Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ le e yìí:
• Kí ló fi hàn pé Jésù ní àwọn àbúrò lọ́kùnrin àti lóbìnrin?
Ohun tó fi hàn ni pé Bíbélì sọ bẹ́ẹ̀ nínú Mátíù 13:55, 56 àti Máàkù 6:3. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà (adelphos) tá a lò nínú ẹsẹ wọ̀nyí túmọ̀ sí “bí ẹnì kan ṣe bá àwọn kan tán, yálà nípa tara tàbí lábẹ́ òfin, kìkì ohun tó [sì] . . . túmọ̀ sí ni ọmọ bàbá àti ìyá kan náà tàbí àwọn tó jọ jẹ́ ọmọ ìyá tàbí ọmọ bàbá.” (The Catholic Biblical Quarterly, January 1992)—12/15, ojú ìwé 3.
• Irú ogun wo làwọn èèyàn ń jà báyìí, kí ló sì fà á?
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ogun abẹ́lé ni kìkì ogun tó ń kó ìdààmú bá aráyé, ìyẹn ogun táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà ń bá ara wọn jà. Ohun tó sì fa èyí ni ìkórìíra ẹ̀yà àti ìran, ìsìn tó yàtọ̀ síra, ìwà ìrẹ́nijẹ, àti rògbòdìyàn ìṣèlú. Ohun mìíràn tó fà á ni fífi ẹ̀mí ìwọra wá ipò agbára àti fífi ìwọra wá owó.—1/1, ojú ìwé 3-4.
• Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò ni lọ́kàn pé káwọn Kristẹni kọ́ àdúrà Olúwa ní àkọ́sórí kí wọ́n lè máa kà á lákàtúnkà?
Jésù fúnni ní àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà tó ń ṣe Ìwàásù lórí Òkè. Ní nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà, ó ṣe àtúnsọ àwọn kókó pàtàkì inú ìtọ́ni tó fún wọn nípa bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà. (Mátíù 6:9-13; Lúùkù 11:1-4) Kókó kan tó gbàfiyèsí ni pé kò tún àwọn ọ̀rọ̀ náà sọ gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ ọ́ ní àkọ́kọ́, èyí sì fi hàn pé kò ni lọ́kàn pé ká kọ́ àdúrà náà ní àkọ́sórí ká lè máa kà á lákàtúnkà.—2/1, ojú ìwé 8.
• Lẹ́yìn Ìkún Omi, ibo ni ẹyẹ àdàbà náà ti rí ewé ólífì tó mu wá sínú ọkọ̀ áàkì?
A ò mọ bí iyọ̀ ṣe wà nínú ìkún omi náà tó, a ò sì mọ ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù ìkún omi náà. Àmọ́, bá a bá gé igi ólífì lulẹ̀, ẹ̀ka tuntun máa ń sọ jáde. Nítorí náà, àwọn igi kan lè ti la ìkún omi náà já kí wọ́n sì yọ ewé lẹ́yìn náà.—2/15, ojú ìwé 31.
• Nígbà tí ogun abẹ́lé ní Nàìjíríà sé ọ̀nà mọ́ àwọn èèyàn Biafra, báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè yẹn ṣe rí oúnjẹ tẹ̀mí?
Wọ́n yan òṣìṣẹ́ ìjọba kan sí ọ́fíìsì kan ní Yúróòpù, wọ́n sì yan ọkàn sí ibi tí àwọn Biafra ti ń gba ẹrù tó ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè. Ẹlẹ́rìí làwọn méjèèjì. Wọn yọ̀ǹda ara wọn láti máa kó oúnjẹ tẹ̀mí wọ Biafra, ìyẹn sì jẹ́ iṣẹ́ tó lè fi ẹ̀mí wọn sínú ewu. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ará láǹfààní títí ogun fi parí ní ọdún 1970.—3/1 ojú ìwé 27.
• Kí ni àbájáde Ìpàdé Àlàáfíà Westphalia, báwo sì ni ọ̀ràn náà ṣe kan ìsìn?
Àtúntò ìsìn pín Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ sí ẹ̀sìn mẹ́ta, ìyẹn ẹ̀sìn Kátólíìkì, àwọn ọmọlẹ́yìn Luther àti àwọn ọmọlẹ́yìn Calvin. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, wọ́n dá Ìparapọ̀ Pùròtẹ́sítáǹtì àti Ìmùlẹ̀ àwọn Kátólíìkì sílẹ̀. Ohun tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ bí ìjà ẹ̀sìn lẹ́kùn ilẹ̀ Bohemia ló wá di ìjàdù agbára láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn aṣáájú Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì máa ń du ipò òṣèlú àti èrè orí okòwò mọ́ra wọn lọ́wọ́. Níkẹyìn, wọ́n ṣe ìpàdé àlàáfíà ní ìpínlẹ̀ Westphalia ní Jámánì. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún márùn-ún, wọ́n fọwọ́ sí ìwé Àdéhùn Àlàáfíà Ìlú Westphalia ní ọdún 1648, èyí ló fòpin sí Ogun Ọgbọ̀n Ọdún, ìgbà yẹn ni ilẹ̀ Yúróòpù òde òní di ilẹ̀ tó ní àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira.—3/15, ojú ìwé 20-23.
• Kí ni ìtumọ̀ àmì tàbí orúkọ “ẹranko ẹhànnà,” ìyẹn àmì 666?
A mẹ́nu kan àmì yìí nínú Ìṣípayá 13:16-18. Ẹranko ẹhànnà náà túmọ̀ sí àkóso ènìyàn, níní tí ẹranko náà sì ní “nọ́ńbà ènìyàn” fi hàn pé àìpé ẹ̀dá àti ẹ̀ṣẹ̀ yóò máa hàn nínú gbogbo ohun tí ìjọba bá ń ṣe. Nọ́ńbà náà 6 àti 60 àti 600 fi hàn pé ẹranko náà kò kúnjú òṣùwọ̀n rára lójú Ọlọ́run. Àwọn tó ní àmì yìí ń bọlá fún Ìjọba orílẹ̀-èdè bí ẹní ń sìn wọ́n, tàbí wọ́n gbójú lé wọn fún ìgbàlà.—4/1, ojú ìwé 4-7.