‘Fún Ìwọ̀nba Ìgbà Díẹ̀ Ni!’—Ìgbésí Ayé Mi Pẹ̀lú Àrùn Kíndìnrín
Mo ṣì rántí ọjọ́ yẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ January 1980 bí àná. Ìyá mi rán mi lọ sí ilé ìtajà láti ra búrẹ́dì kan wá, ṣùgbọ́n bí mo ṣe fẹ́ máa lọ ni tẹlifóònù dún. Dókítà mi ló tẹ̀ wá láago láti sọ èsì àyẹ̀wò àrùn tí mo ṣe. Lójijì, Mọ́mì bú sẹ́kún. Ó ń lérí ẹkún bí ó ṣe ń tún ìròyìn burúkú náà sọ fún mi. Ìṣiṣẹ́ àwọn kíndìnrín mi kò péye. Ó ku ọdún kan, ó pọ̀ jù, ọdún méjì tí kíndìnrín mi yóò fi ṣiṣẹ́ mọ. Dókítà náà tọ̀nà—ọdún kan lẹ́yìn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìtọ́jú ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò.
WỌ́N bí mi ní May 20, 1961, mo jẹ́ àkọ́bí nínú àwa mẹ́fà. Nígbà tí mo dàgbà tó nǹkan bí ọmọ oṣù mẹ́fà, ìyá mi ṣàkíyèsí ẹ̀jẹ̀ nínú ìtọ̀ lára aṣọ ìtẹ́dìí mi. Lẹ́yìn àyẹ̀wò púpọ̀, wọ́n ṣàwárí pé ohun tí ń ṣe mí ni àkópọ̀ àmì àrùn Alport, àrùn àbímọ́ni ṣíṣọ̀wọ́n kan. Fún àwọn ìdí tí a kò mọ̀, kíndìnrín àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní àrùn náà kì í sábà ṣiṣẹ́ mọ́ lẹ́yìn àkókò díẹ̀. Wọn kò sọ èyí fún èmi àti àwọn òbí mi, nítorí náà, n kò dààmú nípa àrùn kíndìnrín.
Lẹ́yìn náà, ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1979, mo ṣàkíyèsí òórùn tí ó jọ bí omiró ammonia nínú èémí mi lówùúrọ̀. N kò fi bẹ́ẹ̀ fiyè sí i, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀ mí. Mo lérò pé ara mi kàn fà lásán ni, nítorí náà, n kò kà á sí. Ní December, mo lọ fún àyẹ̀wò ara tí mo máa ń ṣe lọ́dọọdún, nígbà tí ó sì di January ni wọ́n tẹ̀ mí láago tí mo mẹ́nu kàn lókè.
Bí mo ti ń wakọ̀ lọ sí ilé ìtajà náà—ó ṣe tán, ìyá mi ṣì nílò búrẹ́dì náà—ẹ̀rù ń bà mí. N kò lè gbà gbọ́ pé èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi. Mo ń sunkún pé: “Ọmọ ọdún 18 péré ni mí!” Mo yà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, mo sì dúró. Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí bí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ṣe le tó lára mi.
“Ó Ṣe Wá Jẹ́ Èmi?”
Bí mo ṣe jókòó síbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Pẹ̀lú omijé tí ń dà lójú mi, mo kígbe sókè pé: “Ìwọ Ọlọ́run, ó ṣe wá jẹ́ èmi? Ó ṣe wá jẹ́ èmi? Jọ̀wọ́ máà jẹ́ kí kíndìnrín mi dáwọ́ iṣẹ́ dúró!”
Bí àwọn oṣù inú ọdún 1980 ṣe ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn púpọ̀; àwọn àdúrà mi sì wá ń le sí i, tomijé-tomijé. Ní òpin ọdún náà, mo máa ń dá kú, mo sì máa ń bì léreléra nítorí àwọn ìdọ̀tí olóró májèlé tí ń di púpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí àwọn kíndìnrín mi tí iṣẹ́ rẹ̀ kò péye mọ́ kò sẹ́ dà nù. Ní November, mo bá àwọn ọ̀rẹ́ kan lọ sí ìrìn àjò ìpàgọ́ kan tí ó kẹ́yìn. Ṣùgbọ́n ara mi kò yá, débi pé, mo kàn jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ náà ni, tí mo sì ń gbọ̀n. Ara mi kò lè móoru, kọ̀ọ̀ ni gbogbo ohun tí mo ṣe já sí. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní January 1981, ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ náà ṣẹlẹ̀—kíndìnrín mi dáwọ́ iṣẹ́ dúró pátápátá. Ó di ọ̀ràn kí n bẹ̀rẹ̀ sí í gbàtọ́jú ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò tàbí kí n kú.
Ìgbésí Ayé Ní Lílo Ìlànà Ìfọ̀dọ̀tí Inú Ẹ̀jẹ̀ Kúrò
Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú, dókítà ìdílé wa ti sọ fún mi nípa irú ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò tuntun kan tí kò nílò abẹ́rẹ́, tí ó sì ń fọ ẹ̀jẹ̀ nínú ara. Ìlànà náà ni a mọ̀ sí peritoneal dialysis [ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò láti ara awọ àbònú fẹ́lẹ́fẹ́fẹ́] (PD). Èyí wù mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, níwọ̀n bí mo ti kórìíra abẹ́rẹ́ gan-an. Ìlànà yìí ti di àfirọ́pò tí ó lè ṣiṣẹ́ fún àwọn kan tí ń gbàtọ́jú ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò.
Lọ́nà yíyani lẹ́nu, ara wá ní awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan tí ó lè ṣiṣẹ́ bíi kíndìnrín àtọwọ́dá. Peritoneum—awọ àbònú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí ń fòdì kejì hàn, tí ó ṣe múlọ́múlọ́, tí ó dà bí àpò kan yíká àwọn ẹ̀ya ara tí ń mú oúnjẹ dà—ni a lè lò gẹ́gẹ́ bí asẹ́ láti fọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò. Apá inú awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ní àlàfo kan tí a ń pè ní àlàfo awọ àbònú. Awọ àbònú dà bí àpò kan tí a kò fẹ́ atẹ́gùn sí, tí a kì bọ àárín àwọn ẹ̀yà ikùn.
Bí ìlànà PD ṣe ń ṣiṣẹ́ nìyí: A óò lo ìhùmọ̀ catheter (túùbù) tí a fi sí àbònú nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ láti fi fa àkànṣe omi ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò sínú àlàfo awọ àbònú náà. Omi náà ní dextrose, àti nípasẹ̀ ìlànà ìgbékiri ohun ayòrò, àwọn èròjà àti omi tí a kò nílò mọ́ ni a fà kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gba inú awọ àbònú náà lọ sínú omi ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò, tí ó wà nínú àlàfo awọ àbònú náà. Àwọn èròjà tí a kò nílò mọ́ náà tí ó yẹ kí a tọ̀ dà nù ti wá wà nínú àkànṣe omi ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò náà báyìí. A gbọ́dọ̀ pààrọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́rin lójúmọ́—kí a da omi tí a ti lò náà nù, kí a sì da omi tuntun sínú àlàfo náà. Ó ń gba nǹkan bí ìṣẹ́jú 45 láti pààrọ̀ rẹ̀. Ó jọra pẹ̀lú pípààrọ̀ ọ́ìlì mọ́tò—da ti tẹ́lẹ̀ nù, kí o sì da tuntun sí i, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn sí i, kí ara rẹ sì lè ṣiṣẹ́ geerege!
Ní ìbẹ̀rẹ̀ January 1981, wọ́n gbé ìhùmọ̀ catheter tí mo nílò gan-an sí apá ọ̀tún ìsàlẹ̀ ikùn mi. Lẹ́yìn náà, mo gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlànà ìṣe ìtọ́jú náà fún ọ̀sẹ̀ méjì. Bí ènìyàn kò bá ṣe é bí ó ti yẹ, ní lílo ìlànà dídènà àkóràn kínníkínní, ó lè ní àrùn ìwúlé awọ àbònú—àkóràn líle koko kan nínú awọ àbònú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ náà, tí ó sì lè pani.
Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1981, nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ ìlànà PD, àwọn òbí mi gba ìpè tẹlifóònù míràn tí yóò ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé mi.
Wíwá Kíndìnrín Tuntun Kiri
Láti January 1981, mo ti wà nínú àkọsílẹ̀ orílẹ̀-èdè fún àwọn tí wọ́n fẹ́ẹ́ pààrọ̀ kíndìnrín.a Mo nírètí pé bí mo bá pààrọ̀ kíndìnrín, ìgbésí ayé mi yóò padà sí bí ó ṣe rí tẹ́lẹ̀. N kò mọ ohun tí ń bọ̀ lọ́nà!
Ìtẹniláago kan ní ìdajì oṣù August fi tó wa létí pé a ti rí olùfitọrẹ kan. Nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn, ní nǹkan bí agogo 10 alẹ́, wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ mi fún àyẹ̀wò láti rí i dájú pé ti ẹni náà yóò bá mi lára mu. Ìdílé ọ̀dọ́kùnrin kan, tí ó kú nínú ìjàm̀bá kan lówùúrọ̀ ọjọ́ yẹn, ló mú kíndìnrín náà wá.
A ṣètò ṣíṣe iṣẹ́ abẹ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Ṣáájú kí wọ́n tó lè ṣe iṣẹ́ abẹ náà, a ní láti jíròrò kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì kan, níwọ̀n bí mo ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ẹ̀rí ọkàn mi tí a fi Bíbélì kọ́ kì yóò sì jẹ́ kí n gba ẹ̀jẹ̀ sára. (Ìṣe 15:28, 29) Ní alẹ́ àkọ́kọ́ yẹn ni onímọ̀ ìṣègùn apàmọ̀lára wá rí mi. Ó rọ̀ mí láti gba pé kí ẹ̀jẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó nínú iyàrá iṣẹ́ abẹ, pé àíbàámọ̀. Mo sọ pé rárá.
Ó béèrè pé: “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe bí nǹkan bá yíwọ́? Ṣé kí n jẹ́ kí o kú ni?”
“Ṣe ohunkóhun yòó wù tí ó bá lè ṣe, ṣùgbọ́n ohun yòó wù kí ó ṣẹlẹ̀, má ṣe fún mi ní ẹ̀jẹ̀.”
Lẹ́yìn tí ó lọ, àwọn oníṣẹ́ abẹ wọlé wá. Mo jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kan náà pẹ̀lú wọn, ará sì tù mí gan-an pé wọ́n gbà láti ṣiṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.
Iṣẹ́ abẹ oníwákàtí mẹ́ta ààbọ̀ náà lọ geerege. Oníṣẹ́ abẹ náà sọ pé ìwọ̀nba ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ni mo pàdánù. Nígbà tí mo jí nínú iyàrá ìkọ́fẹpadà, mo kọ́kọ́ nímọ̀lára ohun mẹ́ta—àkọ́kọ́, ebi àti òǹgbẹ àti lẹ́yìn náà, ìrora! Ṣùgbọ́n gbogbo ìyẹn kò já mọ́ nǹkan kan mọ́ nígbà tí mo rí àpò kan ní ilẹ̀, tí omi aláwọ̀ ìyeyè rẹ́súrẹ́sú wà nínú rẹ̀. Ìtọ̀ láti inú kíndìnrín mi tuntun ni. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, mo lè tọ̀! Nígbà tí wọ́n gbé ìhùmọ̀ catheter náà kúrò nínú àpòòtọ̀ mi, tí mo sì lè tọ̀ bí ti ẹnikẹ́ni mìíràn, inú mi dùn gan-an.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ayọ̀ mi jẹ́ fún ìgbà kúkúrú. Ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, mo gbọ́ ìròyìn amúnisoríkọ́—kíndìnrín mi tuntun kò ṣiṣẹ́. N óò ní láti bẹ̀rẹ̀ ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò pẹ̀lú ìrètí pé yóò fún kíndìnrín tuntun náà ní àkókò láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Mo ń bá ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò lọ fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan.
Ó ti di àárín September báyìí, ó sì ti tó oṣù kan tí mo ti wà ní ilé ìwòsàn. Láti ilé ìwòsàn náà sí ilé mi jẹ́ 80 kìlómítà, nítorí náà, ó ṣòro fún àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi láti bẹ̀ mí wò. Aáyun ìjọ mi yun mí gan-an. Mo rí àwọn kásẹ́ẹ̀tì àwọn ohùn tí wọ́n gba sílẹ̀ ní àwọn ìpàdé ìjọ gbà, ṣùgbọ́n nígbà tí mo tẹ́tí sí wọn, ọ̀fun mi fún pọ̀. Mo lo ọ̀pọ̀ wákàtí lémi nìkan ní bíbá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, mo béèrè fún okun láti máa forí tì í lọ lọ́wọ́ rẹ̀. N kò mọ̀ nígbà náà, ṣùgbọ́n àwọn àdánwò tí ó túbọ̀ le koko ń bọ̀ lọ́nà.
N Kò Bẹ̀rù Àtikú
Ó ti pé ọ̀sẹ̀ mẹ́fà gbáko tí wọ́n ti pààrọ̀ kíndìnrín náà, ní báyìí, ìrora sì ti fi hàn kedere pé ara mi ti kọ kíndìnrín náà. Ikùn mi wú sódì lọ́nà tí ó bani lẹ́rù; àwọn dókítà wí fún mi pé àwọ́n ní láti gbé kíndìnrín tí ara kọ̀ náà jáde. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ tún dìde. Àwọn dókítà ṣàlàyé pé lọ́tẹ̀ yìí, iṣẹ́ abẹ náà túbọ̀ ṣòro pàápàá, nítorí pé ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi kéré gan-an. Mo fi sùúrù ṣàlàyé ìdúró mi tí a gbé karí Bíbélì, láìyẹhùn, wọ́n sì gbà níkẹyìn láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà láìlo ẹ̀jẹ̀.b
Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, nǹkan ń yára burú sí i. Nígbà tí mo wà ní iyàrá ìkọ́fẹpadà, omi bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ sínú àwọn ẹ̀dọ̀fóró mi. Lẹ́yìn lílo ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò kíkankíkan fún gbogbo òru ọjọ́ kan, ara tù mí díẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀dọ̀fóró mi tún ti kún padà. Mo tún lo alẹ́ mìíràn ní lílo ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò. N kò rántí ohun púpọ̀ nípa alẹ́ ọjọ́ yẹn, ṣùgbọ́n mo rántí pé bàbá mi wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, tí ó ń wí pé: “Lee, tún mí lẹ́ẹ̀kan sí í! Ó yá. O lè ṣe é! Tún mí lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìyẹn dára, máa mí!” Ó rẹ̀ mí gan-an, ó rẹ̀ mí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Mo wulẹ̀ fẹ́ kí ó parí, kí n sì jí dìde nínú ayé tuntun Ọlọ́run. N kò bẹ̀rù àtikú.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ipò tí mo wà ti burú jáì. Ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi, ti lọ sílẹ̀ sí 7.3—èyí tí ó bá wà déédéé ń ju 40 lọ! Àwọn dókítà sọ̀rètí nù nítorí ipò tí mo wà. Wọ́n gbìyànjú léraléra láti mú mi gba ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sọ pé ó ṣe pàtàkì fún ìkọ́fẹpadà mi.
Wọ́n gbé mi lọ sí ẹ̀ka ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀, nígbà náà ni ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi lọ sílẹ̀ sí 6.9. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìyá mi, ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i. Ó fi ẹ̀rọ ìlọǹkan lọ àwọn oúnjẹ tí ó ní èròjà iron púpọ̀ nínú láti ṣe ohun mímu ní ilé, ó sì gbé wọn wá fún mi. Ó tilẹ̀ bá mi mu nínú rẹ̀, láti fún mi níṣìírí láti mu ún. Ohun àgbàyanu ni ìfẹ́ tí ìyá kan ní fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ ní ilé ìwòsàn ní àárín November, ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi jẹ́ 11. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1987, mo bẹ̀rẹ̀ lílo ìlànà ìtọ́jú EPO (erythropoietin), omi ìsúnniṣe láti inú àkànpọ̀ èròjà oríṣiríṣi tí ń fún mùdùnmúdùn egungun lókun láti gbé àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ lọ sínú iṣan ẹ̀jẹ̀, ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi sì ti tó nǹkan bí 33 báyìí.c
‘Lee, fún Ìwọ̀nba Ìgbà Díẹ̀ Ni!’
Mo ṣe àwọn lájorí iṣẹ́ abẹ mìíràn ní ọdún 1984, 1988, 1990, 1993, 1995, àti 1996—gbogbo rẹ̀ jẹ́ nítorí kíndìnrín mi tí kò ṣiṣẹ́ mọ́. Láàárín ọ̀pọ̀ ọdún tí mo fi ní àrùn kíndìnrín yìí, èrò pé, ‘Fún ìwọ̀nba ìgbà díẹ̀ ni’ ti ṣèrànwọ́ láti mú mi dúró. Ohun yòó wù kí ìṣòro wa jẹ́, èyí tí ó ṣeé fojú rí tàbí tí kò ṣeé fojú rí, a óò ṣàtúnṣe wọn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nínú ayé tuntun tí ń bọ̀. (Mátíù 6:9, 10) Nígbàkigbà tí mo bá dojú kọ ìpèníjà tuntun kan, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sorí kọ́, n óò kàn wí fún ara mi pé, ‘Lee, fún ìwọ̀nba ìgbà díẹ̀ ni!’ ó sì ń ràn mí lọ́wọ́ láti padà ní ojú ìwòye títọ́ nípa àwọn nǹkan.—Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 4:17, 18.
Ní ọdún 1986 ni ìyàlẹ́nu títóbi jù lọ ṣẹlẹ̀ sí mi—mo ṣègbéyàwó. Mo ti ronú pé n kò ní ṣègbéyàwó láé. Mo ti ṣe kàyéfì pé: ‘Ta ni yóò fẹ́ láti fẹ́ mi láé?’ Ṣùgbọ́n Kimberly yọjú. Ó rí irú ọkùnrin tí mo jẹ́ nínú, kì í ṣe èyí tí ń ṣòfò dà nù ní òde. Ó tún rí i pẹ̀lú pé, ipò tí mo wà jẹ́ fún ìwọ̀nba ìgbà díẹ̀.
Ní June 21, 1986, èmi àti Kimberly ṣègbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò wa ní Pleasanton, California. A ti pinnu láti má ṣe bímọ kankan, níwọ̀n bí àrùn mi ti jẹ́ èyí tí òbí ń tàtaré sí ọmọ. Ṣùgbọ́n bóyá èyí pẹ̀lú jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ni. Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a óò fẹ́ láti bímọ bí ìyẹn bá jẹ́ ìfẹ́ inú Jèhófà.
Lónìí, mo ní àǹfààní sísìn gẹ́gẹ́ alàgbà nínú Ìjọ Highland Oaks ní California, àti pé Kimberly ń sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún. Ní báyìí, ìlera mi ń sàn sí i; ìrírí adánniwò tí ó ṣẹlẹ̀ ní 1981 náà ṣèpalára búburú fún mi, ó sì jẹ́ kí n ní okun inú tí kò tó nǹkan. Láti ìgbà náà, àbúrò mi obìnrin ti ní irú àkópọ̀ àmì àrùn Alport tí kò le púpọ̀, méjì lára àwọn àbúrò mi ọkùnrin, tí wọ́n ní àrùn náà, sì ń jìyà lọ́wọ́ àìṣiṣẹ́ mọ́ kíndìnrín, wọ́n sì ń gba ìtọ́jú ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò. Ara àwọn àbúrò mi ọkùnrin méjì tó kù le gan-an.
Mo ṣì ń lo ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò láti ara awọ àbònú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, mo sì dúpẹ́ pé ó ń jẹ́ kí n lè máa rìn kiri. Mo ń wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìrètí àti ìgbẹ́kẹ̀lé nítorí pé, gbogbo ẹ, gbògbò ẹ̀, àwọn ìṣòro ọjọ́ òní—títí kan àrùn kíndìnrín—jẹ́ fún ìwọ̀nba ìgbà díẹ̀.—Gẹ́gẹ́ bí Lee Cordaway ṣe sọ ọ́.
Jí! kò dámọ̀ràn irú ìlànà ìtọ́jú kan pàtó. A kò kọ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí láti ṣàìfún irú àwọn ọ̀nà ìtọ́jú mìíràn, bíi ìlànà hemodialysis (fífa ẹ̀jẹ̀ jáde lára láti fọ ìdọ̀tí inú rẹ̀, kí a sì dá a padà sínú iṣan), níṣìírí. Ìlànà kọ̀ọ̀kan ló ní àǹfààní àti àléébù tirẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan sì gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu àdáṣe tirẹ̀ tí ó mú ẹ̀rí ọkàn lọ́wọ́ nípa irú ìlànà tí yóò lò.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí Kristẹni kan yóò bá fara mọ́ pípààrọ̀ kíndìnrín tàbí bí kò bá ní fara mọ́ ọn jẹ́ ìpinnu àdáṣe.—Wo Ile-Iṣọ Naa, September 15, 1980, ojú ìwé 31.
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ṣíṣe lájorí iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, wo ìwé pẹlẹbẹ How Can Blood Save Your Life?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, ojú ìwé 16 àti 17.
c Bóyá Kristẹni kan yóò fara mọ́ ìlànà ìtọ́jú EPO tàbí kò ní fara mọ́ ọn jẹ́ ìpinnu àdáṣe.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 1, 1994, ojú ìwé 31.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìṣiṣẹ́ ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò láti ara awọ àbònú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́
Ẹ̀dọ̀
Ìṣẹ́jọ ìfun kékeré
Ìhùmọ̀ catheter (ó ń gba omiyòrò mímọ́ tónítóní; ó ń tú omiyòrò ti tẹ́lẹ̀ dà nù)
Awọ àbònú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́
Àlàfo awọ àbònú
Àpò ìtọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Pẹ̀lú aya mi, Kimberly