Ṣé Ìgbàgbọ́ Tí Aláìsàn Kan Ní Ló Ń Wò Ó Sàn?
NÍGBÀ tí a bá ń ṣàìsàn, a máa ń wá ìtura àti ìwòsàn. Ó ṣeé ṣe kó o ti rí i kà nínú Bíbélì pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù Kristi wo àwọn tí onírúurú àìsàn ń ṣe sàn, tó sì fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà nínú ìpọ́njú ní ìtura. Báwo ni àwọn ìwòsàn wọ̀nyẹn ṣe wáyé? Bíbélì sọ pé nípasẹ̀ ‘agbára Ọlọ́run’ ni. (Lúùkù 9:42, 43; Ìṣe 19:11, 12) Nítorí náà, ẹ̀mí mímọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ṣe ìwòsàn náà, kì í wulẹ̀ ṣe ìgbàgbọ́ tí ẹnì kan ní. (Ìṣe 28:7-9) Ìdí nìyẹn tí Jésù kò ṣe sọ́ fún àwọn aláìsàn pé kí wọ́n fi ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní sí òun hàn kí òun tó wò wọ́n sàn.
O lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé fífi iṣẹ́ ìyanu ṣe ìwòsàn ti di nǹkan àtijọ́ ni, tàbí ǹjẹ́ irú ìwòsàn tí Jésù ṣe tún lè wáyé? Ìrètí wo ló wà fún àwọn tí àìsàn aronilára tàbí àìsàn tí kò gbóògùn ń ṣe?’
Bíbélì ṣàlàyé pé nínú ayé tuntun òdodo ti Ọlọ́run, agbára Ọlọ́run yóò mú kí fífi iṣẹ́ ìyanu woni sàn tún wáyé bí irú èyí tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti fi bí Ọlọ́run ṣe máa ṣe é hàn ọ́ àti ìgbà tó máa ṣe ohun tí oníṣẹ́ ìyanu kankan kò lè ṣe, ìyẹn mímú gbogbo àìsàn àti ikú kúrò. Bẹ́ẹ̀ ni o, ‘Ọlọ́run yóò gbé ikú mì títí láé ní ti tòótọ́.’—Aísáyà 25:8.