Ogun Ti Yí Padà
ỌṢẸ́ tí ogun máa ń ṣe kò kéré. Ó máa ń fi ẹ̀mí àwọn sójà ṣòfò, ó sì máa ń fìyà jẹ àwọn aráàlú. Àmọ́ bí ogun ṣe máa ń rí ti yí padà láwọn ọdún àìpẹ́ yìí o. Lọ́nà wo?
Ogun abẹ́lé làwọn èèyàn ń jà lóde òní, ìyẹn ogun táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà ń bá ara wọn jà. Ogun abẹ́lé kì í sì í tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀, òun ló máa ń kó hílàhílo bá àwọn èèyàn jù, ó sì máa ń ba orílẹ̀-èdè jẹ́ gan-an ju ogun tí orílẹ̀-èdè kan máa ń gbé dìde sí orílẹ̀-èdè kejì. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Julián Casanova sọ pé: “Ogun abẹ́lé máa ń ṣe ìpalára gan-an, ó máa ń fa ọ̀pọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó ń yọrí sí ikú ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, ìfipábánilòpọ̀, àti fífipá léni lọ sí ìgbèkùn, kódà ó máa ń yọrí sí ìpẹ̀yàrun nígbà mìíràn tọ́ràn náà bá burú jáì.” Ká sòótọ́, ọgbẹ́ ọkàn téèyàn máa ń ní nígbà táwọn tó jọ jẹ́ aládùúgbò bá hu ìwà ìkà sí ara wọn kì í jinná bọ̀rọ̀.
Ìwọ̀nba ogun díẹ̀ ló wáyé láàárín àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè kan àti ti orílẹ̀-èdè mìíràn látìgbà tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ti parí. Àjọ Ìṣèwádìí Àlàáfíà Àgbáyé ní Stockholm ròyìn pé: “Mẹ́ta péré ni kì í ṣe ogun abẹ́lé lára gbogbo ogun tó wáyé láàárín ọdún 1990 sí 2000.”
Lóòótọ́, àwọn rògbòdìyàn abẹ́lé lè dà bí èyí tí kì í fi bẹ́ẹ̀ kó ìjayà báni, àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde pàápàá lè fojú dì í, àmọ́ ìyà tó máa ń fi jẹni àti bó ṣe máa ń ba nǹkan jẹ máa ń bani nínú jẹ́ gan-an ni. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti kú lákòókò rògbòdìyàn abẹ́lé. Kódà, láàárín ogún ọdún tó kọjá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù márùn-ún èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn láwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tà tí ogun ti sọ di ẹdun arinlẹ̀, ìyẹn orílẹ̀-èdè Afghanistan, orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò, àti orílẹ̀-èdè Sudan. Ogun ẹlẹ́yàmẹ̀yà tó burú jáì láwọn àgbègbè Balkan ti gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000], àwọn agbábẹ́lẹ̀ jagun tó ti wà ní orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà tipẹ́ náà sì ti pa ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn.
Àwọn ọmọdé gan-an ni ọṣẹ́ tí ogun ń ṣe máa ń nípa lé lórí jù lọ. Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé ó lé ní mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọdé tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú àwọn ogun abẹ́lé tó wáyé láàárín ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Àwọn mílíọ̀nù mẹ́fà mìíràn sì fara pa. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ni wọ́n ti sọ di sójà. Ọmọ kékeré kan tó jẹ́ sójà sọ pé: “Wọ́n kọ́ mi. Wọ́n gbé ìbọn lé mi lọ́wọ́. Mo lo oògùn olóró. Mo sì pa àwọn aráàlú. Àwọn tí mo pa pọ̀ gan-an. Ogun lásán ni . . . Àṣẹ tí wọ́n pa fún mi ni mo tẹ̀lé. Mo mọ̀ pé ìwà ibi ni. Kò wu èmi náà bẹ́ẹ̀.”
Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ogun abẹ́lé ti máa ń jà ní gbogbo ìgbà, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé tó ń dàgbà níbẹ̀ ni kò mo ohun tó ń jẹ́ àlàáfíà. Wọ́n ń gbé nínú ayé kan níbi táwọn ẹni ibi ti ba gbogbo ilé ìwé jẹ́ àti níbi táwọn èèyàn ti máa ń fi ìbọn bá ara wọn sọ̀rọ̀. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dunja sọ pé: “Wọ́n ti pa ọ̀pọ̀ èèyàn . . . Èèyàn ò lè gbọ́ orin àwọn ẹyẹ mọ́, kìkì igbe àwọn ọmọdé tí wọ́n ń sunkún nítorí ikú ìyà tàbí baba wọn, àti nítorí ikú ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wọn nìkan lèèyàn ń gbọ́.”
Kí Ló Máa Ń Fa Ogun?
Kí ló máa ń tanná ran irú ogun abẹ́lé tó kún fún ìwà ìkà bẹ́ẹ̀? Ìkórìíra ẹ̀yà àti ìran, ìsìn tó yàtọ̀ síra, ìwà ìrẹ́nijẹ, àti rògbòdìyàn ìṣèlú ni olórí ohun tó máa ń fà á. Ohun pàtàkì mìíràn tó tún máa ń fà á ni ẹ̀mí ìwọra, ìyẹn ni fífi ìwọra wá ipò agbára àti fífi ìwọra wá owó. Àwọn olórí òṣèlú ni ẹ̀mí ìwọra sábà máa ń sún láti jẹ́ kí ìkórìíra tó ń tapo sí ìjà náà túbọ̀ pọ̀ sí i. Ìròyìn kan tí Àjọ Ìṣèwádìí Àlàáfíà Àgbáyé ní Stockholm ṣe fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń kópa nínú ogun “ló ń wa èrè ti ara wọn.” Ìròyìn náà fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ẹ̀mí ìwọra ti máa ń fara hàn, látorí àwọn ọ̀gágun àtàwọn olórí òṣèlú tó ń ṣòwò dáyámọ́ǹdì olówó gọbọi títí dórí àwọn ọmọ kéékèèké tó ń fi ìbọn jalè láwọn abúlé.”
Ohun tó túbọ̀ ń jẹ́ kí ìpànìyàn náà peléke sí i ni bí wọ́n ṣe ń ta àwọn ohun ìjà tó ń ṣe ọṣẹ́ tó burú jáì wọ̀nyí ni owó pọ́ọ́kú. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] èèyàn tó ń kú ní ọdọọdún—tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé—la gbọ́ pé àwọn ìbọn ìléwọ́ lásán ni wọ́n fi ń pa wọ́n. Iye tí wọ́n ń ta adìyẹ kan ni wọ́n ń ta ìbọn àgbétèjìká AK-47 ni orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn àgbègbè kan wà tí àwọn ìbọn àgbétèjìká tí wá pọ̀ gan-an bí àwọn adìyẹ ṣe pọ̀. Àwọn èèyàn fojú bù ú pé àwọn ohun ìjà kéékèèké àtàwọn ohun ìjà tó rọrùn láti lò tó wà jákèjádò ayé báyìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù, èyí tó túmọ̀ sí pé ohun ìjà kan wà fún èèyàn méjìlá tá a bá pín ní dọ́gbadọ́gba.
Ṣé ogun abẹ́lé tó kún fún ìwà ìkà tún máa gbòde kan nínú ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí? Ǹjẹ́ a lè káwọ́ ogun abẹ́lé? Ṣé àwọn èèyàn máa dáwọ́ ìpànìyàn dúró ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Àbájáde Búburú Tí Ogun Abẹ́lé Máa Ń Ní
Nínú àwọn ogun abẹ́lé táwọn èèyàn ti lo ohun ìjà àgbélẹ̀rọ tó ṣe ọṣẹ́ tó burú jáì, ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn to fara pa níbẹ̀ ló jẹ́ àwọn aráàlú dípò tíì bá fi jẹ́ àwọn ológun. Graça Machel, Ògbógi tó ń ṣojú Ọ̀gá Àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ọṣẹ́ Tí Ogun Ń Ṣe fún Àwọn Ọmọdé, sọ pé, “Ó hàn gbangba pé àwọn ọmọdé gan-an ni wọ́n dìídì ń fojú sùn nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ogun wọ̀nyí, kì í ṣe pé ogun náà ṣèèṣì ń pa wọ́n.”
Ìfipábánilòpọ̀ ti di ohun tí wọ́n ń lò nígbà ogun báyìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọdébìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bàlágà tí wọ́n ń rí làwọn abúlé ni wọ́n ń fipá bá lòpọ̀ làwọn àgbègbè kan tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ohun tó ń mú káwọn tó ń fipá báni lòpọ̀ wọ̀nyí ṣe bẹ́ẹ̀ kò ju pé kí wọ́n lè kó jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn tàbí kí wọ́n ba àjọṣe tó wà láàárín ìdílé jẹ́.
Ìyàn àti àìsàn tún máa ń jẹ́ àbájáde ogun. Ohun kan tó tún máa ń jẹ́ àbájáde ogun abẹ́lé ni pé ìwọ̀nba ohun díẹ̀ làwọn èèyàn máa ń gbìn lákòókò náà, ohun tí wọn sì máa kórè kì í tó nǹkan, ìtọ́jú ìṣègùn díẹ̀ ló máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ìyẹn tó bá tiẹ̀ wà rárá, ìwọ̀nba ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ làwọn tó dìídì nílò rẹ̀ sì máa ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé. Ìwádìí kan tàwọn èèyàn ṣe nípa ogun abẹ́lé nílẹ̀ Áfíríkà fi hàn pé ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn ni àìsàn ń pa nígbà tí ebi sì ń pa ìpín méjìdínlọ́gọ́rin kú pátápátá. Ìpín méjì nínú ọgọ́rùn-ún péré ni ìjà náà ń pa ní tààràtà.
Ní ìpíndọ́gba, àárín ìṣẹ́jú méjìlélógún méjìlélógún ni ẹnì kan ń gé lọ́wọ́ tàbí lẹ́sẹ̀ tàbí ti ẹnì kan ń kú nítorí pé ó tẹ bọ́ǹbù tí wọ́n kẹ́ sínú ilẹ̀ mọ́lẹ̀. Nǹkan bí ọgọ́ta sí àádọ́rin mílíọ̀nù bọ́ǹbù tí wọ́n kẹ́ sínú ilẹ̀ ló wà káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní ọgọ́ta.
Wọ́n ń fagbára lé àwọn èèyàn kúrò nílé wọn. Nǹkan bí àádọ́ta mílíọ̀nù àwọn olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn tí wọ́n fipá lé kúrò nílé wọn ló wà káàkiri ayé ní báyìí—ìdajì lára wọn ló sì jẹ́ ọmọdé.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ọmọkùnrin: Fọ́tò látọwọ́ Chris Hondros/Getty Images
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò látọwọ́ Chris Hondros/Getty Images