ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/22 ojú ìwé 3
  • Ogun Ń pa Ọ̀pọ̀ Èwe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ogun Ń pa Ọ̀pọ̀ Èwe
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogun Ti Yí Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ọ̀tọ̀ Làwọn Tó Ń Bógun Lọ Lóde Òní
    Jí!—2000
  • Ọjọ́ Ọ̀la Amọ́kànyọ̀ Fún Àwọn Ọmọ wa
    Jí!—1997
  • Ogun Ha Jẹ́ Aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 10/22 ojú ìwé 3

Ogun Ń pa Ọ̀pọ̀ Èwe

ÌGBÀ ọmọdé yẹ kí ó jẹ́ àkókò aláyọ̀. Àkókò tí a ń ṣìkẹ́ ẹni, tí a ń dáàbò boni. Àkókò tí a kò mọ nǹkan kan. A retí kí àwọn ọmọdé máa ṣeré, kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì máa mú àwọn ànímọ́ tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di àgbàlagbà tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ dàgbà. Kò yẹ kí a máa pa àwọn ọmọdé, ó sì dájú pé kò yẹ kí wọ́n di apànìyàn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àkókò ogun, ọ̀pọ̀ ohun tí kò yẹ kó ṣẹlẹ̀ ló máa ń ṣẹlẹ̀.

Ó bani nínú jẹ́ pé ogun wà káàkiri ayé, ó sì ń pa ọ̀pọ̀ èwe, ó ń ṣèparun fún àwọn ọmọdé àti fún ìgbà ọmọdé. Ní 1993, àwọn ogun ńláńlá bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè 42, ìwà jàgídíjàgan àwọn olóṣèlú sì bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn 37 míràn. Àwọn ọmọdé ń gbé nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè 79 wọ̀nyí.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lónìí ni kò gbúròó àlàáfíà rí. Òpin 1995 ni ó pé 30 ọdún tí ìjà ti ń lọ ní Angola, ọdún 17 ní Afghanistan, ọdún 11 ní Sri Lanka, àti ọdún 7 ní Somalia. Ní ibì kan sí òmíràn, àwọn òṣèlú ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa “ìgbésẹ̀ ìgbékalẹ̀ àlàáfíà,” àmọ́ ìgbésẹ̀ ogun tí kò dáwọ́ dúró ń bá a lọ ní pípa ìwàláàyè ẹ̀dá run.

Ogun sábà máa ń pa àwọn ọmọdé lára, àmọ́ ìyípadà nínú bí ogun ti rí lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti yọrí sí pípa àwọn ara ìlú lọ́pọ̀lọpọ̀ sí i, títí kan àwọn ọmọdé. Nígbà àwọn ìforígbárí ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún, àti ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, nǹkan bí ìdajì lára àwọn tí ogun pa ló jẹ́ aráàlú. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, láti 1939 sí 1945, iye àwọn aráàlú tó kú fi ìpín méjì nínú mẹ́ta pọ̀ sí i ju gbogbo àwọn tí ogun ti pa lọ, lápá kan, ó jẹ́ nítorí jíju bọ́ǹbù lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ sí àwọn ìlú ńlá.

Ní òpin àwọn ọdún 1980, àwọn aráàlú tí ogun pa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ tó ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún! Ohun kan tí ó fa èyí ni pé ogun tún ti ń díjú sí i. Kì í tún ṣe ní pápá ogun nìkan ni àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń kojú ara wọn mọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìforígbárí òde òní ni kì í ṣẹlẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, àmọ́ ló jẹ́ ogun abẹ́lé. Síwájú sí i, ìjà máa ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn abúlé tàbí àwọn ìlú ńlá, àti pé níbẹ̀, láàárín ìwà ipá àti ìfura, àwọn apànìyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ọ̀tá àti àwọn tí wọ́n ń wòran.

Iye ẹ̀mí àwọn ọmọdé tí ń bọ́ pọ̀ lápọ̀jù. A fojú díwọ̀n pé láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá nìkan, gẹ́gẹ́ bí Àjọ Àkànlò Owó ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ti sọ, àwọn ogun ti pa àwọn mílíọ̀nù méjì ọmọdé, ó sì ti sọ mílíọ̀nù mẹ́rin sí mílíọ̀nù márùn-ún mìíràn di aláàbọ̀ ara. Ogun ti sọ àwọn ọmọdé tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù kan di aláìlóbìí, ó sì ti sọ mílíọ̀nù 12 di aláìnílé. Nítorí ogun, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá ọmọdé ni a ti kó hílàhílo bá.

Àwọn ibi ìkówèésí kún fún àwọn ìwé tí ń sọ nípa ogun. Àwọn wọ̀nyí ń jíròrò nípa bí a ṣe ń jagun àti ìdí tí a fi ń jagun; wọ́n ń ṣàpèjúwe àwọn ohun ìjà àti ìwéwèé àfìṣọ́raṣe tí a ń lò; wọ́n ń ṣèrántí àwọn ọ̀gágun tó pàṣẹ ìpakúpa náà. Àwọn fíìmù ń gbé apá arunisókè nínú ogun ga, wọ́n kì í sì í gbé bí ìjìyà tí ń tìdí ogún wá ti pọ̀ tó jáde. Ìwọ̀nba nǹkan ni irú àwọn ìwé àti fíìmù bẹ́ẹ̀ ń sọ nípa àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ tí ń jìyà ìpalára rẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e ṣàgbéyẹ̀wò bí a ti ṣe mú àwọn ọmọdé sìn gẹ́gẹ́ bíi jagunjagun, bí wọ́n ti jẹ́ èyí tí ó ṣeé tètè ṣèpalára fún jù lọ lára gbogbo àwọn tí ń jìyà ìpalára rẹ̀, àti ìdí tí àwa fi sọ pé àwọn ọmọdé òde òní lè gbádùn ọjọ́ ọ̀la amọ́kànyọ̀ kan ní ti gidi.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́