“Ọ̀kan Lára Àwọn Àgbà Iṣẹ́”
NÍGBÀ tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù lákòókò tí Sólómọ́nì Ọba ń ṣàkóso, ìyẹn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn, wọ́n fi bàbà ṣe bàsíà rèǹtèrente kan tí wọ́n máa ń da omi sí, wọ́n sì gbé e sí ẹnu ọ̀nà ní ìta tẹ́ńpìlì. Bàsíà náà wúwo ju ọgbọ̀n tọ́ọ̀nù (ìyẹn ẹgbẹ̀ta àpò sìmẹ́ǹtì) lọ, ó sì lè gbà tó ọ̀kẹ́ méjì lítà [40,000] omi, (tí í ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbàafà [11,000] gálọ̀nù). A pé bàsíà ńlá yìí ní agbada ńlá dídà. (1 Àwọn Ọba 7:23-26) Albert Zuidhof, tó jẹ́ amojú ẹ̀rọ̀ fún Àjọ Aṣèwádìí Ti Ìjọba Kánádà nígbà kan rí, sọ nínú ìwé Biblical Archeologist pé: “Kò sí ìyè méjì níbẹ̀ pé agbada ńlá dídà yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbà iṣẹ́ tí wọ́n tíì ṣe ní ilẹ̀ Hébérù.”
Báwo ni wọ́n ṣe ṣe agbada ńlá yìí? Bíbélì dáhùn pé: “Àgbègbè Jọ́dánì ni ọba ti [da àwọn ohun èlò bàbà] ní ilẹ̀ amọ̀.” (1 Àwọn Ọba 7:45, 46) Zuidhof tún sọ pé: “Ọ̀nà tí a gbà dà á ní láti jọ bí a ṣe máa ń da àwọn agogo ńlá onídẹ lónìí.” Ó ṣàlàyé pé bí a bá fẹ́ ṣe agbada ńlá yìí, ńṣe la ó wá bátànì agbada méjì, à ó ki ọ̀kan bọ èkejì nínú, àlàfo tó bá wà láàárín bátànì agbada méjèèjì yìí là ó da idẹ tá a ti yọ́ yìí sí. Lẹ́yìn tí ó bá ti dì tán la óò ṣí bátànì agbada méjèèjì yìí kúrò láti rí agbada ńlá tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dà náà.
Bí agbada ńlá dídà yẹn ṣe tóbi tó àti bó ṣe wúwo tó fi hàn pé ó gba kéèyàn ní òye iṣẹ́ gidi kó tó lè ṣe é. Àwọn bátànì agbada tá a kì bọ inú ara wọn gbọ́dọ̀ lágbára tí wọ́n á fi lè gbé bàbà dídà tó wúwo tó ọgbọ̀n tọ́ọ̀nù, a sì gbọ́dọ̀ dà á lẹ́ẹ̀kan náà kí agbada ńlá tá a fẹ́ dà náà má bàa sán tàbí kí ó lábùkù. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n dá ọ̀pọ̀ iná ìléru tó gbóná janjan láti yọ́ mẹ́táàlì tí a ó dà sí àlàfo tó wà láàárín bátànì agbada wọ̀nyẹn. Ẹ ò rí pé akọ iṣẹ́ ni!
Nínú àdúrà tí Sólómọ́nì Ọba gbà nígbà tó ń ya tẹ́ńpìlì náà sí mímọ́, ó fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe ní tẹ́ńpìlì náà, ó sọ pé: “O fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ.”—1 Àwọn Ọba 8:24.