Ogun Ha Jẹ́ Aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀ Bí?
OGUN jẹ́ apá-ẹ̀ka kan tí ń múnisoríkọ́ nínú ìròyìn. Kò sí iyèméjì pé àwọn ìròyìn àtìgbàdégbà nípa ìwà òkú-òǹrorò wọ̀nyẹn ń mú ọ lọ́kàn gbọgbẹ́. Bóyá wọ́n sì tún ń mú ọ ṣe kàyéfì nípa ìdí tí àwọn ohun-ìjà fi gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun èlò láti yanjú àwọn aáwọ̀ púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀. Àwọn ènìyàn kì yóò ha kọ́ láti gbé ní àlàáfíà bí?
Ojútùú sí ìyọnu àjàkálẹ̀ ogun dàbí èyí tí ó túbọ̀ ń dàwáàrí ju ìwòsàn fún àrùn AIDS lọ. Ní ọ̀rúndún ogún, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ti pèjọ láti múrasílẹ̀ fún ogun, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ọkùnrin ni a ti rán lọ sí ogun, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìlú-ńlá ni a sì ti sọ di òkìtì àlàpà. Kò dàbí ẹni pé òpin ìpakúpa náà ti súnmọ́lé. Ìṣòwò àwọn ohun-ìjà-ogun tí ń mówó tabua wọlé mú kí ó dájú pé àwọn ẹgbẹ́-ọmọ-ogun lágbàáyé—àti àwọn ọ̀jagun abẹ́lẹ̀—yóò máa gbéṣẹ́ nìṣó lọ́nà bíbanilẹ́rù.
Bí àwọn ohun-ìjà ogun ti túbọ̀ ń ṣekúpani, iye àwọn abájàm̀bárìn ń gasókè fíofío. Iye tí ó ju ìdajì lọ nínú million 65 àwọn ṣójà tí wọ́n jà nínú Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní ni a pa tàbí ṣeléṣe. Ní nǹkan bíi 30 ọdún lẹ́yìn náà, kìkì bọ́m̀bù àtọ́míìkì méjì péré ni ó gba ìwàláàyè àwọn olùgbé ìlú Japan tí wọ́n ju 150,000 lọ. Láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ìforígbárí ni a ti túbọ̀ ń fimọ sí agbègbè àdúgbò. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣokùnfà ikú, pàápàá jùlọ fún àwọn aráàlú, tí wọ́n jẹ́ ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn abájàm̀bárìn nísinsìnyí.
Bí ẹ̀dà-ọ̀rọ̀, ìpakúpa rẹpẹtẹ yìí ti wáyé nínú sànmánì kan tí ó ti rí àwọn ìsapá aláìlábàádọ́gba láti fi òfin ka ogun léèwọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà fún yíyanjú àwọn aáwọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Pẹ̀lú òpin Ogun Tútù láìpẹ́ yìí, ìrètí gíga wà pé, ètò ayé titun, alálàáfíà kan yóò wá sójútáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, àlàáfíà àgbáyé ṣì jẹ́ ẹ̀tàn síbẹ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Èéṣe?
Ó Ha Jẹ́ Ọ̀ranyàn fún Àwọn Ohun Alààyè Bí?
Àwọn òpìtàn àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn kan jẹ́wọ́ pé ogun jẹ́ aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀—pé ó pọndandan pàápàá—kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ apákan ìjàkadì oníyìípadà tegbòtigaga fún wíwàláàyè. Friedrich von Bernhardi tí irú ìrònú bẹ́ẹ̀ ti nípa lé lórí, tí ó sì jẹ́ olùṣèfọ́síwẹ́wẹ́ ọ̀ràn ogun jiyàn ní 1914 pé ogun jà “fún àǹfààní àwọn ohun alààyè, ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ti ìtẹ̀síwájú ọ̀nà-ìwàhíhù.” Àbá-èrò-orí náà ni pé ogun jẹ́ ọ̀nà kan ti a gbà ń fa àwọn ènìyàn tàbí orílẹ̀-èdè aláìlera tu kúrò, tí a sì ń fi àwọn tí ó lágbára jùlọ sílẹ̀.
Agbára káká ni irú iyàn bẹ́ẹ̀ yóò fi rẹ àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn tí ogun ti sọ di opó àti ọmọ-aláìlóbìí lẹ́kún. Yàtọ̀ sí pé ó rínilára níti ọ̀nà-ìwàhíhù, ìrònú yìí ṣàìfiyèsí àwọn òtítọ́ lílekoko nípa àwọn ogun-jíjà òde-òní. Àwọn ìbọn arọ̀jò-ọta kò dá ẹni tí ó lágbára jùlọ mọ̀ yàtọ̀, àti alágbára àti aláìlera sì ni bọ́m̀bù ń parẹ́ ráúráú.
Ní ṣíṣàì ka àwọn ẹ̀kọ́-àríkọ́gbọ́n tí ń múni ṣe wọ̀ọ̀ ti ogun àgbáyé kìn-ín-ní sí, Adolf Hitler ronú nípa dídá ẹ̀yà ajọ̀gálénilórí sílẹ̀ nípa ìṣẹ́gun nínú ogun. Nínú ìwé rẹ̀ Mein Kampf, ó kọ̀wé pé: “Aráyé ti dàgbà di ńlá nínú ìjàkadì ayérayé, nínú àlàáfíà ayérayé nìkan ni ó sì ti ṣègbé. . . . Àwọn tí wọ́n lágbára jù ni wọ́n gbọ́dọ̀ jọbalénilórí wọn kò sì níláti dàpọ̀ mọ́ àwọn aláìlera.” Àmọ́ ṣáá o, dípò kí ó gbé aráyé ga, Hitler fi àráádọ́ta-ọ̀kẹ́ ìwàláàyè rúbọ ó sì pa odidi kọ́ntínẹ́ǹtì kan run ráúráú.
Síbẹ̀, bí ogun kìí báa ṣe ohun tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn fún àwọn ohun alààyè, kí ni ń sún aráyé síhà ìpara-ẹni-run? Àwọn ipá wo ní ń ti àwọn orílẹ̀-èdè lọ́pọn-pọ̀n-ọ́n wọnú “iṣẹ́ àwọn ẹhànnà” yìí?a Tẹ̀lé e ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó-abájọ fífarasin díẹ̀, tí ń ṣèdènà fún ìsapá dídára jùlọ ti àwọn olùwá-àlàáfíà.
Àwọn Okùnfà Ogun
Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Bí àwọn olóṣèlú àti àwọn ọ̀gágun ti máa ń lò ó níye ìgbà, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ipá tí ó lágbára jùlọ fún gbígbé ogun lárugẹ. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ogun nítorí àtidáàbòbo “àǹfààní orílẹ̀-èdè” tàbí gbèjà “ọlá orílẹ̀-èdè.” Nígbà tí ẹ̀mí-èrò-orí náà orílẹ̀-èdè mi, yálà ó jàre tàbí ó jẹ̀bi bá di èyí tí ó gbilẹ̀, àní fífi ọ̀dájú fínni-níràn ni a lè dáláre pé ó jẹ́ ọ̀nà ìdáàbòbo ara-ẹni lọ́wọ́ ìgbéjàkò ọ̀tá.
Kèéta àwùjọ-ẹ̀yà. Ọ̀pọ̀ àwọn ogun ti ẹkùn-ilẹ̀ ń bẹ́ sílẹ̀ nítorí àwọn ìkórìíra tí ó ti wà fún ìgbà pípẹ́ láàárín àwọn ẹ̀yà-ìran, ẹ̀yà, àti àwọn àwùjọ-ẹ̀yà tí a ó sì wá fẹ́ná sí wọn lẹ́yìn náà. Àwọn ogun tí ń panilẹ́kún ní Yugoslavia àtijọ́, ní Liberia, àti ní Somalia jẹ́ àwọn àpẹẹrẹ ti lọ́wọ́lọ́wọ́.
Ìbáradíje ètò-ọrọ̀-ajé àti ti ológun. Ní àwọn ọjọ́ tí ó dàbí ẹni pé àlàáfíà wà ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, àwọn alágbára ilẹ̀ Europe gbé ẹgbẹ́-ọmọ-ogun ńlá ró níti gidi. Germany àti Great Britain lọ́wọ́ nínú ìdíje kíkan ọkọ̀-ogun ojú omi. Níwọ̀n bí orílẹ̀-èdè kàǹkà-kàǹkà kọ̀ọ̀kan tí ó wá lọ́wọ́ nínú ìpakúpa náà níkẹyìn ti gbàgbọ́ pé ogun kan yóò mú kí agbára wọn peléke síi ti yóò sì mú àbùsí àǹfààní ti ètò-ọrọ̀-ajé wá, àwọn àyíká-ipò ti múratán fún ìforígbárí kan.
Ìjà ọlọ́jọ́-pípẹ́ ti ìsìn. Ní pàtàkì nígbà tí àwọn ìpínyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ti ẹ̀yà-ìran bá mú kí ó lágbára, àwọn àìbáradọ́gba ti ìsìn lè mú kí ọ̀rọ̀ di iṣu-ata yán-an yànan. Àwọn ìforígbárí ní Lebanon ati Northern Ireland, àti àwọn ogun tí ń bẹ láàárín India àti Pakistan, ti ní gbòǹgbò wọn nínú kèéta ìsìn.
Arógunyọ̀ tí a kò rí. Bibeli ṣíi payá pé “ọlọrun ayé yìí,” Satani Eṣu, ń gbé kánkán ṣiṣẹ́ síi nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (2 Korinti 4:4) Bí ó ti kún fún ìbínú ńlá tí ó sì ní “ìgbà kúkúrú,” ó ń ru àwọn àyíká-ipò sókè, títíkan àwọn ogun, tí ń mú ipò ègbé ti ilẹ̀-ayé wà burú síi.—Ìfihàn 12:12.
Kò rọrùn láti pa àwọn okùnfà fífarasin fún ogun wọ̀nyí run. Ní èyí tí ó ju 2,000 ọdún sẹ́yìn, Plato sọ pé “àwọn òkú nìkan ni wọ́n ti rí òpin ogun.” Èrò rẹ̀ tí kò fúnni ní ìrètí ha ni òtítọ́ kíkorò náà tí a gbọ́dọ̀ kọ́ láti tẹ́wọ́gbà bí? Tàbí ìdí ha wà fún wa láti retí pé lọ́jọ́ kan ayé kan láìsí ogun yóò wà?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Napoléon ni ó ṣàpèjúwe ogun gẹ́gẹ́ bí “iṣẹ́ àwọn ẹhànnà.” Bí òun ti lo èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti dàgbà nínú iṣẹ́ ológún àti nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 20 ọdún gẹ́gẹ́ bí onípò-àjùlọ olùdarí ẹgbẹ́-ọmọ-ogun, òun ní ìrírí ìwà ẹhànnà ogun-jíjà ní tààràtà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwòrán ẹ̀yìn-ìwé: Àwòrán àfọ̀dàkùn ti John Singer Sargent Gassed
(apákan rẹ̀), Imperial War Museum, London
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Instituto Municipal de Historia, Barcelona