ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 3/1 ojú ìwé 30-31
  • Àjálù Ojú Ọjọ́ Dópin!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjálù Ojú Ọjọ́ Dópin!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ó Dìgbà Tí Ọlọ́run Bá Dá sí Ọ̀ràn Náà
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 3/1 ojú ìwé 30-31

Àjálù Ojú Ọjọ́ Dópin!

“ÀWỌN ÈÈYÀN ayé òde òní kò ní ọ̀wọ̀ kankan mọ́ fún ilẹ̀ ayé yìí nítorí pé wọ́n ń fẹ́ ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ, wọ́n ń wá nǹkan ní kíákíá, wọ́n sì fẹ́ dọlọ́rọ̀ òjijì.” Inú bébà tí wọ́n fi bo ìwé náà 5000 Days to Save the Planet ni wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí sí. Ohun tí ẹ̀mí ìwọra àwọn èèyàn fà la wà nínú rẹ̀ yìí. Yálà òótọ́ ni èrò táwọn èèyàn ní pé ayé yìí ń móoru tàbí kì í ṣóòótọ́, ohun kan tó dájú ni pé, àwọn èèyàn ń ba ilẹ̀ ayé rírẹwà tá à ń gbé yìí jẹ́. Ohun kan ṣoṣo tó lè bá wa yanjú ìṣòro náà ni ìmúṣẹ ìlérí tí Bíbélì ṣe pé, Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.

Ọlọ́run yóò fi ètò tuntun kan rọ́pò ètò ìjọba èèyàn tó ti bà jẹ́ yìí. Kó o tó sọ pé ìsọkúsọ lọ̀rọ̀ yẹn, kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò ná: Ǹjẹ́ a rẹ́ni tó lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe sí ilẹ̀ ayé yìí ju Ẹni tó ṣẹ̀dá rẹ̀ lọ? Ǹjẹ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti darí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé yìí? Bíbélì mú kó ṣe kedere pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ nínú Aísáyà 45:18 pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” Láti lè mú ètè yẹn ṣẹ, Ọlọ́run lè dá sí ọ̀ràn ilẹ̀ ayé, ó sì dájú pé ó máa dá sí i.

Ọ̀nà tí Ọlọ́run yóò gbà dá sí ọ̀ràn náà ni pé á gbé ìjọba tuntun kan kalẹ̀ tí yóò máa ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Nígbà táwọn Kristẹni bá ń gba àdúrà tá à ń pé ní Àdúrà Olúwa, tó sọ pé, “Kí ìjọba rẹ dé,” ìjọba yẹn ni wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún pé kó gba àkóso ayé. (Mátíù 6:9, 10) Ọ̀nà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò máa gbà ṣiṣẹ́ yóò fi hàn pé ó lóye ọ̀nà tí àwọn nǹkan ilẹ̀ ayé gbà ń ṣiṣẹ́ létòlétò. Nígbà náà, yóò wá tún àwọn apá ibi táwọn èèyàn ti bà jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ṣe. Aísáyà 35:1, 6 sọ pé: “Pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò . . . yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. . . . Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.”

Ó Dìgbà Tí Ọlọ́run Bá Dá sí Ọ̀ràn Náà

Lẹ́yìn ìkún omi kan tó wáyé lọ́dún 2002, Helmut Schmidt tó jẹ́ olórí ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì tẹ́lẹ̀ kọ̀wé pé: “Kò ṣẹni tó lè dènà àwọn ipá àdáyébá bí afẹ́fẹ́, omi, iná àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kó má ba ìsédò jẹ́. Ìjábá ń ṣẹlẹ̀ ṣáá ni.” Òótọ́ sì ni. Nígbà tí àjálù ojú ọjọ́ bá wáyé, kò sóhun táwọn èèyàn lè ṣe ju pé kí wọ́n máa bá a yí. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo wàhálà tí irú àjálù bẹ́ẹ̀ lè fà, ó ṣì ní àǹfààní tirẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè sún àwọn èèyàn láti fi ìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wọn, kí wọ́n sì ṣaájò wọn. (Máàkù 12:31) Bí àpẹẹrẹ, ó jọ pé irú ohun tí ìkún omi tó wáyé ní ilẹ̀ Yúróòpù mú káwọn èèyàn kan ṣe nìyẹn. Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè Jámánì làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tọkàntara ti wá ṣe iṣẹ́ [ìrànwọ́]. Ìyẹn ní ìgbà tí iye àwọn èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn tíì pọ̀ jù lọ látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì.”

Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyí. Ìwà àti ìṣe àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìgbésí ayé á ṣe rí lábẹ́ ìjọba Ọlọ́run tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, níbi tí ìfẹ́ àti ẹ̀mí aájò yóò ti gbilẹ̀, tí kò ní sí ẹ̀mí ìwọra àti ìmọtara-ẹni-nìkan mọ́.—Aísáyà 11:9.a

Àwọn Kristẹni lè fi ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tu ara wọn nínú, ó ní: “Dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò pèsè òjò fún ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀, òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé.” (Diutarónómì 11:14) Ìlérí yẹn ń bọ̀ wá ṣẹ láìpẹ́ fún àwọn tí yóò láǹfààní láti gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, ìyẹn ayé kan tí àjálù ojú ọjọ́ kò ti ní wáyé mọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ìjọba tí Bíbélì ṣèlérí rẹ̀ yìí, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ṣíṣàkóso Ojú Ọjọ́ Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ

Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àwọn èèyàn kò ní máa bẹ̀rù mọ́ pé ìjì yóò ba ilé àwọn tàbí nǹkan ọ̀gbìn àwọn jẹ́. (2 Pétérù 3:13) Bíbélì mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, lágbára láti ṣàkóso ojú ọjọ́. Gbé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

◼ Jẹ́nẹ́sísì 7:4: “Ní ọjọ́ méje péré sí i, èmi yóò mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.”

◼ Ẹ́kísódù 14:21: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú òkun náà padà sẹ́yìn nípa ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle láti òru mọ́jú tí ó sì yí ìsàlẹ̀ òkun padà di ilẹ̀ gbígbẹ, a sì pín omi náà níyà.”

◼ 1 Sámúẹ́lì 12:18: “Sámúẹ́lì ké pe Jèhófà, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ààrá àti òjò wá ní ọjọ́ yẹn, tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ènìyàn náà fi bẹ̀rù Jèhófà àti Sámúẹ́lì gidigidi.”

◼ Jónà 1:4: “Jèhófà fúnra rẹ̀ sì rán ẹ̀fúùfù ńláǹlà jáde sí òkun, ìjì líle ńláǹlà sì wá wà lórí òkun; àti ní ti ọkọ̀ òkun náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́.”

◼ Máàkù 4:39: “Pẹ̀lú ìyẹn, ó [Jésù tí Ọlọ́run fún lágbára] gbéra nílẹ̀, ó sì bá ẹ̀fúùfù náà wí lọ́nà mímúná, ó sì wí fún òkun náà pé: ‘Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!’ Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a kò ní bẹ̀rù ojú ọjọ́ tó léwu mọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́