Ṣé Ká Máa Ṣoore Ni Tàbí Ká Máà Sáà Ti Ṣẹnì Kankan Níbi?
“OHUN tí o kò bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ọ, kí ìwọ náà má ṣe é sí wọn.” Gbajúgbajà olùkọ́ àti onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà nì, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Confucius ló sọ ọ̀rọ̀ tó bọ́gbọ́n mu yìí. Kódà lóde òní, tó ti ń lọ sí nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn àkókò tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn, ọ̀pọ̀ ló ṣì gbà pé téèyàn ó bá sáà ti ṣe ibi sáwọn ẹlòmíràn, onítọ̀hún ti jẹ èèyàn rere nìyẹn.
Láìsí àní-àní, ìlànà ìwà híhù tí Confucian gbé kalẹ̀ yìí dára dé àyè kan. Àmọ́, Bíbélì ní tirẹ̀ jẹ́ ká ní èrò mìíràn nípa ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn àti àjọṣe àárín wọn. Láfikún sí ohun tá a lè pè ní ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, ìyẹn ni mímọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dára sí èèyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni, Bíbélì tún mẹ́nu kan ẹ̀ṣẹ̀ àìka-nǹkan-sí. Jákọ́bù tó jẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Bí ẹnì kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.” (Jákọ́bù 4:17) Dípò kí Jésù Kristi kàn fún àwọn Kristẹni nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n má ṣe ibi sí ẹnikẹ́ni, ìmọ̀ràn tó fún wọn ni pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.
Ète Ọlọ́run níbẹ̀rẹ̀ ni pé irú ìwà tí gbogbo èèyàn bá fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn máa hù sí wọn ni kí àwọn náà máa hù sí ọmọnìkejì wọn. Ó fi àpẹẹrẹ àtàtà pé òun bìkítà nípa ire àwọn ẹlòmíràn lélẹ̀ nínú ọ̀nà tó gbà dá ènìyàn, a rí i kà pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fìfẹ́ fún ènìyàn ní ẹ̀rí ọkàn kan, tó jẹ́ pé tí wọ́n bá kọ́ ọ dáadáa, ó lè mú kí wọn máa bá ọmọnìkejì wọn lò lọ́nà tí wọ́n á fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn gbà bá àwọn náà lò pẹ̀lú.
Àwọn èèyàn tó jẹ́ anìkànjọpọ́n tí wọn kì í gba ti ẹlòmíràn rò ń fìyà jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní, kò sì sí ìrètí pé àwọn èèyàn tó ń jìyà náà máa bọ́ ńbẹ̀. Ó ṣe kedere pé, ohun tá a fẹ́ kì í ṣe kìkì pé ká má ṣe ibi sí àwọn ẹlòmíràn ṣùgbọ́n pé ká tún máa ṣe ohun tó dára tó sì máa ṣe wọ́n láǹfààní fún wọn. Nítorí èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí àgbàyanu tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n bá wá sọ ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì fún àwọn aládùúgbò wọn, ìfẹ́ ló ń sún wọn ṣe é, ohun tí wọ́n fẹ́ kéèyàn ṣe sí wọn làwọn náà ń ṣe fún àwọn èèyàn.