Ẹ̀kọ́ Nípa Ẹ̀mí Ìgbéraga àti Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
OHUN kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Dáfídì Ọba jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà nínú ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí ìgbéraga. Nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Dáfídì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù tó sì fi í ṣe olú ìlú ìjọba rẹ̀. Dáfídì gbà pé Jèhófà gan-an ni Ọba Ísírẹ́lì. Ìyẹn ló fi ṣètò pé kí wọ́n gbé Àpótí Májẹ̀mú, tó jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn wá sí Jerúsálẹ́mù. Inú Dáfídì dùn gan-an sí gbígbé tí wọ́n ń gbé Àpótí Májẹ̀mú yìí bọ̀ débi pé kò lè pa ayọ̀ rẹ̀ mọ́ra lójú àwọn aráàlú bó ṣe ń tẹ̀ lé àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí náà. Àwọn ará Jerúsálẹ́mù wá ń wo bí ọba wọn ṣe “ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” tó sì “ń fi gbogbo agbára rẹ̀ jó.”—1 Kíróníkà 15:15, 16, 29; 2 Sámúẹ́lì 6:11-16.
Ṣùgbọ́n Míkálì aya Dáfídì kò dara pọ̀ mọ́ àwọn èrò tó ń bọ̀ tayọ̀tayọ̀ náà. Ojú fèrèsé ló wà tó ń wò wọ́n. Dípò kínú rẹ̀ dùn sí ọ̀nà tí Dáfídì gbà ń fìyìn fún Jèhófà yìí, ńṣe ló “bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 6:16) Kí nìdí tí Míkálì fi ń ro irú èrò bẹ́ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé jíjẹ́ tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù, ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì tó sì tún wá jẹ́ aya ọba Ísírẹ́lì kejì ti jẹ́ kó jọ ara rẹ̀ lójú jù. Ó lè máa rò ó pé kò yẹ kí ọkọ òun tó jẹ́ ọba fara rẹ̀ wọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn, kó máa bá àwọn èrò kẹ́sẹ̀ ijó bọ̀. Ẹ̀mí ìgbéraga yẹn sì hàn nínú ọ̀nà tó gbà kí Dáfídì nígbà tí Dáfídì padà délé. Tẹ̀gàntẹ̀gàn ló fi sọ fún un pé: “Ẹ wo bí ọba Ísírẹ́lì ti ṣe ara rẹ̀ lógo tó lónìí nígbà tí ó tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò lónìí ní ojú àwọn ẹrúbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn akúrí ṣe ń tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò pátápátá!”—2 Sámúẹ́lì 6:20.
Kí ni Dáfídì ṣe nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tó sọ yìí? Dáfídì sọ̀rọ̀ sí Míkálì gan-an, ó jẹ́ kó yé e pé kíkọ̀ ni Jèhófà kọ Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ̀ tó sì yan òun. Dáfídì wá fi kún un pé: “Èmi yóò tilẹ̀ túbọ̀ sọ ara mi di ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí ju èyí, dájúdájú, èmi yóò sì di ẹni rírẹlẹ̀ ní ojú ara mi; àwọn ẹrúbìnrin tí o sì mẹ́nu kàn, àwọn ni èmi ti pinnu láti fi ṣe ara mi lógo.”—2 Sámúẹ́lì 6:21, 22.
Bẹ́ẹ̀ ni o, Dáfídì pinnu láti máa sin Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ nìṣó. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní yìí jẹ́ ká rí ìdí tí Jèhófà fi pe Dáfídì ní “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà mi lọ́rùn.” (Ìṣe 13:22; 1 Sámúẹ́lì 13:14) Láìsí àní-àní, àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀, tó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ga jù lọ, ni Dáfídì ń tẹ̀ lé. Ẹ sì wá wò ó o, ọ̀rọ̀ Hébérù tí Dáfídì lò nígbà tó ń sọ fún Míkálì pé, “èmi yóò sì di ẹni rírẹlẹ̀,” wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan nínú èdè Hébérù tí wọ́n tún máa ń lò láti fi ṣàpèjúwe ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọmọ aráyé. Jèhófà ló ga lọ́lá jù lọ láyé àtọ̀run, síbẹ̀ Sáàmù 113:6, 7 sọ pé: “Ó ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ [ìyẹn, kéèyàn rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti ipò ọlá tàbí iyì rẹ̀, kò lé bá ẹni tó rẹlẹ̀ sí i ní àjọṣe] láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, ó ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde àní láti inú ekuru; ó ń gbé òtòṣì ga àní láti inú kòtò eérú.”
Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó kórìíra “ojú gíga fíofío” táwọn agbéraga èèyàn ní. (Òwe 6:16, 17) Torí pé Míkálì ní ẹ̀mí ìgbéraga àti pé kò tún bọ̀wọ̀ fún ẹni tí Ọlọ́run fi jẹ ọba, Dáfídì fi àǹfààní àtibí ọmọ fóun du Míkálì. Bí Míkálì kò ṣe bímọ kankan nìyẹn títí tó fi kú. Ẹ̀kọ́ ńlá lèyí jẹ́ fún wa o! Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run ní láti ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí wí, ìyẹn: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Pétérù 5:5.