ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/22 ojú ìwé 10-11
  • Ọjọ́ Ọ̀la Amọ́kànyọ̀ Fún Àwọn Ọmọ wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọjọ́ Ọ̀la Amọ́kànyọ̀ Fún Àwọn Ọmọ wa
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tí Wọ́n Bìkítà
  • Ìlérí Ọlọ́run Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Amọ́kànyọ̀
  • Ogun
    Jí!—2017
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́
    Jí!—1996
  • Bí Ogun Ṣe Máa Dópin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 10/22 ojú ìwé 10-11

Ọjọ́ Ọ̀la Amọ́kànyọ̀ Fún Àwọn Ọmọ wa

LÁTI ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí, àwọn ìjọba ayé ti ṣàkọsílẹ̀ oríṣiríṣi àdéhùn fún ìdáàbòbo àwọn aráàlú nígbà ogun, wọ́n sì ti buwọ́ lù ú. Ara wọn ni àwọn àdéhùn tí ó fàyè gba kí ìpèsè aṣọ pa pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́jú ìṣègùn àti oúnjẹ máa dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọdé. Àwọn àdéhùn àgbáyé ṣèlérí láti dáàbò bo àwọn ọmọdé lọ́wọ́ kíkó wọn nífà ìbálòpọ̀, ìdálóró, àti ìwà ipá. Àwọn àdéhùn tún fòfin de gbígba ẹnikẹ́ni tí kò tí ì pé ọmọ ọdún 15 sínú iṣẹ́ ológun adìhámọ́ra.

Ìwé The State of the World’s Children 1996, ìròyìn kan tí Àjọ Àkànlò Owó ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ṣe, kan sáárá sí àwọn òfin wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí “ojúlówó ìṣẹ̀lẹ̀ ìyípadà ńlá,” ó sì fi kún un pé: “Ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí àwọn òṣèlú tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n wà tí a lè wá fi mọ irù ẹni tí àwọn jẹ́ gbé àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n wọ̀nyẹn yẹ̀ wò nínú ìwéwèé wọn.”

Dájúdájú, àwọn òṣèlú tún mọ̀ pé àwùjọ àgbáyé kì í sábà ní agbára ìṣe àti ìfẹ́ inú láti mú àwọn òfin ṣẹ. Ìròyìn náà wá gbà pé, “lójú àyè tí a ti ṣàìka àwọn ìlànà wọ̀nyí sí dé, ó rọrùn láti ṣàìgbọràn sí àkójọ òfin àgbáyé.”

Lẹ́yìn náà, ọ̀ràn owó wà níbẹ̀. Ní 1993, ìforígbárí bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè 79. Márùndínláàádọ́rin lára wọn ló jẹ́ orílẹ̀-èdè tó tòṣì. Ibo ni àwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì wọ̀nyí ti ń rí àwọn ohun ìjà tí wọ́n ń lò? Ọ̀pọ̀ jù lọ ń wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀. Àwọn márùn-ún wo sì ni wọ́n mú ipò iwájú lára àwọn tí ń ta ohun ìdìhámọ́ra fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà? Àwọn orílẹ̀-èdè márùn-ún tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà títí lọ nínú Ìgbìmọ̀ Ààbò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni!

Àwọn Tí Wọ́n Bìkítà

Dájúdájú, àwọn kan wà tí wọ́n bìkítà gidigidi nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọdé nígbà ogun. Tìfẹ́tìfẹ́ ni àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwọn àjọ ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọdé tí ń jìyà ìpalára ogun. Fún àpẹẹrẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọn kì í lọ́wọ́ nínú ogun, ti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ mímú ìfìyàjẹ àwọn ọmọdé nígbà ogun kúrò túmọ̀ sí mímú ogun fúnra rẹ̀ kúrò ní gidi, ìfojúsọ́nà kan tí ó lè jọ pé kò ṣeé ṣe. Nítorí àkójọ àkọsílẹ̀ gbọ́nmisi-omi-òto àti ìforígbárí púpọ̀ tí aráyé ní, ọ̀pọ̀ ènìyàn parí èrò sí pé ẹ̀dá ènìyàn kò lè mú àlàáfíà jákèjádò ayé wá láé. Lọ́nà yí, wọ́n tọ̀nà.

Àwọn ènìyàn tún parí èrò sí pé Ọlọ́run kò ní dá sí àlámọ̀rí àwọn orílẹ̀-èdè tàbí kí ó mú àlàáfíà wá fún pílánẹ́ẹ̀tì náà láé. Lọ́nà yí, wọn kò tọ̀nà.

Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, bìkítà gan-an nípa àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, Jèhófà béèrè pé: “Èmi ha ní inú dídùn rárá pé kí ènìyàn búburú kí ó kú? . . . [bí] kò ṣe pé kí ó yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì yè?” Ọlọ́run fi ìtẹnumọ́ dáhùn pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni tí ó kú.”—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:23, 32.

Rò ó wò ná: Bí Ẹlẹ́dàá wa oníyọ̀ọ́nú bá fẹ́ kí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ ẹni búburú pàápàá ronú pìwà dà, kí wọ́n sì gbádùn ìwàláàyè, dájúdájú, ó fẹ́ kí àwọn ọmọdé wà láàyè, kí wọ́n sì gbádùn ìwàláàyè pẹ̀lú! Síbẹ̀, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ kò ní fàyè gba ìwà búburú títí ayé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé: “A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò . . . Nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí.”—Orin Dáfídì 37:9, 10.

Jésù Kristi, tí ó ṣàgbéyọ àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀ ọ̀run lọ́nà pípé, nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé, ó sì sọ pé, “ìjọba àwọn ọ̀run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.” (Mátíù 19:14) Fífi àwọn ọmọdé rúbọ sí àwọn ọlọ́run ogun jẹ́ ohun ìríra sí Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi.—Fi wé Diutarónómì 18:10, 12.

Ìlérí Ọlọ́run Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Amọ́kànyọ̀

Ọlọ́run ti fàyè gba ogun àti ìjìyà láti àwọn ọ̀rúndún púpọ̀ wá kí òtítọ́ tí wòlíì Jeremáyà sọ baà lè fìdí múlẹ̀ títí ayérayé pé: “Olúwa! èmi mọ̀ pé, ọ̀nà ènìyàn kò sí ní ipa ara rẹ̀: kò sí ní ipa ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Bíbélì ṣèlérí pé, láìpẹ́, Jèhófà yóò dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre nípa ‘mímú ọ̀tẹ̀ tán dé òpin ayé.’ (Orin Dáfídì 46:9) Bákan náà ni a tún sọ tẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì nípa àkókò tí “[àwọn ènìyàn] ó fi idà wọn rọ [abẹ ohun ìtúlẹ̀, NW], wọ́n ó sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.”—Aísáyà 2:4.

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ogun ti gbẹ̀mí wọn? Ìrètí kankan ha wà fún wọn bí? Jésù ṣèlérí àjíǹde àwọn òkú sórí ilẹ̀ ayé tí kò ní sí ogun, ní wíwí pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nínú èyí tí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àwọn ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìgbọ́kànlé sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.

Ó dájú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò ní ìmúṣẹ. Ó ní agbára àti ìmúratán láti ṣe gbogbo ohun tí ó ti pète. (Aísáyà 55:11) Nígbà tí Jèhófà sọ pé òun yóò mú ogun kúrò, kò fi ṣeré. Nígbà tí ó ṣèlérí láti jí àwọn tí wọ́n ti kú dìde sí ìyè, yóò ṣe é. Gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ti sọ, “lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Lúùkù 1:37.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nígbà tí kò bá sí ogun mọ́, gbogbo ọmọdé yóò gbádùn ìgbésí ayé gbígbámúṣé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́