Kí Ni “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn”?
ǸJẸ́ o máa ń ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ọ àti sáwọn èèyàn rẹ lọ́jọ́ iwájú? Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ìròyìn orí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n, tọkàntọkàn ni wọ́n sì fi ń ka ìwé ìròyìn kí wọ́n lè mọ bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣe máa kan ìgbésí ayé wọn. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí là ń fi tọkàntọkàn kà, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ á yé wa dáadáa. Ìdí ni pé tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé òde òní, tó sì tún sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.
Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43) Nítorí náà, àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́ láti mọ ìgbà tí ìjọba tó dára gan-an yẹn máa dé. Kódà, ní ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa Jésù láìṣẹ̀ láìrò, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bi í pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ [ìyẹn ìgbà tó bá ń ṣàkóso] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Jésù dá wọn lóhùn pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló mọ àkókò náà gan-an tí Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé. (Mátíù 24:36; Máàkù 13:32) Àmọ́, Jésù àtàwọn mìíràn sọ àwọn ohun kan tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tó máa jẹ́ ẹ̀rí pé Kristi ti di ọba tó ń ṣàkóso.
Ká tó jíròrò àwọn ẹ̀rí tá a lè fojú rí tí yóò jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí la wà yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó wáyé lọ́run. (2 Tímótì 3:1) Lọ́dún 1914,a Jésù Kristi di Ọba lókè ọ̀run. (Daniel 7:13, 14) Kété lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ó gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì kan. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun.” (Ìṣípayá 12:7) Jésù Kristi ni wọ́n ń pè ní “Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì” nítorí ipò rẹ̀ lọ́run.b (Júúdà 9; 1 Tẹsalóníkà 4:16) Sátánì Èṣù sì ni dírágónì náà. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì burúkú tá a mọ̀ sí ẹ̀mí èṣù tí wọ́n ń tẹ̀ lé e nígbà tí wọ́n ja ogun náà? Jésù ṣẹ́gun wọn, ó sì ‘fi wọ́n sọ̀kò sísàlẹ̀,’ ìyẹn ni pé ó lé wọn kúrò lọ́run sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:9) Látàrí èyí, ‘ọ̀run àtàwọn tó ń gbé inú wọn,’ ìyẹn àwọn ọmọ Ọlọ́run [àwọn áńgẹ́lì] olóòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀. Àmọ́ ṣá, àwọn ẹ̀dá èèyàn ò lè yọ irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . , nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:12.
Sátánì tó kún fún ìbínú ńlá ti fa ègbé sórí ayé, ìyẹn ni pé ó ti mú ìnira àti ìyà bá àwọn tó ń gbé orí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ ègbé yẹn kò ní pẹ́ rárá, “sáà àkókò kúkúrú” ni yóò fi wà. Bíbélì pe àkókò yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ó yẹ kí inú wa dùn pé láìpẹ́, Èṣù ò ní lágbára kankan lórí ayé mọ́. Àmọ́, ẹ̀rí wo ló wà pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Bó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, ojú ìwé 218 àti 219. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
IWÁJÚ ÌWÉ: Fọ́tò iwájú: © Chris Stowers/Panos Pictures; fọ́tò ẹ̀yìn: FAROOQ NAEEM/AFP/Getty Images