sì jẹ́ onígbọràn. Irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn ló jẹ́ kí iṣẹ́ tá à ń ṣe níbi tá a pè ní “iléeṣẹ́ búrẹ́dì” yìí máa bá a lọ láìséwu. Ó máa ń ṣòro gan-an láti rí ibi tó dára tá a máa lò fún títẹ ìwé ní bòókẹ́lẹ́. Àwọn ibì kan dà bíi pé wọ́n dára gan-an fún títẹ ìwé náà, àmọ́ àwọn arákùnrin tó ń gbébẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ já fáfá tó láti ṣiṣẹ́ náà láṣìírí. Àwọn ibòmíràn sì wà tí kò dára fún iṣẹ́ náà, àmọ́ àwọn arákùnrin tó ń gbébẹ̀ já fáfá gan-an. Àwọn arákùnrin múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti ṣe iṣẹ́ náà. Mo mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí mo láǹfààní láti bá ṣiṣẹ́.

Mo Gbèjà Ìhìn Rere

Láwọn ọdún tó kún fún ìṣòro wọ̀nyẹn, wọ́n máa ń fẹ̀sùn kàn wá pé à ń ṣe iṣẹ́ tí kò bófin mú tó lè dojú ìjọba dé, wọ́n sì máa ń pè wá lẹ́jọ́ sí kóòtù. Ìṣòro lèyí jẹ́ fún wa nítorí a kò ní lọ́yà tó máa gbẹjọ́ wa rò. Àwọn lọ́yà kan lójú àánú, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa sọ, wọ́n ò sì fẹ́ ṣẹ ìjọba. Bó ti wù kó rí, Jèhófà mọ ohun tá a nílò, ó sì bá wa yanjú ọ̀ràn náà nígbà tó yá.

Wọ́n ṣe arákùnrin Alojzy Prostak tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò láti ìlú Kraków bọ́ṣẹ ti ń ṣojú nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Ńṣe ni wọ́n ní láti gbé e lọ sílé ìwòsàn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Nítorí pé ó ṣolóòótọ́ láìfi ìyà burúkú tí wọ́n fi jẹ ẹ́ pè, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù nílé ìwòsàn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà bọ̀wọ̀ fún un, wọ́n sì kan sáárá sí i. Ọ̀kan lára wọn jẹ́ lọ́yà, orúkọ rẹ̀ sì ni Witold Lis-Olszewski. Ìgboyà tí Arákùnrin Prostak ní wú u lórí púpọ̀. Ó bá Arákùnrin Prostak sọ̀rọ̀ nígbà bíi mélòó kan ó sì ṣèlérí fún un pé, “Gbàrà tí wọ́n bá ti dá mi sílẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi, màá ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti máa gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ohun tó sọ yẹn gan-an ló sì ṣe.

Ọ̀gbẹ́ni Olszewski ní ẹgbẹ́ agbẹjọ́rò tirẹ̀, bí ẹgbẹ́ náà sì ṣe dúró tì wá gbágbáágbá lákòókò yẹn jọ wá lójú gan-an. Nígbà tí àtakò náà gbóná janjan, wọ́n gbèjà àwọn arákùnrin nínú ẹjọ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n lóṣooṣù, ìyẹn jẹ́ ẹjọ́ kan lóòjọ́ tá a bá ní ká pín in! Wọ́n yàn mí pé kí n máa bá Ọ̀gbẹ́ni Olszewski sọ̀rọ̀ déédéé nítorí ó gbọ́dọ̀ mọ gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ẹjọ́ kọ̀ọ̀kan. Odindi ọdún méje ni mo fi bá a ṣiṣẹ́ láàárín àwọn ọdún 1960 sí àwọn ọdún 1970.

Mo kọ́ ohun púpọ̀ nípa iṣẹ́ òfin láwọn àkókò wọ̀nyẹn. Mo sábà máa ń kíyè sí ọnà tí wọ́n gbà ń ṣe àwọn ẹjọ́ náà, mo máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ táwọn agbẹjọ́rò máa ń sọ, ì báà jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa gbeni tàbí èyí tó máa kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Mó tún kíyè sí báwọn lọ́yà ṣe máa ń fi ohun tó wà nínú ìwé òfin gbèjà èèyàn àti ohun táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi tí wọ́n fẹ̀sùn kàn máa ń sọ. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló wá wúlò fún mi gan-an láti ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́, àgàgà àwọn arákùnrin tó wá ń jẹ́rìí ní kóòtù. Ó yẹ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ àti ìgbà tó yẹ kí wọ́n dákẹ́ nínú kóòtù.

Nígbà tí wọ́n bá ń ṣẹjọ́ kan lọ́wọ́, Ọ̀gbẹ́ni Olszewski sábà máa ń sún sílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kì í ṣe nítorí pé kò lè sanwó láti fi gba yàrá ní òtẹ́ẹ̀lì, àmọ́ ó sọ ohun tó fà á, ó ní: “Ṣáájú kí ẹjọ́ tó bẹ̀rẹ̀, mo fẹ́ mọ bẹ́ẹ̀ ṣe jẹ́ gan-an.” Nítorí ìrànlọ́wọ́ tó ṣe yìí, àwa la jàre èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹjọ́ náà. Ó lọ gbèjà mi láwọn ìgbà bíi mélòó kan, kò sì gba kọ́bọ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó gba ọgbọ̀n ẹjọ́ rò fún wa, síbẹ̀ ó kọ̀, kò gbowó lọ́wọ́ wa. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ní, “Èmi náà fẹ́ kópa díẹ̀ nínú iṣẹ́ yín.” Iṣẹ́ tó ṣe fún wa yìí kì í sì í ṣowó kékeré. Iṣẹ́ tí Ọ̀gbẹ́ni Olszewski àtàwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ń ṣe fún wa yìí kò ṣàìhàn sáwọn aláṣẹ, àmọ́ ìyẹn ò ní kó má ràn wá lọ́wọ́.

Èèyàn ò lè ròyìn bí ohun táwọn arákùnrin wa ṣe nígbà tá à ń jẹ́jọ́ wọ̀nyẹn ṣe jọ àwọn èèyàn lójú tó. Ọ̀pọ̀ wọn ló wá sí kóòtù láti wá wo bí ẹjọ́ náà ṣe ń lọ àti láti fún àwọn arákùnrin tí wọn ń jẹ́jọ́ níṣìírí. Láwọn ìgbà kan tá a ṣe àwọn ẹjọ́ tó pọ̀ gan-an, mo ka iye àwọn ará tó wá síbẹ̀ lápapọ̀, wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] èèyàn láàárín ọdún kan ṣoṣo. Dájúdájú ogunlọ́gọ̀ ńlá Ẹlẹ́rìí ni wọ́n!

Wọ́n Yan Iṣẹ́ Tuntun fún Mi

Nígbà tó máa fi di ọdún 1989 wọ́n ti mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ wa kúrò. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, a kọ́ ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa tuntun a sì yà á sí mímọ́. Wọ́n pè mí láti wá máa bá Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn ṣiṣẹ́. Mo sì fìdùnnú tẹ́wọ́ gba ìpè náà. Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni-mẹ́ta, à ń ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin wa tí wọ́n ń kojú ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀, a sì tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ìgbàgbọ́ wọn mú ṣinṣin kí wọ́n má bàa ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.—Ìṣe 15:29.

Èmi àti ìyàwó mi dúpẹ́ a tún ọpẹ́ dá pé a láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́. Mo sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Nela pàápàá nítorí pé ìgbà gbogbo ló ń ràn mí lọ́wọ́ tó sì ń fún mi níṣìírí. Ní gbogbo ìgbà tí ọwọ́ mi máa ń dí nínú iṣẹ́ Ọlọ́run tàbí nígbà tí wọ́n bá fi mí sẹ́wọ̀n, Nela kò ṣàròyé rí pé mi ò kì í gbélé. Lákòókò ìṣòro, ńṣe ló máa ń tu àwọn èèyàn nínú dípò kó máa bára jẹ́.

Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1974, wọ́n mú èmi àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mìíràn. Àwọn arákùnrin kan tí wọ́n mọ̀ nípa ọ̀ràn náà sì fẹ́ sọ fún ìyàwó mi lọ́nà pẹ̀lẹ́tù. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n béèrè pé, “Arábìnrin Nela, ṣé o ò ní bara jẹ́?” Àyà rẹ̀ kọ́kọ́ já, ó rò pé mo ti kú. Nígbà tó wá mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an, ọkàn rẹ̀ wá balẹ̀, ó sì sọ pé: “Hà, ìyẹn ni pé kò kú! Ó pẹ́ tó ti máa ń ṣẹ̀wọ̀n.” Àwọn arákùnrin náà wá sọ fún mi lẹ́yìn náà pé ọkàn rere tí Nela fi gba ọ̀rọ̀ náà wú àwọn lórí gan-an.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tó ń bani nínú jẹ́ ti ṣẹlẹ̀ sí wa sẹ́yìn, Jèhófà ń san èrè rẹpẹtẹ fún wa nítorí pé à ń pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó pé Lidia ọmọbìnrin wa, àti ọkọ rẹ̀, Alfred DeRusha, jẹ́ tọkọtaya Kristẹni tó ṣeé wò fi ṣàpẹẹrẹ. Wọ́n tọ́ àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì, Christopher àti Jonathan, láti jẹ́ ìránṣẹ́ tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, èyí sì ń fi kún ayọ̀ wa. Àbúrò mi ọkùnrin, Ryszard, àti àbúrò mi obìnrin, Urszula, náà ti jẹ́ Kristẹni olóòótọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Jèhófà kò fi wá sílẹ̀ rí, a sì fẹ́ láti máa fi gbogbo ọkàn wa sìn ín nìṣó. Àwa fúnra wa ti rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 37:34 tó sọ pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé.” À ń fi gbogbo ọkàn wa retí àkókò náà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ní àpéjọ tá a ṣe nínú ọgbà arákùnrin kan nílùú Kraków, 1964

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Èmi àti Nela, ìyàwó mi, àti ọmọbìnrin wa Lidia, 1968

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Mo dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọmọdékùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣáájú kí wọ́n tó ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn fún un láìlo ẹ̀jẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Èmi àti Dókítà Wites, olórí àwọn oníṣègùn tó ń ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn fáwọn ọmọdé láìlo ẹ̀jẹ̀ ní ọsibítù Katowice

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Èmi àti Nela, 2002

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́