ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 2/1 ojú ìwé 5-7
  • Ẹni Tó Wà Nídìí Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹni Tó Wà Nídìí Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀMÌ ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN
  • JÉSÙ MÁA FỌ́ ÀWỌN IṢẸ́ ÈṢÙ TÚÚTÚÚ
  • Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ẹlẹ́ṣin Ijọba naa Gẹṣin
    “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tí Ń Sáré Kútúpà Kútúpà!
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Bi A Ṣe Mọ̀ Pe A Wà ni “Ìkẹhin Ọjọ”
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 2/1 ojú ìwé 5-7

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | OGUN TÓ DA AYÉ RÚ

Ẹni Tó Wà Nídìí Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé

Ogun Àgbáyé Kìíní parí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù November, ọdún 1918. Lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀ èèyàn pa iṣẹ́ ajé wọn tì, wọ́n bọ́ sójú pópó, wọn ǹ jó, wọ́n sì ń yọ̀. Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ tí ayọ̀ wọn fi di ìbànújẹ́, torí pé ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú míì tún ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn ogun náà, jàǹbá tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì fà ju ọṣẹ́ tí àwọn ìbọn arọ̀jò-ọta ṣe, lọ.

Láti oṣù June 1918 ni àrùn gágá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọlu àwọn sójà ní ilẹ̀ Faransé. Àrùn yìí ṣe àwọn èèyàn bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Bí àpẹẹrẹ, láàárín oṣù díẹ̀ péré, iye àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí àrùn gágá pa ní ilẹ̀ Faransé pọ̀ ju iye àwọn tó bógun lọ. Nígbà tí ogun parí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun tó pa dà wálé ló ti kó àrùn gágá, bí àìsàn náà ṣe gbèèràn karí ayé nìyẹn.

Ìyẹn nìkan kọ́, lẹ́yìn tí ogun parí, ebi àti ìṣẹ́ wá gbòde kan. Nígbà tí rògbòdìyàn yìí dópin ní ọdún 1918, ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lu ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù pa. Kódà, nígbà tó fi máa di ọdún 1923, owó tí wọ́n ń ná ní ilẹ̀ Jámánì kò níye lórí mọ́. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà ni ọrọ̀ ajé gbogbo àgbáyé dẹnu kọlẹ̀ pátápátá. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, lọdún 1939, ogun àgbáyé kejì bẹ̀rẹ̀ níbi tí ogun àgbáyé kìíní parí sí. Kí ló fà á tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí fi ń ṣẹlẹ̀ léraléra?

ÀMÌ ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó ṣe okùnfà Ogun Àgbáyé Kìíní àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé míì tó wáyé. Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí ‘orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè,’ tí àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn yóò sì kárí ayé. (Mátíù 24:3, 7; Lúùkù 21:10, 11) Ó tilẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ máa jẹ́. Ìwé Ìṣípayá tó wà nínú Bíbélì ṣàlàyé nípa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó ṣẹlẹ̀ láyé ṣe tan mọ́ ogun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run.—Wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ogun Tó Wáyé ní Ọ̀run àti Lórí Ilẹ̀ Ayé.”

Bákan náà, Ìwé Ìṣípayá tún ṣàpèjúwe àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin kan, èyí tí wọ́n tún máa ń pè ní àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin inú Àpókálíìsì tàbí ìwé Ìṣípayá. Mẹ́ta lára àwọn ẹlẹ́ṣin yìí ṣàpèjúwe àwọn àjálù kan tí Jésù sọ ṣáájú nípa rẹ̀, ìyẹn ogun, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn. (Wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà Ti Ń Gẹṣin Lọ?”) Ó ṣe kedere pé, ogun àgbáyé kìíní ló tanná ran gbogbo wàhálà tá a ṣì ń bá yí títí dòní. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì gan-an lẹni tó dá gbogbo wàhálà náà sílẹ̀. (1  Jòhánù 5:19) Ìgbà wo gan-an ni agbára rẹ̀ máa dópin?

Ìwé Ìṣípayá jẹ́ kó dá wa lójú pé, “sáà àkókò kúkúrú” ló ṣẹ́ kù fún Sátánì. (Ìṣípayá 12:12) Ìdí nìyẹn tí inú fi ń bíi gan-an, tó sì ń rúná sí onírúurú àjálù tí kò ṣe é fẹnu sọ lórí ilẹ̀ ayé. Lọ́nà kan náà, àwọn àjálù tí à ń rí lọ́tùn lósì nínú ayé fi hàn pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló kù fun Sátánì.

JÉSÙ MÁA FỌ́ ÀWỌN IṢẸ́ ÈṢÙ TÚÚTÚÚ

Láti ìgbà tí wọ́n ti ja ogun Àgbáyé Kìíní ni gbogbo nǹkan ti dojú rú fún ọmọ aráyé. Láti ìgbà yẹn ni ogun àjàkú-akátá àti rògbòdìyàn òṣèlú ti ń han àwọn èèyàn léèmọ̀, tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn kò fọkàn tán àwọn olóṣèlú mọ́. Ẹ̀rí tí kò ṣe é já ní koro ni èyí tún jẹ́ pé wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run. (Ìṣípayá 12:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fojú rí alákòóso ayé yìí, ohun tó ṣe kò yàtọ̀ sí ti òǹrorò apàṣẹwàá tó mọ̀ pé omi ti tán lẹ́yìn ẹja òun. Nígbà tí àsìkò Sátánì bá pé, gbogbo wàhálà tó ti dá sílẹ̀ látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní ló máa dópin pátápátá.

Pẹ̀lú òye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí o ní yìí, ó yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé Jésù Kristi Ọba wa ọ̀run pé láìpẹ́, ó máa “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ni wọ́n ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń gbàdúrà pé kí ìjọba Ọlọ́run dé? Lábẹ́ Ìjọba yìí, àwọn èèyàn kò ní sí lábẹ́ ìdarí Sátánì mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ Ọlọ́run ni àwọn olóòótọ́ èèyàn á máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Nínú Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn kò ní jagun mọ́, yálà ogun àgbáyé tàbí ogun èyíkéyìí! (Sáàmù 46:9) Á dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run yìí, kí ìwọ náà lè wà níbẹ̀ nígbà tí àlááfíà máa gbilẹ̀ kárí ayé!—Aísáyà 9:6, 7.

Ogun Tó Wáyé ní Ọ̀run àti Lórí Ilẹ̀ Ayé

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn [1,900] ọdún ṣáájú kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó bẹ̀rẹ̀, Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé” lọ Jésù, àmọ́ kò gbà. (Mátíù 4:8, 9) nígbà tó yá, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì gan-an ni “olùṣàkóso ayé” yìí. (Jòhánù 14:30) Àpọ́sítélì Jòhánù náà sọ ohun tó fara jọ ọ́ pé: “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.

Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Sátánì ní agbára tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé òun náà wà lára àwọn tó fa ogun àgbáyé kìíní àti gbogbo wàhálà tó wáyé lẹ́yìn rẹ̀? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, gbogbo àjálù tó ti ṣẹlẹ̀ láti ọdún 1914 kò ṣẹ̀yìn Sátánì, ohun tí ìwé Ìṣípayá sì sọ gan-an nìyẹn. Díẹ̀ rèé lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìwé Ìṣípayá orí 12 sọ nípa rẹ̀:

  • Ẹsẹ 7 Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run láàárín Máíkẹ́lì, ìyẹn Jésù Kristi àti dírágónì náà, ìyẹn Sátánì.

  • Ẹsẹ 9 A fi Èṣù, “ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé.

  • Ẹsẹ 12 “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”

Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àti àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láyé fi hàn pé lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run fìdí múlẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914 ni ogun bẹ́ sílẹ̀ lọ́run.a Ẹ̀ ò ríi pé mánigbàgbé ní ọdún 1914! Ìdí ni pé, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì méjì ló ṣẹlẹ̀ ní ọdún yẹn, ìyẹn ogun tó wáyé lọ́run àti èyí tó ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

a Ka orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà Ti Ń Gẹṣin Lọ?

Ọba ọ̀run gun ẹṣin funfun kan. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ni Ọba tó ń gun ẹṣin lọ nítorí òdodo. (Sáàmù 45:4) Ohun tó kọ́kọ́ ṣe ni pé, ó lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run.—Ìṣípayá 6:2; 12:9.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ẹni tó gun ẹṣin aláwọ̀ iná náà gba àṣẹ “láti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 6:4) Àìmọye ìgbà ni ogun ti fi ojú àwọn èèyàn rí màbo láti ọdún 1914. Kò ju ọdún mọ́kànlélógún [21] tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí, ni Ogun Àgbáyé Kejì tún bẹ̀rẹ̀. Ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ju ogun àgbáyé kinní lọ. Kódà, ìwádìí kan fi hàn pé, nǹkan bí ọgọ́ta mílíọ̀nù [60,000,000] àwọn èèyàn ló ṣègbé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ìyẹn nìkan kọ́ o, láti ọdún 1945 ni àwọn èèyàn ti ń ja ogun abẹ́lé káàkiri, tí wọ́n sì pa àwọn èèyàn ní ìpakúpa lọ́nà tó burú jáì. Ìwádìí tàwọn òpìtàn kan ṣe fi hàn pé, láàárín ọdún 1901 sí 2000, ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù àwọn èèyàn tó bógun lọ.

Ẹni tó gun ẹṣin dúdú náà ní òṣùwọ̀n kan ní ọwọ́ rẹ̀, tó túmọ̀ sí ìyàn. (Ìṣípayá 6:5, 6) Nígbà tí ogun àgbáyé kìíní ń lọ lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun tó ń bá orílẹ̀-èdè Jámánì jà kò jẹ́ kí oúnjẹ wọlé sí orílẹ̀ èdè náà. Wọ́n há wọn mọ́ débi pé, ebi pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [750,000] àwọn èèyàn kú. Bákan náà, ní ọdún 1921, ó lé ní mílíọ̀nù méjì [2,000,000] èèyàn tí ebi pa kú lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Kò pẹ́ tí irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ láwọn ibòmíì. Lápapọ̀, nǹkan bí àádọ́rin mílíọ̀nù àwọn èèyàn ni ìyàn pa láàárín ọdún 1901 sí 2000. Kò tán síbẹ̀, lọ́dọọdún, àìsí oúnjẹ tó ń ṣara lóore ń pa ohun tó lé ní mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọdé tí wọn ò ju ọmọ ọdún márùn-ún lọ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ẹni tó gun ẹṣin ràndánràndán kan, tó sì ń fi àwọn àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn èèyàn. (Ìṣípayá 6:8) Láàárín ọdún 1901 sí 2000, àjàkálẹ̀-àrùn gágá gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn lọ́nà tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan fojú bù ú pé, iye àwọn èèyàn tí àjàkálẹ̀-àrùn yìí pa fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta mílíọ̀nù [50,000,000]. Ìwé náà, Man and Microbes sọ pé: “Látọjọ́ tí aláyé ti dáyé, kò tíì sí àjàkálẹ̀ àrùn tó tún burú tó báyìí.” Ó wá fi kún un pé: “Kódà, àrùn tó ń jẹ́ kí kókó so síni lára gan-an kì í yára pa àwọn èèyàn tó bẹ́ẹ̀.” Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn àìsàn bí ìgbóná, àrùn ibà àti ikọ́ ẹ̀gbẹ wà lára àwọn àjàkálẹ̀ àrùn míì tó ti pa ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn láàárín ọdún 1901 sí 2000.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́