Wíwàásù Láìjẹ́-Bí-Àṣà Fáwọn Tó Ń sọ Èdè Gẹ̀ẹ́sì Ní Mẹ́síkò
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń dúró de àwọn arìnrìn-àjò ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Áténì, ó lo àǹfààní yẹn láti wàásù láìjẹ́-bí-àṣà. Bíbélì ròyìn pé: “Ó bẹ̀rẹ̀ sí fèrò-wérò . . . ní ojoojúmọ́ ní ibi ọjà pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.” (Ìṣe 17:17) Nígbà tí Jésù ń ti Jùdíà lọ sí Gálílì, ó wàásù láìjẹ́-bí-àṣà fún obìnrin ará Samáríà kan lẹ́bàá kànga. (Jòhánù 4:3-26) Ǹjẹ́ o máa ń lo gbogbo àǹfààní tó o ní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?
Ibi táwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò dára gan-an fún iṣẹ́ ìwàásù àìjẹ́-bí-àṣà. Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń lọ síbi ìgbafẹ́, bí àwọn ọmọ yunifásítì kan ṣe ń lọ làwọn mìíràn ń dé, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tí kì í ṣe ọmọ Mẹ́síkò tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ máa ń lọ sí ọgbà ìtura àtàwọn ilé oúnjẹ déédéé. Ó rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó gbédè Gẹ̀ẹ́sì láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Àní, wọ́n máa ń wà lójúfò láti sọ̀rọ̀ fún ẹnikẹ́ni tó jọ àjèjì tàbí tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é.
Lọ́pọ̀ ìgbà, tí àwọn tó ti orílẹ̀-èdè mìíràn wá láti wàásù fáwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì bá fẹ́ bá àwọn tó jọ àjèjì sọ̀rọ̀, wọ́n á kàn sọ ẹni tí wọ́n jẹ́ fáwọn àjèjì náà, wọ́n á sì tún béèrè ibi táwọn àjèjì náà ti wá. Ìbéèrè yẹn ló máa wá mú kí àjèjì náà fẹ́ mọ ohun tí Ẹlẹ́rìí náà wá ṣe ní Mẹ́síkò, èyí á sì fún Ẹlẹ́rìí náà láǹfààní láti sọ àwọn ohun tó jẹ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni fún onítọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ, ó rọrùn fún Gloria láti bẹ̀rẹ̀ ìwàásù lọ́nà yẹn, ó ń sìn níbi tí wọ́n ti nílò ọ̀pọ̀ oníwàásù ní àgbègbè táwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì wà ní Oaxaca. Gloria lọ wàásù láìjẹ́-bí-àṣà ní gbàgede ìlú, nígbà tó sì ń padà bọ̀, tọkọtaya kan tó wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dá a dúró. Obìnrin náà sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé mo lè bá obìnrin tó jẹ́ èèyàn dúdú pàdé lójú títì ní Oaxaca!” Dípò kí Gloria bínú, ńṣe ló rẹ́rìn ín, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣàwàdà pé kí ló wá ṣe ní Mẹ́síkò. Obìnrin náà ní kí Gloria wá mu kọfí nílé òun. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàdéhùn tán, Gloria fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ̀ ọ́, àmọ́ obìnrin náà kò gba àwọn ìwé ìròyìn náà, ó lóun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Gloria sọ fún un pé inú òun máa ń dún láti bá àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà sọ̀rọ̀ àti pé òun yóò fẹ́ láti mọ èrò rẹ̀ nípa àpilẹ̀kọ náà, “Ǹjẹ́ A Nílò Àwọn Ibi Ìjọsìn?” Obìnrin náà gbà, ó wá sọ pé: “Tó o bá lè mú kí n yí èrò mi padà, ìyẹn á mà dára gan-an o.” Wọ́n jọ sọ̀rọ̀ gan-an bí wọ́n ṣe ń mu kọfí. Nígbà tó yá, tọkọtaya náà padà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àmọ́ àwọn àti Ẹlẹ́rìí náà ṣì jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà.
Gloria tún bá obìnrin kan tó ń jẹ́ Saron sọ̀rọ̀, obìnrin náà jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan láti Washington, D.C., ó sì ń gbé ní Oaxaca níbi tó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni pẹ̀lú àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ ibẹ̀ kó lè parí ẹ̀kọ́ tó máa fi gboyè kejì ni yunifásítì. Lẹ́yìn tí Gloria yin Saron fún akitiyan rẹ̀, ó wá ṣàlàyé ìdí tóun fi wá sí Mẹ́síkò. Èyí mú kí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ dáadáa nípa Bíbélì àtohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún gbogbo èèyàn, kì í wúlẹ̀ ṣe fáwọn mẹ̀kúnnù nìkan. Saron sọ pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fóun nítorí pé nígbà tóun wà ní Amẹ́ríkà, òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí kò tíì jọ sọ̀rọ̀ rí, ọkàn lára àwọn tóun sì máa kọ́kọ́ bá pàdé ní Mẹ́síkò jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Saron gbà pé kí wọ́n máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àjèjì ló ti ṣí lọ sí àwọn ibi ìgbafẹ́ tó wà létí òkun ní Mẹ́síkò, wọ́n ń wá ibi tó dà bíi Párádísè. Ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí yìí ni Laurel fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nílùú Acapulco, ó bi wọ́n pé ibo lo jọ Párádísè ju nínú Acapulco àti ibi tí wọ́n ti wá, ó tún béèrè ohun tí wọ́n fẹ́ràn nípa ibẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé pé láìpẹ́ gbogbo ayé yóò di Párádísè ní ti gidi. Ọ̀nà tó gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin ara Kánádà kan tó bá pàdé ní ọ́fíìsì dókítà ẹranko nìyẹn, èyí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí i bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ǹjẹ́ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí lè gbéṣẹ̀ níbi tó ò ń gbé?
‘Ní Ojú Pópó àti Ní Àwọn Ojúde Ìlú’
Bí wọ́n ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lójú pópó àti ní ojúde ìlú rèé, wọ́n á béèrè pé: “Ǹjẹ́ o gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì?” Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Mẹ́síkò ló gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì nítorí irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tàbí nítorí pé wọ́n ti gbé ní Amẹ́ríkà rí.
Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan lọ bá obìnrin àgbàlagbà kan tí nọ́ọ̀sì kan ń fi kẹ̀kẹ́ arọ tì lọ. Wọ́n bi obìnrin náà bóyá ó gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì. Ó lóun gbọ́ nítorí pé òun ti gbé ní Amẹ́ríkà rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ó gba Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ́wọ́ wọn, kò sì tíì gba àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí rí, ó sọ orúkọ rẹ̀ fún wọn, ìyẹn Consuelo, ó sì tún fún wọn ní àdírẹ́sì rẹ̀. Nígbà tí wọ́n wá a lọ níjọ́ kẹrin, wọ́n rí i pé ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó ló ń gbé, ìyẹn èyí táwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì ń bójú tó. Ó kọ́kọ́ ṣòro fún tọkọtaya Ẹlẹ́rìí náà láti rí Consuelo nítorí pé ara ń fu àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà, wọ́n wá sọ pé Consuelo ò lè ráyè láti gbọ́ tiwọn. Tọkọtaya náà rọ àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà láti bá àwọn sọ fun Consuelo pé àwọn ti dé o, àti pé àwọn á fẹ́ láti kí i. Tọwọ́tẹsẹ̀ ni Consuelo fi gbà wọ́n wọlé. Látìgbà náà ni obìnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún yìí ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé láìfi àwọn ọ̀rọ̀ òdì táwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ń sọ pè. Ó sì ti lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni lẹ́ẹ̀mélòó kan.
Ìwé Òwe 1:20 sọ pé: “Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké sókè ní ojú pópó gan-an. Àwọn ojúde ìlú ni ó ti ń fọ ohùn rẹ̀ jáde.” Kíyè sí bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀ ní gbàgede ìlú San Miguel de Allende. Láàárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kan, Ralph lọ bá ọkùnrin kan tọ́jọ́ orí rẹ̀ wà láàárín ogójì ọdún sí àádọ́ta ọdún tó jókòó sórí àga gbọọrọ kan. Ẹnu ya ọkùnrin náà bí Ralph ṣe wá fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ̀ ọ́, ó wá sọ ìtàn ìgbésí ayé ara rẹ̀ fún Ralph.
Ọkùnrin yìí wà lára àwọn tó jagun Vietnam, ìdààmú ọkàn tó ní nítorí rírí tó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú èèyàn nígbà tó ń ṣiṣẹ́ ológun sì ti dá àìsàn burúkú sí i lára. Wọ́n dà á padà látojú ogun sí àgọ́ àwọn sójà. Nínú àgọ́ náà, wọ́n ní kó máa wẹ òkú àwọn sójà kí wọ́n tó kó àwọn òkú náà lọ sí Amẹ́ríkà. Ní báyìí, ìyẹn ọgbọ́n ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń lálàá burúkú, tí ẹ̀rù sì máa ń bà á. Láàárọ̀ ọjọ́ tó jókòó sí gbàgede ìlú yìí, ńṣe ló ń gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún ìrànlọ́wọ́.
Ọkùnrin ajagunfẹ̀yìntì yìí gba àwọn ìwé ìròyìn náà, ó sì gbà láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lẹ́yìn tó ti lọ sípàdé náà, ó sọ pé wákàtí méjì tóun lò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba ni ìgbà àkọ́kọ́ tóun máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan ni ọkùnrin yìí lò ní San Miguel de Allende, àmọ́ ó gbádùn àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n bá a ṣe, kò sì pa ìpàdé kankan jẹ títí tó fi padà sílùú rẹ̀. Wọ́n ṣe àwọn ètò kan kí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lè máa bá a nìṣó.
Wíwàásù Láìjẹ́-Bí-Àṣà Níbi Iṣẹ́ àti Nílé Ìwé
Ṣé ò ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́? Ohun tí Adrián ṣe nìyẹn, ó máa ń fi ilé háyà fún àwọn tó ń wá sí Cape San Lucas láti lo àkókò ìsinmi wọn. Nítorí èyí, obìnrin kan tó ń jẹ́ Judy tóun àti Adrián jọ ń ṣiṣẹ́ sọ pé: “Lọ́dún mẹ́ta péré sẹ́yìn, tẹ́nì kan bá sọ fún mi pé máa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, máa sọ fónítọ̀hún pé, ‘Láéláé, ìyẹn ò lè ṣẹlẹ̀!’ Àmọ́, mo pinnu pé mo fẹ́ máa ka Bíbélì. Mo rò ó lọ́kàn mi pé, ‘Ṣé ìyẹn máa wá nira fún mi ni, níwọ̀n bí mo ti fẹ́ràn ìwé kíkà?’ Ṣùgbọ́n mi ò rò pé mo kà ju ojú ìwé mẹ́fà lọ tí mo fi mọ̀ pé mo nílò ìrànlọ́wọ́. Ẹnì kan ṣoṣo tí mo sì ronú kàn pé ó lè ràn mí lọ́wọ́ ni ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adrián. Mo fẹ́ràn láti máa bá a sọ̀rọ̀ nítorí pé òun nìkan ṣoṣo ni ọmọlúwàbí tó wà níbi iṣẹ́ wa.” Kíá ni Adrián sọ pé òun yóò mú àfẹ́sọ́nà òun tó ń jẹ́ Katie wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì dáhùn gbogbo ìbéèrè Judy. Katie bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ sígbà yẹn tí Judy fi di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi.
Wíwàásù láìjẹ́-bí-àṣà nílé ìwé ńkọ́? Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì kan ń kọ èdè Spanish ní yunifásítì, àmọ́ wọ́n pa iléèwé jẹ lọ́jọ́ kan nítorí pé wọ́n lọ sí àpéjọ Kristẹni. Nígbà tí wọ́n padà dé kíláàsì, wọ́n ní kí wọ́n fi èdè Spanish sọ ohun tí wọ́n ń ṣe tí wọn ò fi wá sí iléèwé. Wọ́n lo àǹfààní yìí láti fi gbogbo èdè Spanish tí wọ́n gbọ́ wàásù. Olùkọ́ wọn tó ń jẹ́ Silvia nífẹ̀ẹ́ sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì gan-an. Ó ní kí wọ́n máa fi èdè Gẹ̀ẹ́sì bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti di akéde ìhìn rere náà báyìí. Àwọn mélòó kan nínú ìdílé rẹ̀ náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Silvia sọ pé: “Mo rí ohun tí mo ń fi gbogbo ọjọ́ ayé mi wá kiri.” Bẹ́ẹ̀ ni o, wíwàásù láìjẹ́-bí-àṣà lè mú èso rere jáde.
Lílo Àwọn Àǹfààní Mìíràn
Fífi ẹ̀mí aájò àlejò hàn lè yọrí sí wíwàásù fún àwọn èèyàn. Jim àti Gail tí wọ́n ń sìn ní San Carlos, ní Sonora rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Obìnrin kan tó mú ajá rẹ̀ rìn jáde láago mẹ́fà àárọ̀ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà wọn, ó sọ fún wọn pé òun fẹ́ràn bí ọgbà náà ṣe rí. Jim àti Gail ní kí obìnrin náà wọlé wá mu kọfí. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí obìnrin náà máa gbọ́ nípa Jèhófà àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun láti ọgọ́ta ọdún tó ti wà lókè eèpẹ̀. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Adrienne tún máa ń ṣoore fáwọn àjèjì. Ó ń jẹun ní ilé oúnjẹ kan ní Cancún nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan wá bá a, tó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé bóyá orílẹ̀-èdè Kánádà ló ti wá. Nígbà tó sọ fún ọ̀dọ́kùnrin náà pé Kánádà lòun ti wá, ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fún un pé òun àti màmá òun fẹ́ ran àbúrò òun obìnrin kan lọ́wọ́ láti kó ọ̀rọ̀ kan jọ nípa àwọn ará Kánádà, èyí tó fẹ́ mu lọ sílé ìwé. Màmá rẹ̀ gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì, ló bá lọ jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Adrienne. Lẹ́yìn tí Adrienne tí fi sùúrù dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ nípa àwọn ará Kánádà, ó sọ pé: “Àmọ́, ohun pàtàkì kan ló gbé mi wá láti Kánádà o, mo wá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Bíbélì. Ṣé o nífẹ̀ẹ́ sí i?” Obìnrin náà sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ sí i. Ọdún mẹ́wàá rèé tí obìnrin yìí ti fi ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, ó sì ti ń gbìyànjú láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra rẹ̀. Ó fún Adrienne ní nọ́ńbà tẹlifóònù àti àdírẹ́sì rẹ̀, Adrienne sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó gbádùn mọ́ni.
“Fọ́n Oúnjẹ Rẹ sí Ojú Omi”
Sísọ̀ òtítọ́ Bíbélì níbi gbogbo sábà máa ń jẹ́ ká lè wàásù fáwọn èèyàn tí wọ́n ò fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ní ilé oúnjẹ kan térò sábà máa ń pọ̀ sí ni ìlú Zihuatanejo tí èbúté wà, Ẹlẹ́rìí kan ní kí tọkọtaya àjèjì kan wá jókòó níbi tábìlì àwọn nítorí pé kò sí ìjókòó mọ́ nílé oúnjẹ náà. Ọdún méje rèé tí tọkọtaya yìí ti ń rìnrìn àjò orí omi láti ibì kan lọ sí ibòmíràn. Wọ́n sọ èrò òdì táwọn ní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ìgbà tí obìnrin Ẹlẹ́rìí yìí bá tọkọtaya náà pàdé nílé oúnjẹ, ó tún lọ bá wọn nínú ọkọ̀ ojú omi wọn, ó sì ní kí wọ́n wá sí ilé òun. Wọ́n gba ìwé ìròyìn tó lé ní ogun àti ìwé ńlá márùn ún, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn yóò kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí nígbà táwọn bá dé ibi tó kàn táwọn ti máa dúró.
Nígbà tí Jeff àti Deb wà ní àgbàlá ìjẹun kan tó wà níbi táwọn ṣọ́ọ̀bù ìtajà pọ̀ sí ní Cancún, wọ́n kíyè sí bàbá àti ìyá kan àti arẹwà ọmọbìnrin wọn kékeré. Nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà, àwọn òbí rẹ̀ ní kí wọ́n wá jẹ búrẹ́dì tí wọ́n kó ewé àti wàràkàṣì sínú rẹ̀. Àṣé orílẹ̀-èdè Íńdíà ni ìdílé náà ti wá. Wọn ò tíì gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, wọn ò sì tíì rí àwọn ìwé wọn rí. Wọ́n gba ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí wọ́n tó kúrò níbẹ̀.
Ohun tó fara jọ ìyẹn wáyé ní erékùṣù kan tí kò jìnnà sí etíkun Yucatán. Tọkọtaya ará Ṣáínà kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ní kí Jeff ya àwọn ní fọ́tò, Jeff sì ṣe bẹ́ẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Nínú ọ̀rọ̀ wọn, Jeff rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkọtaya náà ti lo ọdún méjìlá ní Amẹ́ríkà, wọ́n ò tíì rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ò tíì bá wọn sọ̀rọ̀ rí! Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jọ sọ̀rọ̀ nìyẹn. Jeff gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà tí wọ́n bá padà délé.
Ohun pàtàkì kan lè wáyé ní àgbègbè rẹ tí yóò fún ọ láǹfààní láti wàásù láìjẹ́-bí-àṣà. Nígbà tí ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wá kí ààrẹ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò nínú ọ̀gbà rẹ̀ tó wà nítòsí Guanajuato, àwọn oníròyìn láti ibi gbogbo lágbàáyé ló wá kí wọ́n lè gbé ìròyìn náà jáde. Ìdílé kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lo àǹfààní yẹn láti fi èdè Gẹ̀ẹ́sì wàásù níbẹ̀. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, oníròyìn kan ti ṣe ìròyìn nípa ọ̀pọ̀ ogun, bí irú èyí tó wáyé ní Kosovo àti Kuwait. Ológun kan tó lúgọ síbì kan ló yìnbọn pa oníròyìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan. Nígbà tí oníròyìn náà gbọ́ nípa àjíǹde, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú omijé lójú, pé ó jẹ́ kí òun mọ̀ pé ìgbésí ayé ní ìtumọ̀. Ó sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ò ní rí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí náà mọ́, òun ò ní gbàgbé ìhìn rere tó wá látinú Bíbélì yìí láé.
Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìrírí wọ̀nyí ṣe fi hàn, a kò mọ ohun tó jẹ́ àbájáde àwọn iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà. Àmọ́, Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò tún rí i.” Ó tún sọ pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.” (Oníwàásù 11:1, 6) Bẹ́ẹ̀ ni o, máa fi ìtara “fọ́n oúnjẹ rẹ” sí ojú omi púpọ̀, kí o sì máa fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ “fún irúgbìn rẹ,” bíi ti Pọ́ọ̀lù, Jésù àtàwọn Ẹlẹ́rìí òde òní tí ń bẹ ní àgbègbè àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì ní Mẹ́síkò.