Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Àwọn Áńgẹ́lì fún Ìrànlọ́wọ́?
ǸJẸ́ ó tọ̀nà láti máa gbàdúrà sáwọn áńgẹ́lì nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò bẹ́ẹ̀. Àní, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ohun tó lè mú ká gbàdúrà . . . sí àwọn áńgẹ́lì . . . kò jú pé kí wọ́n lè bá wa bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n ṣé ó yẹ ká máa gbàdúrà sáwọn áńgẹ́lì láti bá wa bẹ̀bẹ̀?
Orúkọ àwọn méjì péré ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mẹ́nu kàn nínú àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, àwọn ni Máíkẹ́lì àti Gébúrẹ́lì. (Dáníẹ́lì 8:16; 12:1; Lúùkù 1:26; Júúdà 9) Níwọ̀n bí Bíbélì ti dárúkọ àwọn wọ̀nyí, a róye pé olúkúlùkù áńgẹ́lì jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tó lórúkọ tirẹ̀, wọn kì í wulẹ̀ ṣe ipá kan tí a kò mọ̀. Síbẹ̀, àwọn áńgẹ́lì kan kò sọ orúkọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jékọ́bù béèrè orúkọ áńgẹ́lì kan tó wá a wá, áńgẹ́lì náà kò sọ fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 32:29; Àwọn Onídàájọ́ 13:17, 18) Kò síbi tá a to orúkọ àwọn áńgẹ́lì sí nínú Bíbélì, ìyẹn ni kò jẹ́ káwọn èèyàn máa fún wọn láfiyèsí tí kò yẹ.
Ọ̀kan lára iṣẹ́ àwọn áńgẹ́lì ni láti máa jíṣẹ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Àní, ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a túmọ̀ sí “áńgẹ́lì” ní ṣáńgílítí túmọ̀ sí “ìránṣẹ́.” Àmọ́ ṣá o, àwọn áńgẹ́lì kì í ṣe alárinà tó máa ń gbé àdúrà àwọn èèyàn lọ́ sórí ìtẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ. Ọlọ́run ti sọ pé ká máa darí àdúrà sí òun ní orúkọ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, ẹni tó sọ pé: ‘Ohunkóhun yòówù tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, yóò fi í fún yín.’—Jòhánù 15:16; 1 Tímótì 2:5.
Bó ti wù kí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run dí tó, kò ní ṣaláì tẹ́tí sí wa tá a bá gbàdúrà sí i lọ́nà tó yẹ. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́.”—Sáàmù 145:18.