ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/8 ojú ìwé 14-15
  • Ayẹyẹ Carnival Ó Tọ́ Tàbí Kò Tọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayẹyẹ Carnival Ó Tọ́ Tàbí Kò Tọ́?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣefàájì Tàbí Àríyá Aláriwo?
  • Ṣíṣàgbéyọ Àríyá Aláriwo
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Àwọn Tó “Ní Ìtẹ̀sí-ọkàn Títọ́” Ń kọbi Ara Sí Ìwàásù Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Gbogbo Ayẹyẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìpèníjà Ìsìn Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
    Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/8 ojú ìwé 14-15

Ojú Ìwòye Bibeli

Ayẹyẹ Carnival Ó Tọ́ Tàbí Kò Tọ́?

MICHAEL sọ pé: “O kò wulẹ̀ lè jára rẹ gbà mọ́ ọn lọ́wọ́ ni. Orin náà yóò gbé ọ dìde níbi tí o jókòó sí, yóò fa ẹsẹ̀ rẹ sí ijó, yóò kó sí ọ lórí—ayọ̀ carnival ṣubú tẹ̀ ọ́ nìyẹn!” Ní ti gidi, lọ́dọọdún, carnival ń mú orí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn yá gágá, ṣùgbọ́n kò sí ibi tí ìmóríyá náà ti ga tó ti ibi tí Michael ń gbé, Brazil. Láàárín ọ̀sẹ̀ tí ó ṣáájú Ash Wednesday, àwọn ará Brazil á rú sáṣọ ọdún pípinmirin, wọn á gbàgbé gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò ojúmọ́, wọn á sì bẹ̀rẹ̀ àṣehàn aláyẹyẹ tí ń dabarú ìrísí orílẹ̀-èdè náà láti ibi igbó Amazon títí dé etíkun Rio de Janeiro. Ó jẹ́ àkókò láti kọrin, láti jó sáḿbà, àti láti gbàgbéra.

Michael, tí ó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún jẹ́ olùfarajìn fún ayẹyẹ carnival, sọ pé: “Ìdí kan nìyẹn tí ó fi lókìkí bẹ́ẹ̀. Carnival ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti gbàgbé ipò ìnira wọn.” Ní pàtàkì, fún àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tálákà—àwọn tí ń gbé láìní omi tí ó tó, láìní iná mànàmáná, láìníṣẹ́ lọ́wọ́, àti láìnírètí—púpọ̀ wà láti gbàgbé. Fún wọn, carnival dà bí egbòogi apàrora: ó lè má wo ìṣòro náà sàn, ṣùgbọ́n, ó kéré pin, ó ń sọ ìrora náà di aláìlágbára. Fi ojú ìwòye tí àwọn àwùjọ àlùfáà Roman Kátólíìkì kan ní nípa carnival kún un—bíṣọ́ọ̀bù kan sọ pé carnival “wúlò gan-an fún ìṣedéédéé ìrònú òun ìhùwà àwọn ènìyàn.” Nítorí náà, ó rọrùn láti rí ìdí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi rò pé carnival jẹ́ ohun ìnàjú wíwúlò tí ṣọ́ọ̀ṣì fọwọ́ sí. Síbẹ̀, kí ni ojú ìwòye Bibeli nípa ayẹyẹ carnival?

Ìṣefàájì Tàbí Àríyá Aláriwo?

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé “ìgbà láti rẹ́rìn-ín . . . àti ìgbà láti fò káàkiri” wà. (Oniwasu 3:4, NW) Níwọ̀n bí a tún ti lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “rẹ́rìn-ín” sí “ṣayẹyẹ,” ó ṣe kedere pé ní ti Ẹlẹ́dàá wa, kò sí ohun kan tí ó ṣàìtọ́ fún wa láti ní àkókò ìgbafàájì tí ń gbéni ró. (Wo 1 Samueli 18:6, 7.) Ní ti gidi, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ fún wa pé ki a máa yọ̀, kí a sì máa dunnú. (Oniwasu 3:22; 9:7) Nítorí náà, Bibeli fọwọ́ sí ìṣefàájì yíyẹ.

Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli kò fara mọ́ gbogbo onírúurú ìṣefàájì. Aposteli Paulu sọ pé àríyá aláriwo, tàbí ìṣefàájì aláriwo, jẹ́ ti “awọn iṣẹ́ ti ẹran-ara,” àti pé àwọn tí wọ́n bá ń fi àríyá aláriwo ṣèwàhù “kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (Galatia 5:19-21) Nítorí náà, Paulu ṣí àwọn Kristian létí láti “máa rìn lọ́nà bíbójúmu, kì í ṣe ninu awọn àríyá aláriwo.” (Romu 13:13) Nítorí náà, ìbéèrè náà ni pé, Abẹ́ ìsọ̀rí wo ni carnival wà—ìṣefàájì bíbófin mu tàbí àríyá aláriwo aláìbófin mu? Láti dáhùn, ẹ kọ́kọ́ jẹ́ kí a ṣàlàyé síwájú nípa ohun tí Bibeli kà sí àríyá aláriwo.

Àpólà ọ̀rọ̀ náà, “àríyá aláriwo,” tàbí koʹmos lédè Gíríìkì, fara hàn nígbà mẹ́ta nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì, ó sábà máa ń jẹ́ ní èrò àìbáradé. (Romu 13:13; Galatia 5:21; 1 Peteru 4:3) Èyí kò sì yani lẹ́nu nítorí koʹmos wá láti inú àwọn ayẹyẹ olórúkọ burúkú tí àwọn Kristian ìjímìjí tí ń sọ èdè Gíríìkì mọ̀ dunjú. Àwọn wo ni?

Òpìtàn Will Durant ṣàlàyé pé: “Agbo àwọn ènìyàn kan tí ń gbé phalli mímọ́ [àmì ohun ọkùnrin] kiri, tí wọ́n sì ń kéwì [ṣèsàré] sí Dionysus . . . para pọ̀, nínú àkànlò èdè Gíríìkì, jẹ́ komos, tàbí àríyá ẹlẹ́hànnà kan.” Dionysus, ọlọ́run ẹmu nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ ilẹ̀ Gíríìkì, ni àwọn ará Romu tẹ́wọ́ gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tí wọ́n sì sọ ní Bacchus. Síbẹ̀, ìsopọ̀ tí ó ní pẹ̀lú koʹmos la ìyípadà orúkọ náà já. Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bibeli, Ọ̀mọ̀wé James Macknight, kọ̀wé pé: ‘Ọ̀rọ̀ náà, koʹmois, [ìlò ọ̀pọ̀ fún koʹmos] wá láti inú Comus, ọlọ́run àsè àti àríyá ẹlẹ́hànnà. Wọ́n ń ṣe àwọn àríyá ẹlẹ́hànnà yìí láti fi ṣe ìdálọ́lá fún Bacchus, tí wọ́n ń torí bẹ́ẹ̀ pè ní Comastes.’ Dájúdájú, àwọn ayẹyẹ fún Dionysus àti Bacchus jẹ́ ògidì ohun tí ń jẹ́ àríyá aláriwo. Kí ni àwọn àbùdá àsè wọ̀nyí?

Ṣíṣàgbéyọ Àríyá Aláriwo

Gẹ́gẹ́ bí Durant ti sọ, nígbà àwọn ayẹyẹ tí àwọn Gíríìkì fi ń bọlá fún Dionysus, àwùjọ àwọn olùṣayẹyẹ “máa ń mutí láìníjàánu, . . . wọ́n sì ka ẹni tí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ sí òmùgọ̀. Wọ́n máa ń tọ́wọ̀ọ́ rìn lọ́nà ẹlẹ́hànnà, . . . bí wọ́n sì ti ń mutí, tí wọ́n sì ń jó, ni wọ́n ń hùwà ìsínwín, nínú èyí tí wọ́n ń di aláìníjàánu pátápátá.” Macknight kọ̀wé pé, ní irú ọ̀nà kan náà, àwọn àjọ̀dún tí àwọn ará Romu fi ń bọlá fún Bacchus (tí wọ́n ń pè ní Bacchanalia) ṣàgbéyọ ọtí mímu àti àwọn orin oníwà pálapàla àti orin olóhun èlò orin, wọ́n sì jẹ́ ìran “ìwà atẹ́nilógo gidigidi.” Nípa báyìí, àwùjọ onítara ẹhànnà, ìmùtípara, tijótorin onífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́, àti ìwà pálapàla ìbálòpọ̀, para pọ̀ jẹ́ èròjà ìpìlẹ̀ àwọn àríyá aláriwo Gíríìkì òun Romu.

Àwọn carnival òde òní ha ní àwọn èròjà tí ń fa àríyá aláriwo wọ̀nyí nínú bí? Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àyọlò díẹ̀ láti inú ìròyìn nípa ayẹyẹ carnival báyìí: “Àwùjọ aláìsílétòlétò aláriwo giga jù.” “Ìgbòkègbodò ọlọ́jọ́ mẹ́rin ti ìmutípara àti ìṣàríyá ní gbogbo òru.” “Ràbọ̀ràbọ̀ carnival kì í tán lára àwọn alárìíyá aláriwo mélòó kan fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.” “Ariwo tí ń fẹ́rẹ̀ẹ́ dini létí tí ń wá láti ìtòsí sọ àwọn eré ẹgbẹ́ eléré ‘onílù kíkankíkan’ di . . . ọlọ́rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ létí, bí a bá fi wọ́n wéra.” “Lónìí, ayẹyẹ carnival tí kò bá ní àwọn abẹ́yà kan náà lò pọ̀ nínú dà bí ẹní sọ pé òún sebẹ̀ ata láìfata sí i.” “Carnival ti di ọ̀rọ̀ tí ó ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú wíwà níhòòhò goloto.” Àwọn ijó carnival máa ń ṣàgbéyọ “àwọn ìran ìdánìkan hùwà ìbálòpọ̀ . . . àti onírúurú ìṣe ìbálòpọ̀.”

Kò ṣeé sẹ́ pé ìjọra àárín àwọn carnival òde òní àti àwọn àsè ìgbàanì ṣe kedere débi pé, bí alárìíyá ẹhànnà Bacchus kan bá jí dìde báyìí, kò lè ṣi ẹsẹ̀ ijó gbé níbi àríyá carnival òde òní kan. Olóòtú ètò orí tẹlifíṣọ̀n ilẹ̀ Brazil kan, Cláudio Petraglia, sọ pé kò yẹ kí ìyẹ́n báni lẹ́jafùú, nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wí, canival òde òní “pilẹ̀ ṣẹ̀ láti inú àwọn àsè Dionysus àti Bacchus àti pé, láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ìyẹn ni àbùdá carnival.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé a lè so carnival pọ̀ mọ́ àjọyọ̀ Saturnalia ti àwọn kèfèrí ní Romu ìgbà láéláé. Nítorí náà, carnival, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ti sáà míràn, ṣì wà nínú ìdílé kan náà pẹ̀lú àwọn aṣáájú rẹ̀. Kí ni ìdílé náà ń jẹ́? Àríyá aláriwo.

Ipa wo ló yẹ kí ìmọ̀ yìí ní lórí àwọn Kristian lónìí? Ipa kan náà tí ó ní lórí àwọn Kristian ìjímìjí tí ń gbé àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ tí Gíríìkì nípa lé lórí ní Asia Kékeré. Kí wọ́n tó di Kristian, wọ́n ti máa ń lọ́wọ́ “ninu awọn ìṣe ìwà àìníjàánu, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àṣejù nídìí ọtí wáìnì, awọn àríyá aláriwo [koʹmois], ìfagagbága ọtí-mímu, ati awọn ìbọ̀rìṣà tí ó lòdì sí òfin.” (1 Peteru 1:1; 4:3, 4) Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọrun ń wo àwọn àríyá aláriwo gẹ́gẹ́ bí “iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn,” wọ́n ṣíwọ́ nínú lílọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ tí ó jọ carnival.—Romu 13:12-14.

Michael, tí a mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀, ṣe bákan náà. Ó ṣàlàyé ìdí rẹ̀ pé: “Bí ìmọ̀ mi nípa Bibeli ṣe ń pọ̀ sí i, mo rí i pé ayẹyẹ carnival àti àwọn ìlànà Bibeli dà bí epo àti omi—wọn kì í déédéé pò pọ̀.” Ní 1979, Michael pinnu lọ́kàn rẹ̀. Ó yọwọ́ nínú ṣíṣayẹyẹ carnival títí gbére. Yíyàn wo ni ìwọ yóò ṣe?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àgé ilẹ̀ Gíríìkì ṣáájú àkókò àwọn Kristian tí ń ṣàfihàn Dionysus (àwòrán ọwọ́ òsì)

[Credit Line]

Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da onínúure The British Museum

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́