Ìjọsìn Báálì Ìjọsìn Tó Jìjàdù Láti Gba Ìfọkànsìn Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún tí ìjọsìn kan fi ń jìjàdù láti gba ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ẹ̀rù ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ààtò ìbálòpọ̀ takọtabo ló ń fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti ìdúróṣinṣin tì í. Ìjà àjàkú-akátá yìí ni ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín ìjọsìn Báálì àti ìjọsìn Jèhófà.
ǸJẸ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yóò rọ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ Ọlọ́run tòótọ́ tó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì? (Ẹ́kísódù 20:2, 3) Tàbí kẹ̀, ǹjẹ́ wọn yóò mọ̀ọ́mọ̀ yapa lọ sọ́dọ̀ Báálì, àyànfẹ́ ọlọ́run Kénáánì, tó ṣèlérí láti mú kí ilẹ̀ lẹ́tù lójú?
Ìjà tẹ̀mí yìí, tí wọ́n jà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, kàn wá lónìí. Èé ṣe? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.” (1 Kọ́ríńtì 10:11) Ìkìlọ̀ pàtàkì tó wà nínú ìjà mánigbàgbé yìí yóò túbọ̀ wọ̀ wá lọ́kàn, báa bá mọ ẹni tí Báálì ń ṣe àti ohun tí ìjọsìn Báálì ní nínú.
Ta Ni Báálì?
Ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Kénáánì, ní nǹkan bí ọdún 1473 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ni wọ́n kọ́kọ́ fojú gán-án-ní Báálì. Wọ́n rí i pé àwọn ọmọ Kénáánì ń sin ẹgbàágbèje ọlọ́run tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sáwọn ọlọ́run Íjíbítì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ wọn yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì ní àwọn ànímọ́ kan tó yàtọ̀ síra. Ṣùgbọ́n, Bíbélì fi Báálì hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí òléwájú ọlọ́run àwọn ará Kénáánì, àwọn ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí sì jẹ́rìí sí i pé Báálì ta yọ. (Onídàájọ́ 2:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Báálì kọ́ ni alágbára jù lọ láàárín àwọn ọlọ́run wọn, síbẹ̀ Báálì ni ọlọ́run tó ṣe pàtàkì jù lójú àwọn ará Kénáánì. Wọ́n gbà gbọ́ pé ó ní agbára lórí òjò, ẹ̀fúùfù, àti àwọsánmà, àti pé òun nìkan ló lè gba ènìyàn—àti ẹran ọ̀sìn àti irúgbìn wọn—lọ́wọ́ yíyàgàn àti ikú pàápàá. Láìsí ààbò Báálì, kò sí bí wọ́n ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ àjálù látọ̀dọ̀ Mot, ọlọ́run ẹ̀san ti àwọn ará Kénáánì.
Ìjọsìn Báálì kún fún àwọn ààtò tó tan mọ́ ìbálòpọ̀ takọtabo. Àní àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn Báálì, bí àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀, kún fún àmì ìbálòpọ̀ takọtabo. Ó jọ pé, àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀—tí í ṣe àwọn òkúta tí a gbẹ́ ní ìrísí ẹ̀yà ìbímọ akọ—dúró fún Báálì, ẹ̀yà akọ nínú ìbálòpọ̀ takọtabo. Nígbà tó jẹ́ pé, àwọn òpó ọlọ́wọ̀ jẹ́ àwọn nǹkan tí a figi gbẹ́ tó dúró fún Áṣérà, olorì Báálì, èyí sì dúró fún ẹ̀yà abo.—1 Ọba 18:19.
Iṣẹ́ kárùwà inú tẹ́ńpìlì àti fífi ọmọ wẹ́wẹ́ rúbọ jẹ́ àwọn apá pàtàkì mìíràn nínú ìjọsìn Báálì. (1 Àwọn Ọba 14:23, 24; 2 Kíróníkà 28:2, 3) Ìwé náà, The Bible and Archaeology, sọ pé: “Àwọn kárùwà akọ àti abo (àwọn ọkùnrin àti obìnrin ‘mímọ́’) ń bẹ nínú àwọn tẹ́ńpìlì àwọn ará Kénáánì, gbogbo onírúurú àṣà ìbálòpọ̀ takọtabo tó burú jáì sì ni wọ́n ń dán wò níbẹ̀. [Àwọn ará Kénáánì] gbà gbọ́ pé títí dé àyè kan, ààtò wọ̀nyí ló ń mú kí irúgbìn àti ẹran ọ̀sìn láásìkí.” Wọ́n ní torí ìyẹn ni irú ààtò bẹ́ẹ̀ fi jẹ́ apá kan ìjọsìn àwọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn gbangba pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara ló sún àwọn olùjọsìn wọnnì dé ìdí irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀. Báwo wá ni Báálì ṣe sún ọkàn-àyà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀?
Ó Ṣe Fani Mọ́ra Tó Bẹ́ẹ̀?
Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ láti máa ṣe ẹ̀sìn kan tí kò béèrè ohun púpọ̀ lọ́wọ́ wọn. Nínú ìjọsìn Báálì, kò sí pé wọ́n ń pa Òfin mọ́, gẹ́gẹ́ bí Òfin Sábáàtì àti àwọn tó ka àwọn ìwà kan léèwọ̀. (Léfítíkù 18:2-30; Diutarónómì 5:1-3) Ó ṣeé ṣe kí aásìkí àwọn ará Kénáánì mú kí àwọn kan gbà pé ó pọndandan láti tu Báálì lójú.
Àwọn ojúbọ àwọn ará Kénáánì, táa mọ̀ sí àwọn ibi gíga, wà nínú àwọn igbó onígi ṣúúrú ní àwọn ibi tó yọ gọngọ lára àwọn òkè ńláńlá, ó sì dájú pé àwọn ibi báwọ̀nyẹn yóò ti jẹ́ ibi tí wọ́n lè fojú pa mọ́ sí láti máa ṣe irúfẹ́ àwọn ààtò ìbímọlémọ bẹ́ẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi mọ sídìí pípààrà àwọn ojúbọ ilẹ̀ Kénáánì; àwọn náà wá kúkú kọ́ tiwọn. “Àwọn pẹ̀lú sì ń bá a nìṣó láti kọ́ àwọn ibi gíga àti àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀ fún ara wọn lórí gbogbo òkè kéékèèké gíga àti lábẹ́ gbogbo igi tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 14:23; Hóséà 4:13.
Ṣùgbọ́n òkodoro ọ̀ràn náà gan-an ni pé, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara ni ìjọsìn Báálì ń tẹ́ lọ́rùn. (Gálátíà 5:19-21) Àwọn àṣàkaṣà tí wọ́n ń dán wò kì í kàn-án ṣe nítorí ìfẹ́ àtirí èso wọ̀ǹtìwọnti àti kí ẹran ọ̀sìn wọn lè máa bímọ lémọ. Ìbálòpọ̀ takọtabo ni wọ́n ń gbé lárugẹ. Èyí ṣe kedere láti inú àwọn ère kéékèèké táa ti hú jáde, àwọn ère tó ní àwọn ẹ̀yà ìbálòpọ̀ takọtabo tó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, tí ń ṣàpèjúwe ìrusókè ìbálòpọ̀ takọtabo. Jíjẹ, mímu, ijó jíjó, àti orin kíkọ ló máa ń ru wọ́n sókè fún ìwà pálapàla.
A lè fojú inú wo ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìwọ́wé. Pẹ̀lú ojú ọjọ́ tó bá a mu gẹ́ẹ́, àwọn olùjọsìn á wá bẹ̀rẹ̀ sí jó lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jàsè tán, tí ọtí sì ti bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Ète ijó ìbímọlémọ náà ni láti ta Báálì jí, kúrò nínú ipò àìtapútú tó wà ní gbogbo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, kí òjò ìbùkún lè rọ̀ sórí ilẹ̀ náà. Wọn a bẹ̀rẹ̀ sí jó yípo-yípo àwọn ọwọ̀n onírìísí ẹ̀yà ìbímọ akọ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀. Ìṣọwọ́ jó ijó ọ̀hún, pàápàá jù lọ bí àwọn kárùwà inú tẹ́ńpìlì ṣe ń jó o, máa ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè. Orin àti àwọn òǹwòran sì máa ń kó sí wọ́n lórí. Ó sì jọ pé, nígbà tí ijó ọ̀hún bá wá wọra tán, àwọn oníjó á gbéra, ó di ìyẹ̀wù inú ilé Báálì, láti lọ máa bára wọn ṣèṣekúṣe.—Númérì 25:1, 2; fi wé Ẹ́kísódù 32:6, 17-19; Ámósì 2:8.
Wọ́n Rìn Nípa Ohun Tí Wọ́n Rí, Kì Í Ṣe Nípa Ìgbàgbọ́
Nígbà tó jẹ́ pé irúfẹ́ ìjọsìn onífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ fajú ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra, ìbẹ̀rù tún wà lára nǹkan tó sún wọn wọnú ìjọsìn Báálì. Níwọ̀n bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti sọ ìgbàgbọ́ nù nínú Jèhófà, ìbẹ̀rù àwọn òkú, ìbẹ̀rù ọjọ́ ọ̀la, àti ṣíṣe ojú-mìí-tó nínú ọ̀ràn awo, mú wọn wọnú ìbẹ́mìílò, èyí tó tún wé mọ́ àwọn ààtò tó la ìwà ìbàjẹ́ tó légbá kan lọ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopedia, ṣàpèjúwe bí àwọn ará Kénáánì ṣe máa ń júbà àwọn ẹ̀mí òkú gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọsìn àwọn baba ńlá, ìwé náà sọ pé: “Jíjẹ, mímu . . . máa ń wáyé ní sàréè tàbí ní ojú oórì ìdílé pẹ̀lú ààtò ìmutíyó àti àṣà ìbálòpọ̀ (bóyá tó wé mọ́ ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan), irú àṣà tí wọ́n gbà pé àwọn olóògbé náà ń bá àwọn kópa nínú rẹ̀.” Lílọ́wọ́ sí irú àṣà ìbẹ́mìílò oníwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ túbọ̀ mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn jìnnà sí Jèhófà, Ọlọ́run wọn.—Diutarónómì 18:9-12.
Òrìṣà—àti àwọn ààtò tí ń bá a rìn—tún fa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra, àwọn tó jẹ́ pé ó wù wọ́n láti máa rìn nípa ohun tí wọ́n ń rí dípò rírìn nípa ìgbàgbọ́. (2 Kọ́ríńtì 5:7) Kódà, lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn iṣẹ́ àràmàǹdà látọwọ́ Jèhófà ẹni àìrí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fi ilẹ̀ Íjíbítì sílẹ̀ tún sọ pé àwọn nílò ohun kan tí àwọn lè fojú rí, tí yóò máa rán àwọn létí Jèhófà. (Ẹ́kísódù 32:1-4) Bákan náà làwọn kan lára àtọmọdọ́mọ wọn fẹ́ láti máa jọ́sìn ohun kan tó ṣeé fojú rí, bí òrìṣà Báálì.—1 Ọba 12:25-30.
Ta Ló Borí?
Ìjìjàdù láti gba ìfọkànsìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá a nìṣó fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, láti ìgbà tí wọ́n dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, títí di ìgbà tí Bábílónì kó wọn lẹ́rú. Ó jọ pé tí ìhà kan bá ṣẹ́gun lọ o, tó bá tún ṣe sàà, nǹkan á yíwọ́, ìhà kejì á tún mókè. Nígbà mìíràn, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á dúró ṣinṣin ti Jèhófà, ṣùgbọ́n léraléra ni wọ́n máa ń yíjú sí Báálì. Ohun pàtàkì tó máa ń fa èyí ni kíkẹ́gbẹ́ tí wọ́n ń bá àwọn kèfèrí tó yí wọn ká kẹ́gbẹ́.
Lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ará Kénáánì lójú ogun, àwọn ará Kénáánì wá bẹ̀rẹ̀ sí fi oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọn kò lè tètè fura sí bá wọn jà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé nítòsí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì rọ àwọn wọ̀nyí tó ṣẹ́gun wọn pé kí wọ́n kúkú fi àwọn ọlọ́run ilẹ̀ náà ṣe ọlọ́run tiwọn. Àwọn akíkanjú onídàájọ́ bí Gídéónì àti Sámúẹ́lì dènà ìtẹ̀sí yìí. Sámúẹ́lì gba àwọn èèyàn náà níyànjú pé: “Ẹ mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kúrò . . . kí ẹ sì darí ọkàn-àyà yín sọ́dọ̀ Jèhófà láìyà bàrá, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo.” Ní sáà kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Sámúẹ́lì, wọ́n sì “mú àwọn Báálì àti ère Áṣítórétì kúrò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà nìkan ṣoṣo.”—1 Sámúẹ́lì 7:3, 4; Onídàájọ́ 6:25-27.
Lẹ́yìn ìṣàkóso Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì, lọ́jọ́ alẹ́ Sólómọ́nì, ó bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè. (1 Ọba 11:4-8) Àwọn ọba mìíràn ní Ísírẹ́lì àti Júdà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n sì juwọ́ sílẹ̀ fún Báálì. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn olóòótọ́ wòlíì àti ọba, bí Èlíjà, Èlíṣà, àti Jòsáyà, kógun ti ìjọsìn Báálì. (2 Kíróníkà 34:1-5) Síwájú sí i, jálẹ̀ gbogbo sáà yìí nínú ìtàn Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan wà tó dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Jèhófà. Kódà nígbà ayé Áhábù àti Jésíbẹ́lì, nígbà tí ìjọsìn Báálì dé ògógóró rẹ̀, ẹgbẹ̀rún méje ènìyàn kọ̀ láti ‘tẹ eékún wọn ba fún Báálì.’—1 Ọba 19:18.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà táwọn Júù padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì, a kò tún gbúròó ìjọsìn Báálì mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ti àwọn tí a tọ́ka sí nínú Ẹ́sírà 6:21, gbogbo wọn ‘ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun àìmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ náà, láti wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.’
Ìkìlọ̀ Tí A Rí Gbà Ní Ti Ìjọsìn Báálì
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tipẹ́tipẹ́ ni ìjọsìn Báálì ti lọ ráúráú, nǹkan kan ṣì wà tí ẹ̀sìn àwọn ará Kénáánì ìgbà yẹn àti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tòní fi bára mu—ìyẹn ni gbígbé ìbálòpọ̀ lárugẹ. Ó jọ pé afẹ́fẹ́ ìṣekúṣe ló ń fẹ́ ní gbogbo àyíká wa lónìí. (Éfésù 2:2) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Àwọn tí a ń bá jà ni agbára àìrí tí ń ṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, àti àwọn aṣojú ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n ń wá láti orílé iṣẹ́ èṣù gan-an.”—Éfésù 6:12, Phillips.
“Agbára àìrí” yìí tí í ṣe ti Sátánì ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ, kí ó lè kó àwọn èèyàn lọ sígbèkùn nípa tẹ̀mí. (Jòhánù 8:34) Nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tòní tó gbàgbàkugbà, kì í ṣe ààtò ìbímọlémọ ìjelòó ló mú káwọn èèyàn jura sílẹ̀ pátápátá fún ìṣekúṣe, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣe é torí pé kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn, tàbí torí pé kí olúkúlùkù sáà máa ṣe ohun tó wù ú. Ìgbékèéyíde tòní sì ń yíni lérò padà bí tayé ọjọ́sí. Nípasẹ̀ eré ìnàjú, orin, àti ìpolówó ọjà, etí àwọn èèyàn ti kún fún ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàápàá kò ríbi sá sí nínú ohun táà ń sọ yìí. Àní, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn táa yọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni ló jẹ́ pé jíjuwọ́ sílẹ̀ fún irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ ló fà á. Àyàfi bí Kristẹni bá ń bá a lọ ní fífi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe ló fi lè wà ní mímọ́.—Róòmù 12:9.
Ewu ń bẹ fún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ní pàtàkì, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó fà wọ́n mọ́ra ni a ti wé ọ̀ràn ìbálòpọ̀ mọ́. Ọ̀ràn náà tún burú débi pé, wọ́n kò gbọ́dọ̀ gbojú bọ̀rọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ yòókù tí ń yọ wọ́n lẹ́nu ṣáá. (Fi wé Òwe 1:10-15.) Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ló ti wọ wàhálà níbi àwọn àpèjẹ ńlá. Gẹ́gẹ́ bí ti ìjọsìn Báálì ìgbàanì, àwọn nǹkan bí orin, ijó, àti àwọn ohun tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè máa ń kó síni lórí.—2 Tímótì 2:22.
Onísáàmù béèrè pé: “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?” Ó wá fèsì pé: “Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ [Jèhófà].” (Sáàmù 119:9) Gẹ́gẹ́ bí Òfin Ọlọ́run ti pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn ará Kénáánì kẹ́gbẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ń kìlọ̀ fún wa pé ewu wà nínú kíkó ẹgbẹ́ búburú. (1 Kọ́ríńtì 15:32, 33) Ọ̀nà tí Kristẹni ọ̀dọ́ lè gbà fi hàn pé òun dàgbà dénú ni nípa kíkọ̀ jálẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú ohun tó fà á lọ́kàn mọ́ra ṣùgbọ́n tó mọ̀ pé ó lè ba ìwà rere òun jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Èlíjà olóòótọ́, a kò ní máa tẹ̀ síbi ayé tẹ̀ sí nínú àwọn ìpinnu wa.—1 Ọba 18:21; fi wé Mátíù 7:13, 14.
Ìkìlọ̀ mìíràn tún jẹ mọ́ ọ̀ràn sísọ ìgbàgbọ́ nù, tí í ṣe “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” (Hébérù 12:1) Ó jọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ṣì gba Jèhófà gbọ́, ṣùgbọ́n Báálì ni wọ́n yíjú sí gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run tí yóò dáàbò bo irúgbìn wọn, tí yóò sì pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò. Bóyá wọ́n ronú pé tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ti jìnnà jù, àti pé kò sí béèyàn ṣe lè pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́. Bí ìgbà téèyàn ń fọbẹ̀ jẹ̀kọ ni ìjọsìn Báálì rí, gbẹ̀dẹ̀gbẹdẹ ló rọni lọ́rùn—wọ́n tilẹ̀ lè máa rú èéfín ẹbọ sí Báálì, olúkúlùkù lórí òrùlé tirẹ̀. (Jeremáyà 32:29) Ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé wọ́n ṣáko lọ sínú ìjọsìn Báálì nípa wíwulẹ̀ kópa nínú díẹ̀ lára àwọn ààtò rẹ̀, tàbí kí ó jẹ́ nípa rírúbọ sí Báálì lórúkọ Jèhófà.
Báwo ni a ṣe lè sọ ìgbàgbọ́ wa nù, tí a ó sì wá rọra sú lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè? (Hébérù 3:12) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí pàdánù ìmọrírì táa ní tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìpàdé àti àpéjọ wa. Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ fi àìní ìgbẹ́kẹ̀lé hàn nínú ‘oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,’ èyí tí Jèhófà ń pèsè. (Mátíù 24:45-47) Bí èyí bá sọ wá di ahẹrẹpẹ, a lè má “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin” mọ́, tàbí kí ọkàn wa pínyà, bóyá ká wá juwọ́ sílẹ̀ fún kíkó ọrọ̀ jọ tàbí ìṣekúṣe.—Fílípì 2:16; fi wé Sáàmù 119:113.
Pípa Ìwà Títọ́ Wa Mọ́
Láìsí àní-àní, jíjìjàdù láti gba ìfọkànsìn ẹni ṣì ń bá a lọ lónìí. Ṣé a óò dúró ṣinṣin ti Jèhófà ni, àbí a óò jẹ́ kí ìwà pálapàla ayé yìí mú kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀? Ó bani nínú jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jẹ́ kí òòfà fa àwọn wọnú àwọn ìwàkiwà àwọn ará Kénáánì, àwọn Kristẹni kan lónìí, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ti kó sínú páńpẹ́ ìwà tí ń tini lójú.—Fi wé Òwe 7:7, 21, 23.
A lè yẹra fún irú ìpara-ẹni-láyò nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀, báa bá fìwà jọ Mósè, tó “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ, a ní láti “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.” (Júúdà 3) Ṣùgbọ́n nípa dídúró ṣinṣin ti Ọlọ́run wa àti àwọn ìlànà rẹ̀, a lè fojú sọ́nà fún àkókò tí ìjọsìn èké yóò pa rẹ́ ráúráú. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìjọsìn Jèhófà ti borí ìjọsìn Báálì, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ìdánilójú pé láìpẹ́, “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn òpó ọlọ́wọ̀ tí wọ́n ń lò fún ijọsìn Báálì, tó ti wà di òkìtì àlàpà ní Gésérì
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
Musée du Louvre, Paris