ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/22 ojú ìwé 14-16
  • Àrùn Lyme—O Ha Wà Nínú Ewu Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àrùn Lyme—O Ha Wà Nínú Ewu Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Eégbọn, Ìgalà, àti Ìwọ
  • Àmì Àrùn àti Àwọn Ìṣòro Rẹ̀
  • Ìtọ́jú àti Ìdènà
  • Kí Ló Dé Tí Wọ́n Tún Fi Ń Padà Wá?
    Jí!—2003
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 3)
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń gbé Kiri Ìṣòro Tí Ń Gbilẹ̀
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/22 ojú ìwé 14-16

Àrùn Lyme—O Ha Wà Nínú Ewu Bí?

BÍ ÀRÙN AIDS ti ń lókìkí sí i, agbára káká ni a fi ń sọ nípa àrùn Lyme. Síbẹ̀, àrùn Lyme ń yára tàn káàkiri. Ní ti gidi, ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìwé ìròyin The New York Times Magazine pè é ní “àrùn àkóràn tí ń yára tàn káàkiri jù lọ lẹ́yìn àrùn AIDS ní [United States].” Ìròyìn láti àwọn ilẹ̀ míràn fi hàn pé àrùn náà ń tàn káàkiri ní Éṣíà, Europe, àti Gúúsù America pẹ̀lú.

Kí ni àrùn Lyme jẹ́? Báwo ló ṣe ń tàn káàkiri? Ìwọ́ ha wà nínú ewu bí?

Eégbọn, Ìgalà, àti Ìwọ

Ní nǹkan bí 20 ọdún sẹ́yìn, ìṣẹ̀lẹ̀ oríkèé ríro láàárín ìlú Lyme, Connecticut, àti àyíká rẹ̀, tí ó wà ní àríwá ìlà oòrùn United States pọ̀ sí i lọ́nà bíbani lẹ́rù. Àwọn ọmọdé ló sábà máa ń ṣe jù lọ. Oríkèé ríro wọn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èésú, ẹ̀fọ́rí, àti oríkèé sísánni. Olùgbé ibẹ̀ kan sọ pé kò pẹ́ tí “ọkọ òun àti méjì lára àwọn ọmọ òún bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ọ̀pá ìkẹ́sẹ̀.” Láìpẹ́ láìjìnnà, ó ti ran ènìyàn tí ó lé ní 50 ní agbègbè yẹn, láàárín ọdún díẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún sì ń jìyà irú àwọn àmì àrùn aronilára kan náà.

Nígbà tí àwọn olùṣèwádìí mọ̀ pé àìsàn yìí yàtọ̀ sí àwọn àìsàn míràn, wọ́n sọ ọ́ ní àrùn Lyme. Kí ló ń fà á? Borrelia burgdorferi—bakitéríà lílọ́ kan tí ń gbé inú eégbọn ni. Báwo ni ó ṣe ń tàn káàkiri? Ẹnì kan tí ń rìn lọ nínú igbó lè fara kó eégbọn tí ó ní àrùn náà lára. Eégbọn náà yóò ti ẹnu bọ ara ẹni náà, yóò sì tú bakitéríà tí ń fa àrùn náà sára ẹni tí kò rìnnà kore tí ń rìn kiri náà. Níwọ̀n bí àwọn eégbọn tí wọ́n ti kó àrùn yìí ti sábà máa ń yọ́fà ìgbékiri, oúnjẹ, tí wọ́n sì máa ń gùn lára ìgalà, tí ó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fara mọ́ àwọn agbègbè ìgbèríko níbi tí ìgalà ti ń gbá yùn-ùn, kò yani lẹ́nu pé ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn Lyme ti ń pọ̀ sí i.

Àmì Àrùn àti Àwọn Ìṣòro Rẹ̀

Àkọ́kọ́ nínú àmì àrùn Lyme sábà máa ń jẹ́ èésú ara (tí a mọ̀ sí erythema migrans, tàbí EM) tí ó máa ń bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpá kékeré pupa. Láàárín ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀, àpá tí a ń rí náà yóò fẹ̀ di èésú roboto, onígun mẹ́ta, tàbí gorodo tí ó lè tóbi tó owó wẹ́wẹ́ tàbí kí ó bo gbogbo ẹ̀yìn. Ibà, ẹ̀fọ́rí, ọrùn gígan, ara ríro, àti àárẹ̀ sábà máa ń bá èésú náà rìn. Bí a kò bá tọ́jú rẹ̀ lásìkò, ohun tí ó lé ní ìdajì àwọn tí ó kọ lù máa ń jìyà oríkèé sísánni, tí ó sì wúlé, tí ó lè pẹ́ tó oṣù púpọ̀. Ó máa ń jálẹ̀ sí bárakú àrùn oríkèé ríro fún ohun tí ó tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn aláìsàn tí a fi sílẹ̀ láìtọ́jú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀, àrùn náà tún lè ṣe nǹkan fún ètò ìgbékalẹ̀ ọpọlọ, kí ó sì fa àrùn ọkàn-àyà.—Wo àpótí tí ó wà níhìn-ín.

Ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi ka àrùn Lyme sí èyí tí ó ṣòro láti wá rí nítorí pé àwọn àmì tí ó kọ́kọ́ máa ń gbé yọ, tí ó jọ ti òtútù jọra pẹ̀lú àwọn àkóràn míràn. Ní àfikún, 1 nínú ẹni 4 tí ó ń ràn kì í ní èésú—tí àrùn Lyme nìkan máa ń fà—ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn kò sì lè rántí bí eégbọn bá jẹ wọ́n nítorí pé bí ó bá jẹni, kì í dunni.

A tún ń ṣèdíwọ́ fún dídá àrùn náà mọ̀ nítorí pé àwọn àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ fún èròjà agbóguntàrùn, tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kò láyọ̀lé. Àwọn èròjà agbóguntàrùn tí ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ aláìsàn ń fi hàn pé ìgbékalẹ̀ agbára ìdènà àrùn ara rẹ̀ ti ṣàwárí àwọn agbóguntini, àmọ́ àwọn àyẹ̀wò kan kò lè sọ bí bakitéríà àwọn agbóguntini náà bá jẹ́ àrùn Lyme. Nítorí náà, àyẹ̀wò lè fi hàn pé aláìsàn kan ní àrùn Lyme, nígbà tí ó sì jẹ́ pé, ní tòótọ́, àwọn àmì tí ó ń rí wá láti inú àkóràn àwọn bakitéríà míràn. Àjọ Ìlera Orílẹ̀-Èdè ní United States (NIH) wá tipa bẹ́ẹ̀ gba àwọn oníṣègùn níyànjú láti gbé àwárí àrùn tí wọ́n ń ṣe karí bóyá ẹni náà rántí pé eégbọn jẹ òun, àwọn àmì tí aláìsàn ń rí, àti yíyọ àwọn àrùn míràn tí ó lè ti tanná ran àwọn àmì àrùn wọ̀nyẹn sọ́tọ̀ gedegbe.

Ìtọ́jú àti Ìdènà

Bí a bá tètè ṣàwárí rẹ̀, a lè fi oògùn agbógunti kòkòrò àrùn tọ́jú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aláìsàn pẹ̀lú ìyọrísí rere. Bí ìtọ́jú náà bá ṣe tètè bẹ̀rẹ̀ sí ni ìkọ́fẹpadà yóò fi yá, tí yóò sì tètè tán. Fún oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn ìtọ́jú, àárẹ̀ àti ẹ̀fọ́rí ṣì lè wà, àmọ́ àwọn àmì yìí yóò dín kù láìsí pé a tún nílò fífi oògùn agbógunti kòkòrò àrùn ṣètọ́jú mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àjọ NIH kìlọ̀ pé, “ìkọlù àrùn Lyme kì í ṣe ẹ̀rí ìdánilójú pé àìsàn náà kò tún ní ṣeni lọ́jọ́ iwájú.”

Ìfojúsọ́nà agbénilọ́kànsókè yẹn yóò ha yí padà láé bí? Ìtẹ̀jáde ìròyìn kan láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn ti Yunifásítì Yale ní United States kéde pé àwọn olùṣèwádìí ti ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára àṣedánrawò kan tí ó lè dènà àrùn Lyme. Abẹ́rẹ́ àjẹsára “aṣiṣẹ́-méjì-pọ̀” yìí máa ń sún ìgbékalẹ̀ agbára ìdènà àrùn ènìyàn ṣiṣẹ́ láti ṣe àgbéjáde àwọn agbóguntàrùn tí ń ṣèkọlù, tí wọ́n sì ń pa bakitéríà àrùn Lyme tí ń gbógun. Lákòókò kan náà, ó tún ń pa bakitéríà inú ara eégbọn tí ó bá jẹ aláìsàn tí a ti fún lábẹ́rẹ́ àjẹsára.

Dókítà Stephen E. Malawista, ọ̀kan lára àwọn olùṣèwádìí tí wọ́n ṣàwárí àrùn Lyme ní 1975, sọ pé: “Dídán abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí wò jẹ́ lájorí ìdàgbàsókè kan nínú ìsapá wa láti dáàbò bo àwọn ènìyàn kúrò lọ́wọ́ ìyọrísí ibi tí àrùn Lyme lè fà lọ́jọ́ iwájú.” Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lérò pé ní àwọn agbègbè tí ìbẹ̀rù àrùn náà ti dá àwọn ènìyàn jókòó sílé, “abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn ènìyàn tún máa ṣàmúlò ẹgàn lẹ́ẹ̀kan sí i.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ní báyìí, o lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ ìdènà àrùn fúnra rẹ. Àjọ NIH dámọ̀ràn pé: Bí o bá ń kọjá ní àwọn agbègbè tí ó kún fún eégbọn, rìn ní àárín ọ̀nà. Wọ ṣòkòtò gígùn, ṣẹ́ẹ̀tì alápá gígùn, kí o sì dé fìlà. Ki ẹsẹ̀ ṣòkòtò rẹ bọ inú ìbọ̀sẹ̀, kí o sì wọ bàtà aláwọ̀tán. Wíwọ aṣọ títàn mú kí ó túbọ̀ rọrùn láti rí eégbọn. Oògùn alékòkòrò-dànù tí a fi sí aṣọ àti ara ń ṣiṣẹ́ dáadáa, àmọ́ wọ́n lè fa àbájáde búburú ní pàtàkì fún àwọn ọmọdé. Àjọ NIH kìlọ̀ pé: “Ní pàtàkì, àwọn aláboyún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti yẹra fún eégbọn ní àwọn agbègbè tí àrùn Lyme bá wà, nítorí a lè tàtaré èèràn náà sí ọmọ tí a kò tí ì bí,” ó sì lè sọ ìṣeéṣe ìṣẹ́nú tàbí àbíkú di púpọ̀.

Gbàrà tí o bá ti wọlé, wò ó bí eégbọn bá wà lára ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, ní pàtàkì ní àwọn ibi tí irún wà lára. Fara balẹ̀ ṣe èyí, nítorí pé àwọn kògbókògbó eégbọn kéré gan-an bí àmì ìdánudúró tí ó kẹ́yìn gbólóhùn yìí, ó sì rọrùn láti ṣèèṣì fi wọ́n pe ìdọ̀tí. Bí o bá ní ohun ọ̀sìn, yẹ ara wọn wò kí wọ́n tó wọnú ilé—àwọn pẹ̀lú lè kó àrùn Lyme.

Báwo ni ìwọ yóò ṣe já eégbọn náà? Kì í ṣe pẹ̀lú ọwọ́ lásán àmọ́ lo ẹ̀mú tí ẹnu rẹ̀ kú. Rọra fà á, àmọ́ dì í mú mọ́ ibi orí eégbọn náà dáadáa títí yóò fi ju awọ ara náà sílẹ̀, àmọ́ má ṣe tẹ ara rẹ̀. Lẹ́yìn náà, fi oògùn apakòkòrò nu ojú ibi tí ó bù jẹ. Dókítà Gary Wormser, ara America tí ó jẹ́ ògbóǹtagí onímọ̀ nípa àrùn àkóràn, sọ pé jíjá eégbọn náà láàárín wákàtí 24 lè gbà ọ́ lọ́wọ́ àkóràn àrùn Lyme.

A gbà pé kódà ní àwọn agbègbè tí eégbọn kún jabíjabí, ìṣeéṣe láti ní àrùn Lyme asọnidaláàárẹ̀ kò tó nǹkan. Síbẹ̀, lílo àwọn ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ rírọrùn wọ̀nyẹn yóò mú kí ìṣeéṣe tí kò tó nǹkan yẹn túbọ̀ kéré sí i. Ṣé gbogbo wàhálà yìí tóyeyẹ fún ààbò bí? Béèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó bá ní àrùn Lyme.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

Àwọn Àmì Àrùn Lyme

Èèràn Tó Kọ́kọ́ Máa Ń Yọjú:

○ Èésú

○ Iṣan àti oríkèé sísánni

○ Ẹ̀fọ́rí

○ Ọrùn gígan

○ Àárẹ̀ púpọ̀

○ Ibà

○ Iwájú rírọ

○ Àrun lọ́rùnlọ́rùn

○ Oríkèé sísánni, tí ó sì wú fún ìgbà díẹ̀

Èyí tí kò wọ́pọ̀:

○ Ojú wíwú

○ Òòyì

○ Àìlèmíkanlẹ̀

Èèràn Tó Máa Ń Yọjú Gbẹ̀yìn:

○ Oríkèé ríro, tí ń wá tí ń lọ tàbí tí ó ti di bárakú

Èyí tí kò wọ́pọ̀:

○ Ìpàdánù agbára ìrántí

○ Ìṣòro ìpọkànpọ̀

○ Ìyípadà ìmọ̀lára tàbí àṣà oorun sísùn

Ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn àmì wọ̀nyí lè yọjú ní àkókò yíyàtọ̀ síra nígbà tí ó bá ti ranni.—Lyme Disease—The Facts, the Challenge, tí Àjọ Ìlera Orílẹ̀-Èdè ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Rírìn ká inú igbó lè fi ọ́ sínú ewu

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Eégbọn (tí a mú tóbi gan-an)

[Credit Line]

Yale School of Medicine

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Eégbọn (títóbi rẹ̀ gẹ́lẹ́)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́