Àṣejù Eré Ìmárale
ÌWÉ agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ pé: “Àwọn olùṣeré ìmárale láṣejù” ni “ohun àrà ọ̀tọ̀ tí ìlépa wíwà ní ipò ara yíyá gágá mú jáde.” Ìwé agbéròyìnjáde Star ròyìn pé, ṣíṣe eré ìmárale láṣejù ń pọ́n tọkùnrintobìnrin lójú. Àwọn dókítà àti àwọn aṣètọ́jú láìlo egbòogi kan sọ pé, àwọn ọkùnrin lè máa ṣe eré ìmárale láṣejù kí wọ́n baà lè tún pa dà ní okun bíi ti èwe, ṣùgbọ́n ìdí pàtàkì tí àwọn obìnrin fi ń ṣe eré ìmárale láṣejù sábà máa ń jẹ́ nítorí èrò òdì nípa ìrísí ara wọn àti ìṣiṣẹ́gbòdì àṣà ìjẹun wọn.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe eré ìmárale kí ìmọ̀lára àti ìrísí wọn baà lè sàn sí i àmọ́ lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ó wá di àṣejù eré ìmárale kìkì nítorí àìní kan láti ṣe eré ìmárale. Richard Suinn, afìṣemọ̀rònú nínú ọ̀ràn tó jẹ mọ́ eré ìdárayá tí ó tún ń gba onírúurú ẹgbẹ́ àwọn olùdíje Olympic nímọ̀ràn, sọ pé, àṣejù eré ìmárale ń fara hàn kedere nígbà tí a bá “gbé e karí ìfarajìn elérò ìmọ̀lára dípò ara yíyá gágá lọ́nà àfòyeṣe lásán.” Nígbà tí àwọn dókítà àti àwọn aṣètọ́jú láìlo egbòogi bá ń bá ìṣòro yìí jà, wọ́n ń gbìyànjú láti ṣàwárí irú ipa tí eré ìmárale ń ní lórí ìgbésí ayé àwọn àgbàtọ́jú. Bí wọ́n bá ń pa iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe kan tí ń gba àkókò pọ̀ mọ́ bíbójútó agboolé àti àwọn ọmọ, àṣejù eré ìmárale yóò ní ipa búburú lórí ìlera wọn. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Thomas Schwenk, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìpìlẹ̀ ìlera ìdílé, ti sọ, “ara wọ́n ṣì lè yá dáradára, àmọ́ kí ìdíwọ́ àlámọ̀rí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìdíwọ́ ẹnu iṣẹ́, làásìgbò ìdílé máa yọ wọ́n lẹ́nu.”
Ìwé agbéròyìnjáde Star náà to àwọn àmì ìkìlọ̀ kan tí a mọ̀ mọ́ àwọn tí ń sọ eré ìmárale di bárakú pé: ‘Yíyan eré ìmárale ẹlẹ́nìkan, bíi kẹ̀kẹ́ gígùn, lílúwẹ̀ẹ́, eré sísá tàbí gbígbé ohun wíwúwo; àìní ìṣètò eré ìmárale tí ó ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún; ìgbàgbọ́ pé eré ìmárale jẹ́ ọ̀ràn-anyàn àti pé àìṣe é kò ṣeé fara dà; àti ìfàsẹ́yìn tí ń dé bá àwọn apá ìgbésí ayé mìíràn.’
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ wíwà ní ipò ara yíyá gágá mọ àwọn àǹfààní ṣíṣe eré ìmárale níwọ̀nba ní àmọ̀jẹ́wọ́, wọ́n tún kìlọ̀ nípa àwọn ìpalára tí àṣejù eré ìmárale ń ṣe.—Tímótì Kíní 4:8.