ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/22 ojú ìwé 8-10
  • Ọ̀rẹ́ Wa Dídára Jù Lọ Wà ní Ilẹ̀ Ọba ẹ̀mí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rẹ́ Wa Dídára Jù Lọ Wà ní Ilẹ̀ Ọba ẹ̀mí
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ń Fẹ́ Kí A Jọ́sìn Àwọn
  • Ti Jèhófà ni Ìjọsìn
  • A Óò Mú Àwọn Ipá Búburú Kúrò
  • Ọjọ́ Iwájú Kan Láìsí Ibi
  • Àwọn Olùṣàkóso Ní Ilẹ̀-Àkóso Ẹ̀mí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Iṣọtẹ ni Ilẹ Akoso Ẹmi
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ibùgbé Àwọn Ẹni Ẹ̀mí?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Àwọn Ìran Tó Sọ Àwọn Tó Ń Gbé Ní Ọ̀run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/22 ojú ìwé 8-10

Ọ̀rẹ́ Wa Dídára Jù Lọ Wà ní Ilẹ̀ Ọba ẹ̀mí

BÍBÉLÌ ṣàpèjúwe àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí fún wa lọ́nà tí ó ṣe kedere. Jèhófà Ọlọ́run ni ẹni gíga jù lọ ní ọ̀run. Jésù Kristi ni ó ní agbára àti ọlá àṣẹ tẹ̀ lé Jèhófà. Àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ bí ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń ta ko Ọlọ́run, wọ́n sì ń ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Àwọn òkú ń sùn nínú ikú títí tí Ọlọ́run yóò fi jí wọn dìde sí ìyè.

Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ń Fẹ́ Kí A Jọ́sìn Àwọn

Níwọ̀n bí kò ti sí ẹ̀mí ìyè nínú àwọn òkú, kò sí ohun tí a lè jèrè nípa jíjọ́sìn wọn. Rírúbọ sí àwọn òkú wulẹ̀ ń ṣètìlẹ́yìn fún irọ́ Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù ni.

Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń fẹ́ kí a jọ́sìn àwọn bí? Kí a máà rí i! Àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́ ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti ṣe bákan náà. Lẹ́ẹ̀mejì, àpọ́sítélì Jòhánù gbìyànjú láti jọ́sìn àwọn áńgẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n bá a wí, ní sísọ pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! . . . Jọ́sìn Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 19:10; 22:8, 9.

Ní ìyàtọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń fẹ́ kí a jọ́sìn àwọn, kí a sì fi ògo fún àwọn. Èyí hàn gbangba nígbà tí Sátánì dẹ Jésù wò nígbà tí Jésù jẹ́ ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì ròyìn pé: “Èṣù tún mú [Jésù] lọ sí òkè ńlá kan tí ó ga lọ́nà kíkàmàmà, ó sì fi gbogbo àwọn ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀ tí o sì ṣe ìṣe ìjọsìn kan fún mi.’”—Mátíù 4:8, 9.

Jésù fèsì pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Satani! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ fún.’” (Mátíù 4:10) Jésù mọ Òfin Jèhófà, ó sì kọ̀ jálẹ̀ láti rú u.—Diutarónómì 6:13.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì kò lè mú kí Jésù jọ́sìn rẹ̀, ó ti ṣàṣeyọrí lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Dájúdájú, àwọn ènìyàn kéréje ní ń mọ̀ọ́mọ̀ jọ́sìn Sátánì. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nípa lílo ẹ̀tàn, èrú, irọ́, àti ẹ̀rù, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti yí ọ̀pọ̀ ènìyàn padà kúrò nínú ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù Kìíní 5:19) Sátánì ni àwọn tí ń jọ́sìn ní àwọn ọ̀nà tí ó lòdì sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bọlá fún, kì í ṣe Jèhófà. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, wọ́n fi ń rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù, kì í sì í ṣe sí Ọlọ́run.”—Kọ́ríńtì Kìíní 10:20.

Ti Jèhófà ni Ìjọsìn

Ọlọ́run nìkan ló yẹ kí a darí ìjọsìn wa sí. Jèhófà wí fún Mósè pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi. Ìwọ kò gbọdọ̀ ya ère fún ara rẹ, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ lókè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n: nítorí èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí.”—Ẹ́kísódù 20:3-5.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ ẹni tí ìtóbilọ́lá rẹ̀ pọ̀ gidigidi, ẹni tí ó ṣeé sún mọ́ ni. Ọmọlẹ́yìn Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, òun yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Àpọ́sítélì Jòhánù sì kọ̀wé pé: “Èyí . . . ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí [Jèhófà], pé, ohun yòó wù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa. Síwájú sí i, bí àwa bá mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòó wù tí a ń béèrè, àwá mọ̀ pé dájúdájú a óò rí àwọn ohun tí a béèrè gbà níwọ̀n bí a ti béèrè wọn lọ́wọ́ rẹ̀.”—Jòhánù Kìíní 5:14, 15.

Ṣàkíyèsí pé Jòhánù kọ̀wé pé Jèhófà yóò fún wa ní àwọn ohun tí a bá béèrè, bí a bá béèrè wọn “ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ̀.” Láti mọ ohun tí ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò láyọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì.

Bí o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Jèhófà, ìwọ yóò ní ìmọ̀ púpọ̀ sí i nípa àwọn tí ń gbé ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Ìmọ̀ yìí ń yọ wá nínú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, àwọn èrò ìgbàgbọ́, àti àṣà tí Sátánì ń lò láti fi àwọn ènìyàn sínú ìbẹ̀rù àti ìgbèkùn. Nípasẹ̀ ìmọ̀ pípé nípa Ọlọ́run, ìwọ yóò kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé e fún ìrànlọ́wọ́ láti yẹra tàbí láti borí gbogbo ìṣòro ìgbésí ayé rẹ. O lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run yóò sì jẹ́ bí “ààbò àti agbára, lọ́wọ́lọ́wọ́ ìrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú” fún ọ.—Orin Dáfídì 46:1.

A Óò Mú Àwọn Ipá Búburú Kúrò

Má ṣiyè méjì láé pé àwọn ẹ̀mí ipá rere yóò borí àwọn ẹ̀mí ipá ibi. Ní báyìí ná, ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí, a ti ja ogun kan tí ó ti gbá Sátánì àti àwọn olubi alájọṣepọ̀ rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. Ìwé Ìṣípayá sọ pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì [Jésù Kristi tí a jí dìde] àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà ja ìjà ogun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì ja ìjà ogun ṣùgbọ́n òun kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:7-9.

Kí ni àbájáde ogun yẹn? Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Nítìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òún ní.” (Ìṣípayá 12:12) Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀run lè máa yọ̀, níwọ̀n bí kò ti sí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ níbẹ̀ láti fa wàhálà mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, lílé tí a lé e kúrò ní ọ̀run ti mú ègbé púpọ̀, wàhálà ńlá, wá sórí àwọn tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. A ń gbé ní àkókò ègbé yẹn nísinsìnyí.—Tímótì Kejì 3:1-5.

Ọjọ́ Iwájú Kan Láìsí Ibi

Síbẹ̀, Bíbélì tún fún wa ní ìrètí. Ó mú un dá wa lójú pé Èṣù ní “sáà àkókò kúkúrú” kí a tó fòpin sí ìgbòkègbodò rẹ̀. Nígbà tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, Jèhófà yóò mú àwọn ìbùkún àgbàyanu wá sórí gbogbo àwọn tí ń wá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Gbé díẹ̀ lára àwọn ìlérí rẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la yẹ̀ wò:

“Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀, lórí àwọn òkè ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì bíi Lẹ́bánónì.”—Orin Dáfídì 72:16.

“Àwọn àyànfẹ́ mi yóò . . . jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kì yóò ṣiṣẹ́ lásán.”—Aísáyà 65:22, 23.

“Àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.”—Aísáyà 33:24.

“Nígbà náà ni ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití yóò sì ṣí. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n àwọn odi yóò kọrin.”—Aísáyà 35:5, 6.

“[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

“Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.”—Orin Dáfídì 37:29.

Jèhófà nìkan, tí í ṣe Ọlọ́run òtítọ́, ni ó lè mú irú àwọn ìlérí títóbi lọ́lá báyìí ṣẹ. Kò sí ohun tí yóò dá a dúró láti má ṣe mú ète rẹ̀ ṣẹ. “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Lúùkù 1:37.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Níwọ̀n bí o bá ti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́