ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 4/15 ojú ìwé 28-31
  • Bíbélì Elédè Púpọ̀ Ti Complutensian—Ohun Èlò Pàtàkì Nínú Ìtàn Ìtumọ̀ Èdè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbélì Elédè Púpọ̀ Ti Complutensian—Ohun Èlò Pàtàkì Nínú Ìtàn Ìtumọ̀ Èdè
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣètò Bíbélì Náà Sórí Abala Ìwé
  • Ìyàtọ̀ Tó Wà Nínú Bíbélì Vulgate àti Àwọn Èdè Ìpilẹ̀ṣẹ̀
  • Comma Johanneum
  • Ìpìlẹ̀ fún Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Tuntun
  • Bíbélì Ọba Àgbà Ìwé Tó Wúlò Gan-an
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ǹjẹ́ O Rántí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Orúkọ Ọlọ́run àti Ìsapá Alfonso de Zamora Láti Túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Péye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Desiderius Erasmus
    Jí!—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 4/15 ojú ìwé 28-31

Bíbélì Elédè Púpọ̀ Ti Complutensian—Ohun Èlò Pàtàkì Nínú Ìtàn Ìtumọ̀ Èdè

NÍ NǸKAN bí ọdún 1455, ìyípadà dé bá bí wọ́n ṣe máa ń tẹ Bíbélì. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Johannes Gutenberg fi ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé tẹ Bíbélì àkọ́kọ́ jáde, ìyẹn sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa fi ẹ̀rọ tí lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò tẹ̀wé. Ní báyìí, fífọwọ́kọ̀wé tí kò jẹ́ kí ẹ̀dá Bíbélì púpọ̀ wà ti di nǹkan àtijọ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó ṣeé ṣe láti tẹ Bíbélì púpọ̀ sí i láìnáwó púpọ̀ jù. Kò pẹ́ tí Bíbélì fi di ìwé tá a pín kiri jù lọ láyé.

Èdè Látìn ni wọ́n fi kọ Bíbélì tí Gutenberg tẹ̀. Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù fi rí i pé àwọn nílò Bíbélì kan tó ṣeé gbára lé, ìyẹn èyí tó wà ní èdè Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀dà Bíbélì Vulgate ní èdè Látìn nìkan ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fara mọ́, àmọ́ ìdíwọ́ ńlá méjì kan wà. Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ni kò gbédè Látìn. Ṣíwájú sí i, fún ohun tó lé ni ẹgbẹ̀rún-un ọdún, àwọn tó ń ṣe àdàkọ Bíbélì Vulgate ti ṣe àṣìṣe tó pọ̀ gan-an.

Àwọn atúmọ̀ èdè àtàwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nílò Bíbélì tí wọ́n fi èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ àti ìtumọ̀ ti Látìn tá a mú sunwọ̀n sí i. Ní ọdún 1502, kádínà Jiménéz de Cisneros tó jẹ́ olùgbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìṣèlú àti lórí nǹkan tẹ̀mí fún Ọbabìnrin Isabella Kìíní ti orílẹ̀-èdè Sípéènì, pinnu láti tẹ ìwé kan ṣoṣo jáde tó máa kúnjú òṣùwọ̀n ohun tí wọ́n ń fẹ́ yìí. Ohun èlò pàtàkì nínú ìtàn ìtumọ̀ èdè yìí ló wá dohun tá a mọ̀ sí Bíbélì elédè púpọ̀ ti Complutensian. Cisneros fẹ́ kí Bíbélì tó dára jù lọ ní èdè Hébérù, Gíríìkì àti ti Látìn wà nínú Bíbélì elédè púpọ̀ yìí, kí díẹ̀ lára èyí tó wà ní èdè Árámáíkì sì tún wà nínú rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé fífi ẹ̀rọ tẹ̀wé ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, Bíbélì elédè púpọ̀ yìí yóò jẹ́ àṣeyọrí kan tó gbàfiyèsí nídìí iṣẹ́ ìwé títẹ̀.

Nígbà tí Cisneros fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí, ó ra àwọn ìwé Bíbélì tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Hébérù, irú àwọn ìwé Bíbélì wọ̀nyí kúkú pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ó tún wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Gíríìkì àti Látìn. Àwọn ìwé Bíbélì wọ̀nyí ló fẹ́ fi ṣe Bíbélì elédè púpọ̀ náà. Àwùjọ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí Cisneros kó jọ ní Yunifásítì Alcalá de Henares tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Sípéènì ló gbé iṣẹ́ ṣíṣàkójọ ìwé náà lé lọ́wọ́. Erasmus láti ìlú Rotterdam wà lára àwọn tí Cisneros fẹ́ kó wà nínú àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó kó jọ yìí, ṣùgbọ́n gbajúgbajà onímọ̀ èdè púpọ̀ yìí kọ̀ jálẹ̀.

Odindi ọdún mẹ́wàá làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yìí fi ṣàkójọ iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí, lẹ́yìn ìyẹn, ọdún mẹ́rin gbáko ló tún gbà kí wọ́n tó tẹ̀ ẹ́ tán. Ọ̀pọ̀ ìṣòro tó jẹ mọ́ òye iṣẹ́ ló jẹ yọ, nítorí àwọn òǹtẹ̀wé tó wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì kò ní àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi máa ń kọ̀wé lédè Hébérù, Gíríìkì tàbí ti Árámáíkì. Nítorí èyí, Cisneros wá bẹ ògbóǹtarìgì òǹtẹ̀wé ará Sípéènì kan tó ń jẹ́ Arnaldo Guillermo Brocario lọ́wẹ̀ pé kó bá òun ṣe àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi ń kọ̀wé lédè wọ̀nyí. Níkẹyìn, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dún 1514. Iṣẹ́ lórí títẹ ìdìpọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà parí ní July 10, 1517, ìyẹn sì jẹ́ oṣù mẹ́rin ṣáájú ikú kádínà yìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ìdìpọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí wọ́n tẹ̀ jáde, kẹ́ ẹ sì wá wò ó, ìgbà yẹn gan-an ni àjọ tí ìsìn Kátólíìkì gbé kalẹ̀ láti gbógun ti ọmọ ìjọ wọn tó ń yapa ní ilẹ̀ Sípéènì ń mi ìlú tìtì.a

Ṣíṣètò Bíbélì Náà Sórí Abala Ìwé

Òbítíbitì ìsọfúnni ló wà lójú ewé kọ̀ọ̀kan Bíbélì elédè púpọ̀ yìí. Nínú ìdìpọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n pín Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí, ẹ̀dà Vulgate ló wà láàárín ojú ewé kọ̀ọ̀kan; èdè Hébérù wà lápá ọ̀tún; èdè Gíríìkì àti èdè alápapọ̀ tá a túmọ̀ sí Látìn wà lápá òsì. Bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù ṣe jẹ yọ ni wọ́n kọ sáwọn àlàfo tó wà létí ìwé. Ní ìsàlẹ̀ gbogbo ojú ewé tí àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì wà, àwọn olóòtú fi ìtumọ̀ Targum ti Onkelos (ìyẹn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì tá a fi èdè Árámáíkì tún kọ lọ́nà mìíràn) àti ti èdè Látìn síbẹ̀.

Ìdìpọ̀ karùn-ún Bíbélì elédè púpọ̀ náà jẹ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tá a kọ sójú ìwé tó pín sí òpó méjì. Èdè Gíríìkì wà ní òpó àkọ́kọ́, èdè Látìn tó wá látinú Bíbélì Vulgate wà ní òpó kejì. Àwọn lẹ́tà kéékèèké tó ń tọ́ka òǹkàwé síbi táwọn ọ̀rọ̀ tó bára mu wà nínú òpó kọ̀ọ̀kan ni wọ́n fi ṣàlàyé ìbáramu tó wà nínú èdè méjèèjì yìí. Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tó wà nínú Bíbélì elédè púpọ̀ yìí ni odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, tàbí “Májẹ̀mú Tuntun” tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde, kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Erasmus ṣe ẹ̀dà mìíràn.

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fara balẹ̀ ka ìdìpọ̀ karùn-ún yẹn lákàtúnkà kó máa bàa sí àṣìṣe kankan, àní àṣìṣe àádọ́ta péré tó wà níbẹ̀ wọlé nígbà tí wọ́n ń tẹ ìwé náà. Nítorí pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yìí fara balẹ̀ ṣiṣẹ́ wọn, àwọn olófìn-íntótó òde òní gbà pé ìdìpọ̀ karùn-ún yìí dára ju gbajúgbajà ẹ̀dà Gíríìkì tí Erasmus ṣe lọ. Bí àwọn lẹ́tà tó hàn ketekete tó wà nínú ìwé àfọwọ́kọ ayé ọjọ́un ṣe dùn ún wò náà ni àwọn lẹ́tà mèremère tí wọ́n fi ń kọ̀wé lédè Gíríìkì ṣe dùn ún wò. Nínú ìwé The Printing of Greek in the Fifteenth Century tí R. Proctor kọ, ó sọ pé: “A yin orílẹ̀-èdè Sípéènì fún àwọn lẹ́tà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe láti máa fi tẹ ìwé lédè Gíríìkì, kò sì sí iyèméjì pé àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi ń tẹ ìwé lédè Gíríìkì tí wọn ṣe ní orílẹ̀-èdè Sípéènì yìí ló tíì dára jù lọ.”

Oríṣiríṣi àrànṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló wà nínú ìdìpọ̀ kẹfà Bíbélì elédè púpọ̀ náà, irú bí: ìwé atúmọ̀ èdè fún èdè Hébérù àti Árámáíkì, ìtumọ̀ àwọn orúkọ lédè Gíríìkì, Hébérù àti Árámáíkì, àlàyé lórí gírámà èdè Hébérù, àti atọ́ka fún ìwé atúmọ̀ èdè Látìn. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu nígbà náà pé, gbogbo àwọn èèyàn ló ń sọ pé Bíbélì elédè púpọ̀ ti Complutensian dáa gan-an, wọ́n pè é ní “ohun àmúyangàn tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ọnà ìwé títẹ̀ àti ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Ìwé Mímọ́.”

Cisneros fẹ́ kí Bíbélì yìí “ta àwọn èèyàn jí kí wọ́n lè tún nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́,” ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ní Bíbélì yẹn lọ́wọ́ o. Ó rò pé “ńṣe ló yẹ kéèyàn fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa mọ́ bí àdììtú kan, kọ́wọ́ mùtúmùwà má bàa tẹ̀ ẹ́.” Ó tún gbà pé “èdè àtijọ́ mẹ́ta náà nìkan ni Ìwé Mímọ́ gbọ́dọ̀ wà, ìyẹn àwọn èdè tí Ọlọ́run fàyè gbà kí wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ sókè orí Ọmọ rẹ̀ tí wọ́n kàn mọ́ àgbélébùú.”b Nítorí èyí, kò sí èdè Spanish nínú Bíbélì elédè púpọ̀ ti Complutensian.

Ìyàtọ̀ Tó Wà Nínú Bíbélì Vulgate àti Àwọn Èdè Ìpilẹ̀ṣẹ̀

Àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì elédè púpọ̀ náà fa awuyewuye láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó ṣe é. Ìlúmọ̀ọ́ká ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì náà, Antonio de Nebrijac ni wọ́n fi sídìí ṣíṣàtúnṣe Bíbélì Vulgate tí wọ́n fẹ́ fi sínú Bíbélì elédè púpọ̀ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì Vulgate tí Jerome ṣe nìkan ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fọwọ́ sí, Nebrija rí i pé ó yẹ káwọn fi ọ̀rọ̀ inú Bíbélì Vulgate wé Bíbélì tó wà ní èdè Hébérù, Árámáíkì, àti ti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ó fẹ́ ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe tó ti yọ́ wọlé sínú àwọn Bíbélì Vulgate tí wọ́n ti tẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Láti ṣàtúnṣe ìyàtọ̀ èyíkéyìí tó wà láàárín Bíbélì Vulgate àtàwọn Bíbélì tá a fi èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ, Nebrija gba Cisneros níyànjú pé: “Gbé èdè méjèèjì ti ẹ̀sìn wa lárugẹ, ìyẹn èdè Hébérù àti Gíríìkì. Kó o sì dá àwọn tó fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ yìí lọ́lá.” Ó tún dábàá pé: “Ìgbàkígbà tí a bá rí ìyàtọ̀ èyíkéyìí nínú ẹ̀dà Májẹ̀mú Tuntun tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Látìn, ó yẹ ká lọ wo ẹ̀dà tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Gíríìkì. Gbogbo ìgbá tí ẹ̀dà Májẹ̀mú Láéláé tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Látìn bá ti ta ko èyí tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Gíríìkì, a ní láti lọ ṣàyẹ̀wò ojúlówó ẹ̀dà tó wà ní èdè Hébérù láti mọ èyí tó tọ̀nà.”

Kí ni Cisneros ṣe nípa ìmọ̀ràn tí Nebrija fún un yìí? Nínu ọ̀rọ̀ ìṣáájú tí Cisneros kọ sínú Bíbélì elédè púpọ̀ yẹn, ó sọ ohun tó ṣe lórí ìmọ̀ràn yẹn. Ó ní: “A gbé ìtumọ̀ Látìn èyí tí Jerome mímọ́ ṣe sáàárín ìtumọ̀ ti Sínágọ́gù [Bíbélì ní èdè Hébérù] àti ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ìlà Oòrùn Ayé [Bíbélì ní èdè Gíríìkì] gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbé àwọn olè kọ́ sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Jésù, ẹni tó dúró fún Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù tàbí ti Látìn.” Nípa bẹ́ẹ̀, Cisneros kò gba Nebrija láyè láti fi àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣàtúnṣe Bíbélì Vulgate ní èdè Látìn. Níkẹyìn, Nebrija pa iṣẹ́ náà tì dípò táwọn èèyàn yóò fi máa sọ pé ó ṣe àjàǹbàkù iṣẹ́.

Comma Johanneum

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì elédè púpọ̀ ti Alcalá de Henares jẹ́ ìtẹ̀síwájú ńlá nínu ṣíṣe Bíbélì ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n mú sunwọ̀n sí, síbẹ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ máa ń borí ẹ̀kọ́ ìwé nígbà mìíràn. Àwọn èèyàn ní ọ̀wọ̀ ńlá fún Bíbélì Vulgate débi pé nígbà bíi mélòó kan, ó di dandan fáwọn olóòtú láti ṣàtúnṣe sí “Májẹ̀mú Tuntun” lédè Gíríìkì kí wọ́n bàa lè rí i dájú pé ó bá ti Látìn mu dípò tí wọn ì bá fi tún ti Látìn ṣe kó lè bá ti Gíríìkì mu. Ọ̀kan lára àwọn àpẹẹrẹ yìí ni ayédèrú ẹsẹ Bíbélì kan tó gbajúmọ̀ tá a mọ̀ sí comma Johanneum.d Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Gíríìkì ìjímìjí tó ní gbólóhùn náà nínú, èyí sì fi hàn dájúdájú pé ọ̀rúndún bíi mélòó kan lẹ́yìn tí Jòhánù kọ̀wé rẹ̀ tán ni wọ́n kì í bọ ibẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò sí nínú Bíbélì Vulgate ní èdè Látìn àfọwọ́kọ tó pẹ́ jù lọ. Nítorí náà, Erasmus mú èyí tí wọ́n mú wọlé yìí kúrò nínú “Májẹ̀mú Tuntun” lédè Gíríìkì tó ṣe.

Àwọn olóòtú Bíbélì elédè púpọ̀ kò fẹ́ yọ ẹsẹ tó ti wa fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún nínu Bíbélì Vulgate ọlọ́jọ́ pípẹ́ yìí kúrò. Nítorí èyí, wọ́n ò fọwọ́ kan ayédèrú ẹsẹ tó wà nínú Bíbélì Látìn yìí, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n wá fi sínú èdè Gíríìkì kí òpó méjèèjì tí ọ̀rọ̀ náà wà lè bára mu.

Ìpìlẹ̀ fún Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Tuntun

Kì í ṣe nítorí pé Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì àti ti Septuagint tá a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde wà nínú Bíbélì elédè púpọ̀ ti Complutensian nìkan ló mú kí Bíbélì náà ṣe pàtàkì. Ohun mìíràn ni pé, àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó wà nínú Bíbélì elédè púpọ̀ náà jẹ́ ìpìlẹ̀ tó dáa fún Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti Árámáíkì, gẹ́gẹ́ bí “Májẹ̀mú Tuntun” lédè Gíríìkì tí Erasmus ṣe ṣe di Ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì (ìpìlẹ̀ tá a gbé ìtumọ̀ àwọn èdè mìíràn kà) tí gbogbo èèyàn fọwọ́ sí.e Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó wà nínú Bíbélì elédè púpọ̀ yìí ni William Tyndale lò fún títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Nítorí náà, iṣẹ́ tí àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó ṣe Bíbélì elédè púpọ̀ ti Complutensian ṣe, ti ṣe bẹbẹ láti mú ìtẹ̀síwájú bá ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́. Wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde nígbà tí ìfẹ́ táwọn èèyàn ní fún Bíbélì ní gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù ti bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn ronú lórí bí wọn yóò ṣe túmọ̀ rẹ̀ sí èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ. Bíbélì elédè púpọ̀ yìí ti jẹ́ àrànṣe kan nínú ọ̀nà tá a gbà ṣe ìyọ́mọ́ èdè Gíríìkì òun Hébérù àti ọ̀nà tá a gbà pa wọ́n mọ́ títí dòní olónìí. Gbogbo ìsapá yìí ló bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu pé ‘àsọjáde Jèhófà tí a yọ́ mọ́,’ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”— Sáàmù 18:30; Aísáyà 40:8; 1Pétérù 1:25.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ẹ̀dà ni wọ́n tẹ̀ sórí ìwé, wọ́n sì tẹ ẹ̀dà mẹ́fà sórí awọ. Lọ́dún 1984, wọ́n tẹ àwọn ẹ̀dà díẹ̀ mìíràn tó dà bíi ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ gan-an.

b Èdè Hébérù, Gíríìkì, àti Látìn.—Jòhánù 19:20.

c Wọ́n gbà pé Nebrija ni òléwájú nínú àwọn afẹ́dàáfẹ́re ilẹ̀ Sípéènì (ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó ń gba èrò àwọn ẹlòmíràn mọ́ tirẹ̀). Lọ́dún 1942, ó ṣèwé kan tó ń jẹ́ Gramática castellana (Gírámà Èdè Àwọn Ara Castile). Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó pinnu láti fi ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́.

d Nínú 1 Jòhánù 5:7, ayédèrú àfikún tó wà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan kà pé, “ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀, àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí sì jẹ́ ọ̀kan.”

e Fún àlàyé lórí iṣẹ́ Erasmus, wo Ile-Iṣọ Naa, March 15, 1983, ojú ìwé 8 sí 11.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Kádínà Jiménez de Cisneros

[Credit Line]

Biblioteca Histórica. Universidad Complutense de Madrid

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Antonio de Nebrija

[Credit Line]

Biblioteca Histórica. Universidad Complutense de Madrid

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

Biblioteca Histórica. Universidad Complutense de Madrid

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́