Apa 9
Bi A Ṣe Mọ̀ Pe A Wà ni “Ìkẹhin Ọjọ”
1, 2. Bawo ni awa ṣe lè mọ̀ boya a wà ni awọn ọjọ ikẹhin?
BAWO ni a ṣe lè ni idaniloju pe a ń gbe ni akoko ti Ijọba Ọlọrun yoo gbe igbesẹ lodisi eto-igbekalẹ iṣakoso eniyan ti isinsinyi? Bawo ni a ṣe lè mọ pe a ti sunmọ akoko ti Ọlọrun yoo mu opin deba gbogbo iwa buburu ati ijiya girigiri?
2 Awọn ọmọ-ẹhin Jesu ń fẹ lati mọ awọn nǹkan wọnyẹn. Wọn beere lọwọ rẹ̀ ohun ti “ami” wíwà nihin in rẹ̀ ninu agbara Ijọba yoo jẹ ati ti “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” (Matteu 24:3, NW) Jesu dahun nipa sisọ isọfunni ni kikun nipa awọn iṣẹlẹ ati ipo nǹkan ti yoo mi aye jigijigi eyi ti yoo parapọ fihan pe araye ti wọnu “akoko opin,” “ikẹhin ọjọ” ti eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi. (Danieli 11:40; 2 Timoteu 3:1) Awa ninu ọrundun yii ha ti ri ami alapapọ yii bi? Bẹẹni, a ti rii, lọpọ rẹpẹtẹ!
Awọn Ogun Agbaye
3, 4. Bawo ni awọn ogun ọrundun yii ṣe bá asọtẹlẹ Jesu mu?
3 Jesu sọ tẹlẹ pe “orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede, ati ilẹ̀-ọba si ilẹ̀-ọba.” (Matteu 24:7) Ni ọdun 1914 ayé lọwọ ninu ogun kan ti o ri kiko awọn orilẹ-ede ati ilẹ-ọba jọ lọna kan ti o yatọ si ogun eyikeyii ṣaaju rẹ̀. Ni mimọ otitọ iṣẹlẹ naa ni amọjẹwọ, awọn opitan ni akoko naa pe e ni Ogun Nla naa. O jẹ èkínní ogun iru rẹ̀ ninu itan, ogun agbaye kìn-ín-ní. Nǹkan bi 20,000,000 awọn ọmọ ogun ati ara ilu ni wọn padanu iwalaaye wọn, ti o pọ gidigidi rekọja ogun iṣaaju eyikeyii lọ.
4 Ogun Agbaye I samisi ibẹrẹ awọn ọjọ ikẹhin. Jesu sọ pe eyi ati awọn iṣẹlẹ miiran yoo jẹ “ipilẹṣẹ ipọnju.” (Matteu 24:8) Iyẹn jasi otitọ, niwọn bi Ogun Agbaye II ti tun buru jai ju bẹẹ lọ, nǹkan bi 50,000,000 awọn ọmọ ogun ati ara ilu ni wọn padanu iwalaaye wọn. Ninu ọrundun 20 yii, eyi ti o fi pupọpupọ ju 100,000,000 eniyan lọ ni a ti pa ninu awọn ogun, eyi ti o ju ilọpo mẹrin ti apapọ 400 ọdun ti o ti kọja lọ! Iru ibẹnu àtẹ́ lu iṣakoso eniyan lọna giga wo ni eyi jẹ!
Awọn Ẹri Miiran
5-7. Ki ni diẹ lara awọn ẹri miiran pe a wà ni awọn ọjọ ikẹhin?
5 Jesu fi awọn apa pataki miiran ti yoo bá awọn ọjọ ikẹhin rin pọ kun un pe: “Isẹlẹ nla yoo si wà kaakiri, ati iyan ati ajakalẹ aarun [ibẹsilẹ aarun].” (Luku 21:11) Iyẹn bá awọn iṣẹlẹ lati 1914 mu rẹgi, niwọn bi idaamu lati inu iru awọn jamba wọnni ti bisii lọna ti o gọntiọ.
6 Awọn isẹlẹ nlanla ń ṣẹlẹ leralera, ti o ń gba ọpọlọpọ iwalaaye. Aarun gágá nikanṣoṣo pa nǹkan bii 20,000,000 eniyan kete lẹhin Ogun Agbaye I—awọn idiwọn kan jẹ 30,000,000 tabi ju bẹẹ lọ. AIDS ti gba ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun iwalaaye o sì lè gba araadọta ọkẹ sii lọjọ iwaju ti kò jinna. Lọdọọdun araadọta awọn eniyan ni wọn ń ku lọwọ okunrun ọkan, aarun jẹjẹrẹ, ati awọn aarun miiran. Araadọta ọkẹ sii ń ku iku wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ti ebi. Laisi iyemeji ‘awọn ẹlẹṣin ti Apokalipsi’ pẹlu awọn ogun, ọ̀wọ́n ounjẹ, ati ibẹsilẹ aarun wọn ń ge iye ti o ga pupọ lara idile eniyan lulẹ lati ọdun 1914.—Ìfihàn 6:3-8.
7 Jesu tun sọ tẹlẹ nipa ibisi ninu iwa ọdaran ti a ń niriri rẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ pẹlu. O wi pe: “Ati nitori ẹ̀ṣẹ̀ yoo di pupọ, ifẹ ọpọlọpọ yoo di tutu.”—Matteu 24:12.
8. Bawo ni asọtẹlẹ ti o wà ni 2 Timoteu ori 3 ṣe ba akoko wa mu?
8 Siwaju sii, asọtẹlẹ Bibeli sọ nipa iwolulẹ iwarere ti o han kedere tobẹẹ jakejado ayé lonii pe: “Ni ikẹhin ọjọ igba ewu yoo de. Nitori awọn eniyan yoo jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnu, agberaga, asọ̀rọ̀ buburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ, alainifẹ, alaile-dariji-ni, abanijẹ́, alaile-ko-ra-wọn-nijaanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere, onikupani, alagidi, ọlọkan giga, olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ. Awọn ti wọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun ṣugbọn ti wọn sẹ agbara rẹ̀ . . . awọn eniyan buburu, ati awọn ẹlẹtan yoo maa gbilẹ siwaju si i.” (2 Timoteu 3:1-13) Gbogbo iwọnyẹn ti jasi otitọ ni iṣoju wa gan an.
Koko-Ipilẹ Miiran
9. Ki ni ṣẹlẹ ni ọrun ti o ṣe kongẹ pẹlu ibẹrẹ awọn ọjọ ikẹhin lori ilẹ̀-ayé?
9 Koko-ipilẹ miiran tun wà ni idi ibisi giga ninu ijiya ni ọrundun yii. Ni ṣiṣe kongẹ pẹlu ibẹrẹ awọn ọjọ ikẹhin ni 1914, ohun kan ṣẹlẹ ti o tubọ ko araye sinu ewu titobiju. Ni ìgbà naa, gẹgẹ bi asọtẹlẹ kan ninu iwe ti o kẹhin Bibeli ti ṣalaye: “Ogun si ń bẹ ni ọrun: Maikẹli [Kristi ninu agbara ti ọrun] ati awọn angẹli rẹ̀ bá dragoni [Satani] naa jagun; dragoni si jagun ati awọn angẹli rẹ̀ [awọn ẹmi eṣu]. Wọn kò si lè ṣẹgun; bẹẹni a kò si ri ipo wọn mọ́ ni ọrun. A si le dragoni nla naa jade, ejò laelae nì, ti a ń pe ni Eṣu ati Satani, ti ń tan gbogbo ayé jẹ, a si le e jù si ilẹ̀-ayé, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.”—Ìfihàn 12:7-9.
10, 11. Bawo ni a ṣe nipa lori iran eniyan nigba ti a le Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ sori ilẹ̀-ayé?
10 Ki ni awọn abajade rẹ̀ fun idile eniyan? Asọtẹlẹ naa ń baa lọ pe: “Egbe ni fun aye ati fun okun! Nitori Eṣu sọkalẹ tọ̀ yin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgbà kukuru ṣá ni oun ni.” Bẹẹni, Satani mọ pe eto-igbekalẹ rẹ̀ ti ń sunmọ opin rẹ̀, nitori naa oun ń ṣe gbogbo ohun ti o lè ṣe lati yi awọn eniyan lodisi Ọlọrun ṣaaju ki oun ati ayé rẹ̀ to di eyi ti a mu kuro loju ọna. (Ìfihàn 12:12; 20:1-3) Ẹ wo bi awọn ẹda ẹmi wọnyẹn ti dibajẹ to nitori pe wọn ṣi ominira ifẹ-inu tiwọn lò! Ẹ wo bi awọn ipo nǹkan ti buru lekenka to lori ilẹ̀-ayé labẹ agbara-idari wọn, paapaa lati ọdun 1914!
11 Kò yanilẹnu pe Jesu sọ tẹlẹ nipa akoko wa pe: “Lori ilẹ̀-ayé idaamu fun awọn orilẹ-ede nitori ìpáyà . . . Àyà awọn eniyan yoo maa já fun ibẹru, ati fun ireti awọn nǹkan wọnni ti ń bọ sori ayé.”—Luku 21:25, 26.
Opin Akoso Eniyan ati ti Ẹmi Eṣu Sunmọle
12. Ki ni ọkan lara awọn asọtẹlẹ ti o ṣẹku lati ni imuṣẹ ṣaaju opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi?
12 Awọn asọtẹlẹ Bibeli meloo ni o ṣẹku lati ni imuṣẹ ki Ọlọrun to pa eto-igbekalẹ isinsinyi run? O mọ niwọnba gidi gan an! Ọkan lara awọn ti o ṣẹku wà ninu 1 Tẹsalonika 5:3, ti o ṣalaye pe: “Bi wọn ti ń sọrọ nipa alaafia ati ailewu lọwọ, lojiji jàm̀bá kọja sori wọn.” (The New English Bible) Eyi fihan pe opin eto-igbekalẹ yii yoo bẹrẹ “bi wọn ti ń sọrọ.” Lai ri i tẹlẹ lati ọdọ aye, iparun yoo kọlu wọn nigba ti wọn kò ronu rẹ̀ rara, nigba ti afiyesi awọn eniyan wà lori alaafia ati ailewu wọn ti wọn ń ṣereti rẹ̀.
13, 14. Akoko ijangbọn wo ni Jesu sọtẹlẹ, bawo si ni yoo ṣe wá si ipari?
13 Akoko ń tan lọ fun aye yii labẹ agbara idari Satani. Laipẹ yoo de opin rẹ̀ ni akoko ijangbọn ti Jesu sọ pe: “Ipọnju nla yoo wà, iru eyi ti kò si lati ìgbà ibẹrẹ ọjọ iwa di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ ki yoo si si.”—Matteu 24:21.
14 Otente “ipọnju nla” naa yoo jẹ ogun Ọlọrun ni Armageddoni. Akoko yẹn ni wolii Danieli sọrọ nipa rẹ̀ nigba ti Ọlọrun yoo “fọ tuutu, yoo si pa gbogbo ijọba wọnyii run.” Eyi yoo tumọ si opin gbogbo awọn iṣakoso eniyan ti lọwọlọwọ yii ti wọn kò gbarale Ọlọrun. Nigba naa akoso Ijọba rẹ̀ atọrunwa yoo wa gba idari gbogbo àlámọ̀rí awọn eniyan lẹkun-un-rẹrẹ. Kò tun ni ṣẹlẹ mọ lae, ni Danieli sọ, pe ki a tun fi ọla aṣẹ iṣakoso fun “orilẹ-ede miiran.”—Daniel 2:44; Ìfihàn 16:14-16.
15. Ki ni yoo ṣẹlẹ si agbara-idari Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀?
15 Ni akoko naa gbogbo agbara-idari ti Satani ati ẹmi eṣu yoo dẹkun pẹlu. Awọn ẹda ẹmi ọlọ̀tẹ̀ wọnni ni a mu kuro loju ọna ti wọn kì yoo fi tun lè “tan awọn orilẹ-ede jẹ mọ́.” (Ìfihàn 12:9; 20:1-3) A ti dajọ iku fun wọn ti wọn si ń reti iparun. Iru itura wo ni yoo jẹ fun araye lati bọ kuro lọwọ agbara-idari asọnidibajẹ wọn!
Ta Ni Yoo Laaja? Ta Ni Kò Ni Laaja?
16-18. Ta ni yoo la opin eto-igbekalẹ yii ja, ta si ni ki yoo ṣe bẹẹ?
16 Nigba ti a bá mu idajọ Ọlọrun ṣẹ lodisi aye, ta ni yoo laaja? Ta ni kò ni laaja? Bibeli fihan pe awọn ti wọn ń fẹ akoso Ọlọrun ni a o daabobo wọn yoo si laaja. Awọn ti kò fẹ akoso Ọlọrun ni a ki yoo daabobo ṣugbọn a o pa wọn run papọ pẹlu ayé Satani.
17 Owe 2:21, 22 sọ pe: “Ẹni iduroṣinṣin [awọn ti wọn tẹriba fun akoso Ọlọrun] ni yoo joko ni ilẹ naa, awọn ti o pé yoo si maa wà ninu rẹ̀. Ṣugbọn awọn eniyan buburu [awọn ti kò tẹriba fun akoso Ọlọrun] ni a o ke kuro ni ilẹ̀-ayé, awọn olurekọja ni a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.”
18 Orin Dafidi 37:10, 11 sọ bakan naa pe: “Nigba diẹ awọn eniyan buburu ki yoo si . . . Ṣugbọn awọn ọlọkan tutu ni yoo jogun ayé wọn o si maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia.” Sm 37 Ẹsẹ 29 fikun un pe: “Olododo ni yoo jogun ayé yoo si maa gbe inu rẹ̀ laelae.”
19. Imọran wo ni awa gbọdọ fi sọkan?
19 Awa nilati fi imọran Orin Dafidi 37:34 sọkan, ti o wi pe: “Duro de Oluwa [“Jehofa,” NW], ki o si maa pa ọna rẹ̀ mọ, yoo si gbé ọ leke lati jogun ayé: nigba ti a bá ke awọn eniyan buburu kuro iwọ o ri i.” Sm 37 Ẹsẹ 37 ati 38 sọ pe: “Ma kiyesi ẹni pipe, ki o si maa wo ẹni diduro ṣinṣin; nitori alaafia ni opin ọkunrin naa. Ṣugbọn awọn alarekọja ni a o parun pọ; iran awọn eniyan buburu ni a o ke kuro.”
20. Eeṣe ti a fi lè sọ pe iwọnyi jẹ awọn akoko amunilaraya gágá lati maa gbe?
20 Bawo ni o ti ń tuni-ninu to, bẹẹni, bawo ni o ti ń runi soke to lati mọ̀ pe Ọlọrun bikita nitootọ ati pe laipẹ oun yoo mu opin deba gbogbo iwa buburu ati ijiya! Bawo ni o ti munilaraya gágá to lati wa mọ̀ pe imuṣẹ awọn asọtẹlẹ ologo wọnni ku kiki akoko kukuru sii!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Bibeli sọ asọtẹlẹ awọn iṣẹlẹ ti yoo parapọ di “ami” awọn ọjọ ikẹhin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Laipẹ, ni Armageddoni, awọn ti kò tẹriba fun isakoso Ọlọrun ni a o parun. Awọn ti wọn tẹriba yoo laaja sinu aye titun ododo kan