ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 4/1 ojú ìwé 30-31
  • Liberia—Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run Ń Tẹ̀ Síwájú Láìfi Ogun Pè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Liberia—Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run Ń Tẹ̀ Síwájú Láìfi Ogun Pè
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ìrànlọ́wọ́ Fáwọn Aláìní
  • Ìhà Táwọn Èèyàn Kọ sí Ìhìn Rere Náà
  • Bí Ẹnì Kan Ṣe Yí Padà
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 4/1 ojú ìwé 30-31

Liberia—Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run Ń Tẹ̀ Síwájú Láìfi Ogun Pè

Ó TI lé lọ́dún mẹ́wàá tógun abẹ́lé ti ń jà ní Liberia. Nígbà tó fi máa di ìdajì ọdún 2003, àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti kó ogun wọ olú ìlú, ìyẹn Monrovia. Àìmọye ìgbà ló di kànńpá fún ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti fi ilé wọn sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn ti jí ẹ̀rù wọn kó.

Ó bani nínú jẹ́ pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ni wọ́n pa nínú ìjà tó wáyé ní olú ìlú náà. Ẹlẹ́rìí méjì wà lára àwọn tí wọ́n pa, ọkùnrin kan àtobìnrin kan. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí yòókù ṣe lábẹ́ ipò tó le koko yìí, ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n sì rí gbà?

Ìrànlọ́wọ́ Fáwọn Aláìní

Jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí ogun náà ń lọ lọ́wọ́, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Liberia ṣètò ìrànlọ́wọ́ fáwọn aláìní. Wọ́n pèsè oúnjẹ, àwọn ohun èlò pàtàkì inú ilé àti oògùn. Ní gbogbo ìgbà táwọn ọlọ̀tẹ̀ fi gba èbúté, oúnjẹ wọ́n bí ojú. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti wòye pé ó ṣeé ṣe kí irú nǹkan báyìí ṣẹlẹ̀ ni wọ́n fi tètè kó àwọn ohun kòṣeémáàní pa mọ́ fún ẹgbẹ̀rún méjì àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti sá lọ sínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà káàkiri ìlú. Àwọn arákùnrin fi ọgbọ́n pín oúnjẹ náà débi pé ó gbé wọn di ìgbà tí wọ́n ṣí èbúté náà padà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Belgium àti ti Sierra Leone kó oògùn wá, ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti ilẹ̀ Faransé sì kó aṣọ wá.

Láìka bí ipò nǹkan ṣe burú tó sí, àwọn ará wa kò sọ̀rètí nù wọ́n sì láyọ̀. Ohun tí ẹnì kan tó sá kúrò nílé lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ fara jọ ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn sọ. Ó sọ pé: “Àwọn ipò tá à ń wàásù nípa rẹ̀ nìyí; a ti ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”

Ìhà Táwọn Èèyàn Kọ sí Ìhìn Rere Náà

Láìfi rògbòdìyàn tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà pè, àwọn Ẹlẹ́rìí ń rí àbájáde tó dára nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ní January 2003, wọ́n ní iye akéde Ìjọba tó pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ, wọ́n jẹ́ ẹgbàajì ó dín mọ́kànlélọ́gọ́fà [3,879]. Nígbà tó sì di February ọdún kan náà, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ṣe jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ àti okòólénígba ó lé méje [15,227].

Kíá làwọn èèyàn ń fìfẹ́ hàn sí ìhìn rere náà. Àpẹẹrẹ kan ni ti èyí tó ṣẹlẹ̀ ní abúlé kan ní ìhà gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Ìjọ kan wéwèé láti ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní abúlé ńlá Bewahn, abúlé yìí tó nǹkan bí ìrìn wákàtí márùn síbi tí wọ́n ti máa ń ṣèpàdé. Káwọn ará tó lọ sábúlé náà láti lọ pe àwọn èèyàn wá sí Ìṣe Ìrántí, baálẹ̀ abúlé náà ti rí ìwé ìkésíni gbà. Nígbà tó gba ìwé ìkésíni náà, ó gbé Bíbélì rẹ̀, ó sì lọ́ bá àwọn ará abúlé náà, ó ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé ìkésíni náà, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí. Nígbà táwọn akéde dé sí abúlé náà, wọ́n rí i pé wọ́n ti bá wọn ṣe iṣẹ́ tí wọ́n wá ṣe! Baálẹ̀ abúlé náà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìyàwó rẹ̀ méjèèjì wá sí Ìṣe Ìrántí náà. Lápapọ̀, èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló wá. Látìgbà yẹn ni baálẹ̀ abúlé náà kò ti lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì fún wọn nílẹ̀ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan.

Bí Ẹnì Kan Ṣe Yí Padà

Ìwà àwọn ará wa náà ti yí èrò tí àwọn kan tó jẹ́ alátakò ní nípa òtítọ́ padà. Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Opoku. Òjíṣẹ́ kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe pàdé rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, ó sì fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọ̀ ọ́. Opoku fẹ́ ka àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn náà, ṣùgbọ́n kò lówó lọ́wọ́. Aṣáájú ọ̀nà náà ṣàlàyé fún un pé a kò díye lé ìwé wa, ó fún un ní ìwé ìròyìn náà, ó sì ṣètò láti padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí aṣáájú ọ̀nà náà padà dé, Opoku bi í pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ mí? Èyí tó pọ̀ ju lọ nínú àwọn èèyàn yín tó wà nílùú Harper ló mọ̀ mí. Nígbà kan sẹ́yìn, ńṣe ni mo máa ń lé àwọn ọmọ yín kúrò ní iléèwé!” Ó wá ṣàlàyé pé òun ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀gá àgbà iléèwé gíga tó wà nílùú yẹn, àti pé nígbà yẹn, òun ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé wọ́n kọ̀ láti kí àsíá.

Àmọ́ ṣá o, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Opoku rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ Kristẹni hàn ló mú kó túnnú rò. Nígbà àkọ́kọ́, ó rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe bójú tó ẹnì kan tó jẹ́ arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí nígbà tí àìsàn ńlá kan kọ lù ú. Kódà wọ́n ṣètò pé kó lọ gbàtọ́jú ní orílẹ̀-èdè kan tó wà nítòsí. Opoku rò pé “èèyàn ńlá” kan ni arákùnrin tó ń ṣàìsàn yìí jẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n nígbà tó yá ló wá rí i pé kì í ṣèèyàn ńlá. Nígbà kejì, Opoku wà lára àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Côte d’Ivoire láwọn ọdún 1990. Lọ́jọ́ kan tí òùngbẹ ń gbẹ ẹ́, ó lọ ra omi lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan. Owó ńlá ni Opoku mú lọ́wọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin yìí kò sì ní ṣéńjì, bó ṣe fún Opoku lómi nìyẹn láìgba kọ́bọ̀. Nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà fún Opoku lómi tán, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ o rò pé àkókò kan lè wà táwa èèyàn yóò máa fún ara wa ní nǹkan láìgba owó kankan lórí ẹ̀?” Opoku béèrè lọ́wọ́ ọmọkùnrin náà bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ọmọkùnrin náà sì sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Ìwà ọ̀làwọ́ àti inú rere tí arákùnrin yìí fi hàn wú u lórí gan-an ni. Níkẹyìn, bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe náà ṣe fún Opoku ní ìwé ìròyìn láìgba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ mú kó rí i pé èrò tí òun ní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí kò tọ̀nà àti pé òun ní láti ṣe ìyípadà. Ó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ní báyìí, ó ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará tó wà ní orílẹ̀-èdè Liberia ń dojú kọ ipò tó le koko, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, wọ́n sì ń fi ìṣòtítọ́ polongo ìhìn rere nípa àkókò tí nǹkan yóò dára lábẹ́ ìṣàkóso òdodo ti Ìjọba Ọlọ́run. Jèhófà kò ní gbàgbé iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí orúkọ rẹ̀.—Hébérù 6:10.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 30]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

MONROVIA

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ní àkókò yánpọnyánrin, àwọn èèyàn Jèhófà máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn aláìní nípa tara àti nípa tẹ̀mí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́