‘Ọlọ́run Kì í Gbé Inú Àwọn Tẹ́ńpìlì Tá a Fọwọ́ Kọ́’
ÓDÁJÚ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ àwọn tẹ́ńpìlì Áténà dáadáa, nítorí pé ó máa ń rí wọ́n làwọn ìlú tó bá ṣèbẹ̀wò sí nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopædia Britannica ṣe wí, kì í ṣe kìkì abo ọlọ́run tó wà fún ogun jíjà àti ọgbọ́n nìkan ni wọ́n mọ Áténà sí, wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí “ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ọ̀nà tó sì tún máa ń lépa àlàáfíà.”
Páténónì ni tẹ́ńpìlì tó lókìkí jù lọ lára àwọn tí wọ́n kọ́ fún Áténà, wọ́n sì kọ́ ọ sí ìlú Áténì tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ abo ọlọ́run yìí. Níwọ̀n bí wọ́n ti ka Páténónì sí ọ̀kan lára àwọn tẹ́ńpìlì tó tóbi lọ́lá jù lọ ní ayé ìgbàanì, inú rẹ̀ ni wọ́n gbé ère Áténà tí gígùn rẹ̀ jẹ́ mítà méjìlá, tí wọ́n sì fi wúrà àti eyín erin ṣe sí. Tẹ́ńpìlì tí wọ́n fi mábìlì funfun kọ́ yìí ti gbàfiyèsí gbogbo èèyàn ní ìlú náà fún nǹkan bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún kí Pọ́ọ̀lù tó bẹ Áténì wò.
Bí wọ́n ti ń wò Páténónì lọ́ọ̀ọ́kán, Pọ́ọ̀lù wàásù fún àwùjọ àwọn ará Áténì kan nípa ‘Ọlọ́run tí kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì tá a fọwọ́ kọ́.’ (Ìṣe 17:23, 24) O ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí àwọn tẹ́ńpìlì Áténà ṣe tóbi tó tàbí bí àwọn òrìṣà inú rẹ̀ ṣe lẹ́wà tó ló mú kí Áténà jọ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù lójú ju Ọlọ́run tí kò ṣeé fojú rí tí wọn kò sì mọ̀. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, kò yẹ ká rò pé Ẹlẹ́dàá èèyàn “dà bí wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a gbẹ́ lére nípasẹ̀ . . . ènìyàn.”—Ìṣe 17:29.
Àwọn ọlọ́run àtàwọn abo ọlọ́run bí Áténà tó jẹ́ pé àwọn tẹ́ńpìlì àtàwọn ère ni ògo wọn ti wà nígbà kan rí, àmọ́ wọn kò sí mọ́ báyìí. Ère Áténà ti pa run kúrò nínú tẹ́ńpìlì Páténónì ní ọ̀rúndún kárùn-ún Sànmánì Tiwa, díẹ̀ lára àwókù tẹ́ńpìlì rẹ̀ ló ṣẹ́ kù. Ta ló ń wá ọgbọ́n àti ìtọ́sọ́nà lọ sọ́dọ̀ Áténà lónìí?
Ọ̀ràn ti Jèhófà “Ọlọ́run àìnípẹ̀kun” ẹni tí ẹnikẹ́ni kò lé rí yàtọ̀ pátápátá. (Róòmù 16:26 1 Jòhánù 4:12) Àwọn ọmọkùnrin Kórà kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Ọlọ́run yìí, Ọlọ́run wa ni fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣamọ̀nà wa.” (Sáàmù 48:14) Ọ̀nà kan tá a fi lè máa rí ìtọ́sọ́nà Jèhófà Ọlọ́run gbà ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọrọ̀ rẹ̀ déédéé, ká sì máa fi àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa.