ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/1 ojú ìwé 30-31
  • Ṣíṣe Oore Fáwọn Èèyàn Lákòókò Ìṣòro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣe Oore Fáwọn Èèyàn Lákòókò Ìṣòro
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Àwọn Ìṣe Ìgbàlà Jehofa Nísinsìnyí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/1 ojú ìwé 30-31

Ṣíṣe Oore Fáwọn Èèyàn Lákòókò Ìṣòro

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń sapá lójú méjèèjì láti máa tẹ̀ lé ìlànà yìí, ìyẹn láti máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, ní pàtàkì fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Àìmọye ìgbà la máa ń rí i tí wọ́n ń ṣe èyí lákòókò táwọn èèyàn bá níṣòro. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè mẹ́ta lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

Ní oṣù December 2002, ìjì ńlá kan jà ní Guam, àní afẹ́fẹ́ ìjì ńlá náà fẹ́ dé ibi tí ó jìnnà tó ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà ní wákàtí kan péré. Ọ̀pọ̀ ilé ló ya lulẹ̀, àwọn ilé mìíràn sì bà jẹ́ tán pátápátá. Kíá làwọn ìjọ ibẹ̀ ṣètò àwọn tó máa ṣèrànwọ́ fáwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí tí jàǹbá náà ṣe lọ́ṣẹ́ jù lọ. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Guam fi àwọn nǹkan tá a máa fi tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe ránṣẹ́ títí kan àwọn òṣìṣẹ́, ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Hawaii ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, àwọn káfíńtà wá láti Hawaii láti wá bá wọn tún àwọn ilé tó bà jẹ́ kọ́, lára àwọn arákùnrin tó wà ní Guam sì lo àkókò ìsinmi tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ láti bá àwọn ará tó wá láti Hawaii kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà. Fífi táwọn ará fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tayọ̀tayọ̀ jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo àwọn tó ń gbé lágbègbè yẹn.

Ní ìgbèríko Mandalay tó wà ní orílẹ̀-èdè Myanmar, ibì kan gbaná lójijì nítòsí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ilé tí arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ kan àti ìdílé rẹ̀ ń gbé kò jìnnà síbi tí iná náà ti ń jó. Afẹ́fẹ́ ń darí iná náà sí àgbègbè ibi tí ilé arábìnrin náà wà, ìdí nìyẹn tó fi sá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ń tún gbọ̀ngàn náà ṣe lákòókò yẹn, èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará wà níbẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wọn láti rí arábìnrin náà nítorí pé wọn ò mọ̀ pé àgbègbè ibẹ̀ ló ń gbé. Lẹ́yẹ-ò-sọkà, àwọn ará ran òun àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti kó ẹrù wọn lọ síbi tó láàbò. Nígbà tí ọkọ arábìnrin náà tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí gbọ́ pé iná ń jó, ó sáré lọ́ sílé, nígbà tó sì délé ó bá àwọn arákùnrin tí wọ́n ń ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́. Ohun tí wọ́n ṣe yìí wú ọkùnrin náà lórí gan-an, ó sì mọrírì rẹ̀, ìtura ló sì tún jẹ́ fún un nítorí pé nígbà tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá wáyé àwọn jàǹdùkú máa ń jí ẹrù àwọn èèyàn kó ni. Oore táwọn ará ṣe fún arábìnrin yìí mú kí òun àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n sì ń wá sí gbogbo ìpàdé báyìí.

Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ń gbé lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì ni ìyàn mú nítorí ọ̀dá àti ohun ọ̀gbìn wọn tí kò ṣe dáadáa. Kíá ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè náà pèsè oúnjẹ fáwọn aláìní. Inú Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n ti ń pín oúnjẹ náà fáwọn èèyàn, nígbà mìíràn wọ́n á pín in lẹ́yìn ìpàdé ìjọ. Arábìnrin kan tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ sọ pé: “Inú ìbànújẹ́ ni mo máa ń wà nígbà tí mo bá wá sípàdé, nítorí pé mi ò mọ nǹkan tí màá fún àwọn ọmọ mi jẹ tá a bá padà sílé.” Ìrànlọ́wọ́ tí àwọn ará ṣe fún un tìfẹ́tìfẹ́ jẹ́ ìṣírí fún un. Ó ní: “Bíi pé wọ́n jí mi dìde ló ṣe rí lára mi!”

Àwọn Ẹlẹ́rìí tún máa ń “ṣe ohun rere” nípa tẹ̀mí fáwọn èèyàn nípa sísọ ọ̀rọ̀ Bíbélì tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ti ìrètí fún wọn. Wọ́n fara mọ́ ohun tí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan gbà gbọ́ láyé ọjọ́un tó sọ pé: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”—Òwe 1:33.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

1, 2. Wọ́n ń pín oúnjẹ fáwọn aláìní ní Mòsáńbíìkì

3, 4. Ìjì ńlá tó jà ní Guam ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé jẹ́

[Àwọn Credit Line]

Ọmọdé, apá òsì: Andrea Booher/FEMA News Photo; obìnrin, òkè: AP Photo/Pacific Daily News, Masako Watanabe

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́