Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Gẹ́gẹ́ bí 1 Sámúẹ́lì 19:12, 13 ṣe sọ, kí nìdí tí Dáfídì tí í ṣe ìránṣẹ́ olóòótọ́ fún Jèhófà, fi gba Míkálì ìyàwó rẹ̀ láyè láti ní ère tẹ́ráfímù?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká gbé ìtàn náà yẹ̀ wò ní ṣókí. Nígbà tí ìyàwó Dáfídì gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù Ọba ń pète láti pa Dáfídì, kíá ló káràmáásìkí ọ̀rọ̀ náà. Bíbélì sọ pé: “Míkálì mú kí Dáfídì sọ̀ kalẹ̀ gba ojú fèrèsé, kí ó bàa lè lọ, kí ó sì fẹsẹ̀ fẹ, kí ó sì sá àsálà. Nígbà náà ni Míkálì mú ère tẹ́ráfímù [tí ó rí bí èèyàn], ó sì fi í sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú, ó sì fi àwọ̀n irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí ó fi ẹ̀wù bò ó.” Nígbà táwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù wá láti mú Dáfídì, Míkálì sọ fún wọn pé: “Ó ń ṣàìsàn.” Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yìí ló fawọ́ aago sẹ́yìn fún àwọn tó ń wá Dáfídì, ó sì fún Dáfídì láyè láti sá fún ẹ̀mí rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 19:11-16.
Ìwádìí tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣe fi hàn pé láyé ọjọ́un, kì í ṣe tìtorí ẹ̀sìn nìkan làwọn èèyàn ṣe ń fi ère tẹ́ráfímù sínú ilé, àmọ́ ó tún jẹ́ nítorí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ òfin. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìhágún ti máa ń jẹ́ ká mọ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ogún lóde òní, bẹ́ẹ̀ náà ni ère tẹ́ráfímù ṣe rí láyé ọjọ́un. Ẹ̀rí fi hàn pé lábẹ́ àwọn ipò kan, tí ẹnì kan bá ní ère tẹ́ráfímù bàbá ìyàwó rẹ̀ lọ́wọ́, ẹni náà lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti jogún àwọn nǹkan ìní bàbá ìyàwó rẹ̀. Èyí jẹ́ ká mọ ìdí tí Rákélì fi jí ère tẹ́ráfímù bàbá rẹ̀ nígbà kan àti ìdí tí bàbá rẹ̀ náà fi ń wá ọ̀nà lójú méjèèjì bí òun á ṣe rí ère náà gbà padà. Àmọ́ nínú àpẹẹrẹ yẹn, Jékọ́bù ọkọ Rákélì kò mọ̀ pé ìyàwó òun ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 31:14-34.
Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè kan, a fún wọn ní Òfin Mẹ́wàá, èkejì lára òfin náà sì sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan. (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Nígbà tó ṣe, wòlíì Sámúẹ́lì mẹ́nu ba òfin náà nígbà tó ń bá Sọ́ọ̀lù Ọba sọ̀rọ̀. Ó ní: “Ìṣọ̀tẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ìwoṣẹ́, fífi ìkùgbù ti ara ẹni síwájú sì jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú lílo agbára abàmì àti ère tẹ́ráfímù.” (1 Sámúẹ́lì 15:23) Nítorí èyí, kò dájú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lo ère tẹ́ráfímù fún híhá ogún. Síbẹ̀síbẹ̀, ó jọ pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí àwọn Júù dì mú láyé ìgbàanì yìí ni àwọn kan lára ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì ń tẹ̀ lé. (Àwọn Onídàájọ́ 17:5, 6; 2 Àwọn Ọba 23:24) Gbígbé tí Míkálì gbé ère tẹ́ráfímù sínú ilé fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ọkàn ló fi ń sin Jèhófà. Dáfídì kò mọ̀ nípa ère tẹ́ráfímù náà, bẹ́ẹ̀ ni kò tìtorí pé Míkálì jẹ́ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù Ọba kó wá gbà á láyè láti ní in.
Èrò tí Dáfídì ní nípa ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe sí Jèhófà ló fi hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi, ó sì yẹ ní bíbẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù. Nítorí gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí. Ní ti Jèhófà, òun ni ó ṣe ọ̀run.”—1 Kíróníkà 16:25, 26.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èkejì nínú Òfin Mẹ́wàá sọ pé a ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère bí ère tẹ́ráfímù tí àwòrán rẹ̀ wà níbí yìí
[Credit Line]
Látinú ìwé The Holy Land, Apá Kejì, 1859