Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí 1 Kọ́ríńtì 10:8 fi sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún [23,000] nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ṣubú lọ́jọ́ kan ṣoṣo nígbà tí Númérì 25:9 sọ pé ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì [24,000] ni?
Onírúurú nǹkan ló lè fa ìyàtọ̀ nínú iye tí ẹsẹ Bíbélì méjèèjì yìí sọ. Àlàyé kan tó rọrùn jù lọ nípa rẹ̀ ni pé, ó lè jẹ́ pé iye tó jẹ́ gan-an bọ́ sáàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún [23,000] àti ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì [24,000], tó fi jẹ́ pé a lè kúkú pè é ní ọ̀kan nínú ọ̀nà méjèèjì.
Tún wo àlàyé mìíràn tó ṣeé ṣe kó jẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Ṣítímù láti fi ṣe ìkìlọ̀ fáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ìgbàanì, tó jẹ́ ìlú kan táwọn èèyàn mọ̀ mọ́ ìwàkiwà. Ó kọ̀wé pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.” Àwọn tí Jèhófà pa nítorí híhu ìwà àgbèrè nìkan ni Pọ́ọ̀lù kàn tọ́ka sí, ó ní wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún.—1 Kọ́ríńtì 10:8.
Àmọ́ ní ti Númérì orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ó sọ fún wa pé: “Bí Ísírẹ́lì ṣe so ara rẹ̀ mọ́ Báálì ti Péórù nìyẹn; ìbínú Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sí Ísírẹ́lì.” Ìyẹn ni Jèhófà fi pàṣẹ pé kí Mósè pa “gbogbo àwọn olórí nínú àwọn ènìyàn náà.” Mósè wá pàṣẹ pé kí àwọn onídàájọ́ ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. Níkẹyìn, nígbà tí Fíníhásì gbéra tó sì pa ọmọ Ísírẹ́lì tó mú ọmọbìnrin Mídíánì wá sínú ibùdó, “òjòjò àrànkálẹ̀ náà dáwọ́ dúró.” Gbólóhùn tó parí ìtàn náà ni: “Àwọn tí ó sì kú nínú òjòjò àrànkálẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì.”—Númérì 25:1-9.
Ẹ̀rí fi hàn pé àti “àwọn olórí nínú àwọn ènìyàn náà” táwọn onídàájọ́ pa àtàwọn tí Jèhófà fúnra rẹ̀ pa ló pa pọ̀ jẹ́ iye tí ìwé Númérì sọ yìí. Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn olórí táwọn onídàájọ́ pa tó ẹgbẹ̀rún, tí àròpọ̀ àwọn tó kú fi jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì. Yálà àwọn olórí tàbí baba ìsàlẹ̀ wọ̀nyí ṣàgbèrè ni o, tàbí wọ́n kópa nínú ayẹyẹ wọn, tàbí wọ́n fọwọ́ sí àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ o, wọ́n ṣáà jẹ̀bi ẹ̀sùn níní “ìsopọ̀ pẹ̀lú Báálì Péórù.”
Ìwé kan tó ṣàlàyé lórí Bíbélì sọ pé gbólóhùn náà, “ní ìsopọ̀ pẹ̀lú,” tí a lò níhìn-ín lè túmọ̀ sí “kéèyàn so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹnì kan.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ àwọn tó ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ “ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Báálì Péórù,” wọ́n ba ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run jẹ́. Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà gbẹnu wòlíì Hóséà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Àwọn fúnra wọn wọlé tọ Báálì ti Péórù, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ya ara wọn sí mímọ́ fún ohun tí ń tini lójú, wọ́n sì wá di ìríra bí ohun ìfẹ́ wọn.” (Hóséà 9:10) Ìdájọ́ Ọlọ́run tọ́ sáwọn tó dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò lóòótọ́. Ìyẹn ni Mósè ṣe rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: “Ojú ẹ̀yin fúnra yín rí ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀ràn Báálì ti Péórù, pé olúkúlùkù ọkùnrin tí ó rìn tọ Báálì ti Péórù lẹ́yìn ni ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pa rẹ́ ráúráú kúrò ní àárín rẹ.”—Diutarónómì 4:3.