Èmi Kìnnìún Tí Ń Bú Ramúramù Nígbà Kan Rí Wá Di Àgùntàn Onínú Tútù
BÍ ENRIQUE TORRES KÉKERÉ ṢE SỌ Ọ́
WỌ́N bí mi ní ọdún 1941 ní erékùṣù Caribbean tó wà ní Puerto Rico, tí èdè tó wọ́pọ̀ tí àwọn èèyàn ń sọ níbẹ̀ jẹ́ èdè Spanish. Kòlàkòṣagbe, tí ń ṣe ẹ̀sìn Àgùdà ni àwọn òbí mi, ṣùgbọ́n wọn ò fi ẹ̀kọ́ ìsìn kankan kọ́ èmi, àti àbúrò mi obìnrin àti àbúrò mi ọkùnrin (tó kú lọ́mọdé), a kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì.
Ìdílé wa ṣí kúrò ní Puerto Rico lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní ọdún 1949. New York City ní Ìlà Oòrùn Harlem, tó ń jẹ́ El Barrio la ń gbé. Ibẹ̀ la ń gbé títí di ọdún 1953. Kò rọrùn fún mi láti máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìṣòro yìí mú kí n máa rò pé mi ò kúnjú òṣùwọ̀n.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Kó Ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́
Nígbà tó yá, ìdílé wa kó lọ sí àdúgbò Prospect Heights ní Brooklyn. Àárín àsìkò yìí ni àwọn ojúgbà mi tí mo ń bá kẹ́gbẹ́ sún mi wọ ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìta kan. Nígbà tó yá, wọ́n fi mí ṣe olórí ẹgbẹ́ náà. Lẹ́yìn ìyẹn ni mo wá di olórí ẹgbẹ́ ọmọ ìta mìíràn, tó máa ń jí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé. Bákan náà ni mo tún ń gba gbèsè tí àwọn atatẹ́tẹ́ láìbófinmu jẹ fún alájọ tẹ́tẹ́ ládùúgbò. Látorí ìyẹn, mo di fọ́léfọ́lé, wọ́n sì mú mi nígbà bíi mélòó kan kí n tó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Lásìkò yẹn, mi ò lọ iléèwé mọ́.
Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ìjọba rán mi lọ sígbèkùn ní Puerto Rico fún ọdún márùn-ún gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀bẹ̀ fún dídín ìjìyà mi kù. Wọ́n mú mi lọ síbi tí bàbá mi àgbà àti ìdílé rẹ̀ ń gbé. Gbajúmọ̀ ọlọ́pàá tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún, tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ni. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ọdún kan ni bàbá mi àgbà dá mi padà sí Brooklyn nítorí ọtí àmudàlúrú tí mo ń mu, tí mo ń bá àwọn èèyànkéèyàn kẹ́gbẹ́, tí mo sì ń fọ́lé kiri.
Ipa Tí Bàbá Mi Kó Nínú Ọ̀rọ̀ Mi
Nígbà tí mo padà sí New York City láti Puerto Rico, mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí bá bàbá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n ìgbésí ayé tèmi ò gba apá ibẹ̀ yẹn. Mi ò jáwọ́ gbígbé ìgbésí ayé aláìwà-bí-Ọlọ́run, mo sì di ajoògùnyó àti ọ̀mùtípara. Mo wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta fọ́léfọ́lé àti adigunjalè, èyí tó mú kí wọ́n mú mi ní ọdún 1960. Wọ́n dá mi lẹ́bi, wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta.
Ní ọdún 1963, wọ́n tú mi sílẹ̀ lábẹ́ àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n tún mú mi fún ẹ̀sùn ìfọ́lé, mo sì ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ti Erékùṣù Rikers, ní New York City. Wọ́n tú mi sílẹ̀ ní ọdún 1965. Àmọ́, wọ́n tún mú mi fún ẹ̀sùn ìpànìyàn lọ́dún yẹn kan náà. Ìwà òǹrorò, bíi ti kìnnìún gbáà ni mo ní!
Ilé ẹjọ́ fi mí sẹ́wọ̀n ogún ọdún ní ẹ̀wọ̀n Dannemora, ní ìhà gúúsù ìpínlẹ̀ New York. Ibẹ̀ ni mo ti dara pọ̀ mọ́ àwọn oníwàkiwà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Bó ti wù kó rí, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bá bàbá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì ń sìn bí alàgbà nínú ìjọ kan ní Harlem. Ó sábà máa ń wá bẹ̀ mí wò nígbà tí mo ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, ìgbà gbogbo ló sì máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, orúkọ Rẹ̀, àti ète Rẹ̀.
Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí mo wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Dannemora, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tó ń yáni lówó èlé gọbọi. Lásìkò yẹn, ní ọdún 1971, rúkèrúdò kan bẹ́ sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n mìíràn ní Ìpínlẹ̀ New York, Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Elétò Ìyíwàpadà ti Attica. Ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn ló kọ nípa rúkèrúdò yìí, àwọn ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n jákèjádò ayé sì sọ nípa rẹ̀. Lẹ́yìn rúkèrúdò yìí, ọ̀gá wọ́dà ronú pé ó yẹ kí òun kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn níwàkiwà sọ́tọ̀ kí irú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn má bàa ṣẹlẹ̀ ní Dannemora. Ó wá kó àwọn wọ̀nyí sọ́tọ̀ sínú àwọn ilé àkànṣe kan.
Lára ẹgbàá ó lé igba [2,200] ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀, àwa bí igba ni wọ́n kó sọ́tọ̀. Wọ́n tún ṣe àyẹ̀wò kínníkínní síwájú sí i, èyí sì yọrí sí ṣíṣa àwọn kan, wọ́n sì lù wọ́n lálùbami. Ní àfikún sí i, wọ́n máa ń fi oògùn sínú oúnjẹ wa gẹ́gẹ́ bí apá kan ohun tí wọ́n pè ní “ètò ìyíwàpadà.”
Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n máa mú mi sí ilé àdádó yẹn látàrí híhùwà ewèlè. Ṣùgbọ́n, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe mí bọ́ṣẹ ṣe ń ṣojú, ó sì pa mí lára gan-an. Àwọn ẹ̀ṣọ́ kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lọ́wọ́, wọ́n de ẹsẹ̀ mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì ń lù mí lálùbami lọ́pọ̀ ìgbà. Mo tún ní láti fara da ìwọ̀sí ẹlẹ́yàmẹ̀yà tí wọ́n ń fi kàn mí léraléra nítorí pé mo jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn. Nítorí ìwọ̀sí àti lílù tí wọ́n ń lù mí, mo kọ̀ láti jẹun tó pọ̀ tó ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi mú mi sọ́tọ̀ fún oṣù mẹ́ta. Èyí mú kí ń fi nǹkan bí ogún kìlógíráàmù fọn.
Àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ṣebí ẹni pé àwọn ò gbọ́ gbogbo ìbéèrè bàbá mi nípa ara mi tí kò yá. Èyí mú kí n sọ̀rètí nù, mo bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí àwọn òṣèlú láti ràn mí lọ́wọ́, kí wọ́n sì ṣe nǹkan nípa ìyà tí wọ́n fi ń jẹ mí.
Léraléra ni bàbá mi ń lọ sí àwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn láti sọ nípa lílu àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n wà ní ilé àkànṣe náà lálùbami, fífìwọ̀sí lọ̀ wọ́n, àti fífi oògùn sínú oúnjẹ wọn. Ìwé ìròyìn Amsterdam News nìkan ṣoṣo ló ṣe nǹkan sí i nípa kíkọ àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí ipò tí ń bani nínú jẹ́ náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá mi tún lọ sọ́dọ̀ Kọmíṣọ́nnà Ètò Ìyíwàpadà, ní Albany, New York, ohun tó sì máa ń wí fún bàbá mi ni pé ibi tí gbogbo àwọn tó kù wà ni mo wà. Ńṣe ni àwọn òṣèlú tí mo ń kọ̀wé sí nípa ipò tí a wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kọtí ikún. Inú mi bà jẹ́ gan-an ju ti ìgbàkigbà rí lọ, nítorí pé ńṣe ló wá jọ pé kò sí ẹni tí mo lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́ mọ́.
Ìgbà yẹn ni mo wá rántí díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí bàbá mi ti bá mi sọ tẹ́lẹ̀. Mo wá pinnu láti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.
Yíyíjú sí Ọlọ́run
Kí n tó gbàdúrà mo rántí bí bàbá mi ṣe máa ń fún mi níṣìírí léraléra pé kí n yé máa gbàdúrà sí Jésù bí kò ṣe sí Bàbá Jésù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà. Mo dọ̀bálẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀ inú ẹ̀wọ̀n, mo sì sọ pé mo kábàámọ̀ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé tí mo ń tọ̀ tẹ́lẹ̀, èyí tó yọrí sí lílo iye tó ju ìdajì gbogbo ọdún tí mo ti lò láyé ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Mo fi tọkàntọkàn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè bọ́ nínú wàhálà yìí nítorí mo ti wá mọ̀ pé òun nìkan ló ní agbára láti yọ mí nínú ìṣòro yìí.
Mi ò mọ bí àdúrà tí mo gbà náà ṣe gùn tó, ṣùgbọ́n mo gbé gbogbo ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá yẹ̀ wò, mo sì tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Jèhófà pẹ̀lú ẹ̀mí ìrònúpìwàdà. Mo ṣèlérí pé màá gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n mú mi kúrò níbi tó dà bí àjàalẹ̀ tí wọ́n dá fi mí sí náà lọ sí àárín ọgbà ẹ̀wọ̀n táwọn tó kù wà. Ìgbà yẹn ni mo ṣíwọ́ yíyan oúnjẹ lódì.
Láti mú ìlérí tí mo ṣe pé màá kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà ṣẹ, mo bẹ̀rẹ̀ sí ka Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí nípa ìtumọ̀ Bíbélì yìí ni èèpo ẹ̀yìn aláwọ̀ ewé tó ní. Mo fẹ́ràn èyí nítorí pé àwọ̀ ṣíṣì, àwọ̀ tí ń múni sorí kọ́ ni àwọ̀ aṣọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, àwọn iyàrá ẹ̀wọ̀n, odi ẹ̀wọ̀n, àti àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ ibẹ̀ ní. Nígbà tó yá, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé wọ́n yí àwọ̀ gbogbo wọn padà sí àwọ̀ ewé. Ẹ̀ka Ètò Ìyíwàpadà ló fọwọ́ sí i pé kí wọ́n lo àwọ̀ yìí lẹ́yìn rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ti Attica.
Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, tí bàbá mi ti ṣètò pé kí wọ́n máa mú wá fún mi. Kíka ìrírí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ṣẹ̀wọ̀n nítorí dídi ìgbàgbọ́ wọn mú, tí ìyà tó ti jẹ wọ́n sì ju tèmi lọ wú mi lórí gidigidi. Àwọn èèyàn wọ̀nyí ò kúkú hùwà burúkú kankan ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n di ìṣòtítọ́ wọn sí Ọlọ́run mú ni wọ́n ṣe jìyà láìnídìí. Àmọ́, ìyà tí èmi ń jẹ tọ́ sí mi. Nígbà tí mo ka àwọn ìrírí yẹn, ó wọ̀ mí lọ́kàn, ó sì fún mi níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lẹ́yìn ọdún kan, wọ́n pè mí síwájú ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìtúsílẹ̀ lábẹ́ àyẹ̀wò. Wọ́n gbé ọ̀rọ̀ mi yẹ̀ wò, títí kan ìrírí agbonijìgì tí mo ní nílé àkànṣe tí wọ́n ju èmi nìkan sí. Inú mi dùn nígbà tí mo gbọ́ pé wọ́n fẹ́ tú mi sílẹ̀ lọ́dún 1972 níbàámu pẹ̀lú ètò ìtúsílẹ̀ lábẹ́ àyẹ̀wò.
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí mo jáde lẹ́wọ̀n, mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní àgbègbè Harlem tí àwọn tí ń sọ èdè Spanish pọ̀ sí. Ṣùgbọ́n mo ṣì ń nímọ̀lára pé mi ò tóótun láti máa dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti kọ́ nípa Jèhófà, ètò àjọ rẹ̀, àti àwọn èèyàn rẹ̀. Mo tún nílò àkókò láti mú ara mi bá àwùjọ ẹ̀dá mu lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí mo ti lò lẹ́wọ̀n.
Ìbànújẹ́ ló jẹ́ pé n kò lè pa àwọn ìwà mi àtijọ́ tì. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí joògùn yó, mo ń hùwà ọ̀daràn, mo sì ń gbé ìgbésí ayé aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan sí i. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, èyí tún mú kí wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́ẹ̀kan sí i. Àmọ́, mo nímọ̀lára pé ó ní láti jẹ́ pé Jèhófà rí nǹkan tó dára nínú ọkàn-àyà mi, nítorí ọ̀rọ̀ mi ò sú u. Ohun tí mo kàn lè sọ fún yín ni pé yálà èèyàn wà lẹ́wọ̀n tàbí kò sí lẹ́wọ̀n, Jèhófà kì í pa àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tì, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rọ̀ wọn kì í sú u.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Lọ́tẹ̀ yìí, nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Dannemora, mo lo àǹfààní ètò tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n gbé mi lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ìyíwàpadà ti Mid-Orange, tó jẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n alábọ́ọ́dé ẹ̀ṣọ́, ní àríwá ìpínlẹ̀ New York. Èyí yàtọ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹlẹ́ṣọ̀ọ́ gíga jù lọ ní Dannemora.
Lẹ́yìn ọdún méjì tí mo ti wà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ìyíwàpadà ti Mid-Orange, mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ẹlẹ́wọ̀n mìíràn ń ṣe, tí àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n fọwọ́ sí. Ìyá rẹ̀, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló ṣètò pé kí wọ́n wá máa bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí. Níkẹyìn, nípa títẹ̀síwájú láti máa gba ìmọ̀ sínú, mo bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, èyí tó wá mú kí n tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ̀ lẹ́ẹ̀meje láti tú mi sílẹ̀ lábẹ́ àyẹ̀wò, wọ́n wá tú mi sílẹ̀ bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kẹjọ lábẹ́ àyẹ̀wò. Ìdí tí wọ́n ní àwọn fi kọ̀ láti tú mi sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ lábẹ́ àyẹ̀wò ni pé “ìtẹ̀sí àtihùwà ọ̀daràn ti jọba lọ́kàn” mi. Wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́yìn tí mo ti ṣe ọdún mẹ́jọ lára ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí wọ́n ní kí n ṣe lẹ́wọ̀n.
Ìtúsílẹ̀ Kúrò Nínú Òkùnkùn Níkẹyìn
Nígbà tí wọ́n tú mi sílẹ̀, ọkàn mi tún ṣáko lọ, mo sì tún juwọ́ sílẹ̀ fún àṣà ìjoògùnyó fún ìgbà díẹ̀. Bákan náà, mo ń gbé pọ̀ pẹ̀lú obìnrin kan nínú ìdè ìgbéyàwó àjọgbà. Ọdún 1972 la bẹ̀rẹ̀ àjọṣe náà. Ṣùgbọ́n ní ọdún 1983, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún bẹ̀rẹ̀ sí bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́tẹ̀ yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Àmọ́, kí n tó bẹ̀rẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ àti lílọ sípàdé, mi ò joògùn mọ́, mi ò sì mu sìgá mọ́.
Síbẹ̀síbẹ̀, mo ṣì ń gbé pẹ̀lú obìnrin tí a jọ wà nínú ìdè ìgbéyàwó àjọgbà náà, ní ìlòdì sí òfin Ọlọ́run nípa ìgbéyàwó. Èyí ń da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú, nítorí náà, mo gbìyànjú kí obìnrin náà lè gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí a sì fìdí àjọṣe wa múlẹ̀ lábẹ́ òfin nípa ṣíṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n ó sọ pé èèyàn kan ló kọ Bíbélì, pé àwọn ọkùnrin ló ṣe é láti fi tẹ àwọn obìnrin lórí ba àti pé kò pọn dandan kí a ṣègbéyàwó.
Mo ronú pé mi ò lè máa gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla pẹ̀lú obìnrin tí kò bọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run nípa ìgbéyàwó. Nítorí náà, mo fòpin sí àjọṣe wa, mo sì kó lọ sí Brooklyn. Mo mọ̀ pé mi ò lè máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti ète rẹ̀ bí àwọn àlámọ̀rí ìgbésí ayé mi kò bá sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin rẹ̀.
Nígbà tí mo bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìdè tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, tí mo sì ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọdún mẹ́ta, mo fi ẹ̀rí ọkàn mímọ́ ya ara mi sí mímọ́ fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, mo sì fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa ṣíṣèrìbọmi ní àpéjọpọ̀ kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Mi ò kábàámọ̀ rárá nípa ìlérí tí mo ṣe pé màá mọ Ọlọ́run tí bàbá mi sábà máa ń sọ orúkọ rẹ̀ fún mi. Bákan náà, màá ṣiṣẹ́ kára láti pa ìlérí tí mo ṣe fún Jèhófà nínú àjàalẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Dannemora mọ́ títí òun yóò fi mú ọ̀pọ̀ ìbùkún tó ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.
Fífojúsọ́nà fún Párádísè
Mo ń fojú sọ́nà gan-an fún ìgbà tí Jèhófà yóò sọ gbogbo ilẹ̀ ayé yìí di párádísè ẹlẹ́wà. (Sáàmù 37:11, 29; Lúùkù 23:43) Bákan náà ni mo ń fojú sọ́nà fún ìlérí mìíràn tí Ọlọ́run ṣe—àjíǹde àwọn òkú láti jàǹfààní wíwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Àkókò yẹn á mà ga o, nígbà tí màá lè kí àwọn olùfẹ́ mi tó ti kú káàbọ̀ láti inú sàréè, títí kan bàbá mi, àbúrò mi ọkùnrin, àti àwọn mìíràn tí mo mọ̀ tí ikú pa láìtọ́jọ́! Mo sábà máa ń ronú nípa ìrètí yìí, ó sì máa ń mú inú mi dùn. Ayọ̀ mìíràn tí mo ní nísinsìnyí ni pé àwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì àti àwọn kan lára àwọn ọmọ wọn ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ti ṣèrìbọmi.
Nísinsìnyí, bí mo ṣe ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìgbàgbọ́ mi, tí mo sì ń sọ ìrírí mi fún wọn, ó máa ń tẹ́ mi lọ́rùn láti jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀rọ̀ ìtùnú tí onísáàmù náà sọ, tí a ṣàkọsílẹ̀ sínú Sáàmù 72:12-14 pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.”
Sùúrù tí Jèhófà ní fún mi ti mú ọkàn-àyà mi yọ̀, ó sì ti mú kí n kọ́ àwọn ìwà tó ń fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ ní, kí n sì máa fi wọ́n ṣèwàhù—kì í ṣe àwọn ìwà rírorò tó jọ ti kìnnìún, bí kò ṣe àwọn ànímọ́ alálàáfíà, onínúure, àti ọlọ́kàn tútù tí àgùntàn ní. Èyí ṣe pàtàkì, nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ ọ́, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò fi ojú rere hàn sí.”—Òwe 3:34.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]
“Wọ́n tún mú mi fún ẹ̀sùn ìfọ́lé, mo sì ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ti Erékùṣù Rikers, ní New York City. Wọ́n tú mi sílẹ̀ ní ọdún 1965. Àmọ́, wọ́n tún mú mi fún ẹ̀sùn ìpànìyàn lọ́dún yẹn kan náà. Ìwà òǹrorò, bíi ti kìnnìún gbáà ni mo ní!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ọjọ́ tí mo ṣèrìbọmi