Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Carnival Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Ojú-Ìwòye Bíbélì: Ayẹyẹ Carnival—Ó Tọ́ Tàbí Kò Tọ́?” (June 8, 1996) Mo ń gbé ní Brazil, carnival sì máa ń jẹ́ àkókò amóríyá kan níbí. Mo sábà máa ń ní ìdẹwò dídara pọ̀ nínú ayẹyẹ náà. Mo mọ̀ pé kò tọ́, àmọ́ n kò lóye ìdí náà gan-an. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ yìí fi hàn kedere pé carnival ní àríyá aláriwo nínú, àti pé Ọlọ́run ń wo irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “awọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn.”—Róòmù 13:12.
F. M. M., Brazil
Ìsinmi Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ọ̀wọ́ náà, “Ṣé Ìsinmi Lò Ń Lọ?—Ohun Tó Yẹ Kí O Mọ̀.” (June 22, 1996) Ó bọ́ sákòókò gẹ́lẹ́ nítorí pé ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, a lọ sí ìsinmi. Àwọn kókó náà ṣàǹfààní púpọ̀. Ẹ ṣeun lẹ́ẹ̀kan sí i.
L. J., United States
Àrùn Lyme Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Àrùn Lyme—O Ha Wà Nínú Ewu Bí?” (June 22, 1996) Gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn kan, mo ti pàdé àwọn olùgbàtọ́jú mélòó kan tí wọ́n ní àrùn yí ní lọ́ọ́lọ́ọ́, mo sì lè fìdí àwọn ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ tí ẹ mẹ́nu bà múlẹ̀. Nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ, a kì í fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn olùgbàtọ́jú, wọ́n sì ń ní àìsàn náà fún ìgbà pípẹ́. Jí! jíròrò nípa oríṣi tí ó ní oríkèé ríro, tí ó wọ́pọ̀ ní United States. Ní Europe, a ti ṣàwárí oríṣi ohun méjì míràn tí ń fa àrùn náà, tí àwọn àyẹ̀wò lọ́nà àṣà kò lè wá rí. Àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn wúlò fún àrùn Lyme nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nìkan, wọn kì í sì í gbéṣẹ́ mọ́ lẹ́yìn náà.
I. S., Germany
Nítorí pé mo ní àrùn Lyme, mo rí i pé àpilẹ̀kọ yìí fúnni níṣìírí gidigidi. Mo rò pé gbogbo ẹni tí ó kà á yóò ronú gidigidi lórí àrùn yí, wọn yóò sì lo gbogbo ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ tí ó bá pọn dandan.
D. P., United States
Ìṣòro Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Mo mọrírì àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Kẹ́kọ̀ọ́?” (June 22, 1996) gidigidi. Mo ń tiraka nílé ẹ̀kọ́ nítorí àwọn kan lára àwọn ìdí tí ẹ mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ náà. N óò lo àwọn ìdámọ̀ràn yín. Ẹ ṣeun púpọ̀púpọ̀.
R. C., United States
Mo ti ń pàdánù ọkàn ìfẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, n kì í sì í pọkàn pọ̀ nílé ẹ̀kọ́. Nípa lílo àwọn ìdámọ̀ràn tí ẹ fúnni nínú àpilẹ̀kọ náà, mo nírètí pé n óò mú àwọn àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ mi sunwọ̀n sí i.
M. E. O., Uganda
N kò ní ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ kankan, àmọ́ n kò wulẹ̀ fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ni. Ó tún máa ń ṣòro fún mi láti rántí àwọn òfin ìṣírò pẹ̀lú. Tóò, àpilẹ̀kọ yìí mẹ́nu ba àpètúnpè àti jíjẹ ọ̀rọ̀ lẹ́nu gẹ́gẹ́ bí ìrànwọ́ kan fún àwọn ìṣòro ìrántí onígbà kúkúrú. Mo kọ́kọ́ rò pé ó jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti máa kàwé sókè ketekete fún ara mi gbọ́, àmọ́ nígbà tí mo ṣe é, ó jẹ́ ohun amóríyá!
N. I., Japan
Ìgárá Arúfin Ẹ ṣeun fún títẹ̀ tí ẹ tẹ ìrírí Franck Mannino jáde, tí ó ní àkọlé náà, “Ìgárá Arúfin Ni Mí Tẹ́lẹ̀.” (June 22, 1996) Ó wọ̀ mí lọ́kàn, ó sì mú kí n mọ bí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, Jèhófà, ti jẹ́ alágbára tó. Mo ti ń ṣiṣẹ́ sìn ín fún 30 ọdún, ìrírí yìí sì ti fún mi níṣìírí láti ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù náà nígbà tí mo ṣì ní òmìnira láti ṣe bẹ́ẹ̀.
E. B., Ítálì
Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì àǹfààní lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Àìní ètò ara ẹni ti mú kí n sọ pípẹ́ lẹ́yìn dé ìpàdé di àṣà. Franck Mannino kò ní òmìnira púpọ̀ lẹ́wọ̀n, ṣùgbọ́n ìgbésí ayé rẹ̀ so èso gidigidi.
D. W., United States
Ìtara tí Franck Mannino fi hàn, kódà, nígbà tó wà ní àhámọ́ lẹ́wọ̀n, ru mí lọ́kàn sókè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lọ́nà búburú, ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere títayọ nísinsìnyí.
C. R., United States