Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Àrùn Kíndìnrín Àpilẹ̀kọ náà “‘Fún Ìwọ̀nba Ìgbà Díẹ̀ Ni!’—Ìgbésí Ayé Mi Pẹ̀lú Àrùn Kíndìnrín” (November 22, 1996) mú èmi àti ọkọ mi lọ́kàn le ní àkókò lílekoko kan nínú ìgbésí ayé wa. Bíi ti ẹni tí ó kọ àpilẹ̀kọ náà, ọkọ mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbàtọ́jú lílo ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò láti ara awọ àbònú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì ṣòro. Nígbà míràn, a máa ń sọ̀rètí nù gan-an. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ yín jẹ́ ìtùnú ńlá, ó ń rán wa létí pé àìṣiṣẹ́ dáradára kíndìnrín wulẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ni, pé Ìjọba Ọlọ́run yóò mú un kúrò láìpẹ́, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn àìsàn míràn.
V. Q., Ítálì
Kíkà nípa ọkùnrin kan tí kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn ìdílé tàbí ìjọsìn rẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń bá àrùn kan tí kò níwòsàn jìjàkadì, mú mi sunkún. Ajíhìnrere alákòókò kíkún, ọmọ ọdún 18 tí ara rẹ̀ yá gágá ni mí, mo sì mọ bí mo ti máa ń fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìlera mi tó lọ́pọ̀ ìgbà. Kíkà nípa ìgbàgbọ́ àti ìṣarasíhùwà Lee Cordaway ń fúnni níṣìírí gan-an.
J. S., United States
Ní 1992, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún 11, mo mọ̀ pé mo ní àrùn kíndìnrín, tí ó wá yọrí sí àìṣiṣẹ́mọ́ kíndìnrín níkẹyìn. Mo ní láti gba ìtọ́jú lílo ìlànà ìfọ̀dọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀. Inú mi dùn pé ẹ ṣàlàyé ìlànà náà dáradára gan-an nítorí pé àwọn ènìyàn sábà máa ń ṣe kàyéfì nípa bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́. Bí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi ti kà pé ipò tí mo dojú kọ lónìí náà kò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo mú wa lọ́kàn le.
A. H., United States
Láti ìgbà tí mo ti ka àpilẹ̀kọ tó sọ nípa Lee Cordaway ni àánú ti ń ṣe mí. Ó yà mí lẹ́nu pé ó kú! Èmi àti ọkọ mi dàníyàn láti fi ìkíni onífẹ̀ẹ́ wa ránṣẹ́ sí aya rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ ọ̀wọ́n. Ìrírí rẹ̀ mú mi rí i pé àwọn ìṣòro tèmi kò tó nǹkan. Ẹ wo irú ọkùnrin Kristẹni olùṣòtítọ́ ọ̀wọ́n tí ó jẹ́! Àpẹẹrẹ rẹ̀ fún mi níṣìírí.
F. H., United States
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́wàá péré tí kò sì ní àrùn kankan ni mí, mo ń gbádùn àwọn àpilẹ̀kọ tí ń fúnni níṣìírí bẹ́ẹ̀ yẹn. Mo dàníyàn pé kí Lee Cordaway lè ka lẹ́tà yì, àmọ́ mo mọ̀ pé kò ní lè kà á àyàfi nígbà àjíǹde rẹ̀ nínú Párádísè.
E. T., United States
Àwọn Alárìnkiri Mo fẹ́ láti sọ bí mo ṣe mọrírì àpilẹ̀kọ yín náà, “Àwọn Alárìnkiri àti Ìlàkàkà Wọn Láti Dòmìnira” (November 22, 1996), tó. N kò kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn nípa àwọn Alárìnkiri lákọ̀ọ́dunjú ní ilé ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ gan-an nínú àwọn àpilẹ̀kọ yín!
S. B., United States
Orin Rọ́ọ̀kì Àfidípò Ọmọ ọdún 18 ni mí, ẹ kọ àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Orin Rọ́ọ̀kì Àfidípò—Ó Ha Wà fún Mi Bí?” dáradára. (November 22, 1996) Mo fẹ́ràn orin rọ́ọ̀kì àfidípò, nítorí náà mo ronú pé àpilẹ̀kọ náà yóò gbéjà ko èrò mi. Àmọ́ nígbà tí mo kà á tán, mo wulẹ̀ ní ìmọrírì ni. Mo ń ní ìsoríkọ́, mo sì mọ̀ pé irú orin tí mo yàn lè mú kí ìsoríkọ́ mi le sí i tàbí kí ó ràn mí lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀. Mo fẹ́ràn ọ̀nà tí àpilẹ̀kọ náà gbà béèrè pé, ‘O kò ṣe wá orin tí ń dá ọ lára yá?’ Ẹ ṣeun fún ìṣírí àti ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ yìí.
J. D., United States
Lọ́nà tí ó ṣòro láti gbà gbọ́, ìsọfúnni náà tọ̀nà, kò sì ní ẹ̀tanú. Mo ríi pé díẹ̀ lára àwọn orin wọ̀nyí ń fani mọ́ra. Ẹ ṣeun tí ẹ kìlọ̀ fúnni láìdẹ́bi fún gbogbo ìṣọ̀wọ́ orin náà.
S. C., United States
Ìtàn Ẹranko Mo fẹ́ràn láti máa ka àwọn àpilẹ̀kọ tí ẹ ń tẹ̀ jáde nípa àwọn ẹranko. Nítorí pé n kò tí ì gbọ́ nípa ẹranko platypus rí, àpilẹ̀kọ náà “Platypus Àràmàǹdà” (December 8, 1996) mú mi ṣe kàyéfì! Nínú ìtẹ̀jáde kan náà, àpilẹ̀kọ náà “Ẹranko Kudu Yìí Rántí” tí ó sọ nípa ìbádọ́rẹ̀ẹ́ fífani-lọ́kànmọ́ra tí ó wà láàárín ẹranko kan àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú wọ̀ mí lọ́kàn. Ẹ wo bí ó ti dára tó nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ẹranko!
F. A., Brazil