ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 46 ojú ìwé 112-ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 1
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Lórí Òkè Kámẹ́lì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Lórí Òkè Kámẹ́lì
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Èlíjà Gbé Ọlọ́run Tòótọ́ Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ó Ń Ṣọ́nà, Ó sì Ní Sùúrù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 46 ojú ìwé 112-ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 1
Iná látọ̀dọ̀ Jèhófà jó ẹbọ Èlíjà

Ẹ̀KỌ́ 46

Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Lórí Òkè Kámẹ́lì

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọba tó jẹ lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ni kò dáa. Áhábù sì wà lára àwọn tó burú jù nínú wọn. Obìnrin abọ̀rìṣà kan tó ń jọ́sìn Báálì ló fẹ́. Jésíbẹ́lì lorúkọ obìnrin náà. Áhábù àti Jésíbẹ́lì mú káwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jọ́sìn Báálì, wọ́n sì tún pa àwọn wòlíì Jèhófà. Kí ni Jèhófà wá ṣe sọ́rọ̀ náà? Jèhófà rán wòlíì Èlíjà sí Áhábù.

Èlíjà sọ fún Ọba Áhábù pé òjò ò ní rọ̀ ní Ísírẹ́lì torí ìwà burúkú tó ń hù. Ohun tí Èlíjà sọ ṣẹ lóòótọ́, kò sí òjò fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ta, ohun ọ̀gbìn kankan ò sì hù. Ebi wá ń pa àwọn èèyàn náà. Jèhófà tún rán Èlíjà pa dà sọ́dọ̀ Áhábù. Áhábù wá sọ fún un pé: ‘Oníjọ̀gbọ̀n ni ẹ́. Ìwọ lo fa gbogbo wàhálà yìí.’ Èlíjà wá sọ fún un pé: ‘Èmi kọ́ ni mo ní kí òjò má rọ̀, ìwọ lo fà á torí pé Báálì lò ń sìn. A máa ṣe ohun kan tó máa jẹ́ ká mọ Ọlọ́run tòótọ́. Kó àwọn èèyàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtàwọn wòlíì Báálì wá sórí Òkè Kámẹ́lì.’

Bí gbogbo wọn ṣe pé jọ sórí òkè yẹn, Èlíjà sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ tẹ̀ lé e, àmọ́ tó bá jẹ́ Báálì ni, ẹ tẹ̀ lé e. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ni pé, káwọn wòlíì Báálì tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (450) rú ẹbọ kí wọ́n sì ké pe ọlọ́run wọn, èmi náà máa rú ẹbọ, màá sì ké pe Jèhófà. Ọlọ́run tó bá finá jó ẹbọ ẹ̀ ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Àwọn èèyàn yẹn sì fara mọ́ ohun tó sọ.

Àwọn wòlíì Báálì gbé ẹbọ wọn sílẹ̀, ó wá ku kí Báálì fi iná jó ẹbọ náà. Látàárọ̀ títí di ọ̀sán ni wọ́n fi ń pè é, wọ́n ní: ‘Báálì dá wa lóhùn.’ Nígbà tí Báálì ò dáhùn, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, ó ní: ‘Ẹ pariwo gan-an, bóyá ó ń sùn lọ́wọ́, ó sì yẹ kẹ́nì kan lọ jí i.’ Ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn wòlíì Báálì ń pe ọlọ́run wọn, àmọ́ kò sẹ́ni tó dá wọn lóhùn.

Èlíjà wá bẹ̀rẹ̀ sí í to igi jọ, ó gbé ẹran sórí ẹ̀, ó sì da omi lé e lórí. Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀ọ́ dá mi lóhùn, káwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà mú kí iná já bọ́ látọ̀run, ó sì jó ẹbọ náà. Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: ‘Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!’ Èlíjà wá sọ pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn wòlíì Báálì yẹn sá lọ o, ẹ mú wọn.’ Àwọn wòlíì Báálì tí wọ́n pa lọ́jọ́ yẹn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (450).

Lẹ́yìn ìyẹn, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú bọ̀ látorí òkun, Èlíjà wá sọ fún Áhábù pé: ‘Òjò máa tó rọ̀, tètè máa lọ sílé.’ Bí ojú ọ̀run ṣe ṣú bolẹ̀ nìyẹn, atẹ́gùn bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ gan-an, kí wọ́n tó mọ̀, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lójijì. Áhábù fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin ẹ̀ sáré gan-an. Àmọ́, Jèhófà fún Èlíjà lágbára débi pé ó sáré ju kẹ̀kẹ́ náà lọ! Ṣùgbọ́n, ṣé gbogbo ìṣòro Èlíjà ti wá tán nìyẹn? A máa rí i nínú orí tó kàn.

“Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.”​—Sáàmù 83:18

Ìbéèrè: Kí ló ṣẹlẹ̀ lórí Òkè Kámẹ́lì? Kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé Jèhófà dáhùn àdúrà Èlíjà?

1 Àwọn Ọba 16:29-33; 17:1; 18:1, 2, 17-46; Jémíìsì 5:16-18

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́