“Òun Ni Ìwé Tí Ó Kọ́kọ́ Kà”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine sábà máa ń bá àwọn tí ń dúró láti wọ ọkọ̀ ojú irin sọ̀rọ̀. Wọ́n fún obìnrin kan tí ó fi ìfẹ́ hàn nínú Bíbélì ní ẹ̀dà ìwé náà, Iwe Itan Bibeli Mi, ìtẹ̀jáde kan tí o lo ọ̀pọ̀ àwòrán bí ó ti ń sọ àwọn ìtàn inú Bíbélì bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra.
Lẹ́yìn náà, obìnrin náà tún rí Ẹlẹ́rìí náà ní ibùdókọ̀ ojú irin kan náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìwé náà, ní ṣíṣàlàyé pé: “Ọmọkùnrin mi kì í fẹ́ ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Agbára káká ló fi ń gbé wọn kà. Àmọ́ nígbà tí mo fún un ní ìwé Itan Bibeli náà, ó rí àwọn àwòrán náà, ó sì ní ìfẹ́ ọkàn gidigidi láti kà á. Ó ka ìwé náà tán láàárín nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì. Òun ni ìwé tí ó kọ́kọ́ kà. Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ, inú rẹ̀ dùn láti mọ Ọlọ́run. Inú èmi náà sì ń dùn bí mo ṣe ń rí ìyípadà wọ̀nyí lára rẹ̀. Jọ̀wọ́ fún mi ní ohun mìíràn sí i kí n kà.”
Obìnrin mìíràn wà nítòsí, ó sì fetí kọ́ ọ̀rọ̀ yí. Ó béèrè bí òun náà bá lè rí ẹ̀dà kan ìwé náà, Iwe Itan Bibeli Mi, gbà. Ìwọ pẹ̀lú lè gba ìsọfunni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 256 yí gbà tàbí bí ẹnì kan ṣe lè kàn sí ọ nílé rẹ láti bá ọ jíròrò ìníyelórí ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa kíkọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.