Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? O ò ṣe wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí?
• Irú Bíbélì wo ni Bíbélì elédè púpọ̀ ti Complutensian, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ni wọ́n fi tẹ Bíbélì elédè púpọ̀ yìí. Àwọn ìwé Bíbélì tó dáa jù lọ tó wà nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní èdè Hébérù, Gíríìkì, Látìn àti díẹ̀ lára èyí tó wà ní èdè Árámáíkì, ni wọ́n tó sí òpó kọ̀ọ̀kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bíbélì elédè púpọ̀ yìí ló mú kó ṣeé ṣe láti túmọ̀ Bíbélì tó wà ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ lọ́nà tó péye jù lọ.—4/15, ojú ìwé 28 sí 31.
• Báwo ni ẹ̀dá èèyàn ṣe lè múnú Ọlọ́run dùn?
Níwọ̀n bí Jèhófà ti wà láàyè ní ti gidi, ó lè ronú, ó lè gbé àwọn nǹkan ṣe, ó sì ń mọ nǹkan lára. Òun jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì máa ń láyọ̀ láti rí i pé òun mú àwọn ète òun ṣẹ. (1 Tímótì 1:11; Sáàmù 104:31) Bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára Ọlọ́run sí i, bẹ́ẹ̀ la óò túbọ̀ máa rí àwọn ohun tá a lè ṣe láti mú ọkàn rẹ̀ yọ̀.—5/15, ojú ìwé 4 sí 7.
• Kí nìdí tí Dáfídì fi gba Míkálì ìyàwó rẹ̀ láyè láti ní ère tẹ́ráfímù?
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba pète láti pa Dáfídì, Míkálì ran Dáfídì lọ́wọ́ láti sá fún ẹ̀mí rẹ̀, ó wá gbé ère kan tó ṣeé ṣe kò rí bí èèyàn sórí àga. Ìdí tó fi ní ère tẹ́ráfímù lè jẹ́ nítorí pé gbogbo ọkàn kọ́ ló fi ń sin Ọlọ́run. Dáfídì pàápàá ò mọ̀ pé Míkálì nírú nǹkan bẹ́ẹ̀ sílé, bẹ́ẹ̀ ni kò tìtorí pé ó jẹ́ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù Ọba kó wà gbà á láyè láti ní in. (1 Kíróníkà 16:25, 26)—6/1, ojú ìwé 29.
• Kí ni kókó pàtàkì tí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ dá lé lórí?
Nípasẹ̀ ohun tí Ọlọ́run sọ lẹ́yìn ìkún omi, nínu Òfin Mósè, àti àṣẹ tó wà nínú Ìṣe 15:28, 29, ńṣe ló tọ́ka sí ìrúbọ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ Jésù tí wọ́n ta sílẹ̀. Ipasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù nìkan la fi lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. (Kólósè 1:20)—6/15, ojú ìwé 14 sí 19.
• Iṣẹ́ ìyanu mélòó ni Bíbélì sọ pé Jésù ṣe?
Ìwé Ìhìn rere tọ́ka sí iṣẹ́ ìyanu márùndínlógójì tí Jésù ṣe. Àmọ́ kò sọ iye gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe títí kan àwọn iṣẹ́ ìyanu mìíràn tí a kò ròyìn rẹ̀. (Mátíù 14:14)—7/15, ojú ìwé 5.