ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/08 ojú ìwé 4-7
  • Ìgbà Wo Làwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Làwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Àmì Náà?
  • Ìgbà Wo Ni “Àkókò Òpin” Máa Bẹ̀rẹ̀?
  • Ìgbà Wo Ni “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Máa Dópin?
  • Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Bi A Ṣe Mọ̀ Pe A Wà ni “Ìkẹhin Ọjọ”
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ṣé Òpin Ayé Ti Sún Mọ́lé?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kí Ni “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 4/08 ojú ìwé 4-7

Ìgbà Wo Làwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn?

KÒ TÍÌ pẹ́ rárá tí ìwé ìròyìn Sky & Telescope gbé àpilẹ̀kọ kan jáde níbi tó ti sọ pé: “Ní bílíọ̀nù ọdún ó lé díẹ̀ sígbà tá a wà yìí, a retí pé kí ilẹ̀ ayé gbiná, kí gbogbo ohun alààyè tó wà nínú ẹ̀ kú tán, káyé sì di aṣálẹ̀ gbígbẹ táútáú. Báwọn ẹ̀dá abẹ̀mí ṣe máa là á já ò tiẹ̀ yé wa.” Kí ló dé tí irú nǹkan báyìí fi máa ṣẹlẹ̀? Ìwé ìròyìn Astronomy sọ pé: “Ńṣe ni Oòrùn tó ń mú ganrín-ganrín á mú kí omi òkun hó yaya, tá á sì yan ayé yìí gbẹ bíi gbúgbúrú.” Ó fi kún un pé: “Ìṣẹ̀lẹ̀ amúni-kún-fún-ẹ̀rù yìí kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ tá a fi ń dẹ́rù bani, kádàrá tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ ni.”

Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “[Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Kò sí àníàní pé Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé mọ ohun tó lè ṣe tí ayé á fi máa wà títí lọ. Kódà, ńṣe ló “ṣẹ̀dá rẹ̀ . . . kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Àmọ́ kò dá a nítorí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ẹ̀dá. Ọlọ́run ti ṣètò láti gba agbára ìṣàkóso padà nípasẹ̀ Ìjọba tí Dáníẹ́lì sọ nípa rẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 2:44.

Jésù wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó sọ nípa àkókò kan tí Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè àtàwọn èèyàn. Ó ṣèkìlọ̀ nípa ìpọ́njú ńlá kan tí irú ẹ̀ ò tíì wáyé rí. Ó sì sọ àwọn àmì alápá púpọ̀ tó máa fi hàn pé àkókò òpin ti sún mọ́lé.—Mátíù 9:35; Máàkù 13:19; Lúùkù 21:7-11; Jòhánù 12:31.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èèyàn pàtàkì bíi Jésù ló sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń ṣe kàyéfì nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Ìgbà wo làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé? Àwọn kan ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, wọ́n sì ti wá mọ ìgbà tó ṣeé ṣe kí àkókò òpin yẹn wáyé. Ẹnì kan tó ṣèwádìí ọ̀rọ̀ yìí ni Alàgbà Isaac Newton, tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ ìṣirò, tó sì gbáyé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́rin sẹ́yìn. Òun ló ṣàwárí agbára òòfà, òun ló sì bẹ̀rẹ̀ ìṣirò tí wọ́n ń pè ní calculus.

Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 1:7) Nígbà tó sì ń sọ “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan” fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:3, 36) Lẹ́yìn tó sì ti fi bí Jèhófà ṣe pa àwọn èèyàn búburú run láyé Nóà wé ìparun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà “wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn,” ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—Mátíù 24:39, 42.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ àkókò pàtó tí “ètò àwọn nǹkan” yìí máa kásẹ̀ ńlẹ̀, “àmì” tí Jésù sọ pé a máa rí jẹ́ ká mọ̀ pé àsìkò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1) Ó yẹ ká “wà lójúfò” ní àkókò yẹn ká “lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.”—Lúùkù 21:36.

Kí Jésù tó sọ àmì tí wọ́n máa rí gan-an, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra kí a má bàa ṣì yín lọ́nà; nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá ní orúkọ mi, wí pé, ‘Èmi ni ẹni náà,’ àti pé, ‘Àkókò yíyẹ ti sún mọ́lé.’ Ẹ má ṣe tẹ̀ lé wọn. Síwájú sí i, nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun àti rúgúdù, kí ẹ má ṣe jáyà. Nítorí nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì yóò wáyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Lúùkù 21:8, 9.

Kí Ni Àmì Náà?

Jésù ń bá a lọ láti sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà, ó ní: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn; àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.” (Lúùkù 21:10, 11) Jésù tún sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Àwọn nǹkan tí Jésù mẹ́nu kàn bí ogun, àwọn ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ kì í ṣe nǹkan tuntun. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ti ń ṣẹlẹ̀ látayébáyé. Ìyàtọ̀ tó máa wà níbẹ̀ ni pé gbogbo wọn máa ṣẹlẹ̀ sọ́wọ́ kan náà.

Wá bi ara rẹ pé, ‘Ìgbà wo ni gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere ṣẹlẹ̀ sọ́wọ́ kan náà?’ Láti ọdún 1914 làwọn ogun tó ń gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń jà káàkiri ayé; àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ńláńlá ti fa jàǹbá tí ń pani lẹ́kún, irú bí alagbalúgbú omíyalé tí wọ́n ń pè ní sùnámì; àwọn àrùn bí ibà, àrùn gágá àti àrùn éèdì tí ń pa tọmọdé tàgbà túbọ̀ ń tàn kálẹ̀; ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lebi sì ti pa kú. Aráyé ń gbé nínú ìbẹ̀rù nítorí àwọn aṣebi tó ń páni láyà àtàwọn ohun èlò ogun runlé-rùnnà; bẹ́ẹ̀ sì ni ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé kò gbẹ́yìn. Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gan-an lọ̀rọ̀ náà rí.

Ẹ má sì tún gbàgbé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tímótì 3:1-5) Bẹ́ẹ̀ ni o, “àwọn àkókò lílekoko” tó kún fún ìwà àìlófin, àìní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn, ìwà òkú òǹrorò àti fífi ẹ̀hónú gbéra ẹni lékè á gbilẹ̀ kárí ayé.a

Àmọ́, ṣó ṣeé ṣe kí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tó máa ṣáájú àkókò òpin ṣì wà níwájú? Ṣáwọn ẹ̀rí míì ṣì wà tó fi ìgbà táwọn ọjọ́ wọ̀nyí máa bẹ̀rẹ̀ hàn?

Ìgbà Wo Ni “Àkókò Òpin” Máa Bẹ̀rẹ̀?

Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì ti rí ìran àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn àkókò rẹ̀, áńgẹ́lì tó fi hàn án sọ fún un pé: “Ní àkókò yẹn [“àkókò òpin” tí Dáníẹ́lì sọ nípa rẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 11:40], Máíkẹ́lì [Jésù Kristi] yóò dìde dúró, ọmọ aládé ńlá tí ó dúró nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ.” (Dáníẹ́lì 12:1) Kí ni Máíkẹ́lì máa ṣe?

Ìwé Ìṣípayá mẹ́nu bá àkókò tí Máíkẹ́lì máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso bí Ọba. Ó ní: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:7-9, 12.

Ìṣirò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ogun tó máa fọ ọ̀run mọ́ nípa lílé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run yìí máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láyé nítorí inú tó ń bí Èṣù, torí ó mọ̀ pé àkókò kúkúrú lòun ní láti fi ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Ìbínú rẹ̀ máa lékenkà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn títí dìgbà ogun Amágẹ́dọ́nì tí Kristi máa fẹnu ẹ̀ gbolẹ̀.—Ìṣípayá 16:14, 16; 19:11, 15; 20:1-3.

Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù ti sọ ohun tó máa tẹ̀yìn ogun tó máa wáyé lọ́run yìí yọ, ó ní: “Mo sì gbọ́ tí ohùn rara kan ní ọ̀run wí pé: ‘Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀, nítorí pé olùfisùn àwọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa!’” (Ìṣípayá 12:10) Ṣó yé ẹ pé ńṣe ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń polongo pé Ìjọba tí Kristi máa ṣàkóso ti fìdí múlẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba náà múlẹ̀ lọ́run látọdún 1914.b Àmọ́, bí Sáàmù 110:2 ṣe sọ, “láàárín àwọn ọ̀tá” ni Jésù á ti máa ṣàkóso títí tó fi máa tó àkókò tí Ìjọba náà máa nasẹ̀ dé orí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:10.

Ó dùn mọ́ni nínú pé áńgẹ́lì tó sọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ fún wòlíì Dáníẹ́lì tún sọ pé: “Ní ti ìwọ, Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà, títí di àkókò òpin. Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” (Dáníẹ́lì 12:4) Èyí náà tún jẹ́ ẹ̀rí pé “àkókò òpin” la wà yìí. Ohun táwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí kò tún ṣàjèjì sí wa mọ́, kódà à ń wàásù rẹ̀ kárí ayé.c

Ìgbà Wo Ni “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Máa Dópin?

Bíbélì ò sọ bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣe máa gùn tó gan-an. Àmọ́, ó dájú pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ipò ayé á máa burú sí i bí àkókò tí Sátánì ní ṣe ń dín kù sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ta wá lólobó tẹ́lẹ̀ pé “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:13) Nígbà tí Jésù sì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ọjọ́ wọnnì yóò jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú irúfẹ́ èyí ti kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn, kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé Jèhófà ké àwọn ọjọ́ náà kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là. Ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́ tí ó ti yàn, ó ti ké àwọn ọjọ́ náà kúrú.”—Máàkù 13:19, 20.

Lára àwọn ohun tó ṣì ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ ni “ìpọ́njú ńlá,” tó fi mọ́ ogun Amágẹ́dọ́nì àti kíká Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lọ́wọ́ kò, kí wọ́n má bàa ta aráyé ní jàǹbá mọ́. (Mátíù 24:21) Ọlọ́run, “ẹni tí kò lè purọ́,” ti ṣèlérí pé àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ṣẹlẹ̀ dandan. (Títù 1:2) Ó sì máa dá sí ọ̀ràn náà nípa mímú kí ogun Amágẹ́dọ́nì jà àti nípa jíju Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.

Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kóun tó pa àwọn olubi run. Ní ti “àwọn ìgbà àti àwọn àsìkò” ó kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.” (1 Tẹsalóníkà 5:1-3) Bíbélì ò sọ ohun tó fà á tí wọ́n á fi máa tan àwọn èèyàn nípa pípariwo “àlàáfíà àti ààbò”; àmọ́ ìyẹn ò lè dá dídé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà dúró.d

Tó bá dá wa lójú pé òótọ́ làwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ti ń nímùúṣẹ, ó ti tó ká ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Lọ́nà wo? Pétérù dáhùn pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” (2 Pétérù 3:11, 12) Síbẹ̀, o ṣì lè máa ronú pé, ‘Kí ni mo wá fẹ́ rí gbà nídìí ṣíṣe ohun tí Bíbélì sọ yìí?’ Ìbéèrè tí àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn gan-an nìyẹn.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àwọn ẹ̀rí síwájú sí i nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wo Jí! April-June 2007, ojú ìwé 8 sí 10 àti Ilé Ìṣọ́ September 15, 2006 ojú ìwé 4 sí 7, ti October 1, 2005, ojú ìwé 4 sí 7. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí.

b Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìṣirò àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, wo ojú ìwé 215 sí 218 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

c Wo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! àti ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn 2008 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 31 sí 39. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

d Wo ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! (àtúntẹ̀ ti ọdún 2006), ojú ìwé 250 àti 251, ìpínrọ̀ 13 àti 14.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Jésù sọ pé Ọlọ́run nìkan ló mọ “ọjọ́ àti wákàtí” náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Alàgbà Isaac Newton

[Credit Line]

© A. H. C./age fotostock

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọdún 1914 làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ráwọn àmì tó sọ pé wọ́n máa rí

[Àwọn Credit Line]

© Fọ́tò Heidi Bradner/Panos

© Fọ́tò Paul Smith/Panos

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́