ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 7/1 ojú ìwé 3-4
  • Ọlọ́run Ha Tẹ́wọ́ Gba Gbogbo Onírúurú Ìjọsìn Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Ha Tẹ́wọ́ Gba Gbogbo Onírúurú Ìjọsìn Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjọsìn Tí Ó Gbé Ìbéèrè Dìde ní Àkókò Ìgbàanì
  • A Kó Èérí Bá Ìjọsìn Mímọ́ Gaara
  • Ìjọsìn Báálì Ìjọsìn Tó Jìjàdù Láti Gba Ìfọkànsìn Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àkókò Yìí Gan-an Ló Yẹ Kó O Gbé Ìgbésẹ̀ Kánkán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 7/1 ojú ìwé 3-4

Ọlọ́run Ha Tẹ́wọ́ Gba Gbogbo Onírúurú Ìjọsìn Bí?

ỌLỌ́RUN dá àìní fún ohun tẹ̀mí mọ́ ènìyàn—àìní láti jọ́sìn. Kì í ṣe ohun kan tí ó ṣàdédé jẹ yọ. Ó jẹ́ apá kan ènìyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé, aráyé ti mú onírúurú ọ̀nà ìjọsìn dàgbà, fún àwọn tí ó sì pọ̀ jù lọ, ìwọ̀nyí kò tí ì mú ìdílé aláyọ̀, tí ó wà ní ìṣọ̀kan wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ṣì ń ja àwọn ogun afẹ̀jẹ̀wẹ̀ ní orúkọ ìsìn. Èyí gbé ìbéèrè pàtàkì náà dìde pé: Bí ẹnì kan ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run ha ṣe pàtàkì bí?

Ìjọsìn Tí Ó Gbé Ìbéèrè Dìde ní Àkókò Ìgbàanì

Àwọn orílẹ̀-èdè ìgbàanì tí wọ́n gbé ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn pèsè ìtàn ọ̀ràn kan tí ó ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Ọ̀pọ̀ jọ́sìn ọlọ́run tí a ń pè ní Báálì. Wọ́n tún jọ́sìn àwọn obìnrin alábàákẹ́gbẹ́ Báálì, irú bí Áṣérà. Ìjọsìn Áṣérà ní lílo òpó mímọ́ ọlọ́wọ̀ kan tí a gbà gbọ́ pé ó dúró fún ìbálòpọ̀ takọtabo. Àwọn awalẹ̀pìtàn tí ń ṣiṣẹ́ ní ẹkùn yìí ti hú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ère àwọn obìnrin tí wọ́n wà ní ìhòòhò jáde. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé, àwọn ère wọ̀nyí “ṣàfihàn abo-ọlọ́run kan tí a fi àwọn ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ hàn kedere, tí ó fi ọwọ́ kó ọmú rẹ̀ sókè,” tí “ó sì ṣeé ṣe kí ó ṣojú fún . . . Áṣérà.” Ohun kan tí ó dájú ni pé, ìjọsìn Báálì sábà máa ń jẹ́ ti oníwà pálapàla gan-an.

Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé, ìjọsìn Báálì ní ààtò bòńkẹ́lẹ́ tí ó kún fún ìbálòpọ̀ takọtabo nínú. (Númérì 25:1-3) Ṣékémù, ará Kénáánì fipá bá Dínà ọ̀dọ́ tí ó jẹ́ wúńdíá lò pọ̀. Láìka èyí sí, a kà á sí ọkùnrin tí ó yẹ ni bíbọlá fún jù lọ nínú ìdílé rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2, 19) Bíbá ìbátan ẹni tímọ́tímọ́ lò pọ̀, bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, àti bíbá ẹranko lò pọ̀, wọ́pọ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún. (Léfítíkù 18:6, 22-24, 27) Ọ̀rọ̀ náà gan-an, “ìwà àwọn ará Sódómù,” àṣà àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, wá láti inú orúkọ ìlú kan tí ó fìgbà kan rí wà ní apá yẹn nínú ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 19:4, 5, 28) Ìjọsìn Báálì tún ní ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú. Họ́wù, àwọn olùjọsìn Báálì máa ń ju ọmọ wọn láàyè sínú iná tí ń jó lala, gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn! (Jeremáyà 19:5) Gbogbo àṣà wọ̀nyí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn. Lọ́nà wo?

Ọ̀mọ̀wé Merrill Unger nínú ìwé rẹ̀ Archaeology and the Old Testament ṣàlàyé pé: “Ìwà òkú òǹrorò, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti pípa ìtàn ìwáṣẹ̀ àwọn ará Kénáánì tì, burú púpọ̀ ju ti ibòmíràn lọ ní àwọn agbègbè Itòsí Ìlà Oòrùn nígbà yẹn. Àmì ànímọ́ títayọ ti àwọn ọlọ́run àjúbàfún ti àwọn ará Kénáánì, pé wọn kò ní ìwà rere kankan bí ó ti wù kí ó mọ, ti ní láti ṣokùnfà bí àwọn olùjọsìn wọn ṣe mú àwọn ìwà tí ó burú jáì dàgbà, tí wọ́n sì lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà tí ń ba ìwà rere jẹ́ ní àkókò yẹn, irú bí ìwà aṣẹ́wó tí a kà sí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀, [àti] fífi ọmọ rúbọ.”

Ọlọ́run ha tẹ́wọ́ gba ìjọsìn àwọn ará Kénáánì bí? Ó dájú pé kò tẹ́wọ́ gbà á. Ó kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní bí wọn yóò ṣe jọ́sìn òun ní ọ̀nà mímọ́ gaara. Nípa àwọn àṣà tí a mẹ́nu kàn lókè, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe ba ara yín jẹ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí: nítorí pé nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo lé jáde níwájú yín díbàjẹ́: Ilẹ̀ náà sì díbàjẹ́: nítorí náà ni mo ṣe bẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wò lórí rẹ̀, ilẹ̀ tìkára rẹ̀ sì bi àwọn olùgbé rẹ̀ jáde.”—Léfítíkù 18:24, 25.

A Kó Èérí Bá Ìjọsìn Mímọ́ Gaara

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ìjọsìn mímọ́ gaara. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yọ̀ọ̀da kí ìjọsìn Báálì máa bá a nìṣó ní ilẹ̀ wọn. Láìpẹ́, a tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sínú gbígbìyànjú láti pa ìjọsìn Jèhófà pọ̀ mọ́ ti Báálì. Ọlọ́run ha tẹ́wọ́ gba irú àmúlùmálà ìjọsìn yìí bí? Gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà àkóso Ọba Mánásè yẹ̀wò. Ó tẹ́ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó dáná sun ọmọkùnrin rẹ̀ alára gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ, ó sì pidán. “Ó sì gbé ère òrìṣà fífín [ʼashe·rahʹ ní èdè Hébérù] kalẹ̀ tí ó ti ṣe ní ilé náà tí Olúwa sọ . . . pé, Ní ilé yìí, . . . ni èmi óò fi orúkọ mi sí láéláé.”—Àwọn Ọba Kejì 21:3-7.

Àwọn ọmọ abẹ́ Mánásè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọba wọn. Ní tòótọ́, ó “tàn wọ́n láti ṣe búburú ju èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe.” (Àwọn Ọba Kejì 21:9) Dípò tí wọn yóò fi kọbi ara sí àwọn ìkìlọ̀ tí àwọn wòlíì Ọlọ́run ṣe léraléra, Mánásè dẹ́ṣẹ̀ ìpànìyàn dórí fifi ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ kún Jerúsálẹ́mù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mánásè yí padà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọmọkùnrin rẹ̀ àti àtẹ̀lé rẹ̀, Ọba Ámónì, mú ìjọsìn Báálì padà wá.—Àwọn Ọba Kejì 21:16, 19, 20.

Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣẹ́wó nínú tẹ́ḿpìlì. Ojú wo ni Ọlọ́run fi wo irú ohun tí ìjọsìn Báálì gbé jáde yìí? Nípasẹ̀ Mósè, ó kìlọ̀ pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú owó ọ̀yà àgbèrè, tàbí owó ajá [ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹni tí ń gba òmùṣu bọmọdé lòpọ̀], wá sínú ilé OLÚWA Ọlọ́run rẹ fún ẹ̀jẹ́kẹ́jẹ̀ẹ́: nítorí pé ìríra ni àní àwọn méjèèjì sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ.”—Diutarónómì 23:17, 18.

Ọmọ-ọmọ Mánásè, Ọba Jòsáyà, fọ tẹ́ḿpìlì náà mọ́ tónítóní kúrò nínú ìwà pálapàla ti ìjọsìn Báálì. (Àwọn Ọba Kejì 23:6, 7) Ṣùgbọ́n ẹ̀pa kò bóró mọ́. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Ọba Jòsáyà kú, ìjọsìn òrìṣà tún ń wáyé nínú tẹ́ḿpìlì Jèhófà. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 8:3, 5-17) Nítorí náà, Jèhófà mú kí ọba Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ run. Òkodoro òtítọ́ ìtàn bíbani nínú jẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí pé irú àwọn ìjọsìn kan ń bẹ tí Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà. Ní ọjọ́ wa ńkọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́