Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Fún ọ Lókun?
KÍ LO máa ń ṣe nígbà tó o bá dojú kọ ìṣòro? Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, rírántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ipò tó wà mu ló ràn án lọ́wọ́. (Mátíù 4:1-11) Bákan náà, nígbà tí àwọn ìṣòro kan ń bá Dáfídì Ọba fínra, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fún un lókun. Ó sọ pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”—Sáàmù 94:19.
Lọ́nà kan náà, rírántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn láàyò lè tù wá nínú tàbí kó fún wa lókun nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin Rex, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún báyìí, ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láti ọdún 1931. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Mo sábà máa ń wò ó pé mi ò tóótun nígbà tí wọ́n bá ní kí n bójú tó iṣẹ́ àkànṣe kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.” Báwo ló ṣe borí ìṣòro yìí? “Mo máa ń rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo yàn láàyò, ìyẹn Òwe 3:5, èyí tó sọ pé: ‘Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.’ Rírántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí àti fífi í sílò ló ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi láṣeyọrí.”
Kódà, àwọn ògo wẹẹrẹ pàápàá ń jàǹfààní látinú níní ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n yàn láàyò. Ọmọ ọlọ́dún mẹ́fà kan tó ń jẹ́ Jack sọ pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí òun yàn láàyò ni Mátíù 24:14. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí máa ń sún un láti tẹ̀ lé àwọn òbí rẹ̀ lọ wàásù. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ràn kí n máa tẹ̀ lé màmá mi, bàbá mi, àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin lọ wàásù ní gbogbo ọjọ́ Sátidé.”
Bíi ti Jésù, ṣé ìwọ náà máa ń rí àwọn ohun kan tó lè dán ìgbàgbọ́ rẹ wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Nígbà náà, o lè fi Fílípì 4:13 ṣe ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o yàn láàyò. Bíi ti Dáfídì Ọba, ǹjẹ́ ‘ìrònú tí ń gbéni lọ́kàn sókè’ máa ń dààmú rẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, rírántí Fílípì 4:6, 7 lè ṣèrànwọ́ fún ọ láti fara dà á. Ǹjẹ́ o máa ń ṣàníyàn nígbà mìíràn pé iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Ọlọ́run kò já mọ́ nǹkan kan? Nígbà náà, fífi 1 Kọ́ríńtì 15:58 sọ́kàn yóò fún ọ lókun.
Bá a bá ń rántí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wúlò gan-an fún wa, ó fi hàn pé à ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa sa agbára nígbèésí ayé wa. (Hébérù 4:12) Irú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn láàyò bẹ́ẹ̀ lè fún wa lókun, wọ́n sì tún lè tù wá nínú. —Róòmù 15:4.